ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/06 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 3/06 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 13

Orin 41

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 15 àti Jí! January-March lọni. (Lo àbá kẹta fún Jí! January-March) Ní ìparí ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ní kí akéde náà pe onílé wá síbi Ìrántí Ikú Kristi nípa lílo èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn náà.

20 min: Ipa Tí Kristi Ń Kó Nínú Ìṣètò Ọlọ́run. Àsọyé tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 10 sí 13. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ méjì àkọ́kọ́ lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ipa Tí Kristi Ń Kó,” lo ìṣẹ́jú mẹ́ta tàbí mẹ́rin láti dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìkésíni náà. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2006, ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 3.

15 min: “Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Nínú Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àṣefihàn tó dá lórí ojú ìwé 3 nínú àkìbọnú. Ká tètè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti máa kọ́ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣètò àṣefihàn mẹ́ta tá a múra sílẹ̀ dáadáa, tí yóò fi hàn bá a ṣe lè fi ohun tó wà ní (1) ojú ìwé 4 sí 5, (2) ojú ìwé 6 àti (3) ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 7, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá a bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò. Jẹ́ káwọn ará mọ ohun tí wọ́n á máa fojú sọ́nà fún nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kó o sì jíròrò kókó náà pẹ̀lú wọn lẹ́yìn àṣefihàn ọ̀hún. A lè máà pẹ́ púpọ̀ lórí ìjíròrò àwọn ìpínrọ̀ kan nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ní ìparí àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí akéde bá onílé ṣàdéhùn pé òun ń padà bọ̀ wá bẹ̀ ẹ́ wò.

Orin 125 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 20

Orin 18

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àpótí náà, “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi.”

15 min: “Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jọlá Ẹbọ Ìràpadà.”a Ìjíròrò tó tẹ̀lé èyí yóò sọ bá a ṣe lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ojú ìwé 206 sí 208 láti fi pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi.

20 min: Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ń Ṣe Láti Bọlá fún Ọlọ́run. Darí ìjíròrò náà tó dá lórí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ojú ìwé 206 sí 208 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò tó ìṣẹ́jú kan láti fi hàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá onílé jíròrò kókó náà nípa kíka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà kó o wá ní kí àwùjọ dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀lé e yìí láìka àwọn ìpínrọ̀ náà: (ìpínrọ̀ 2) Ìgbà wo ni Jésù fi Ìrántí Ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀? (ìpínrọ̀ 3) Báwo ló ṣe yẹ kí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa máa wáyé lemọ́lemọ́ tó? (ìpínrọ̀ 4) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Ìrántí Ikú Kristi? (ìpínrọ̀ 5) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò yí ẹran ara rẹ̀ padà sí búrẹ́dì, àti pé kò yí ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ padà sí wáìnì? (ìpínrọ̀ 6) Kí ni búrẹ́dì aláìwú túmọ̀ sí? (ìpínrọ̀ 7) Kí ni wáìnì pupa túmọ̀ sí? (ìpínrọ̀ 8) Ta ló yẹ kó jẹ nínú búrẹ́dì, kó sì mu nínú wáìnì náà? (ìpínrọ̀ 9) Ìgbà wo la máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, kí sì nìdí tó fi yẹ ká wà níbẹ̀? Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì tó wà níbẹ̀ bí àkókò bá ṣe wà sí. Gba gbogbo gbòò níyànjú láti jíròrò àwọn àlàyé yìí pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn míì tí wọ́n máa ń pè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi nípa kíka àwọn ìpínrọ̀ tá a mẹ́nu bà lókè yìí. Jíròrò àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ kó o sì rí i pé àwọn ìbéèrè tó rọrùn láti dáhùn bí irú èyí tá a béèrè lábẹ́ ìjíròrò yìí lo lò.

Orin 134 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 27

Orin 44

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù March sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tá à ń ṣe. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! January-March. (Lo àbá kẹrin fún Jí! January-March.) Kó o sì tún fi hàn bá a ṣe lè lo ìwé ìkésíni tá a tẹ̀ láti pe àwọn tó bá fìfẹ́ hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

15 min: Ìrírí táwọn ará ní. Ní kí àwùjọ sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lóṣù March. Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. O lè ṣe àṣefihàn ìrírí kan tàbí méjì tó fa kíki.

15 min: “Kọ́ Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Láti Máa Rìn Lọ́nà Tí Ọlọ́run Fẹ́.”b Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2004, ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 9.

Orin 170 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 3

Orin 199

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní ṣókí, ṣàgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, “Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan an? Ká sì Gbádùn Rẹ̀” tó wà lójú ìwé 6 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2006. Sọ̀rọ̀ lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Kó o sì tún fi hàn bá a ṣe lè lo ìwé ìkésíni tá a tẹ̀ láti pe àwọn tó bá fìfẹ́ hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

15 min: Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Máa Múra Sílẹ̀. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2005, ojú ìwé 4, apá 4. O tún lè fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2004, ojú ìwé 1. Lo àpèjúwe láti jẹ́ kí kókó náà ṣe kedere nípa mímú àpẹẹrẹ látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, orí 1.

20 min: Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ Ń Fún Wa Lókun. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2006. Ṣe àṣefihàn ìdílé kan tó ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ ti ọjọ́ náà pa pọ̀.

Orin 93 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́