Sáàmù
Àdúrà ẹni tí ìnilára bá nígbà tí nǹkan tojú sú u,* tó sì ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ níwájú Jèhófà.+
2 Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi nígbà tí mo wà nínú wàhálà.+
3 Nítorí àwọn ọjọ́ mi ń pa rẹ́ lọ bí èéfín,
Àwọn egungun mi sì ti di dúdú bí ibi ìdáná.+
4 Ọkàn mi dà bíi koríko tí a gé, tó sì ti rọ,+
Nítorí mi ò rántí jẹ oúnjẹ mi.
6 Mo dà bí ẹyẹ òfú tó wà ní aginjù;
Mo dà bí òwìwí kékeré tó wà láàárín àwókù.
8 Àwọn ọ̀tá mi ń pẹ̀gàn mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
Àwọn tó ń fi mí ṣẹ̀sín* ń lo orúkọ mi tí wọ́n bá fẹ́ gégùn-ún.
9 Eérú ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ,+
Omijé sì ti dà pọ̀ mọ́ ohun tí mò ń mu,+
10 Nítorí ìbínú rẹ àti ìrunú rẹ,
O gbé mi sókè kí o lè jù mí sí ẹ̀gbẹ́ kan.
13 Ó dájú pé wàá dìde, wàá sì ṣàánú Síónì,+
Torí àkókò ti tó láti ṣe ojú rere sí i;+
Àkókò tí a dá ti pé.+
15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,
Gbogbo ọba ayé yóò sì máa bẹ̀rù ògo rẹ.+
19 Ó ń bojú wolẹ̀ láti ibi gíga rẹ̀ mímọ́,+
Láti ọ̀run, Jèhófà ń wo ayé,
20 Kí ó lè gbọ́ bí ẹlẹ́wọ̀n ṣe ń kérora,+
Kí ó lè dá àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún sílẹ̀,+
21 Ká lè kéde orúkọ Jèhófà ní Síónì+
Àti ìyìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,
22 Nígbà tí àwọn èèyàn àti àwọn ìjọba
Bá kóra jọ láti sin Jèhófà.+
23 Ó gba agbára mi láìtọ́jọ́;
Ó gé ọjọ́ ayé mi kúrú.
26 Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó;
Gbogbo wọn á gbó bí aṣọ.
Wàá pààrọ̀ wọn bí aṣọ, wọn ò sì ní sí mọ́.
27 Àmọ́ ìwọ kò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ kò sì ní dópin láé.+
28 Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò máa wà láìséwu,
A ó sì fìdí àtọmọdọ́mọ wọn múlẹ̀ gbọn-in níwájú rẹ.”+