Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 18
Orin 120 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 6 ìpínrọ̀ 19 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 78 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Lúùkù 1-3 (10 min.)
No. 1: Lúùkù 1:24-45 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìyàtọ̀ Wo Ló Wà Láàárín Ọkàn àti Ẹ̀mí?—td 40B (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?—td 13A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
12 min: “Ẹ Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe àṣefihàn alápá méjì tó dá lórí bí akéde kan ṣe lo ìdánúṣe láti kí àlejò kan káàbọ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sì parí, ó béèrè àwọn ìsọfúnni tó yẹ lọ́wọ́ àlejò náà kó lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀.
18 min: “Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi ìṣẹ́jú méje ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń jíròrò ẹ̀kọ́ kan nínú ìwé náà pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Orin 20 àti Àdúrà