ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/14 ojú ìwé 7
  • Àwọn Orin Tuntun Tí A Ó Máa Lò Nínú Ìjọsìn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Orin Tuntun Tí A Ó Máa Lò Nínú Ìjọsìn!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Orin Yin Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Ǹjẹ́ O Ti Múra Tán Láti Kọrin sí Jèhófà Láwọn Ìpàdé Ìjọ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Kọrin Sí Jèhófà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 12/14 ojú ìwé 7

Àwọn Orin Tuntun Tí A Ó Máa Lò Nínú Ìjọsìn!

1 Ní ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, tó wáyé ní October 4, 2014, a ṣèfilọ̀ pé a ó tún ìwé orin wa tí à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ ṣe. Ìròyìn ayọ̀ mà nìyẹn o! A rán gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà létí pé àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn wa.—Sm. 96:2.

2 O lè máa rò ó pé, ‘Kí nìdí tó fi pọn dandan ká ṣàtúnṣe sí ìwé orin wa?’ Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú ká ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àtúnṣe máa ń bá òye wa nípa àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́, èyí sì gba pé ká ṣe àtúnṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ orin wa bákan náà. (Òwe 4:18) Ìdí míì ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò nínú ìwé orin tí à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ la mú jáde látinú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti tẹ́lẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àfi ká ṣàtúnṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn báyìí kó lè bá àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò nínú ẹ̀dà Bíbélì tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì mu. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ kékeré kọ́ lá máa ṣe kí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà tó lè bá òye tuntun tá a ní báyìí mu, a pinnu pé àwọn orin tuntun díẹ̀ la ó fi kún ìwé orin náà.

3 Ṣé ó dìgbà tí a bá tẹ ìwé orin tuntun jáde ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn orin tuntun yìí ni? Rárá o. Inú wa dùn láti sọ fún yín pé àwọn orin tuntun yìí yóò wà lórí ìkànnì jw.org láwọn oṣù díẹ̀ sí i. Tí orin tuntun kan bá ti jáde, a ó fi sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ pé ká kọ ọ́ níparí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ọ̀rọ̀ náà, “orin tuntun” la ó máa fi dáa mọ̀.

4 Bí A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Orin Tuntun Náà: Kò rọrùn láti kọ́ orin tuntun, àmọ́ bíi ti onísáàmù náà, a kò ní fẹ́ “dákẹ́ jẹ́ẹ́” tá a bá ń kọrin láwọn ìpàdé ìjọ. (Sm. 30:12) Àwọn ohun tó o lè ṣe rèé tó o bá fẹ́ mọ orin tuntun.

  • Máa gbọ́ ohùn orin tá a fi dùrù kọ tí a máa gbé sórí Ìkànnì wa ní àgbọ́túngbọ́. Bí o bá ṣe ń gbọ́ ohùn orin náà léraléra tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rọrùn fún ẹ tó láti máa rántí rẹ̀.

  • Mọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà, kó o sì gbìyànjú láti há wọn sórí.

  • Máa kọ ọ̀rọ̀ orin náà tẹ̀ lé ohùn rẹ̀. Máa kọ ọ́ títí wàá fi mọ̀ ọ́n kọ dáadáa.

  • Máa lo àkókò díẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé rẹ láti fi àwọn orin tuntun náà dánra wò títí gbogbo ìdílé rẹ yóò fi mọ̀ ọ́n kọ.

5 Ní àwọn oṣù tó ń bọ̀, tí a bá fi orin tuntun sí ìparí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, àwọn ará á kọ́kọ́ tẹ́tí sí ohùn orin náà tá a fi dùrù kọ. Lẹ́yìn náà, àwọn ará yóò kọ orín náà tẹ̀ lé ohùn orin bí a ti máa ń ṣe tá a bá ń kọ àwọn orin tó kù.

6 Tí ìwọ náà bá rò ó wò, wàá rí i pé ńṣe la máa ń pa ohùn wa pọ̀ láti yin Jèhófà tá a bá ń kọrin láwọn ìpàdé wa. Torí náà, kò ní dára ká sọ ọ́ di àṣà wa láti máa dìde kúrò láyè wa láì nídìí nígbà tí a bá fẹ́ kọrin ní àwọn ìpàdé wa.

7 Ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà fi hàn pé a mọrírì àwọn orin wa tó jẹ́ mímọ́. Ní àwọn ìpàdé àyíká àti àgbègbè, a máa ń gbọ́ ohùn orin ká tó bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa láti àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé tí wọ́n fi ara wọn jìn máa ń sanwó ọkọ̀ ara wọn wá sí Patterson, New York, kí wọ́n lè ṣe orin aládùn tí a máa lò nínú ìjọsìn wa. Nígbà náà, bí ẹni tó jẹ́ alága láwọn àpéjọ bá sọ fún wa pé ká jókòó, ká sì tẹ́tí sí ohùn orin tá a ti ṣètò sílẹ̀, ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́gán. Èyí máa jẹ́ ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀ de àwọn nǹkan tá a máa gbádùn.—Ẹ́sírà 7:10.

8 A máa kọ orin tuntun tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!” ní ìparí ìpàdé tòní. Ìpàdé ọdọọdún tí a ṣe láìpẹ́ yìí ni a ti kọ orin yìí, a sì dìídì ṣe é ni láti fi sàmì ọgọ́rùn-ún ọdún tí a gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ ní ọ̀run.

9 Ó dájú pé “àwọn ohun rere” látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn orin tuntun yìí. (Mát. 12:35á) Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa kọ́ àwọn orin tuntun yìí, a ó sì máa fi tọkàntọkàn kọ wọ́n, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ máa fi ìyìn àti ọlá fún Ọlọ́run wa!—Sm. 147:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́