Eyín Erin—Báwo Ló Ṣe Níye Lórí Tó?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ
Níbi ìpàdé àpérò àgbáyé kan ní Harare, Zimbabwe, ní June 1997, àwọn aṣojú láti orílẹ̀-èdè 138 dìbò pé kí wọ́n dẹwọ́ òfin tí wọ́n ti ṣe lọ́dún méje ṣáájú, tí wọ́n fi de òwò eyín erin kárí ayé. Ìpinnu náà, tí wọ́n ṣe lẹ́yìn àríyànjiyàn lílekoko kan, fún àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta ní gúúsù Áfíríkà—Botswana, Namibia, àti Zimbabwe—láyè lábẹ́ àwọn ipò àfilélẹ̀ kan, láti máa ta eyín erin fún orílẹ̀-èdè kan, Japan. Inú àwọn aṣojú láti gúúsù Áfíríkà dùn dẹ́yìn nítorí ìpinnu yìí, wọ́n sì mórin bọnu. Àwọn aṣojú mìíràn dààmú tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù lórí ohun tí èyí lè túmọ̀ sí fún erin ilẹ̀ Áfíríkà.
NÍGBÀ tí Hannibal gbógun ti ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù ní ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, ó ní ọ̀wọ́ erin ilẹ̀ Áfíríkà tí a fi dọ́sìn lọ́dọ̀. Ní àkókò wọ̀nyẹn, ó ṣeé ṣe kí iye àwọn erin ilẹ̀ Áfíríkà tó wà ti jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́wàá-mẹ́wàá, kí wọ́n sì ti wà láti Cape dé Cairo.
Nǹkan yí padà. Alákìíyèsí kan sọ pé: “Ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ láàárín ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ erin yí padà sí ìwọ̀nba erin díẹ̀ tí ń kéré sí i láàárín ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn.” Bí iye ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i, àwọn erin ń pàdánù ìjìjàdù ilẹ̀. Kókó mìíràn tó mú kí iye àwọn erin máa dín kù ni bí Aṣálẹ̀ Sàhárà ṣe ń fẹ̀ lọ síhà gúúsù.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju àwọn wọ̀nyí lọ ni bí àwọn ènìyàn ṣe ń béèrè fún eyín erin. A kò ka eyín erin mọ́ ohun tó wúlò fún egbòogi kankan, bí a tí ṣe fún egungun ẹkùn àti ìwo ẹranko rhino. Síbẹ̀, ó níye lórí gidigidi, ó rẹwà, ó lálòpẹ́, ó sì rọrùn láti fi gbẹ́ nǹkan. Látayébáyé ni a ti ka eyín erin mọ́ àwọn ohun tó níye lórí gan-an, tó sì ń dáni lọ́rùn.
Irínwó ọdún lẹ́yìn ikú Hannibal, Ilẹ̀ Ọba Róòmù pa àwọn erin àríwá Áfíríkà nípakúpa láti tẹ́ ìfẹ́-ọkàn wọn láti ní eyín erin lọ́rùn. Láti ìgbà náà wá ni ìfẹ́ ọ̀kan àìníjàánu náà sì ti ń bá a lọ ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ìyánhànhàn náà ti lágbára sí i—kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọnà àti àwọn ohun èlò ìjọsìn bí ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti fi ṣe dùùrù olóhùn gooro. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Battle for the Elephants ṣe wí, ní 1910 nìkan, nǹkan bí 700 tọ́ọ̀nù eyín erin (tó túmọ̀ sí 13,000 erin tí a pa) ni a fi ṣe 350,000 dùùrù olóhùn gooro ní United States.
Pípẹran-Láìgbàṣẹ Lọ́nà Tí Kò Níjàánu
Lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní, àwọn ènìyàn kò béèrè fún eyín erin tó bẹ́ẹ̀ mọ́, wọ́n gbé àwọn òfin ìdáàbòbo-ẹran tuntun kalẹ̀, àwọn erin sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó fi di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, pípa ẹran lọ́pọ̀ yanturu tún bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun. Ní báyìí, àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ní láárí bọ̀ ló ń béèrè eyín erin.
Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn kókó méjì ló ń tọ́ka àjálù fún àwọn erin ní Áfíríkà. Èkíní ni bí àwọn ohun ìjà fífúyẹ́, tó sì díjú, ṣe wà lọ́pọ̀ yanturu sí i. Ó ti rọrùn láti yìnbọn pa odindi agbo-erin láìṣe ẹyọ kan péré. Lọ́nà kejì, àwọn ohun èlò oníná tí a fi ń gbẹ́ nǹkan túmọ̀ sí pé a lè yára sọ eyín erin di àwọn ohun títà. Látijọ́, oníṣọ̀nà ará Japan kan ti lè lo odindi ọdún kan láti gbẹ́ eyín erin kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ní lílo àwọn ohun èlò oníná, ilé iṣẹ́ eléèyàn mẹ́jọ kan tí ń ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti hanko (àwọn òǹtẹ̀ orúkọ tó gbajúmọ̀ ní Japan) lè lo eyín àwọn 300 erin tán lọ́sẹ̀ kan péré. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń béèrè fún eyín erin sí i ti mú kí owó rẹ̀ lọ sókè sí i. Dájúdájú, owó rẹpẹtẹ náà kò lọ sápò àwọn apẹran-láìgbàṣẹ náà, àpò àwọn alágbàtà àti àwọn oníṣòwò, tí ọ̀pọ̀ lára wọn di ọlọ́rọ̀ jaburata, ló ń lọ.
Iye erin tí a ń tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù múni gbọ̀n rìrì. Láàárín nǹkan bí ẹ̀wádún méjì, Tanzania pàdánù ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn erin rẹ̀, àwọn apẹran-láìgbàṣẹ ló pa èyí tó pọ̀ jù. Kẹ́ńyà pàdánù ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún erin rẹ̀. Uganda pàdánù ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún. Lákọ̀ọ́kọ̀, àwọn apẹran-láìgbàṣẹ ń yìnbọn pa kìkì àwọn àgbà akọ erin nítorí pé eyín tiwọn lo tóbi jù. Ṣùgbọ́n bí àwọn àgbà erin náà ṣe ń tán lọ, àwọn apẹran-láìgbàṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn pa àwọn ọmọ erin pàápàá nítorí eyín wọn kéékèèké. Láàárín àkókò yẹn, ó ṣeé ṣe kí àwọn erin tí a pa nítorí eyín wọn ti lé ní mílíọ̀nù kan, tí ó dín iye erin ilẹ̀ Áfíríkà kù sí 625,000.
Ìfòfindè Kárí Ayé
Àwọn ìsapá láti kápá òwò eyín erin, kí a sì fòpin sí ìpakúpa náà, forí ṣánpọ́n gan-an. Níkẹyìn, ní October 1989, níbi ìpàdé àpérò kan ní Switzerland, Àdéhùn Fífi Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Ewéko àti Ẹranko Tí A Wu Léwu Ṣòwò Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè (CITES) fòfin de gbogbo ìṣòwò-eyín-erin láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀. Wọ́n fi owó rẹpẹtẹ ṣètìlẹ́yìn fún ìfòfindè náà láti dáàbò bo àwọn erin nínú igbó.
Àwọn kan sọ tẹ́lẹ̀ pé fífòfinde òwò eyín erin yóò mú kí owó rẹ̀ lọ́jà fàyàwọ́ pọ̀ sí i, pípẹran-láìgbàṣẹ yóò sì pọ̀ sí i. Òdì-kejì rẹ̀ ni ohun tó ṣẹlẹ̀. Iye owó lọ sílẹ̀ dòò, ọjà tó ti ń mówó wọlé nígbà kan rí sì kógbá sílé. Bí àpẹẹrẹ, ní Íńdíà, àràtúntà eyín erin lọ sílẹ̀ ní ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún, ó sì di dandan pé kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ń lo eyín erin ní orílẹ̀-èdè náà wá iṣẹ́ mìíràn ṣe. Pípẹran-láìgbàṣẹ dín kù lọ́nà gbígbàfiyèsí. Kí ìfòfindè náà tó dé, ó kéré tán, àwọn apẹran-láìgbàṣẹ tó wà ní Kẹ́ńyà ń pa 2,000 erin lọ́dún kan. Nígbà tó fi di 1995, iye náà ti dín kù sí 35. Síwájú sí i, iye àwọn erin ní Kẹ́ńyà pọ̀ sí i láti 19,000 tó wà ní 1989 sí nǹkan bí 26,000 tó wà lónìí.
Nítorí ìdí wọ̀nyí, Àjọ Aṣèwádìí Ọ̀ràn Àyíká, tó fìdí kalẹ̀ sí London, gbóríyìn fún ìfòfinde òwò eyín erin náà gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí kíkàmàmà nínú ìtàn ìdáàbòbò ti lọ́ọ́lọ́ọ́.” Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló fara mọ́ ìtara ọkàn rẹ̀, ní pàtàkì, ní gúúsù Áfíríkà.
Àwọn Erin Gúúsù Áfíríkà
Àwọn orílẹ̀-èdè gúúsù Áfíríkà ní erin tó lé ní 200,000, tàbí nǹkan bí ìdá mẹ́ta gbogbo erin tó wà ní Áfíríkà. Lọ́nà kan, èyí jẹ́ nítorí àwọn ìlànà ìdáàbòbò tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ àti lọ́nà mìíràn, nítorí pé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ ológun adìhámọ́ra-tẹnutẹnu tó pa àwọn agbo-erin ní Ìlà Oòrùn àti Àáríngbùngbùn Áfíríkà.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí iye àwọn erin náà ṣe ń pọ̀ sí i, ìforígbárí sábà máa ń wà láàárín àwọn erin àti àwọn ènìyàn tí ń gbé àwọn àgbègbè àrọko. Ó ṣe tán, ikùn àgbà erin fẹ̀, ó sì lè jẹ ewéko tó lé ní 300 kìlógíráàmù lọ́jọ́ kan ṣoṣo. Bí erin kan bá ń gbé àdúgbò rẹ, ìwọ náà mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Ẹgbẹ́ Aṣàbójútó Ohun Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Áfíríkà, tó fìdí kalẹ̀ sí Zimbabwe, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ará àrọko ilẹ̀ Áfíríkà ń fojú ẹ̀rù, ìfura àti ìkóguntini wo erin. Láàárín wákàtí mélòó kan péré, àwọn erin lè pa gbogbo ọ̀nà ìgbọ́bùkátà àwọn ènìyàn run nípa jíjẹ àwọn irè oko wọn run tàbí títẹ àwọn ohun ọ̀sìn wọn pa. Wọ́n tún ń ba àwọn ilé àti ilé ẹ̀kọ́, ibùso ẹran, igi eléso, ìsédò àti ojú ilẹ̀ jẹ́. Lójoojúmọ́ ni àwọn ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò ń gbé ìròyìn nípa àwọn nǹkan tí erin bà jẹ́.”
Àwọn orílẹ̀-èdè ìhà gúúsù Áfíríkà máa ń fi àṣeyọrí tí wọ́n ṣe láti ní iye àwọn erin jíjọjú yangàn. Ṣùgbọ́n ìdáàbòbò gbówó lérí gan-an, wọn kò sì gbà gbọ́ pé ó yẹ kí a fìyà jẹ àwọn nítorí àwọn ìṣòro tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nílẹ̀ Áfíríkà ń ní. Wọ́n ronú pé, òwò eyín erin tí ó láàlà yóò mú kí owó lè máa wọlé padà láti fi gbọ́ bùkátà àwọn ìsapá wọn láti dáàbò bo àwọn erin náà, kí wọ́n sì san àsanpadà fún àwọn àgbẹ̀ àrọko lórí ohun tí wọ́n bá pàdánù.
Ìtòjọpelemọ Eyín Erin
Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn erin ti ń yan kiri, a ń to eyín erin jọ. Ó ń jẹ́ ti àwọn erin tí a pa lọ́nà bíbófinmu láti dín iye wọn kù, àwọn tó kú lọ́nà àdánidá, àti àwọn tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tó kó wọn jọ lọ́nà àìbófinmu. Kí la ń fi àwọn eyín erin wọ̀nyí ṣe?
Kẹ́ńyà ń dáná sun àwọn eyín erin rẹ̀. Láti July 1989 wá, Kẹ́ńyà ti dáná sun eyín erin tó níye lórí tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là, láìsí ìsanpadà tààrà kankan láti òde wá. Ní 1992, Zambia pẹ̀lú dáná sun ìtòjọpelemọ eyín erin rẹ̀. Ìsọfúnni náà ṣe kedere pé: Kẹ́ńyà àti Zambia kò fẹ́ kópa nínú òwò eyín erin.
Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tọ́jú àwọn ìtòjọpelemọ tiwọn pamọ́ fún ìdókòwò ọjọ́ iwájú. Àjọ TRAFFIC, àjọ títóbijù tí ń bójú tó ọ̀ràn àwọn ẹran ìgbẹ́ lágbàáyé fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àròpọ̀ eyín erin tí àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà pa mọ́ kéré tán, ó tó tọ́ọ̀nù 462, tó níye lórí tó mílíọ̀nù 46 dọ́là. Botswana, Namibia, àti Zimbabwe, àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta tí wọ́n yọ̀ǹda fún láti máa bá Japan ṣòwò nísinsìnyí, ní 120 tọ́ọ̀nù eyín erin. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń béèrè pé, ‘Ní àgbègbè kan tí àwọn ènìyàn ń tiraka ní ti ọrọ̀ ajé, èé ṣe tí a fi ń jẹ́ kí eyín erin máa bu sí ilé ìkóǹkanpamọ́? A kò ṣe tà á, kí a sì lo owó rẹ̀ fún ìdáàbòbò?’
A Ṣì Ń Dààmú
Nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ń jiyàn pé dídẹwọ́ òfin tí a fi de òwò eyín erin yóò ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo erin, àwọn mìíràn gbà gbọ́ dájú pé ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo tí kò ní jẹ́ kí àwọn apẹran-láìgbàṣẹ lókun sí i ni ìfòfindè pátápátá. A ń dààmú lórí bí a ṣe fọwọ́ dan-indan-in mú ìkápá òwò náà tó. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà ìtajà lè pèsè ọ̀nà àbáyọ kan tí eyín àwọn erin tí a pa láìgbàṣẹ lè máa gbà wọjà òwò bíbófinmu náà? Bákan náà, pípẹran-láìgbàṣẹ tí a finú rò ńkọ́? Ǹjẹ́ dídẹwọ́ ìfòfindè náà lè túmọ̀ sí pé àwọn tí ń retí pé a óò túbọ̀ dẹwọ́ ìfòfindè náà lọ́jọ́ iwájú yóò pa àwọn erin, wọn yóò sì kó eyín wọn pa mọ́?
Láfikún sí ìdààmú wọ̀nyí ni kókó náà pé ìbọn ti pọ̀ sí i ju ti ìgbàkigbà rí lọ ní Áfíríkà. Àwọn ogun abẹ́lé tó ṣẹlẹ̀ níbí ti mú kí ọwọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣe tán láti lo ìbọn àgbétèjìká láti fi wá owó nítorí ipò ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ, tẹ àwọn ìbọn náà. Nehemiah Rotich, olùdarí Ẹgbẹ́ Aláàbò Ẹran Ìgbẹ́ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, kọ̀wé pé: “Kò sí iyèméjì pé, pẹ̀lú iye owó tí a gbé lé orí eyín erin [nítorí òwò tí a sọ dọ̀tun náà], àwọn ènìyàn yóò dojú ìbọn wọ̀nyí kọ àwọn erin—ó ṣe tán, ó túbọ̀ rọrùn láti pa erin nínú ọgbà ohun alààyè títóbi kan ju láti ja báńkì kan lólè nínú ìlú ńlá lọ.”
Ìṣòro mìíràn láfikún ni pé àwọn ìgbésẹ̀ lòdì sí pípẹran-láìgbàṣẹ gbówó lórí, wọ́n sì tún ṣòro. Rírìn káàkiri àwọn àgbègbè gbígbòòrò tí àwọn erin ti ń jẹun ń náni lówó. Ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, èyí nira láti rí.
Kí Ni Ọjọ́ Ọ̀la Àwọn Erin?
A ṣì ń wo ohun tí ìpinnu láti dẹwọ́ òfin òwò eyín erin yóò mú wá. Síbẹ̀, bí nǹkan bá lọ dáadáa pàápàá, wíwu-erin-léwu kò ní kásẹ̀ nílẹ̀. Iye àwọn ènìyàn tó nílò ilẹ̀ láti fi dáko àti fún àwọn ète mìíràn, tí ń pọ̀ sí i, tún ń wu erin léwu. Ní gúúsù Áfíríkà nìkan, fún ètè iṣẹ́ àgbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, ó lé ní 850,000 hẹ́kítà igbó—ìwọ̀n ilẹ̀ tó jẹ́ ìdajì gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì—tí àwọn ènìyàn ń gé lulẹ̀ lọ́dọọdún. Ó dájú pé bí iye àwọn ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i ni iye àwọn erin túbọ̀ ń kéré sí i.
Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Kókó kan wà tí gbogbo ẹni tó ti ṣàkíyèsí ìṣòro náà fohùn ṣọ̀kan lé lórí pé: erin ilẹ̀ Áfíríkà dojú kọ ọjọ́ ọ̀la lílekoko kan. Ìṣòro ibùgbé àdánidá [nítorí iye ènìyàn tí ń pọ̀ sí i] yóò túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ erin yóò kú láìtọ́jọ́, lọ́nà kan tàbí òmíràn. Bí àwọn ọdẹ tó gbàṣẹ kò bá pa wọ́n, tí a kò pa wọ́n lọ́nà bíbófinmu láti dín iye wọn kù—tàbí tí àwọn apẹran-láìgbàṣẹ kò pa wọ́n—púpọ̀ sí i lára wọn ni ebi yóò pa kú, tí iye wọn yóò sì dín kù.”
Ìfojúsọ́nà tí kò dán mọ́rán yìí gbójú fo èrò àti ète Ẹlẹ́dàá erin, Jèhófà Ọlọ́run, dá. Àníyàn tí Ọlọ́run ní fún àwọn ẹ̀dá tí ó ti dá hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:6) Bí Ọlọ́run kò bá gbàgbé ológoṣẹ́ kékeré kan, ó lè dá wa lójú pé kò ní gbójú fo ìṣòro tí ń kojú erin lákátabú dá.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Nípa Eyín Erin
“Ó dájú pé nǹkan rírẹwà kan ni eyín erin. Ó ní irú ìtànyanranyanran àti ìwọnilọ́kàn kan tí kò dà bí ti ohunkóhun mìíràn tí a ń lò fún ọ̀ṣọ́ tàbí ohun gbígbẹ́. Ṣùgbọ́n, mo sábà máa ń lérò pé àwọn ènìyàn ń gbàgbé pé eyín erin kan ni. A ń ní ìtẹ̀sí láti tò ó pọ̀ mọ́ jéèdì, igi teak, igi ẹ́bónì, ohun ọ̀ṣọ́ amber, kódà, wúrà àti fàdákà pàápàá, ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà, pé: Ara ẹranko kọ́ la ti mú àwọn ohun tó kù wá; eyín erin jẹ́ eyín ọ̀gangan kan tó ta yọ. Nígbà tí ẹnì kan bá mú ẹ̀gbà ọwọ́ rírẹwà tí a fi eyín erin ṣe tàbí ọnà gbígbẹ́ tí ń dáni lọ́rùn kan dání, ó yẹ kí ẹni náà ní àfikún òye pé ègé eyín erin yẹn wá láti ara erin kan tí ó ti fìgbà kan rí ń rìn kiri, tí ó ń fi eyín rẹ̀ jẹun, tí ó ń fi gbẹ́lẹ̀, tí ó ń fi gún nǹkan, tí ó ń fi ṣeré, tí ó sì ń fi jà, kí ó sì mọ̀ síwájú sí i pé, pípa ni wọ́n pa erin náà kí ègé eyín erin náà tó lè dé ọwọ́ òun.”—Elephant Memories, láti ọwọ́ Cynthia Moss.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Nípa Àwọn Erin
Àwọn erin lágbára púpọ̀, bí wọ́n bá sì ń bínú, ilẹ̀ máa ń mì ni. Erin lè fi ọwọ́jà rẹ̀ gbé ènìyàn, kí ó sì sọ ọ́ nù bí òkò. Síbẹ̀, erin tún lè máa fi ọwọ́jà rẹ̀ pa ọ́ lára tàbí kí ó rọra fi mú oúnjẹ lọ́wọ́ rẹ. Àwọn erin ní làákàyè, wọ́n ṣòro lóye, wọ́n sì lè pani lẹ́rìn-ín. Wọ́n ń ṣàgbéyọ ìdúróṣinṣin ti ìdílé, wọ́n sì ń bá èkíní-kejì wọn ṣètọ́jú ibi tó bá ti fara pa, wọ́n ń bójú tó èyí tó bá ń ṣàìsàn nínú wọn, wọ́n sì ń dárò ikú mẹ́ńbà ìdílé wọn. Nígbà tí wọ́n máa ń ṣàìka òkú àwọn ẹranko mìíràn sí, wọ́n ń dá egungun àwọn erin mìíràn mọ̀, wọ́n sì ń hùwà padà nípa títú wọn ká tàbí sísin wọ́n.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn orílẹ̀-èdè méjì ti dáná sun àwọn eyín erin wọn; àwọn mìíràn tọ́jú àwọn ìtòjọpelemọ tiwọn pamọ́ bí ohun ìdókòwò