Ìdáàbò Bò Ní Ìdojú Kọ Àkúrun
ÌWỌ̀YÁ ìjà láàárín ìdáàbòbò àti àkúrun ń bá a lọ láìdẹwọ́. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ aláàánú ń ti ìjọba láti ṣàmúlò àwọn òfin ìdáàbòbò tí ó túbọ̀ le koko sí i láti lè dáàbò bo àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu.
Fún àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí, onírúurú àwùjọ́ pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ China, wọ́n sì jèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn nínú ìsapá láti fòpin sí dídọdẹ àwọn béárì dúdú ilẹ̀ Éṣíà. A ti ń dọdẹ àwọn ẹranko wọ̀nyí nítorí òróòro àti àpò òróòro wọn, tí a máa ń lò fún egbòogi ìṣègùn ìbílẹ̀ ní ìhà Ìlà Oòrùn.
Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́pọ̀ Orílẹ̀-Èdè
Dídáàbò bo irú ọ̀wọ́ kan ní orílẹ̀-èdè kan ṣùgbọ́n tí a ń pa á run níbòmíràn kò lè mú ìdáàbòbò náà yọrí sí rere. Lójú ìwòye èyí, ẹ̀rí ti wà pé ìfohùnṣọ̀kan ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdé bágbà mu—ọ̀pọ rẹ̀ ló sì wà. Àdéhùn Lórí Ìjónírúurú Ohun Alààyè, Àdéhun Rio, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní òpin ọdún 1993, tí Ìfohùnṣọ̀kan Lórí Ìdáàbò Bo Àdán ní Europe sì tẹ̀ lé e. Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Àgbáyé Lóri Pípa Ẹja Àbùùbùtán fi ibi ìdáàbò bo ẹja àbùùbùtán Òkun Gúúsù kún ti Òkun India nínú ìgbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ẹja àbùùbùtán ńlá, alára rírọ̀. Ṣùgbọ́n bóyá àdéhùn tí ó lágbára jù lọ ni Àdéhùn Òwò Àjọṣe Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu.—Wo àpótí.
Ènìyán ṣì ní púpọ̀ láti kọ́ nípa ìbátan àwọn ẹ̀dá sí èkíní-kejì wọn. Àwọn apẹja ará Ìlà Oòrun Áfíríkà tí wọ́n kó ẹja ńlá perch odò Náìlì lọ sínú Adágún Victoria láti pèsè oúnjẹ ti ṣokùnfà ohun tí onímọ̀ nípa ẹranko, Colin Tudge, pè ní “ìjábá títóbi jù lọ nínú ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn nínú ọ̀rúndún yìí.” Nǹkan bí 200 lára 300 irú ọ̀wọ́ ẹja ìbílẹ̀ adágún náà ni ó kú run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ẹ̀rí lọ́ọ́lọ́ọ́ di ẹ̀bi dídabarú ìbáradọ́gba àwọn irú ọ̀wọ́ ru ìṣànlọ erùpẹ̀, àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó múlé gbe adágún náà ti ṣàgbékalẹ̀ àjọ kan láti pinnu oríṣi ìrú ọ̀wọ́ ẹja tí a lè ṣẹ̀ṣẹ̀ kó sínú adágún náà láìfi àwọn ti ìbílẹ̀ sínú ewu.
Bí Ẹ̀dá Ènìyán Ṣe Dá Sí I
Ọ̀nà kan tí ó ní àṣeyọrí ni ètò ìbísí nípamọ́ tí àwọn ọgbà ẹranko kan ń bójú tó. Tudge sọ pé: “Bí gbogbo ọgbà ẹranko àgbáyé bá lo agbára àti ohun àmúṣọrọ̀ wọn fún ìdàgbàsókè ìbísí nípamọ́, tí àwọn ará ìlú bá sì ṣètìlẹ́yìn gidi fún àwọn ọgbà ẹranko náà, nígbà náà, wọn yóò lè pawọ́ pọ̀ dáàbò bo gbogbo irú ọ̀wọ́ ẹ̀dá eléegun ẹ̀yìn tí ó ṣeé ṣe kí ó nílò ìbísí nípamọ́ ní ọjọ́ iwájú tí a lè rí tẹ́lẹ̀.”—Last Animals at the Zoo.
Ọgbà ẹranko erékùṣù kékeré Jersey ní Britain ń ṣe ìbísí àwọn ẹranko ṣíṣọ̀wọ́n pẹ̀lú èròǹgbà láti tún dá wọn padà sínú ìgbẹ́. Ní 1975, kìkì 100 odídẹrẹ́ St. Lucia ló ṣẹ́ kù sí ibùgbé àdánidá wọn ní erékùṣu Caribbean. A kó méje lára àwọn ẹyẹ wọ̀nyí lọ sí Jersey. Nígbà tí ó fi di 1989, ọgbà ẹranko náà ti ṣe ìbísí 14 sí i, wọ́n sì ti dá díẹ̀ lára wọn padà sí St. Lucia. Nísinsìnyí, ìròyín sọ pé iye tí ó tó 300 ni ó wà ní erékùṣù yẹn.
Irú ìwéwèé kan náà ti kẹ́sẹ járí níbòmíràn pẹ̀lú. Ìwé ìròyin National Geographic ròyìn pé àwọn ìkokò pupa 17 tó ṣẹ́ kù ní Àríwá America bí sí i dáradára ní ìpamọ́ débi pé a ti dá èyí tí ó lé ní 60 lára wọn padà sínú ìgbẹ́.
Ó Ha Kẹ́sẹ Járí Jù Bí?
Kò sábà fi dandan túmọ̀ sí pé àkúrun ń halẹ̀ mọ́ àwọn ẹranko tí ó wà nínú ewú. Gẹ́gẹ́ bí ìwe Endangered Species—Elephants ṣe wí, láàárín 1979 sí 1989, iye àwọn erin ilẹ̀ Áfíríkà dín kù láti 1,300,000 sí 609,000—tí díẹ̀ làra èyí jẹ́ nítorí àtikó eyín erin jọ láìgbàṣẹ. Ìdààmú àwọn ará ìlú pọ̀ lórí ìjọba láti fòfin de òwò eyín erin. Síbẹ̀, àtakò lòdì sí ìfòfindè lórí eyín erín di gbígbóná janjan. Èé ṣe?
Ní àpapọ̀ Zimbabwe àti Gúúsù Áfíríkà, àwọn ìlànà ìdáàbòbó kẹ́sẹ járí tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọgbà ohun alààyè orílẹ̀-ède wọn àti àwọn ibi ìdáàbò bo ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn fi ní iye erin tí ó pọ̀ jù. Ìwé ìròyin New Scientist ròyìn pé Zimbabwe gbọ́dọ̀ kó 5,000 erin kúrò ní Ọgbà Ohun Alààyè ní Hwange. Àwọn ẹgbẹ́ eléròǹgbà ìdáàbòbò dámọ̀ran kíkó wọn lọ síbòmíràn. Àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ohun alààyè náà gbà láti ta àwọn tí erin náà fi pọ̀ jù, wọ́n sì dábàá pé kí àwọn ẹ̀ka Ìwọ̀ Oòrùn Ayé tí ń ṣàtakò sí pípa wọ́n láti dín iye wọn kù “pèsè ìrànwọ́ owó fún ìṣínípò àwọn ẹran náà, dípò wíwulẹ̀ pèsè ìmọ̀ràn nìkan.”
Ìfojúsọ́nà Tí Kò Dájú
Síbẹ̀síbẹ̀, àìkẹ́sẹjárí ń ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ ń ṣàníyàn nípa ipò ọ̀ràn àwọn irú ọ̀wọ́ tí a dá padà sínú ìgbẹ́. Ẹkùn Siberia gbádùn ìwàláàyè dáadáa ní ìpamọ́, ṣùgbọ́n nínú ìgbẹ́, yóò nílò nǹkan bí 260 kìlómítà igbó, tí kò ní àwọn adọdẹpẹran láìgbàṣẹ, níbùú lóròó. Ní àfikún sí i, ìwé ìròyin The Independent on Sunday sọ pé, “dá ẹkùn kan tí a tọ́ dàgbà nínú ọgbà ẹranko padà sínú ibùgbé àdánidá rẹ̀ ní tààrà, ebi yóò sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pa á kú.” Ìfojúsọ́nà onídàágùdẹ̀ ní tòótọ́!
Ní ti gidi, gbogbo irú ọ̀wọ́ kọ́ ló ní àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùrànlọ́wọ́ tirẹ̀. Kì í sì í wulẹ̀ẹ́ ṣe nítorí pé kò sí ẹni tí yóò ṣiṣẹ́ ló mú ìṣòro náà díjú. Bí ó ti wù kí àwọn olùdáàbò bó fara jìn tó, ìrètí wo ni wọ́n ní láti kẹ́sẹ járí lójú ìwà ìbàjẹ́, ìwọra, àti ìdágunlá àwọn aláṣẹ pa pọ̀ mọ́ ogun àti ìhalẹ̀ ikú mọ́ni? Nígbà náà, kí ni ojútùú ìṣòro àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu? Báwo ni ó sì ṣe kàn ọ́?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ohun Ìjà Àgbáyé Kan
Àdéhùn Òwò Àjọṣe Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu jẹ́ ohun ìjà lílágbára kan nínú ogun lòdì sí fífi àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu ṣòwò láìbófin mu. Awọ àmọ̀tẹ́kùn, eyín erin, egungun ẹkùn, ìwo ẹranko rhino, àti ìjàpá wà lára àwọn ọjà tí a fòfin dè ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Àdéhùn náà nasẹ̀ dé orí igi gẹdú àti onírúurú ọ̀wọ́ ẹja tí a ń wu léwu.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé ìròyin Time kìlọ̀ pé: “Láìjẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà bá wá ọ̀nà láti rí i pé a rọ̀ mọ́ àwọn òfin náà, . . . wọ́n lè rí i pé àwọn ẹranko tí wọ́n ń gbìyànjú láti dáàbò bò ti pòórá.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ìsapá ìdáàbòbò mélòó kan ha ti kẹ́sẹ járí jù bí?
[Credit Line]
Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀dá onínúure Clive Kihn