ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/02 ojú ìwé 3
  • “Ẹ . . . Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ . . . Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti ‘Ṣiṣẹ́ Kára Ká sì Là Kàkà’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 4/02 ojú ìwé 3

“Ẹ . . . Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”

1 “Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Kíkún” àti “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà” ni àwọn àkọlé tá a lò nínú àwọn àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February àti March 2002. (Kól. 1:25; 1 Tím. 6:18) Nínú àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyẹn, a fún wa níṣìírí pé kí a túbọ̀ sapá láti ran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sí Ìṣe Ìrántí, láti ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tún máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i, àti láti ran àwọn ọmọ wa àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó tóótun lọ́wọ́ kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí kéde ìhìn rere. Kò sí àní-àní pé a ti ṣàṣeyọrí dé ìwọ̀n àyè kan látàrí bá a ṣe sapá taápọntaápọn. Nítorí náà, “níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa [bá a nìṣó ní ṣíṣe] ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”—Gál. 6:10.

2 Ké sí Wọn Láti Tún Máa Pésẹ̀ sí Ìpàdé Ìjọ: Ní ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ ẹ̀ka Nàìjíríà, iye àwọn èèyàn tó lé ní 250,000 ló máa ń wá sí ibi Ìṣe Ìrántí lọ́dọọdún bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe akéde ìhìn rere. Níwọ̀n bí wíwá tí wọ́n ń wá ti fi hàn pé wọ́n fi ìfẹ́ hàn dé ìwọ̀n àyè kan, kí ló yẹ ká ṣe láti mú kí àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun di onígbàgbọ́”? (Ìṣe 13:48) Ẹ jẹ́ ká fún wọn níṣìírí láti tún máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ bó bá ti lè ṣeé ṣe kó yá tó.

3 Èé ṣe tó ò fi ké sí olùfìfẹ́hàn kan láti máa bá ọ lọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, kóun náà lè gbádùn ìjíròrò alárinrin tá a máa ń ní bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà? Bó bá jẹ́ pé ìbátan rẹ tàbí ojúlùmọ̀ rẹ ni onítọ̀hún, tá a sì ti yan apá kan fún ọ láti bójú tó ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, o lè ké sí i láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Máa sọ àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tá a máa gbọ́ láwọn ọ̀sẹ̀ tó wà níwájú fún un. (Ẹ rí i pé ẹ ń lẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àsọyé tó bágbà mu mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.) Máa lo àǹfààní èyíkéyìí tó bá ṣí sílẹ̀ láti máa ta ìfẹ́ rẹ̀ jí kó bàa lè jọ́sìn Jèhófà. Síwájú sí i, bí ẹnì kan nínú ìjọ kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè fi pẹ̀lẹ́tù nawọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ sí i.

4 Ẹ Máa Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí: Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń wá sí ibi Ìṣe Ìrántí ló ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Àmọ́, nígbà tó di àkókò kan, wọ́n dáwọ́ fífi ìtara wàásù ìhìn rere náà dúró. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti “máa ṣe ohun rere . . . ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Nítorí náà, àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ jẹ́ àwọn ẹni tó yẹ ká ní lọ́kàn ní pàtàkì láti máa ṣe ohun rere sí.

5 Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ ìṣírí tí àwọn alàgbà àtàwọn ẹlòmíràn sọ fún àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kan ti sún wọn láti tún máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí àwọn alàgbà bá yàn ọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú akéde kan tó ti bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i, o ní láti mọ̀ pé ìfẹ́ tí ìwọ fúnra rẹ ní fún Jèhófà àti fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni yóò jẹ́ kí onítọ̀hún lè fi ìgboyà wàásù. Jẹ́ kí ó rí i bí o ṣe ń lọ́wọ́ nínú onírúurú apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí òun náà bàa lè rí ayọ̀ nínú rẹ̀, kí ó bàa lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó, kí ó sì lè gba ìbùkún Jèhófà.

6 Ẹ Fi Ìpìlẹ̀ Tó Dára Lélẹ̀ fún Àwọn Akéde Tuntun Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù: Nígbà tí obìnrin olùfìfẹ́hàn kan mọ̀ pé òun ti rí ètò àjọ Ọlọ́run tòótọ́, ojú ẹsẹ̀ ló ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó yẹ kó ṣe, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” Bá a bá ti fọwọ́ sí i pé kí ẹni tó ò ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, jẹ́ kí ó mọ ìjẹ́pàtàkì ‘títètè bẹ̀rẹ̀,’ nípa báyìí, wàá lè fi ìpìlẹ̀ tó dára lélẹ̀ fún akéde tuntun náà. Ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí yóò máa lò láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó sì máa kópa nínú rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

7 Bó bá jẹ́ pé ọmọ rẹ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, bá a ṣiṣẹ́ kó o sì ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí àti agbára rẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ, yóò jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ pé yóó lè fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn lọ́nà tó máa fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn, yóó lè máa ka Bíbélì lọ́nà tó já geere, yóó sì lè máa fi ìwé lọni. Bó bá pàdé ẹnì kan nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tí ẹni náà sì fi ìfẹ́ hàn, kọ́ ọ bó ṣe máa ṣe ìpadàbẹ̀wò àti bó ṣe máa ran onítọ̀hún lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú.

8 Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tìrẹ Alára Gbòòrò Sí I: Ǹjẹ́ yóó lè ṣeé ṣe fún ọ láti fi kún ìsapá rẹ nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere láwọn oṣù tó máa tẹ̀ lé sáà Ìṣe Ìrántí? Ǹjẹ́ o lè fi wákàtí kan tàbí méjì kún iye wákàtí tó ò ń lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá? Ṣé o ti ń ronú nípa àkókò tó o máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i? Àbí o lè ṣètò àwọn àlámọ̀rí ìgbésí ayé rẹ kó o lè kó wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? Gbogbo ìsapá tá a bá ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́! (Ìṣe 8:26-39) Bá a ti ń wo ọjọ́ iwájú, ẹ jẹ́ ká “máa lépa ohun rere sí ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn.”—1 Tẹs. 5:15.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Ẹ Máa Bá A Nìṣó Láti Ran Àwọn Wọ̀nyí Lọ́wọ́:

□✔ Àwọn tó pésẹ̀ sí ibi Ìṣe Ìrántí

□✔ Àwọn akéde tó ti bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i

□✔ Àwọn akéde tuntun tí kò tíì ṣèrìbọmi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́