Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ January 1
Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:16,17. Kó o wá sọ pé: “Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Ádámù máa dẹ́ṣẹ̀. Àwọn míì rò pé ìwà àgàbàgebè ni ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn ì bá jẹ́ ká sọ pé ó ti mọ̀ pé wọ́n máa dẹ́ṣẹ̀. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 13 ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”
Ji! January–March
“Ka Jákọ́bù 3:7, 8. Kó o wá sọ pé: “Ǹjẹ́ o gbà pé ó ṣòro láti kó ahọ́n wa níjàánu? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì tá a lè lò ká lè túbọ̀ máa kó ẹ̀yà ara wa tó kéré, àmọ́ tó lágbára gan-an yìí ní ìjánu.” Lo àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 30.”
Ilé Ìṣọ́ February 1
“Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló sábà máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ lóde òní. Kí lo rò pé ó ń fà á? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ìmọ̀ràn yìí tó ti ṣe ọ̀pọ̀ tọkọtaya láǹfààní. [Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ohun mẹ́fà tó sábà máa ń jẹ́ ìṣòro àwọn tọkọtaya, ó sì sọ bí títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.”
Ji! January–March
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń béèrè pé: ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà, kí nìdí tí kò fi pa Èṣù run?’ Ǹjẹ́ irú èrò yẹn ti wá sí ìwọ náà lọ́kàn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 10 àti 11 fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí. Ó tún sọ bí ayé ṣe máa rí nígbà tí Ọlọ́run bá pa Èṣù run.” Ka Ìṣípayá 21:3, 4.