Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 14
Orin 72 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 17 ìpínrọ̀ 16 sí 20, àti àpótí tó wà lójú ìwé 181 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì Kíkà: Nehemáyà 9-11 (10 min.)
No. 1: Nehemáyà 11:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Tó Máa Gba Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Kò Lóǹkà—td 33D (5 min.)
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Gbà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn—1 Pét. 4:10 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
12 min: Bá A Ṣe Lè Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Pẹ̀lú Ẹni Tí A Kò Mọ̀ Rí. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 62 sí 64. Ní ṣókí fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó mọ béèyàn ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nígbà tó bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà tàbí nígbà tó bá ń wàásù láti ilé dé ilé.
18 min: “Àkókò Ìrántí Ikú Kristi Máa Ń Jẹ́ Ká Lè Fi Kún Ìgbòkègbodò Wa!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó apá yìí. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò àpilẹ̀kọ náà, sọ ètò ti ìjọ ṣe lórí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá láàárín oṣù March, April àti May. Sọ onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣètò ara rẹ̀ lọ́nà táá fi lè lo àádọ́ta wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá láàárín oṣù kan. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún tó kọjá bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wọn dí tàbí tí wọ́n ní àìlera.
Orin 8 àti Àdúrà