Ǹjẹ́ O Ti Múra Tán Láti Kọrin sí Jèhófà Láwọn Ìpàdé Ìjọ?
1 Nígbà tá a bá ń múra sílẹ̀ láti kópa ní àwọn ìpàdé ìjọ, ó yẹ ká máa múra láti kọ àwọn orin ìyìn. Gbé àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
2 Mọ Ìtumọ̀ Àwọn Ọ̀rọ̀ Orin Náà: Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé orin kọ̀ọ̀kan kà àti àwọn èyí tá a tò sí ìparí àwọn orin náà máa jẹ́ ká mọ bí àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn ṣe bá Ìwé Mímọ́ mu.
3 Ẹ Máa Fi Dánra Wò: Ẹ lè lo díẹ̀ lára àkókò tẹ́ ẹ fi ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti máa fi àwọn orin tuntun náà dánra wò, kẹ́ ẹ lè mọ̀ ọ́n kọ. Ohùn orin tá a fi dùrù kọ tá a máa lò ní ìpàdé ìjọ ni kẹ́ ẹ lò nígbà tẹ́ ẹ bá fi ń dánra wò. Ẹ tún lè kọ́ díẹ̀ lára ohùn àwọn orin tuntun náà tẹ́ ẹ bá tẹ́tí sí àwo orin tá a fi ẹnu kọ lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Sing to Jehovah—Vocal Renditions, Disc 1.
4 Ǹjẹ́ wàá ti múra tán nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí lo ìwé orin tuntun náà, Kọrin sí Jèhófà láwọn ìpàdé ìjọ bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ April 5, ọdún 2010? Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ bó o bá wáyè láti mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn orin náà, tó o sì ń kọ wọ́n láti fi dánra wò.