Ǹjẹ́ Mo Lè Túbọ̀ Ṣe Dáradára Nílé Ẹ̀kọ́?
“Máàkì ló ṣe pàtàkì jù lójú àwọn òbí mi. ‘Kí lo gbà nínú ìdánwò ìṣírò tí o ṣe? Kí lo gbà nínú ìdánwò èdè Gẹ̀ẹ́sì tí o ṣe?’ Kì í dùn mọ́ mi nínú rárá!”—Sam, ọmọ ọdún 13.
SAM nìkan kọ́ ló ní ìṣòro yìí. Ní gidi, àwọn òǹkọ̀wé ìwé “Could Do Better” kọ̀wé pé: “A kò tíì pàdé òbí tó rò pé ọmọ òun ń ṣe dáradára nílé ẹ̀kọ́ tó bí ó ṣe lágbára láti ṣe.” Ṣùgbọ́n bí ti Sam, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ rò pé àwọn òbí àwọn ń dààmú àwọn jù láti mú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ àwọn sunwọ̀n sí i—bóyá kí àwọn tilẹ̀ ta yọ. Wọ́n lè máa kojú àfikún ìdààmú ní iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀dọ́langba kan ráhùn pé: “Àwọn olùkọ́ kì í mú sùúrù tó. Wọ́n ń fẹ́ kí o máa rántí nǹkan lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí o kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn á mú kí o rí ara rẹ bí òpònú. Nítorí náà, n kì í ṣòpò gbìyànjú pàápàá.”
Àwọn ọ̀dọ́ tí kò ṣe tó ohun tí àwọn òbí àti olùkọ́ retí ni a sábà máa ń pè ní aláìdójúùlà. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ni kì í dójú ìlà nílé ẹ̀kọ́ ní àkókò pàtó kan. Èé ṣe? Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, kì í fi ìgbà gbogbo jẹ́ nítorí jíjẹ́ ọ̀lẹ tàbí nítorí àìlèkẹ́kọ̀ọ́.a
Ìdí Tí Àwọn Kan Kò Fi Ń Dójú Ìlà
Lóòótọ́, bí ó bá kan iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, àwọn ọ̀dọ́ kan wà tí ó tẹ́ lọ́rùn pé kí wọ́n ṣáà máa lọ ní fàájì láìsakun. Herman, ọmọ ọdún 15 jẹ́wọ́ pé: “Bí mo bá ṣáà ti lè ṣèwọ̀nba díẹ̀ tí mo sì yege, ìyẹn náà ti tó.” Síbẹ̀síbẹ̀, kí a má gbè síbì kan, gbogbo ọ̀dọ́ kọ́ ni kò já ẹ̀kọ́ kúnra. Ó kàn lè jẹ́ pé ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan ní pàtó kò dùn mọ́ wọn. Àwọn kan tún wà tí ó ṣòro fún láti mọ bí ìwúlò ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣe níye lórí tó. Reuben, ọmọ ọdún 17, sọ ọ́ báyìí pé: “Àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan wà tó dá mi lójú pé n kò ní lò lẹ́yìn tí mo bá ti kúrò nílé ẹ̀kọ́.” Lọ́nà tó rọrùn, àìsí ọkàn ìfẹ́ tàbí ìṣírí lè yọrí sí àìdójúùlà.
Àwọn kókó abájọ mìíràn tún wà. Bí àpẹẹrẹ, bí ọ̀nà ìkọ́ni olùkọ́ kan bá ti yá jù fún ọ, ó lè já ọ kulẹ̀. Bí ó bá fà jù, ó lè sú ọ. Kíkẹ́gbẹ́ tún lè nípa lórí bí o ṣe ń ṣe dáradára sí nílé ẹ̀kọ́. Ìwé Kids Who Underachieve sọ pé: “Bí ọmọ kan tó jáfáfá, tó sì lọ́pọlọ ìwé, bá ń fẹ́ láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà àwọn ojúgbà rẹ̀ tí kò ní góńgó ìwé kíkọ́, ó lè rò pé ó di dandan fún òun láti ṣàìdójúùlà.” Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ́langba kan ráhùn pé nígbà tí òun ń ṣiṣẹ́ àṣekára nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ilé ẹ̀kọ́, àwọn tó kù ń jowú òun, wọ́n sì ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́. Dájúdájú, ọ̀dọ́ kan lè kojú òtítọ́ tó wà nínú ìlànà tó wà nínú Òwe 14:17 pé: “Ènìyàn tí ó ní agbára láti ronú ni a kórìíra.”
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ohun tó ń fa àìdójúùlà ń díjú. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ kan ń ní èrò òdì nípa ara wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Èyí lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá ń sábà pé ọmọ kan ní orúkọ ìnagijẹ tí kò dára, bí dọ̀ǹgíṣọlá, arìndìn, tàbí ọ̀lẹ. Ó bani nínú jẹ́ pé irú ìpenilórúkọ bẹ́ẹ̀ lè di àsọtẹ́lẹ̀ tí ń ṣẹ nínú ara rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí dókítà kan ṣe sọ ọ́, “bí wọ́n bá sọ pé o yadi, tí o sì gbà á gbọ́, ìwọ yóò hùwà bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìsúnniṣe tí àwọn òbí àti àwọn olùkọ́ ń fúnni ń jẹ́ elérò rere. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà náà pàápàá, àwọn ọ̀dọ́ lè rò pé a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ju bó ti yẹ lọ. Bí ó bá jọ pé bí ọ̀ràn tìrẹ ti rí nìyẹn, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé, kì í ṣe pé àwọn òbí àti olùkọ́ rẹ ń fẹ́ mú ọ bínú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n wulẹ̀ ń fẹ́ kí o sa agbára rẹ ní kíkún ni. Síbẹ̀, hílàhílo dídé ojú ìlà lè mú ki o ronú láti wulẹ̀ jáwọ́. Ṣùgbọ́n mọ́kàn: O lè túbọ̀ ṣe dáradára sí i nílé ẹ̀kọ́.
Níní Ìsúnniṣe
Ìgbésẹ̀ kìíní ni láti ní ìsúnniṣe! Láti ṣe ìyẹn, o ní láti rí i pé ohun tí o ń kọ́ ní ète. Bíbélì wí pé: “Ẹni tí ń túlẹ̀ yẹ kí ó túlẹ̀ ní ìrètí, ẹni tí ó sì ń pakà yẹ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìrètí jíjẹ́ alábàápín.” (1 Kọ́ríńtì 9:10) Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti rí ìjẹ́pàtàkì “títúlẹ̀” nínú àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, ‘Mo fẹ́ láti di olùṣètò ìlànà ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà. Nítorí náà, kí ni mo ní láti kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn fún?’
Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ohun tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ ló jọ pé ó tan mọ́ra—ó kéré tán, ní báyìí. Ṣùgbọ́n gbìyànjú láti ní èrò gbígbòòrò. Níní ìmọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti inú oríṣiríṣi ẹ̀ka ẹ̀kọ́ yóò ṣàlékún ohun tí o mọ̀ nípa ohun tó ń lọ láyìíká rẹ. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé níní ìmọ̀ tó kárí dáradára ti ràn àwọn lọ́wọ́ láti “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo,” tí ń fún wọn ní àǹfààní ìyíwọ́padà ní sísọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà fún àwọn ènìyàn tí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ síra. (1 Kọ́ríńtì 9:22) Kódà, bí ó bá jọ pé ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan kò níye lórí tó bẹ́ẹ̀, o ń jàǹfààní nípa mímọ̀-ọ́n dunjú. Ó kéré pin, ìwọ́ yóò ṣàlékún “agbára” tí o ní “láti ronú,” ohun kan tí yóò ṣe ọ́ láǹfààní níkẹyìn.—Òwe 1:1-4.
Ilé ẹ̀kọ́ tún lè ṣàgbéyọ àwọn ẹ̀bùn àbínibí fífarasin tí o ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Máa rú sókè bí iná, ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ń bẹ nínú rẹ.” (2 Tímótì 1:6) Ó ṣe kedere pé a ti yan Tímótì sí iṣẹ́ ìsìn àkànṣe kan nínú ìjọ Kristẹni. Ṣùgbọ́n agbára ìlèṣeǹkan tí Ọlọ́run fi fún un—“ẹ̀bùn” rẹ̀—nílò ìmúdàgbà, kí ó má bàa wà láìṣiṣẹ́, kí ó sì ṣòfò. Dájúdájú, àwọn agbára ìwé tí o mọ̀ kì í ṣe ẹ̀bùn kan tí Ọlọ́run fún ọ ní tààrà bí ẹ̀bùn tí ó fún Tímótì. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn agbára ìlèṣeǹkan tí o ní—yálà nínú iṣẹ́ ọnà, orin, ìṣírò, sáyẹ́ǹsì, tàbí àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ mìíràn—jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún ọ, ilé ẹ̀kọ́ sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, kí o sì mú wọn dàgbà.
Àṣà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rere
Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ yóò nílò ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tó gbámúṣé láti jàǹfààní nínú lílọ sílé ẹ̀kọ́. (Fi wé Fílípì 3:16.) Máa wéwèé àkókò púpọ̀ tó láti kárí ọ̀pọ̀ ohun tí o fẹ́ ṣe, ṣùgbọ́n máa fún ara rẹ ní àkókò ìsinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí o lè nara. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí o ń ṣe bá ní ìwé kíkà nínú, kọ́kọ́ wò gààrà kárí ohun tí o fẹ́ kà náà kí o lè mọ ohun tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè lórí àwọn àkọlé orí kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn àkọlé kéékèèké. Lẹ́yìn náà, kà á, kí o wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ bí o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, wò ó bóyá o lè rántí àwọn ohun tí o ti kọ́.
So àwọn ohun tí o kọ́ mọ́ àwọn tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì kan lè jẹ́ fèrèsé kan tí o ń gbà ‘rí àwọn ànímọ́’ Ọlọ́run “tí a kò lè rí” ‘ní kedere.’ (Róòmù 1:20) Ẹ̀kọ́ nípa ìtàn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ẹ̀rí òtítọ́ inú gbólóhùn náà múlẹ̀ fúnra rẹ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Bí o ti ń fi ara rẹ fún ẹ̀kọ́ kíkọ́, ó ṣeé ṣe kí o rí i pé ẹ̀kọ́ kíkọ́ túbọ̀ ń rọrùn sí i—ó túbọ̀ ń gbádùn mọ́ni pàápàá! Sólómọ́nì wí pé: “Sí olóye, ìmọ̀ jẹ́ ohun rírọrùn.”—Òwe 14:6.
Ní Ìṣarasíhùwà Títọ́
Nígbà mìíràn, bí ó ti wù kí ó rí, àìdójúùlà ní ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí ẹnì kan yàn. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń fún ọ níṣìírí láti ṣàṣeyọrí, tàbí àwọn fúnra wọn kì í dójú ìlà? Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Nítorí náà, fi ọgbọ́n yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ. Máa bá àwọn tí wọ́n ní ìṣarasíhùwà títọ́ nípa ilé ẹ̀kọ́ kẹ́gbẹ́. Má ṣe lọ́ra láti bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀ fúnra rẹ nípa ètè rẹ láti mú kí máàkì tí o ń gbà sunwọ̀n sí i. Láìsíyèméjì, olùkọ́ rẹ yóò ṣe ìsapá àrà ọ̀tọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí o bá ń ní èrò òdì nípa agbára ìlèṣeǹkan rẹ, gbé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Nígbà tí àwọn ènìyàn ń ṣàríwísí agbára ìsọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fèsì pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:6) Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù pọkàn pọ̀ sórí okun rẹ̀, kì í ṣe sórí àwọn àìlera rẹ̀. Kí ni okun tí o ní? Bí o kò bá dá a mọ̀, èé ṣe tí o kò bá àgbàlagbà alátìlẹ́yìn kan jíròrò? Irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ibi tí o lókun sí, kí o sì lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Títẹ̀síwájú Láìka Àwọn Ìṣòro Sí
“Fi gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo agbára rẹ, sí àwọn nǹkan wọ̀nyí, kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn kedere fún gbogbo ènìyàn láti rí.” (1 Tímótì 4:15, Phillips) Bí ìgbà tí baba kan ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì tó ti ṣàṣeyọrí náà láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Gíríìkì náà, “ìlọsíwájú,” túmọ̀ ní olówuuru sí “lílà kọjá síwájú,” èyí tó mú àwòrán ẹnì kan tí ń la ọ̀nà kọjá nínú ìgbẹ́ wá síni lọ́kàn. Nígbà mìíràn, lílọ sílé ẹ̀kọ́ lè jọ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n yóò túbọ̀ rọrùn láti kọjá lójú ọ̀nà lílọ sílé ẹ̀kọ́ náà bí o bá ń ronú pé èrè tó ń bọ̀ níkẹyìn níye lórí tó bẹ́ẹ̀.
Ìsapá, ìsúnniṣe, àti ẹ̀kọ́ kíkọ́ wà nífẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Bí àpèjúwe: Ronú nípa ẹnì kan tí ń lo ohun èlò ìkọrin kan. Bí ó bá ń gbádùn rẹ̀, yóò túbọ̀ máa lò ó sí i. Bí ó ti ń lò ó sí i tó, ni ó ń mọ̀ ọ́n lò dáradára sí i tó, tó sì ń fi kún ayọ̀ rẹ̀ ní àbárèbábọ̀. Bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i tó, ni ó túbọ̀ ń rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́ tó. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ mú ọ rẹ̀wẹ̀sì. Sa ipa tí ó pọn dandan, bá àwọn tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ta yọ kẹ́gbẹ́, sì fí àwọn ọ̀rọ̀ tí Asaráyà sọ fún Ọba Ásà ìgbàanì sọ́kàn pé: “Ẹ má . . . jẹ́ kí ọwọ́ yín rọ jọwọrọ, nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.”—2 Kíróníkà 15:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ọ̀ràn yìí, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ní àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ lè máa kojú ìṣòro gbígbàfiyèsí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Jí!, June 22, 1996, ojú ìwé 11 sí 13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Má ṣe lọ́ra láti bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ètè rẹ láti mú kí máàkì tí o ń gbà sunwọ̀n sí i
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Kódà, bí ó bá jọ pé ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan kò níye lórí tó bẹ́ẹ̀, o ń jàǹfààní nípa mímọ̀-ọ́n dunjú