ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 27-29
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Níbo Ni Màá Ti Ráyè?
  • Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Ni Kó O Kọ́kọ́ Ṣe
  • ‘Ra Àkókò Padà’ ní Ilé Ẹ̀kọ́
  • Lílo Àkókò Rẹ Lọ́nà Tó Túbọ̀ Gbéṣẹ́ Sí I
  • Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Dáadáa Sí I Níléèwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Gba Òdo Nílé Ìwé?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Rí i Dájú Pé O Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 27-29

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?

‘Mo máa tó jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga, másùnmáwo tó ń bá mi báyìí sì kọjá sísọ. . . . Ká mú tàwàdà kúrò, ọ̀pọ̀ àròkọ ni mo ní láti kọ, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni mo sì ní láti dúró sọ níwájú kíláàsì. Mi ò ráyè rárá láti ṣe wọ́n.’—Ọmọ ọdún méjìdínlógún kan ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.

ǸJẸ́ ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n máa ń fún ọ níléèwé máa ń wọ̀ ọ́ lọ́rùn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ń sapá láti mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ dáńgájíá sí i, kí wọ́n sì tún máa gba máàkì púpọ̀ sí i, ńṣe ni wọ́n ń mú kí iṣẹ́ àṣetiléwá túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Láwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń lò ju wákàtí mẹ́ta lọ lálaalẹ́ láti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá. Ìwádìí kan tí Yunifásítì Michigan ṣe fi hàn pé iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n ń fún àwọn ọ̀dọ́mọdé tó ń relé ẹ̀kọ́ ti fìgbà mẹ́ta pọ̀ sí i ju èyí táwọn ọ̀dọ́mọdé máa ń ṣe lógún ọdún sẹ́yìn.”

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ iṣẹ́ àṣetiléwá ò mọ sọ́dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan o. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó jẹ́ pé nǹkan bí ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́tàlá níbẹ̀ ló sọ pé àwọn ń lò ju wákàtí méjì lọ lójúmọ́ fún ṣíṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, lórílẹ̀-èdè Taiwan àti Korea, ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún ló ń ṣe bẹ́ẹ̀, ti ilẹ̀ Faransé sì lé ní ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún. Katie, ọmọ yunifásítì kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dárò pé: “Nígbà míì, ara máa ń ni mí gan-an nígbà tí iṣẹ́ àṣetiléwá bá kúnlẹ̀ gègèrè.” Ohun kan náà ni Marilyn àti Belinda, tí wọ́n ń lọ sílé ìwé ní ìlú Marseilles, nílẹ̀ Faransé, sọ. Marilyn sọ pé: “A sábà máa ń lo wákàtí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lálaalẹ́ láti ṣiṣẹ́ àṣetiléwá. Bí àwọn nǹkan míì bá wà fún ọ láti ṣe, agbára káká ni wàá fi ráyè ṣe é.”

Níbo Ni Màá Ti Ráyè?

Ǹjẹ́ kò ní dára bó o bá lè fi wákàtí díẹ̀ kún ọjọ́ èyíkéyìí tó o bá fẹ́ lò fún iṣẹ́ àṣetiléwá, débi pé bó o bá parí iṣẹ́ àṣetiléwá náà, wàá lè ráyè láti bójú tó àwọn nǹkan míì? Ní ti gidi, o lè ṣe ohun tó jọ̀yẹn bó o bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìlànà Bíbélì tó wà nínú Éfésù 5:15, 16, tó kà pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òǹkọ̀wé Bíbélì yìí kò ní iṣẹ́ àṣetiléwá lọ́kàn nígbà tó ń kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ìlànà tó wà nínú ohun tó kọ ṣeé lò nínú ìgbésí ayé ẹni. Bó o bá fẹ́ ra ohun kan o gbọ́dọ̀ fi ohun mìíràn sílẹ̀. Kókó tó ń fà yọ ni pé kó o tó lè wá àkókò fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ohun kan wà tó o gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, kí loun náà?

Ìmọ̀ràn ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jillian ni pé: “Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o fẹ́ láti ṣe.” Ìyẹn ni pé kó o mọ àwọn ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe. Àwọn ìpàdé Kristẹni àtàwọn nǹkan tẹ̀mí ló yẹ kó gba iwájú nínú àkọsílẹ̀ rẹ. Má sì ṣe gbàgbé ojúṣe rẹ nínú ilé, àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ.

Lẹ́yìn náà, gbìyànjú láti ṣe àkọsílẹ̀ bó o ṣe ń lo àkókò rẹ ní ti gidi fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan. Ìyàlẹ́nu lohun tó o máa rí á jẹ́ fún ọ. Báwo làkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n ṣe pọ̀ tó? èyí tó o fi ń wá ìsọfúnni kiri lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ńkọ́? èyí tó o fi ń wo sinimá? èyí tó o fi ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù? èyí tó o fi ń bẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ wò? Wàyí o, báwo ni ọ̀nà tó o gbà ń lo àkókò rẹ ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀ pé wàá fẹ́ láti ṣe? Ó lè jẹ́ pé ohun tó o nílò kò ju pé kó o ṣàgbéyẹ̀wò àkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n, tó o fi ń báni sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù tàbí èyí tó o fi ń wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, nípa bẹ́ẹ̀ wàá rí ọ̀nà tó o lè gbà ra àkókò tó pọ̀ gan-an padà!

Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Ni Kó O Kọ́kọ́ Ṣe

Èyí ò túmọ̀ sí pé o ò ní wo tẹlifíṣọ̀n mọ́ tàbí kó o wá fi gbogbo ìgbádùn du ara rẹ o. O wulẹ̀ lè gbé ìlànà kalẹ̀ fúnra rẹ, ìyẹn ni pé, “Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni màá kọ́kọ́ ṣe.” Ẹsẹ Bíbélì kan tó o lè lò sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Bí àpẹẹrẹ, níwọ̀n bí ilé ìwé tóò ń lọ ti ṣe pàtàkì, o lè gbé òfin kalẹ̀ fúnra rẹ pé o ò ní tan tẹlifíṣọ̀n àyàfi bó o bá parí àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tó o múra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀, tó o sì parí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ. Òótọ́ ni pé ó lè dùn ọ́ bóò bá wo eré tó o kúndùn láti máa wò lórí tẹlifíṣọ̀n. Àmọ́, tá a bá ní ká sòótọ́ tó wà níbẹ̀, ìgbà mélòó lo ti jókòó sídìí tẹlifíṣọ̀n láti wo kìkì eré tó o fẹ́ràn, àmọ́ tó jẹ́ pé iwájú rẹ̀ lo wà títí tí ilẹ̀ fi ṣú, tóò sì lè mú ohunkóhun ṣe?

Lọ́nà mìíràn, ó yẹ kó o fọwọ́ pàtàkì mú lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ń wọ̀nà fún ṣíṣe ìdánwò tàbí iṣẹ́ àṣetiléwá pàtàkì kan, o ti lè bẹ̀rẹ̀ sí gbára dì fún un ṣáájú àkókò kó má bàa dí ìpàdé rẹ lọ́wọ́. O tiẹ̀ tún lè gbìyànjú láti jíròrò bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú àwọn olùkọ́ rẹ, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wàá mọrírì rẹ̀ gan-an bí wọ́n bá jẹ́ kó o tètè mọ̀ nípa iṣẹ́ àṣetiléwá èyíkéyìí tó lè bọ́ sọ́jọ́ ìpàdé. Ó ṣeé ṣe káwọn olùkọ́ kan gbà láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀.

Akọsílẹ̀ Bíbélì nípa ọ̀rẹ́ Jésù tó ń jẹ́ Màtá tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà mìíràn kan tó lè ṣèrànwọ́. Alákíkanjú àti òṣìṣẹ́ aláápọn ni Màtá, ṣùgbọ́n kò mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láti kọ́kọ́ ṣe. Lọ́jọ́ kan, ó ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ níbi tó ti ń gbìyànjú láti se àsè tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ fún Jésù, nígbà tí Màríà arábìnrin rẹ̀ ń tẹ́tí sí Jésù dípò kó máa ràn án lọ́wọ́. Nígbà tí Màtá ṣàròyé nípa èyí, Jésù sọ fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò. Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 10:41, 42.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Má ṣe kó irin méjì bọná lẹ́ẹ̀kan náà. Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí sílò bí ohun kan bá wà fún ọ láti ṣe? Ó dára, ṣé ò “ń ṣàníyàn, [tó] o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀,” bóyá ò ń gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá àti iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ pa pọ̀? Bí iṣẹ́ kan bá wà tóò ń ṣe, ǹjẹ́ lóòótọ́ ni ìdílé rẹ nílò owó tó ń tìdí iṣẹ́ náà wá? Àbí, ó kàn ṣáà wù ọ́ pé kó o ní owó díẹ̀ lọ́wọ́ tí wàá lè fi ra àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe pé o nílò?

Bí àpẹẹrẹ, láwọn ilẹ̀ kan àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ láti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tiwọn. Agbaninímọ̀ràn kan nílé ìwé gíga, Karen Turner, ṣàlàyé pé, “ńṣe làwọn ọ̀dọ́ òde òní ń fi torí-tọrùn ṣiṣẹ́ láti lówó lọ́wọ́, torí pé owó gọbọi ló ń náni láti lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́.” Àmọ́ ṣá o, Turner parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí ẹni ń lé eku méjì tó pòfo ni nígbà téèyàn bá ń kó nǹkan púpọ̀ mọ́ra lẹ́ẹ̀kan náà, irú bí iṣẹ́, ìgbòkègbodò lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹpẹtẹ. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ kẹ́rù wọ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́rùn.” Èwo làbùrọ̀ dẹ́rù para ẹ bí kò bá pọn dandan láti ṣe bẹ́ẹ̀? Bóò bá ráyè bójú tó iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ, bóyá o lè dín àkókò tó o fi ń ṣiṣẹ́ kù tàbí kó o kúkú fi iṣẹ́ náà sílẹ̀.

‘Ra Àkókò Padà’ ní Ilé Ẹ̀kọ́

Láfikún sí wíwá àkókò sí i lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́, ronú nípa bó o ṣe lè túbọ̀ lo àkókò rẹ dáadáa nígbà tó o bá wà nílé ẹ̀kọ́. Josue sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti ṣe èyí tí mo bá lè ṣe lára iṣẹ́ àṣetiléwá mi láwọn àkókò tí n kò bá níṣẹ́ ní kíláàsì. Lọ́nà yẹn, ó máa ń ṣeé ṣe fún mi láti tọ olùkọ́ lọ bí ohun kan ò bá yé mi lára ohun tá a kọ́ ní kíláàsì lọ́jọ́ náà.”

Ohun mìíràn tó tún yẹ kó o gbé yẹ̀ wò ni dídín àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tí kò pọn dandan tóò ń ṣe kù. Bákan náà, o tún lè fẹ́ láti fòpin sí díẹ̀ lára àwọn ìgbòkègbodò tóò ń lọ́wọ́ sí lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́. Nípa ṣíṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ láwọn ọ̀nà wọ̀nyí, o lè rí àkókò púpọ̀ sí i fún ìkẹ́kọ̀ọ́.

Lílo Àkókò Rẹ Lọ́nà Tó Túbọ̀ Gbéṣẹ́ Sí I

Wàyí o, jẹ́ ká gbà pé o ti yẹ̀ ẹ́ sọ́tùn-ún sósì, o sì ti rí àkókò díẹ̀ sí i fún iṣẹ́ àṣetiléwá. Báwo ni wàá ṣe lo àkókò yẹn dáadáa? Bó o bá lè ṣe ìdajì lára iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ láàárín àkókò yẹn, ǹjẹ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o ti jèrè ìdajì sí i lára àkókò tó o nílò? Nítorí náà, àwọn àbá díẹ̀ rèé nípa bó o ṣe lè lo àkókò rẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i.

◼ Wéwèé ohun tó o máa ṣe. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ, kọ́kọ́ ronú nípa àwọn nǹkan bí èyí: Iṣẹ́ wo ni màá kọ́kọ́ mú ṣe? Báwo ni àkókò tó máa gbà mí á ṣe pọ̀ tó? Àwọn nǹkan wo—irú bí ìwé, bébà, báírò àti kakulétọ̀—ni màá nílò láti fi ṣiṣẹ́ náà?

◼ Wá ibi tí wàá ti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ńṣe ló yẹ kó jẹ́ ibi tí ohunkóhun ò ti ní máa pín ọkàn rẹ níyà. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Elyse sọ pé, ‘Bó o bá ní tábìlì ìkàwé, lò ó. Wàá lè pọkàn pọ̀ dáadáa bó o bá jókòó sára dípò kó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn.’ Bí o kò bá dá yàrá tìẹ ní, ó ṣeé ṣe kí àwọn àbúrò rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin gbà pé àwọn ò ní máa yọ ẹ́ lẹ́nu bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Bóyá o sì lè lo ọgbà ìtura kan tàbí ibi ìkówèésí gbogbo gbòò. Bó o bá dá yàrá tìẹ ní, má ṣe pa ara ẹ láyò nípa ṣíṣí tẹlifíṣọ̀n tàbí gbígbé orin tí ń pín ọkàn níyà sí i nígbà tó o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́.

◼ Máa ṣíwọ́ sinmi. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, bí ọkàn rẹ bá ń pínyà, ṣíṣíwọ́ díẹ̀ láti sinmi lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ kó o sì máa kàwé rẹ lọ.

◼ Má ṣe máa sún ohun tó yẹ ní ṣíṣe síwájú! Katie, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ tẹ́lẹ̀, sọ pé: “Mo máa ń sún ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe síwájú gan-an ni. Kì í ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó bá yẹ kí n ṣe àyàfi tó bá ti fẹ́ bọ́ sórí pátápátá.” Kó o má bàa máa sún ohun tó o bá fẹ́ ṣe síwájú, ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ pàtó fún iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ kó o sì máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé fún Màtá, àwọn nǹkan tó dára jù lọ láti máa lépa—‘àwọn tó jẹ́ ìpín rere’—ni àwọn nǹkan tẹ̀mí. Rí i dájú pé iṣẹ́ àṣetiléwá ò gba àwọn ìgbòkègbodò pàtàkì bíi Bíbélì kíkà, kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni mọ́ ọ lọ́wọ́. Ìwọ̀nyí lohun tó máa mú kó o túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé rẹ títí ayérayé!—Sáàmù 1:1, 2; Hébérù 10:24, 25.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Gbígbìyànjú láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà á mú kó ṣòro fún ọ láti ráyè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ètò tó dára lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí àkókò púpọ̀ sí i fún iṣẹ́ àṣetiléwá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́