Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní January: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. February: Ẹ lè lo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa mí ì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Báwo Ni Òtítọ́ Ṣe Ń Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Rẹ?”
◼ Inú wa dùn láti fi tó yín létí pé lọ́dún 2010, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Benin City ní March 12-13 àti June 26; Badagry ní April 2-3 àti August 14; Lekki ní June 11-12 àti February 12; Uli ní August 20-21 àti June 19. Bákan náà, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe lédè Faransé ní: Bàdágìrì ní April 30 sí May 1 àti August 6. Èdè Faransé àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà la máa fi ṣe àwọn àpéjọ yìí látòkèdélẹ̀. A ké sí gbogbo àwọn tó gbọ́ àwọn èdè yìí pé kí wọ́n wá.