ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 96
  • Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí táwọn olùkọ́ fi máa ń fún àwọn ọmọ iléèwé ní iṣẹ́ àṣetiléwá?
  • Ìmọ̀ràn to máa ràn ẹ́ lọ́wọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?
    Jí!—2004
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Dáadáa Sí I Níléèwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Gba Òdo Nílé Ìwé?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Máàkì Rẹ̀ Lè Gbé Pẹ́ẹ́lí
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 96
Ọ̀dọ́kùnrin kan ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ láàárín òru, ó sì tan tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?

“Láago kan òru, kéèyàn má tíì sùn, kó máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, kò rọrùn rárá. Bí oorun, bí oorun lá máa ṣèèyàn.”​—David.

“Mo ṣì máa ń wà nídìí ìwé láago mẹ́rin ààbọ̀ ìdájí nígbà míì, mo sì gbọ́dọ̀ jí láago mẹ́fà àárọ̀ kí n lè múra ilé ìwé. Kò dẹrùn fún mi rárá!”​—Theresa.

Ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá máa ń pọ̀ jù fún ẹ ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa kọ́ ẹ lọ́gbọ́n tó máa dáa sí i.

  • Kí nìdí táwọn olùkọ́ fi máa ń fún àwọn ọmọ iléèwé ní iṣẹ́ àṣetiléwá?

  • Ìmọ̀ràn to máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí nìdí táwọn olùkọ́ fi máa ń fún àwọn ọmọ iléèwé ní iṣẹ́ àṣetiléwá?

Díẹ̀ lára ẹ̀ ni pé, iṣẹ́ àṣetiléwá . . .

  • máa ṣí ojú àti ọpọlọ ẹ sí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ò tíì mọ̀

  • máa jẹ́ kó o di ẹni tó ṣe é gbara lé

  • máa jẹ́ kó o lè ṣètò àkókò rẹ dáadáa

  • máa jẹ́ kó o lóye ohun tí olùkọ́ ń kọ́ ẹa

“Àwọn olùkọ́ máa ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá torí kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè fi ohun tí wọ́n ti kọ́ dánra wò dípò kó kàn jẹ́ pé ńṣe làwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn gba etí ọ̀tún wọlé, tó sì ń gba tòsì jáde.”​—Marie.

Ní pàtàkì, ẹ̀kọ́ ìṣirò àti sáyẹ́ǹsì máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè yanjú ìṣòro. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé, àwọn ẹ̀kọ́ yẹn máa jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Torí náà, iṣẹ́ àṣetiléwá dà bí eré ìmárale fún ọpọlọ rẹ!

Bóyá o gbà pé iṣẹ́ àṣetiléwá máa ṣe ẹ́ láǹfààní àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o ní láti mọ̀ pé ohun tó yẹ kó o ṣe ni. Ohun kan tó o gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn rèé: Lóòtọ́, o kò lè pinnu bí iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n máa fún ẹ ṣe máa pọ̀ tó, àmọ́ ó lè má gbà ẹ́ lákòókò tó pọ̀. Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.

Ìmọ̀ràn to máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

Tó bá jẹ́ pé kò rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n ń fún ẹ, má ṣe rò pé òkè ìṣòrò tó ò lè borí ni. Àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Ìmọ̀ràn 1: Múra sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.” (Òwe 21:5) Rí i dájú pé gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kó ní sídìí láti máa dìde káàkiri.

    Tún wa ibi tó rọrùn fún ẹ tí wàá ti lè pọkàn pọ̀. Àwọn kan máa ń fẹ́ ibi tó pa rọ́rọ́ tí iná sì wà níbẹ̀. Àwọn míì sì máa ń kúrò nílè wọn, wọ́n tiẹ̀ le lọ sí ilé ìkówèésí.

    “Tó o bá ní ìwé tàbí kàlẹ́ńdà tó o fi ń kọ àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tó o fẹ́ ṣe àti déètì tó o fẹ́ parí wọ́n, wàá lè fọgbọ́n ṣètò àkókò rẹ lọ́nà tó dáa. Tó o bá ń fọkàn sí iṣẹ́ àṣetiléwá tó yẹ kó o ṣè àti ìgbà tó yẹ kó o ṣe é, àníyàn rẹ máa dín kù.”​—Richard.

  • Ìmọ̀ràn 2: Ṣètò iṣẹ́ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ . . . létòlétò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn rẹ̀, pinnu iṣẹ́ àṣetiléwá tó o máa kọ́kọ́ ṣe àtèyí tó máa ṣe tẹ̀ lé e.

    Àwọn kan máa ń fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyí tó nira. Ó sì máa ń yá àwọn míì lára tí wọ́n bá kọ́kọ́ ṣe àwọn èyí tó rọ̀. Èyí tó bá rọrùn fún ẹ ni kó o ṣe nínú méjèèjì.

    “Ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an téèyàn bá níbi tó ń kọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe sí àti bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá lásìkò, kò sì ní kà ẹ́ láyà.”​—Heidi.

  • Ìmọ̀ràn 3: Jára mọ́ṣẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára, ẹ má ṣọ̀lẹ.” (Róòmù 12:11) Má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan míì gba àsìkò tó yẹ kó o fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mọ́ ẹ lọ́wọ́, láìka bó ti wù kó wù ẹ́ tó.

    Àwọn tó ti mọ́ lára láti máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la kì í parí iṣẹ́ wọn lásìkò àbí kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa kánjú parí ẹ̀, ìyẹn sì máa ń ṣàkóbá fún ẹ̀kọ́ àti ìṣẹ́ wọn. Ohun tó o lè ṣe tó ò bá fẹ́ kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ ni pé kó o máa tètè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ.

    “Tí mo bá tètè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi ní gbàrà tí mo bá dé láti ilé ìwé tàbí tí mo bẹ̀rẹ̀ sí i ṣiṣẹ́ lórí ohun kan tí wọ́n ní kí ń ṣe láìpẹ́ sígbà tí wọ́n fún mi, ṣe ni ọkàn mi máa ń balẹ̀, ó sì máa ń fún mi láyè láti ṣe àwọn nǹkan míì.”​—Serina.

    ÀBÁ: Àkókò kan náà ni kó o máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ lójoojúmọ́. Ìyẹn máa jẹ́ kó o kóra rẹ níjàánu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó máa mọ́ ẹ lára.

  • Ìmọ̀ràn 4: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Bíbélì sọ pé: “Iwájú rẹ gan-an ni kí o tẹjú mọ́.” (Òwe 4:25) Tó o bá fẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun, ní pàtàkì àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, pín ọkàn rẹ níyà nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́.

    Ọ̀dọ́kùnrin kan ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́, kó sì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ̀ níyà.

    Tó bá jẹ́ pé ṣe ló ń ti orí ìkànnì kan bọ́ sí òmíì, tó sì ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ó máa gba ìlọ́po méjì àkókò tó yẹ kó o fi parí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ. Àmọ́ tó o bá pọkàn pọ́, wàá rí i pé o kò ní ṣe wàhálà tó pọ̀, wàá sì tún ráyé ṣeré.

    “Ọkàn rẹ̀ ò ní pa pọ̀ tó o bá tan fóònù, kọ̀ǹpútà, àwọn ohun tó o fi ń gbá géèmù àti tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀. Ohun tó máa ń ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo máa ń pa fóònù, máa sì pa gbogbo ohun èlò ìgbàlódé tó lè pín ọkàn mi níyà tó bá wà nítòsí.”​—Joel.

  • Ìmọ̀ràn 5: Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” (Fílípì 4:5) Máa fún ara rẹ ní ìsinmi kí iṣẹ́ náà má bàá mú ẹ lómi kọjá bó ṣe yẹ. O lè rìn jáde, o lè gun kẹ̀kẹ́ tàbí kó o sáré.

    Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ohun tá a gbé yẹ̀ wó yìí, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ ṣì pọ̀ jù fún ẹ, bá àwọn olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá rí i pé, ò ń gbìyànjú lóòótọ́, wọ́n lè pinnu láti dín iṣẹ́ tí wọ́n ń gbé fún ẹ kù.

    “Má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ àṣetiléwá sọ ẹ di ẹni tí kò láyọ̀ àtẹni tí gbogbo nǹkan sú. Sa gbogbo ipá rẹ. Àwọn nǹkan kan wà tí kò yẹ kó sọ ẹ́ dìdàkudà, ọ̀kan lára ẹ̀ ni iṣẹ́ àṣetiléwá.”​—Julia.

Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ohun wo ni mo nílò fún iṣẹ́ àṣetiléwá mi?

  • Àkókò wo ló dáa jù tó yẹ kí ń fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi?

  • Ibo ló dáa jù tí màá ti lè pọkàn pọ̀?

  • Báwo ni mi ò ṣe ní máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la?

  • Àwọn ohun wo ló lè pín ọkàn mi níyà?

  • Báwo ni mi ò ṣe ní jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tàbí àwọn nǹkan míì pín ọkàn mi níyà?

  • Báwo ni màá ṣe rí i dájú pé mo tètè ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi láìsì pé ó ń kó mi lọ́kàn sókè?

ÌRÀNNÍLÉTÍ PÀTÀKÌ: Rí i dájú pé o mọ ohun tí olùkọ́ rẹ fẹ́ kó o ṣe nínú iṣẹ́ àṣetiléwá tó fún ẹ. Tí kò bá yé ẹ, béèrè lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ kó o tó kúrò nílé ìwé.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Angelique.

“Èyí tí mo bá rí i pé ó rọ̀ nínú iṣẹ́ àṣetiléwá ni mo máa ń kọ́kọ́ ṣe, kó má bàá tètè sú mi. Ìyẹn ló máa ń mú kó rọrùn fún mi láti ṣe àwọn tó kù, kí n sì tó mọ́ máa ti parí àwọn tó kù.”​—Angelique.

Austen.

“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò fẹ́ràn kí n máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, síbẹ̀ ó ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe lè fọgbọ́n lo àkókò rẹ̀, kí n sì di ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ìyẹn ló jẹ́ kí n gbà pé ara ẹ̀kọ́ tó yẹ kéèyàn kọ́ nígbèésí ayé ni iṣẹ́ àṣetiléwá jẹ́.”​—Austen.

Àtúnyẹ̀wò: Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?

Múra sílẹ̀. Rí i dájú pé gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Wá ibi tó rọrùn fún ẹ̀ tí wàá ti lè pọkàn pọ̀.

Ṣètò iṣẹ́ rẹ. Pinnu iṣẹ́ àṣetiléwá tó o máa kọ́kọ́ ṣe àtèyí tó máa ṣe tẹ̀ lé e.

Jára mọ́ṣẹ́. Jẹ́ akínkanjú; má ṣe máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la.

Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Fi ọkàn rẹ́ sí ohun tó ò ń ṣe, ní pàtàkì, má ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn rẹ níyà.

Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Máa fún ara rẹ ní ìsinmi kí iṣẹ́ náà má bàá mu ẹ́ lómi kọjá bó ṣe yẹ.

a Inú ìwé náà, School Power, látọwọ́ Jeanne Schumm la ti mú àwọn kókó yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́