ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/02 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 4/02 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Kí àwọn akéde sọ fún àwọn tí wọ́n ń wàásù fún pé wọ́n lè ṣe ìtìlẹyìn ọrẹ fún iṣẹ́ yíká ayé. Níbi tí ẹnì kan bá ti fi ìfẹ́ hàn, jẹ́ kí onítọ̀hún wà lára àwọn tí wàá máa mú ìwé ìròyìn lọ fún déédéé. Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o sì ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. June: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, fi ìwé pẹlẹbẹ kan tó bá àkókò yẹn mu tí ìjọ ní lọ́wọ́ lọni. July: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” A tún lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, àti Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, lọni níbi tó bá ti bá àkókò mu.

◼ Ó pọn dandan pé kí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa níbí máa ní àkọsílẹ̀ tó bágbà mu nípa àdírẹ́sì àti tẹlifóònù gbogbo alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé. Bí ìyípadà èyíkéyìí bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29), kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa níbí lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú àkànṣe nọ́ńbà ti àgbègbè (area code).

◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tí ó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún wọn nípa lílo fọ́ọ̀mù Literature Request Form (S-14). Kí ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ yóò tó láti lò fún, ó kéré tán, ọdún kan. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sínú wọn dáadáa. Bí àwọn tó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà kò bá lè rántí déètì náà gan-an tí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí wọ́n fojú díwọ̀n déètì kan kí wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ síbì kan.

◼ Nígbàkigbà tí o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tí o sì fẹ́ láti lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, àtọ̀dọ̀ ọ́fíìsì ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè yẹn ni kó o ti béèrè ìsọfúnni nípa déètì, àkókò, àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka wà ní ojú ewé tó kẹ́yìn nínú ìwé Yearbook wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́.

◼ Ní May 25, 2002, kò ní sí àyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá gba ìwé kankan lọ́jọ́ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́