ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/08 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 1/08 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tó bá ti wà ṣáájú ọdún 1991 tàbí ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó bá wà lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ẹ lo ìwé Kí ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Ẹ sapá lákànṣe láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́ hàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n sì tún wá gbọ́ àwíyé àkànṣe àmọ́ tí wọn kì í wá sípàdé ìjọ déédéé. Ìdí tẹ́ ẹ fi fẹ́ padà bẹ̀ wọ́n wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ Níwọ̀n bí oṣù March ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February tàbí ó pẹ́ tán ní March 2, àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ọ̀dọ̀ Ta Lo Ti Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro?”

◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí ní ọjọ́ Sátidé, March 22, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀, àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan gbìyànjú láti dá Ìrántí Ikú Kristi ṣe. Àmọ́, ó lè má ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ni wọ́n ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára wọn lè lọ gba ibòmíràn tí wọ́n máa lò lálẹ́ ọjọ́ yẹn. A dábàá pé níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ó kéré tán kí ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín ìgbà tí ìjọ kan bá ṣe tán kí ìjọ kejì tó bẹ̀rẹ̀ tiwọn, kí gbogbo àwọn tó bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lè ráyè kíra wọn. Ó yẹ ká ronú nípa bí àwọn ọkọ̀ tá a máa gbé wá kò ṣe ní ṣèdíwọ́, ká sì tún ronú nípa ibi tá a máa gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò sílẹ̀ àti gbígbé èrò. Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ fún ìjọ wọn.

◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ rí i pé lẹ́tà tá a fi yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn S-202, wà nínú fáìlì ìjọ. Bí ti aṣáájú-ọ̀nà èyíkéyìí ò bá sí níbẹ̀, kí akọ̀wé kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti béèrè fún un.

◼ Láti ọ̀sẹ̀ August 4, 2008, ìwé Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn la máa bẹ̀rẹ̀ sí kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

◼ Àwọn kan ti ń béèrè pé àwọn wo ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan la lẹ́tọ̀ọ́ láti gba àwọn ìwé wọ̀nyí, nítorí náà a ò gbọ́dọ̀ fún àwọn tó fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ wa lóde ẹ̀rí tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ la ò gbọ́dọ̀ fún àwọn ọ̀rẹ́ wa. Àwọn ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìwé Jàǹfààní. Ní tàwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìwé A Ṣètò Wa, ìwé yẹn alára sọ lójú ìwé 81 ìpínrọ̀ kẹta pé: “Bí àwọn alàgbà bá ti lè pinnu pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti yẹ lẹ́ni tó lè máa bá àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí, ó ti yẹ lẹ́ni tó lè ní ẹ̀dà kan ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà.” Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ máa kó àwọn ìwé wọ̀nyí sórí tábìlì tá a ti ń gbàwé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

◼ Àwo DVD Tuntun Tó Wà:

The Bible—A Book of Fact and Prophecy lórí àwo DVD (dvbbl) (Apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí fídíò yìí pín sí ló wà lórí àwo DVD yìí, ìyẹn The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy; The Bible—Mankind’s Oldest Modern Book àti The Bible—Its Power in Your Life)

◼ Láwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tó máa wáyé lọ́dún 2008, a ó ya àwọn ibì kan sọ́tọ̀ fáwọn adití láwọn àpéjọ tá a tò sísàlẹ̀ yìí. Ibi tá a bá sì yà sọ́tọ̀ fún wọn yìí la ti máa túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà Ti Amẹ́ríkà:

Akábọ (EE-08) March 29 àti August 16 sí 17

Àkúrẹ́ (WE-12) April 19 àti August 23 sí 24

Àwì (EE-21) March 16 àti June 7 sí 8

Bàdágìrì (WE-02) May 3 àti August 16 sí 17

Bàdágìrì (WE-04) February 2 sí 3 àti June 7

Bàdágìrì (WE-14) May 4 àti September 6 sí 7

Bàdágìrì (WE-23) February 9 sí 10 àti June 8

Benin City (ME-01) April 27 àti September 27 sí 28

Dálùwọ́n (WE-01) May 3 sí 4 àti August 16

Dálùwọ́n (WE-03) May 10 sí 11 àti August 17

Dálùwọ́n (WE-13) March 1 sí 2 àti June 15

Dálùwọ́n (WE-22) June 7 sí 8 àti September 14

Dálùwọ́n (WE-29) June 29 àti September 27 sí 28

Ẹnúgu (EE-17) May 25 àti September 27 sí 28

Ẹnúgu (EE-19) April 13 àti July 12 sí 13

Ìbàdàn (WE-09) March 9 àti August 2 sí 3

Ìbàdàn (WE-10) April 6 àti September 6 sí 7

Igurúta Àlì (EE-22) March 15 sí 16 àti August 9

Iléṣà (WE-15) March 29 sí 30 àti July 5

Ìlọrin (WE-17) March 2 àti July 19 sí 20

Kàdúná (NE-01b) April 12 sí 13 àti August 23

Ọ̀tà (WE-05) February 3 àti June 21 sí 22

Ọ̀tà (WE-06) March 8 sí 9 àti June 28

Ọ̀tà (WE-07) February 10 àti July 12 sí 13

Ọ̀tà (WE-25) February 16 àti July 19 sí 20

Ùbogò (ME-07) March 29 sí 30 àti July 12

Ùlì (EE-24) February 10 àti June 28 sí 29

Uyó (EE-20) March 1 sí 2 àti June 22

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́