ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 December ojú ìwé 5
  • Fi Orin Yin Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Orin Yin Jèhófà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Kọrin Ìyìn Sí Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Orin Ìjọba Ọlọ́run Máa Ń Jẹ́ Ká Nígboyà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àwọn Orin Tuntun Tí A Ó Máa Lò Nínú Ìjọsìn!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 December ojú ìwé 5
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà Orin 84: Wá Wọn Lọ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Orin Yin Jèhófà

Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi orin yin Jèhófà nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n. (Iṣe 16:25) Ó dájú pé orin tí wọ́n ń kọ yẹn fún wọn lókun láti fara da ipò tí wọ́n wà. Àwa náà ńkọ́ lónìí? Tá a bá wà nínú ìṣòro, àwọn orin tá à ń lò ní ìpàdé àti àwọn orin tí wọ́n fẹnu kọ máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Àmọ́ ju gbogbo ìyẹn lọ, àwọn orin yẹn tún máa ń fìyìn fún Jèhófà. (Sm 28:7) Ó ti pẹ́ tí ètò Ọlọ́run ti máa ń rọ̀ wá pé ká gbìyànjú láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sórí. Ṣé o ti ṣe bẹ́ẹ̀? A lè fi àwọn orin yẹn dánra wò ká sì kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn nígbà ìjọsìn ìdílé.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN ỌMỌDÉ Ń FI ORIN YIN JÈHÓFÀ, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì ń kọ orin ní yàrá ìgbohùnsílẹ̀

    Tá a bá ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run, àǹfààní wo ló máa ṣe fún wa?

  • Arábìnrin kan ń múra àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n tó lọ kọ orin

    Báwo làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń gbohùn sílẹ̀ ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún àwọn tó fẹ́ wá kọrin?

  • Ìdílé kan ń kọ orin nígbà ìjọsìn ìdílé

    Báwo làwọn ọmọdé àti ìdílé wọn ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún orin tí wọ́n fẹ́ lọ kọ?

  • Àwọn ọmọdé ń kọ orin

    Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wo lo fẹ́ràn jù, kí sì nìdí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́