ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 orí 13 ojú ìwé 114-120
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Dáadáa Sí I Níléèwé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Dáadáa Sí I Níléèwé?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Wọ́n Ní Kó O Ṣe Látiléwá
  • Bó O Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí
  • Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?
    Jí!—2004
  • Ǹjẹ́ Mo Lè Túbọ̀ Ṣe Dáradára Nílé Ẹ̀kọ́?
    Jí!—1998
  • Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?
    Jí!—2011
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 orí 13 ojú ìwé 114-120

ORÍ 13

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Dáadáa Sí I Níléèwé?

KÁ SỌ pé o bára ẹ nínú igbó kìjikìji kan. Igbó náà dí pa débi pé kò sí ìtànṣán oòrùn kankan tó lè tàn sórí ilẹ̀. Àwọn igi inú igbó tó sì hù lọ́tùn-ún lósì ò jẹ́ kó o ríbi tó o lè rìn sí. Àfi kó o fi àdá gé àwọn igi kan nínú igbó yẹn kó o bàa lè ríbi gbà.

Àwọn kan lè sọ pé bí iléèwé ṣe rí gẹ́lẹ́ la sọ yìí. Ó ṣe tán, inú kíláàsì lo sábà máa ń wà ní gbogbo ọ̀sán, àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá kì í sì í jẹ́ kó o sùn bọ̀rọ̀ lálẹ́. Ṣé bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára tìẹ náà nìyẹn? Kọ iṣẹ́ iléèwé tó o rí pé ó le jù fún ẹ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ó ṣeé ṣe kí dádì tàbí mọ́mì ẹ àtàwọn tíṣà ẹ ti máa sọ fún ẹ pé ó yẹ kó o túbọ̀ fi kún bó o ṣe ń ṣe sí nínú iṣẹ́ yẹn. Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ fi nǹkan ni ẹ́ lára o! Wọ́n kàn fẹ́ kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe ni. Kí lo wá lè ṣe tí gbogbo nǹkan bá fẹ́ tojú sú ẹ torí bí wọ́n ṣe ń fẹ́ kó o túbọ̀ fi kún gbogbo ohun tó ò ń ṣe yìí? Bó o bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó tọ́, wàá lè ṣàṣeyọrí nínú àwọn iṣẹ́ iléèwé ẹ bí ìgbà téèyàn bá ń fi àdá la ọ̀nà nínú igbó kìjikìji. Àwọn ìgbésẹ̀ wo nìyẹn?

● Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́: Fojú tó dáa wo ẹ̀kọ́ kíkọ́. Bó o bá jẹ́ kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ máa wù ẹ́, ó máa rọrùn fún ẹ láti máa ṣe dáadáa níléèwé. Torí náà, ó máa dáa kó o ro ọ̀rọ̀ yìí láròjinlẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ń túlẹ̀ yẹ kí ó túlẹ̀ ní ìrètí, ẹni tí ó sì ń pakà yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìrètí jíjẹ́ alábàápín.”—1 Kọ́ríńtì 9:10.

Ó lè má rọrùn fún ẹ láti rí ìdí tó fi yẹ kó o sa gbogbo ipá rẹ lórí àwọn iṣẹ́ iléèwé ẹ kan. Ìdí ni pé, ó lè dà bíi pé àwọn iṣẹ́ kan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níléèwé báyìí ò wúlò. Àmọ́, bó o bá mọ onírúurú nǹkan látinú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn, òye tó o máa ní nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń lọ láyìíká ẹ á túbọ̀ pọ̀ sí i. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo,” wàá sì lè bá oríṣiríṣi èèyàn tó wá láti ibi tó yàtọ̀ síra sọ̀rọ̀. (1 Kọ́ríńtì 9:22) Wàá lè túbọ̀ máa ronú jinlẹ̀, o ò sì ní kábàámọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

● Ìgbésẹ̀ Kejì: Máa fojú tó tọ́ wo àwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe. Iléèwé máa jẹ́ kó o mọ àwọn ẹ̀bùn tó o ní. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé kó ‘ru ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ń bẹ nínú rẹ̀ sókè bí iná.’ (2 Tímótì 1:6) Ó ṣe kedere pé, wọ́n ti fún Tímótì láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́, ó ní láti máa lo “ẹ̀bùn” tí Ọlọ́run fún un, kí ẹ̀bùn yẹn má bàa wọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tààràtà, Ọlọ́run kọ́ ló tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fún ẹ lẹ́bùn tó mú kó o já fáfá nínú àwọn iṣẹ́ kan tó o mọ̀ dunjú níléèwé. Ó dájú pé ẹ̀bùn tó o ní yàtọ̀ sí tàwọn ẹlòmíì. Iléèwé máa jẹ́ kó o túbọ̀ já fáfá nínú lílo àwọn ẹ̀bùn náà, ọ̀pọ̀ nǹkan tó ò sì mọ̀ nípa ara ẹ ló máa hàn sójú táyé.

Má ṣe máa ronú pé o ò lè ṣe dáadáa ju bó o ṣe ń ṣe lọ, torí ìyẹn lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í gbòdo níléèwé. Bí èrò tí ò dáa bá fẹ́ máa wá sí ẹ lọ́kàn nípa àwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe, má ṣe gbà á láyè. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn èèyàn kan ṣe lámèyítọ́ Pọ́ọ̀lù, ó fèsì pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:6) Pọ́ọ̀lù mọ ibi tóun kù sí. Àmọ́ ó tún mọ ibi tóun dáa sí.

Ìwọ ńkọ́? Ibo lo dáa sí? Bó bá ṣòro fún ẹ láti mọ̀, o ò ṣe béèrè lọ́wọ́ àgbàlagbà kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Irú ẹni yẹn lè jẹ́ kó o mọ àwọn ibi tó o dáa sí, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ lè ṣe dáadáa sí i.

● Ìgbésẹ̀ Kẹta: Máa kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Kò sí bó o ṣe lè ṣe dáadáa níléèwé láìjẹ́ pé o ṣiṣẹ́ àṣekára. Kò sígbà tó ò ṣì ní kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀rọ̀ yìí lè má dùn-ún gbọ́ létí o, àmọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́. Bó bá yá, wàá bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ẹ̀ dáadáa.

Bó o bá fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, o ní láti ṣètò àkókò ẹ dáadáa. Má gbàgbé pé, nígbà tó o bá wà níléèwé, ìwé ẹ làkọ́kọ́. Bíbélì ṣáà sọ pe, “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. (Oníwàásù 3:1, 4; 11:9) Torí náà, ó dájú pé wàá fẹ́ máa wáyè fún eré ìtura bí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ṣe máa ń fẹ́.a Àmọ́, Oníwàásù 11:4 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ nínú èyí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé, ìwé ẹ làkọ́kọ́, o wá lè ṣeré lẹ́yìn tó o bá kàwé tán. Fọkàn balẹ̀, àyè méjèèjì ló máa yọ!

Bó O Ṣe Lè Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Tí Wọ́n Ní Kó O Ṣe Látiléwá

Kí lo máa ṣe bí iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún ẹ láti iléèwé bá pọ̀ gan-an? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Sandrine, ó ní: “Wákàtí méjì sí mẹ́ta lálaalẹ́, títí kan òpin ọ̀sẹ̀, ni mo máa ń fi ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún mi látiléèwé.” Kí lo lè ṣe táwọn iṣẹ́ yẹn ò fi ní wọ̀ ẹ́ lọ́rùn ju bó ṣe yẹ lọ? Gbìyànjú àwọn àbá tó wà lójú ìwé 119.

Bó O Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí

Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn lórí bó ṣe lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó ní: ‘Máa lépa àwọn nǹkan wọ̀nyí. Àwọn ni kí o jẹ́ kí ó gba gbogbo àkókò rẹ, kí ìtẹ̀síwájú rẹ lè hàn sí gbogbo ènìyàn.’ (1 Tímótì 4:15, Ìròhìn Ayọ̀) Bákan náà, bó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ẹ̀kọ́ iléèwé ẹ, gbogbo èèyàn á rí bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú.

Ronú nípa àpèjúwe tá a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa lẹ́ẹ̀kan. Bó o bá bára ẹ nínú igbó kìjikìji, o máa nílò àdá tó o lè fi la ọ̀nà, kó o bàa lè ríbi gbà kọjá. Ohun tó o máa ní láti ṣe níléèwé náà fara jọ ìyẹn. Dípò tí wàá fi jẹ́ kí gbogbo nǹkan sú ẹ torí ohun tí Dádì tàbí Mọ́mì àtàwọn tíṣà ẹ ń fẹ́ kó o ṣe nípa àwọn iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níléèwé, ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta tá a ti sọ nínú orí yìí, kó o bàa lè kẹ́sẹ járí. O ò ní kábàámọ̀ pó o ṣe àwọn ohun tá a sọ wọ̀nyí, torí pé wàá túbọ̀ mọ̀wé ẹ!

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 18, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Kí lo lè ṣe táwọn kan bá tún ń halẹ̀ mọ́ ẹ níléèwé pẹ̀lú gbogbo wàhálà tíṣẹ́ iléèwé ti ń fún ẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ka púpọ̀ sí i nípa eré ìtura nínú Apá Kẹjọ ìwé yìí.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.”—Oníwàásù 11:4.

ÌMỌ̀RÀN

Bó o bá fẹ́ kàwé, kọ́kọ́ yẹ̀ ẹ́ wò látòkèdélẹ̀, kó o bàa lè mọ àwọn ohun tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, kó o béèrè àwọn ìbéèrè tó dá lórí àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó bá wà níbẹ̀. Kó o wá ka ìwé náà láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Tó o bá kà á tán, gbìyànjú bóyá o lè rántí àwọn nǹkan tó o bá kà láìwòwé.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o bá ń jí ìwé wò nígbà ìdánwò, àwọn èèyàn lè má fọkàn tán ẹ mọ́, ó sì lè mú kó o ya olódo. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, inú Ọlọ́run ò ní dùn sí ẹ.—Òwe 11:1.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Tá a bá máa ṣe ìdánwò tó ń bọ̀, ó wù mí kí n gba ․․․․․ nínú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí: ․․․․․

Ohun tí màá ṣe, kí n bàa lè mọ iṣẹ́ yẹn dáadáa ni pé: ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi yẹ kó o fojú sí ìwé ẹ?

● Ìgbà wo ló yẹ kó o máa kàwé tàbí kó o máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ látiléèwé?

● Ibo, nínú ilé yín, lo rí i pó dáa jù fún ẹ láti máa kàwé tó o sì ti lè máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ látiléèwé?

● Báwo lo ò ṣe ní jẹ́ káwọn ohun tó o máa ń ṣe nígbà tọ́wọ́ bá dilẹ̀ àti eré ìtura nípa lórí iṣẹ́ iléèwé ẹ?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 117]

Mo máa ń rí i pé ọwọ́ táwọn kan tá a jọ jẹ́ ojúgbà fi mú iṣẹ́ iléèwé náà ni wọ́n fi mú kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí pàápàá. Àwọn tí kò fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ iléèwé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.’’—Sylvie

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 119]

Wá ibi tó o ti lè máa kàwé. Kò gbọ́dọ̀ sáwọn nǹkan tó lè pín ọkàn ẹ níyà níbẹ̀. Tó bá ṣeé ṣe, orí tábìlì ni kó o ti máa kàwé. Má tan tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀.

Mọ ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe. Torí pé iṣẹ́ iléèwé ẹ ṣe pàtàkì, pinnu pé o ò ní tan tẹlifíṣọ̀n, àyàfi tó o bá ṣe é tán.

Má ṣe máa fòní dónìí. Ní ètò pàtó nípa àwọn nǹkan tí wàá máa ṣe nínú ilé, kó o sì máa tẹ̀ lé e.

Múra bó o ṣe fẹ́ ṣe é. Pinnu bó o ṣe fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn, èyí tó o fẹ́ kọ́kọ́ ṣe, èyí tó o fẹ́ ṣe tẹ̀ lé e àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kọ ètò tó o ṣe sórí ìwé àti iye àkókò tó o fẹ́ lò fún iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Fagi lé èyí tó o bá ti ṣe lórí ìwé tó o ṣètò ẹ̀ sí.

Máa sinmi. Tó o bá rí i pé ọkàn ẹ ò fẹ́ sí nínú ìwé tó ò ń kà mọ́, sinmi díẹ̀. Àmọ́ má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó padà sídìí ìwé ẹ.

Má rora ẹ pin. Máa rántí pé, ọmọléèwé tó bá ń kàwé ẹ̀ dáadáa sábà máa ń ṣe dáadáa níléèwé ju àwọn tó mọ̀wé lọ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ yege. Bó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, ó dájú pé wàá yege.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 116]

Lílọ síléèwé dà bíi fífi àdá lànà nínú igbó kìjikìji, béèyàn bá ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ó máa ṣàṣeyọrí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́