Lẹ́tà Tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Kọ
Bí a ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wọnú ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, a láyọ̀ láti kọ ìwé yìí sí ‘gbogbo ẹgbẹ́ ará’ jákèjádò ayé, láti fi kan sáárá sí yín fún iṣẹ́ àṣekára tí ẹ̀ ń ṣe. (1 Pét. 2:17) Ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, Jésù béèrè pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” (Lúùkù 18:8) Akitiyan tí ẹ fi ìtara ṣe nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá fi hàn pé a lè fi ìdánilójú dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí ìbéèrè Jésù yìí! Wọ́n ti ṣáátá àwọn kan lára yín wọ́n sì ti fi wọ́n ṣẹ̀sín nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Láwọn ibi púpọ̀, ẹ̀ ń fara da ogun, ìjábá, àìsàn àti ebi. (Lúùkù 21:10, 11) Nítorí ìtara tẹ́ ẹ ní fún àwọn iṣẹ́ àtàtà, Jésù ṣì lè “bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé.” Láìsí àní-àní, ayọ̀ ń bẹ ní ọ̀run nítorí èyí!
Ká sòótọ́ kò rọrùn láti ní ìfaradà. Ẹ gbé ohun tí àwọn ará wa ń dojú kọ lórílẹ̀-èdè kan ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà yẹ̀ wò. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lemọ́lemọ́ ni wọ́n ń hùwà ipá sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè yẹn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọlọ́pàá tú àpéjọ alálàáfíà kan ká, èyí táwọn tó wá síbẹ̀ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700]. Àwọn igi tí wọ́n gbé dínà kò jẹ́ kí àwọn ẹgbẹ̀rún ó lé ọ̀ọ́dúnrún [1,300] Ẹlẹ́rìí mìíràn lè wá síbẹ̀. Àwùjọ àwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n fi agọ̀ bojú, táwọn ọlọ́pàá wà lára wọn, ya bo ibi ìpàdé náà, wọ́n lu ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n péjọ, wọ́n sì sọ iná sí gbọ̀ngàn táwọn ará fẹ́ẹ́ lò fún àpéjọ náà. Ní àwọn ìgbà mìíràn, àwọn agbawèrèmẹ́sìn ti fi kùmọ̀ tí wọ́n kan ìṣó mọ́ lára lu àwọn ará wa ní ìlù ìkà.
Irú àwọn ìgbéjàkoni bẹ́ẹ̀ máa ń mú kára èèyàn bù máṣọ àmọ́ kò yà wá lẹ́nu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni a mí sí láti kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tím. 3:12) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni fara da ọ̀rọ̀ èébú àti líluni, wọ́n tiẹ̀ pa àwọn kan lára wọn pàápàá. (Ìṣe 5:40; 12:2; 16:22-24; 19:9) Bọ́rọ̀ ṣe rí ní ọ̀rúndún ogún nìyẹn, ó sì dájú pé bí yóò ṣe máa bá a nìṣó nìyẹn ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí. Síbẹ̀, Jèhófà sọ fún wa pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” (Aísá. 54:17) Ìdánilójú àgbàyanu yìí mà ń fini lọ́kàn balẹ̀ o! Láìsí àní-àní, a ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Abájọ tó fi sún wòlíì rẹ̀ Sekaráyà láti kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sek. 2:8) Àwọn tó ń gbógun ti àwọn olùjọsìn Jèhófà kò lè ṣẹ́gun wọn délẹ̀délẹ̀. Ìjọsìn mímọ́ gaara ló máa borí!
Fún àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè tá a mẹ́nu kan lókè yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe bẹbẹ, ní ti pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn akéde pọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001. Dájúdájú, àwọn arákùnrin wa forí ti ìnira tí wọ́n ń dojú kọ níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ti ń ṣe níbi gbogbo. Jákèjádò ayé, nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé mẹ́rìndínláàádọ́rin [5,066] èèyàn ló ń ṣe ìrìbọmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fàmì ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà hàn. Àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí ti pinnu nísinsìnyí, bíi ti àwa ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù, láti “dúró lọ́nà tí ó pé . . . àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Kól. 4:12.
Bákan náà, tún gbé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Gíríìsì ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yẹ̀ wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì fi ṣe àtakò gbígbóná janjan sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní báyìí, ìjọba ti kà wọ́n sí “ẹ̀sìn táyé mọ̀.” Ìwé àkọsílẹ̀ tí wọ́n fi fìdí ẹ̀rí ìyọ̀ǹda yìí múlẹ̀ tún sọ síwájú sí i pé, Bẹ́tẹ́lì ilẹ̀ Gíríìsì jẹ́ “ibi ọ̀wọ̀, tí a ti yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run.” A tún láyọ̀ láti sọ fún un yín pé nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ọ̀pọ̀ ilé ẹjọ́ ti ṣèdájọ́ tó dá ìjọsìn wa láre ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Bulgaria, Jámánì, Kánádà, Japan, Romania àti Rọ́ṣíà. A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o, fún bó ṣe ṣí ilẹ̀kùn ìgbòkègbodò sílẹ̀ gbayawu láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn!
Bá a ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, a lè rí i pé òun ni Ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n jù lọ tá a lè ní. Àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ ń múnú wa dùn, nítorí a mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń kọ́ wa, ó sì ń tọ́ wa sọ́nà. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, a ó ṣì máa bá a nìṣó láti máa dojú kọ àwọn àdánwò ìgbàgbọ́. Àmọ́ ṣá o, ìgbàgbọ́ tí kò lè mì tá a ní nínú Jèhófà yóò mú wa dúró. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” (Ják. 1:2, 3) Láfikún sí i, ìfaradà wa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí sì ń fún wa láyọ̀ tó pọ̀ gan-an! Kí ó dá ẹ̀yin ará wa ọ̀wọ́n lójú pé Jèhófà yóò ran olúkúlùkù wa lọ́wọ́. Bá a bá dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, ó dájú pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti wọ ayé tuntun. Ó fẹ́ kí a ṣàṣeyọrí.
Nítorí náà, a rọ ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, pé kẹ́ ẹ máa fi àwọn ìbùkún àgbàyanu tó wà níwájú sọ́kàn. Ǹjẹ́ kí a ní irú èrò tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní, ẹni tó kọ̀wé pé: “Mo ṣírò rẹ̀ pé àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí kò já mọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo tí a óò ṣí payá nínú wa.” (Róòmù 8:18) Gbára lé Jèhófà nígbà tó o bá ń dojú kọ ìpọ́njú èyíkéyìí. Fara dà á, má ṣe juwọ́ sílẹ̀. O ò ní kábàámọ̀ rẹ̀ láé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.”—Háb. 2:4.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà