Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú yín á dùn láti mọ̀ pé ní òpin ọdún iṣẹ́ ìsìn 2010, àwọn àkéde tó ròyìn ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún ó lé ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́rìnlélógójì [320,266]. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ròyìn náà sì pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàafà àti méjìlélọ́gọ́jọ [31,162], ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a darí jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn-ún [687,104]. Láfikún sí i, àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé mọ́kànléláàádọ́ta [14,051] tó ṣe ìrìbọmi lọ́dún iṣẹ́ ìsìn náà ju iye àwọn tó ṣe ìrìbọmi lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá lọ.