Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò tá a máa ṣe láìṣíwèéwò lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọ̀sẹ̀ January 7 sí April 22, 2002. Lo abala bébà ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà sílẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí tìrẹ fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn ní gbogbo àwọn ibi tá a ti tọ́ka sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Bẹ́ẹ̀ Ni tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Ní Oníwàásù 2:2, ohun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé kò yẹ ká máa rẹ́rìn-ín ká sì máa yọ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5.]
2. Ríronú ṣáá nípa ‘ìgbà táyé ṣì dáa’ kò lè mú kí ipò àwọn nǹkan sàn fún wa nísinsìnyí ju ti ìgbà àtijọ́ lọ. (Oníw. 7:10) [w87-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 5]
3. Ní Aísáyà 1:7, wòlíì náà ń tọ́ka sí ìparun Júdà nígbà ìṣàkóso Áhásì. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 16.]
4. Bí o bá ń ṣiyèméjì gidigidi nípa ẹnì kan tó ò ń fẹ́ sọ́nà, ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ni pé kó o fòpin sí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ náà. [fy-YR ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 19]
5. Ìfẹ́ máa ń bo àwọn àṣìṣe mọ́lẹ̀ ni kì í mú wọn kúrò, níwọ̀n bí kò ti sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé kankan tí ó lè bọ́ lọ́wọ́ àṣìṣe. (1 Pét. 4:8; Sm. 130:3, 4; Ják. 3:2) [fy-YR ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 5]
6. ‘Ìṣe tó ṣàjèjì àti iṣẹ́ tó kàmàmà’ lóde-òní tí a sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní Aísáyà 28:21 ń tọ́ka sí ìparun àwọn orílẹ̀-èdè ní Amágẹ́dọ́nì. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 295 ìpínrọ̀ 16; ojú ìwé 301 ìpínrọ̀ 28.]
7. Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 24:38, 39 ṣe fi hàn, àjẹjù oúnjẹ àti àmujù ọtí, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn mìíràn ló mú kí Àkúnya Omi gbá àwọn èèyàn ọjọ́ Nóà lọ. [w00-YR 2/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 6]
8. Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n ń sìn ín láìmọ tara wọn nìkan bá béèrè. [w00-YR 3/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 3]
9. “Àwọn orílẹ̀-èdè” tí Aísáyà 60:3 ń tọ́ka sí ni àwọn ìjọba olóṣèlú orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan tí ìmọ́lẹ̀ tí Ọlọ́run ń fúnni ti fà mọ́ra. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w00-YR 1/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 4.]
10. Jèhófà “sọ” Jeremáyà “di mímọ́” kí wọ́n tó bí i ní ti pé, Ó pinnu àyànmọ́ ayérayé rẹ̀. (Jer. 1:5) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 4/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 2.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
11. Ní Oníwàásù 11:1, kí ni ‘fífọ́n oúnjẹ’ túmọ̀ sí? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 11.]
12. Ní Aísáyà 6:8, ta ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà, “wa”? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 93 àti 94 ìpínrọ̀ 13.]
13. Ní ìmúṣẹ Aísáyà 9:2, báwo ni “ìmọ́lẹ̀ ńlá” ṣe tàn ní Gálílì? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 126 ìpínrọ̀ 17.]
14. Aláfijọ òde-òní wo ni a lè tọ́ka sí ní ti ìṣubú Bábílónì lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Tiwa àti bó ṣe pa run yán-ányán-án lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? (Aísá. 13:19, 20; 14:22, 23) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 30 àti 31.]
15. Ọ̀nà wo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fi ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “alóre” tá a ṣàpèjúwe ní Aísáyà 21:6? (Mát. 24:45) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 221 àti 222 ìpínrọ̀ 11.]
16. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ló wà nínú Òwe 31:10 fún ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń wá ẹni tí yóò bá ṣègbéyàwó? [w00-YR 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]
17. Nínú ìwé Aísáyà 43:9, ìpèníjà wo ni a nawọ́ rẹ̀ sí àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 2/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3.]
18. Ọ̀nà wo ni ẹsẹ̀ àwọn tí wọ́n ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fi “dára rèǹtè-rente”? (Aísá. 52:7) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 4/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 6.]
19. Kí ló pọn dandan pé ká ṣe tá ò bá ní gbà kí ọkàn wa tàn wá jẹ? (Jer. 17:9) [w00-YR 3/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4]
20. Kí làwọn tí wọ́n ń ‘rìn ní ọ̀nà Jèhófà’ gbọ́dọ̀ ṣe? (Jer. 7:23) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 8/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. “Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀” ní ti pé “ọwọ́ ọ̀tún” sábà máa ń dúró fún __________________________ ; nípa bẹ́ẹ̀, èyí fi hàn pé __________________________ rẹ̀ ni ó ń sún un láti máa tọ ipa ọ̀nà tó tọ́ tó sì ṣètẹ́wọ́gbà. (Oníw. 10:2; Mát. 25:33) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 8.]
22. Lára àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ṣeni láǹfààní tó wà nínú ìwé Orin Sólómọ́nì ni __________________________ àti __________________________. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 11/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 9.]
23. Olùfi àwọn ìlú Júdà ṣèjẹ, tí a mẹ́nu kàn nínú Aísáyà 33:1 ni __________________________, òun fúnra rẹ̀ sì ni àwọn ọ̀tá máa ṣẹ́gun rẹ̀ lọ́dún 632 ṣáájú Sànmánì Tiwa, tí yóò sì fi ìkógun ńláǹlà sílẹ̀ fún àwọn olùgbé __________________________, tí wọn yóò ‘kó o jọ bí aáyán.’ (Aísá. 33:4) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 343 ìpínrọ̀ 4; ojú ìwé 345 ìpínrọ̀ 6.]
24. Fífi Aísáyà 54:1 wéra pẹ̀lú Gálátíà 4:26, 27 jẹ́ ká mọ̀ pé “àgàn tí kò bímọ” náà dúró fún “ __________________________ ; nígbà tí “obìnrin tí ó ní ọkọ tí í ṣe olówó orí rẹ̀” dúró fún __________________________. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 8/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 8.]
25. Nígbà tí àwọn èèyàn bá fi wá ṣẹ̀sín tàbí tí wọ́n ṣá wa tì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó yẹ ká rántí pé __________________________ kọ́ ni wọ́n ń ta kò, bí kò ṣe __________________________, Ẹni tí ó ni iṣẹ́ tá à ń jẹ́. (2 Kọ́r. 4:1, 7) [w00-YR 1/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
26. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ìran tó rí nípa ògo Jésù ní ọ̀run, ó tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a “bí ní kògbókògbó,” èyí tó túmọ̀ sí pé (ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ẹni tá a fi ẹ̀mí bí; ó di ẹni tí a yàn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè ṣáájú àkókò tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀; ó dà bí ẹni pé ó ti ní àǹfààní dídi ẹni tí a bí tàbí tí a jí dìde sí ìyè tẹ̀mí ṣáájú àkókò tó yẹ kó ṣẹlẹ̀). (1 Kọ́r. 9:1; 15:8) [w00-YR 1/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6]
27. Orúkọ oyè náà “Baba Ayérayé” ń tọ́ka sí agbára àti ọlá àṣẹ tí Mèsáyà Ọba ní láti fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní (okun nípa tẹ̀mí; ìyè àìleèkú ní ọ̀run; ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé). (Aísá. 9:6; Jòh. 11:25, 26) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 26.]
28. Nínú ìmúṣẹ òde òní ti Aísáyà 66:7, ‘ọmọ ọkùnrin’ tí a bí náà dúró fún (Jésù Kristi; Ìjọba Mèsáyà; orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun kan ní 1919). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 1/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3.]
29. Fífi ìwà ọ̀làwọ́ ‘bọlá fún Jèhófà’ nípa lílo àwọn ohun ìní wa, ìyẹn àkókò wa, ẹ̀bùn àbínibí wa, agbára wa àti àwọn nǹkan ìní wa nípa tara máa ń mú àwọn ìbùkún (nípa tara; jìngbìnnì nípa tẹ̀mí; ní ti ìṣúnná owó) wá látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Òwe 3:9, 10) [w00-YR 1/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1]
30. Nínú ìmúṣẹ rẹ̀ òde òní, “orílẹ̀-èdè náà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà” tí a sọ nínú Jeremáyà 7:28 ń tọ́ka sí (Bábílónì Ńlá; Kirisẹ́ńdọ̀mù; agbára ayé keje). [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 4/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 10.]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sí ìsàlẹ̀ yìí:
Òwe 24:16; Oníw. 3:11; Aísá. 40:8; Aísá. 32:1, 2; Lúùkù 14:28
31. Ní àkókò yíyẹ, ibi tí iṣẹ́ Ọlọ́run kọ̀ọ̀kan á ti bá ète rẹ̀ mu rẹ́gí yóò fara hàn. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 9/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 8.]
32. Ó yẹ kí àwọn tí ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó ní èrò tó bójú mu nípa àwọn ìbùkún tó wà nínú ìgbéyàwó àti àwọn ohun tó máa ná wọn. [fy-YR ojú ìwé 13 àti 14 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
33. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fẹ́ ìfàsẹ́yìn kù nínú ìgbésí ayé, ẹnì kan tó jẹ́ olùṣèfẹ́ Ọlọ́run kò ní juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tó dára. [w00-YR 2/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1]
34. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí ète rẹ̀ tó sọ, ni ẹnikẹ́ni kò lè sọ di aláìwúlò tàbí kó ṣèdíwọ́ fún láti má ṣe ní ìmúṣẹ. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo ip-1-YR ojú ìwé 401 ìpínrọ̀ 10.]
35. Ìjọ jẹ́ ibi ààbò nísinsìnyí pàápàá, ibi tí àwa Kristẹni ti ń rí ààbò láàárín àwọn ará wa, lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti àwọn alàgbà. [w01-YR 3/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 17]