ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/8 ojú ìwé 4-8
  • Ọgbà Ẹranko—Ìrètí Ìkẹyìn Fún Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ kẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọgbà Ẹranko—Ìrètí Ìkẹyìn Fún Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ kẹ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Àyànfúnni fún Ọ̀rúndún Tuntun Tí Ń Bọ̀
  • Àwọn Ọgbà Ẹranko Ṣọ̀kan Nínú Ìgbékalẹ̀ Àsokọ́ra Kárí Ayé Kan
  • Ohun Tí Yóò Ran Àwọn Ọgbà Ẹranko Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí
  • Ìwádìí Nínú Aginjù Mú Kí Àwọn Ọgbà Ẹranko Lè Mú Ọmọ Púpọ̀ Sí I Jáde
  • Báwo Ni Góńgó Ìdáàbòbo Àwọn Ẹranko Ṣe Lè Dòótọ́ Tó?
  • Ìdáàbò Bò Ní Ìdojú Kọ Àkúrun
    Jí!—1996
  • Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ Orí Ilẹ̀ Ayé Tí Ń Pòórá
    Jí!—1997
  • Ìgbà Tí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Yóò Jẹ́ Ibi Ààbò
    Jí!—1997
  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ tó
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 7/8 ojú ìwé 4-8

Ọgbà Ẹranko—Ìrètí Ìkẹyìn Fún Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ kẹ̀?

NÍ LỌ́Ọ́LỌ́Ọ́, ìyípadà tegbòtigaga kan ti ṣẹlẹ̀ láìsí ìdíwọ́ ní àwọn ọgbà ẹranko tí ó túbọ̀ ní ìtẹ̀síwájú lágbàáyé. Ẹ̀rí kedere kan ni ṣíṣàtúntò àwọn ohun àfihàn wọn ní ìbámu pẹ̀lú èròǹgbà “ìmúbáramu ìrísí ojú ilẹ̀”—ìṣàfarawé àgbègbè àdánidá àwọn ẹranko, tí ó ní àwọn ewéko, òkúta, àjàrà, ìkùukùu, ìró, àti àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ó lè wà pa pọ̀ pàápàá, nínú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìnáwó rẹ̀ pọ̀—a ń ná nǹkan bíi bílíọ̀nù 1.2 dọ́là lọ́dọọdún fún ìmúsunwọ̀n àwọn ọgbà ẹranko àti odò ọ̀sìn ní United States nìkan—a kà á sí pé àwọn ìyípadà pọn dandan nítorí ipa iṣẹ́ ìlépa góńgó tuntun kan tí àwọn ọgbà ẹranko ní.

Iṣẹ́ Àyànfúnni fún Ọ̀rúndún Tuntun Tí Ń Bọ̀

Bí àìtó àwọn ohun abẹ̀mí ti ń wu ilẹ̀ ayé léwu, àwọn ọgbà ẹranko tó gbawájú lágbàáyé ti pinnu pé ìdáàbòbò, ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, àti ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni iṣẹ́ àyànfúnni àwọn fún ọ̀rúndún kọkànlélógún. Bí ìpèníjà náà ti sún wọn ṣiṣẹ́, tí ìjẹ́kánjúkánjú rẹ̀ sì ń fagbára mú wọn, àwọn ọgbà ẹranko mélòó kan tilẹ̀ ti sọ orúkọ náà, ọgbà ẹranko, nù, wọ́n sì yan àwọn ọ̀rọ̀ bí “ibi ààbò ẹran ìgbẹ́” tàbí “ọgbà ìdáàbòbò” rọ́pò.

Ìwé The World Zoo Conservation Strategy ló ń mú ipò iwájú nínú ìtẹ̀sí tuntun náà. Ìwé Strategy, tí òǹkọ̀wé kan ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “àkọsílẹ̀ pàtàkì jù lọ tí àwùjọ òṣìṣẹ́ ọgbà ẹranko tí ì mú jáde rí,” ní gidi, jẹ́ ìwé àkọsílẹ̀ ète ẹ̀kọ́ nípa ẹranko; ó “ṣàlàyé àwọn ẹrù iṣẹ́ àti àǹfààní tí àwọn ọgbà ẹranko àti odò ọ̀sìn lágbàáyé ní sí ìhà dídáàbò bo onírúurú ẹran ìgbẹ́ kárí ayé.” Nígbà tí ó ń kó iyè méjì èyíkéyìí nípa ìgbàgbọ́ tuntun náà dà nù, ìwé Strategy fi kún un pé: “Ní ti gidi, ẹ̀tọ́ gan-an tí ọgbà ẹranko kan tàbí odò ọ̀sìn kan ní láti wà sinmi lórí ipa tí ó ní láti kó nínú ìdáàbòbò.”

Kíkọ́ àwọn aráàlú lẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣèwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, lórí sísin àwọn ẹran ìgbẹ́ ní pàtàkì, ṣe kókó fún ipa iṣẹ́ tuntun yìí. Àárín àwọn èwe òde òní ni àwọn olùtọ́jú ọgbà ẹranko ọjọ́ ọ̀la wà, tí wọn yóò ní ẹrù iṣẹ́ dídáàbòbo ìyókù tí a bá gbà sílẹ̀ nínú àwọn irú ọ̀wọ́ tí iye wọn ń pọ̀ sí i, tí ń kú run nínú ìgbẹ́. Wọn yóò ha lè fi ọgbọ́n àti ìfarajìn bójú tó ohun àfúnniṣọ́ yìí bí? Aráyé lápapọ̀ yóò ha sì ní ojú ìwòye tí kì í ṣe ti àìmọ̀kan nípa àwọn ẹ̀dá bí? Fún ète yìí, ìwé Strategy ń fún ọgbà ẹranko kọ̀ọ̀kan níṣìírí láti dáwọ́ lé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, kí ó sì rí ara rẹ̀ bí apá kan nínú “ìgbékalẹ̀ àsokọ́ra ẹ̀rí ọkàn kárí ayé.”

Àwọn Ọgbà Ẹranko Ṣọ̀kan Nínú Ìgbékalẹ̀ Àsokọ́ra Kárí Ayé Kan

Nítorí ìtóbi-dé-góńgó iṣẹ́ ìdáwọ́lé wọn, ọ̀pọ̀ ọgbà ẹranko ń sowọ́ pọ̀ dí ìgbékalẹ̀ àsokọ́ra kárí ayé kan, tí ó ní nǹkan bí 1,000 ọgbà ẹranko nínú ní báyìí. Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè bí Àjọ Ọgbà Ẹranko Lágbàáyé àti Àjọ Àgbáyé fún Ìdáàbòbò Ẹ̀dá àti Ọrọ̀ Àdánidá, so àwọn ọgbà ẹranko wọ̀nyí pọ̀, wọ́n sì ń pèsè àbójútó àti ìdarí fún wọn.

Nígbà tí ìwé Zoo—The Modern Ark ń tọ́ka sí ìdí kan tí ń múni nípá fún irú àjọṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Bí a óò bá dènà ayọ́kẹ́lẹ́-finiṣèjẹ náà, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ohun alààyè tó bára wọn tan, ọgbà ẹranko kan kò lè wulẹ̀ máa ṣàbójútó ẹkùn Siberia mélòó kan tí o ní, bí àpẹẹrẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ẹkùn Siberia tí a ń sìn ní gbogbo ọgbà ẹranko kọ́ńtínẹ́ǹtì kan—tàbí lágbàáyé pàápàá—ni a gbọ́dọ̀ bójú tó bí agbo kan ṣoṣo.” Ní gidi, a nílò ọgọ́rọ̀ọ̀rún nínú irú ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan láti dín ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ohun alààyè tó bára wọn tan—ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ṣínà fún àìlèbímọ àti àkúrun—kù, tàbí kí a tilẹ̀ mú un kúrò pátápátá, ó sì ṣe kedere pé èyí kọjá agbára ọgbà ẹranko kan ṣoṣo. Ìwé Strategy wí pé: “Àgbájọ ńlá gbogbo ọ̀nà tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó yìí yóò pọn dandan láti fún àwọn ohun alààyè orí Ilẹ̀ Ayé wa . . . ní àǹfààní lílàájá tí ó ṣeé ṣe jù lọ. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló wà tí ó gbà gbọ́ pé bí a bá kùnà láti dáàbò bo àwọn irú ọ̀wọ́ mìíràn, a óò kùnà láti gba ara wa là.” Dájúdájú, ẹ̀mí ìrònú ọjọ́ iwájú tí ó jẹ́ ti ibi yìí ti gbójú fo ìlérí tí ó wà nínú Bíbélì nípa párádísè ilẹ̀ ayé kan tí a mú bọ̀ sípò.—Ìṣípayá 11:18; 21:1-4.

Ohun Tí Yóò Ran Àwọn Ọgbà Ẹranko Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí

Yánpọnyánrin ọ̀ràn àkúrun tún ti mí sí ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan onímọ̀ ẹ̀rọ gíga tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti ṣèrànwọ́ fún bíbímọ níbi àfidọ́sìn: àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé ọdọọdún International Zoo Yearbook (IZY), àti Àgbékalẹ̀ Ìsọfúnni Nípa Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Kárí Ayé (ISIS) tí a fi sínú ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹranko ń ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àkọsílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹranko inú irú ọ̀wọ́ kan tí ń gbé ọgbà ẹranko, níbi yòó wù kí wọ́n wà lágbàáyé. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àgbáyé kan, ó jẹ́ ọ̀nà láti dáàbò bo àkójọ apilẹ̀ àbùdá onílera àti mímú kí ‘ayọ́kẹ́lẹ́-finiṣèjẹ’ náà, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ohun alààyè tó bára wọn tan, dín kù. Ọgbà Ẹranko Berlin ló ṣí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ọgbà ẹranko kìíní ní 1923, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèmújáde irú ọmọ ẹranko wisent, tàbí ẹranko bison ti ilẹ̀ Europe, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú run nínú Ogun Àgbáyé Kìíní.

Láti mú kí ìpínkiri àwọn ìsọfúnni oníṣirò ti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, IZY, àti ìsọfúnni oníṣirò nípa ẹ̀dá ènìyàn, rọrùn, àgbékalẹ̀ ISIS gorí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ní 1974 ní United States. Ìsokọ́ra oníná mànàmáná rẹ̀ tí ń gbòòrò sí i àti àkójọ ìsọfúnni fún ìwádìí àti àmúlò rẹ̀ kíkàmàmà, tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ń ran àwọn ọgbà ẹranko lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ láti sọ èròǹgbà àjọṣepọ̀ ọ̀pọ̀ ọgbà ẹranko di òtítọ́ gidi.

Lára àwọn ọ̀nà àdánidá tí àwọn ọgbà ẹranko fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà ni àmì ìdámọ̀ ásíìdì DNA, ìṣípòpadà ọlẹ̀, ìmúlóyún lóde ara, àti ìsọdikékeré ìwọ̀n ooru ara (mímú kí àtọ̀ àti ọlẹ̀ dì). Àmì ìdámọ̀ ásíìdì DNA ń ran àwọn ọgbà ẹranko lọ́wọ́ láti dá àwọn òbí mọ̀ láìkùsíbìkan, èyí tí ó ṣe pàtàkì láti kápá ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ohun alààyè tó bára wọn tan láàárín àwọn irú ọ̀wọ́ bí àwọn ẹran ìgbẹ́ tí ń tọ́wọ̀ọ́ rìn, níbi tí ó ti ṣòro láti tọpa àwọn tí ó jẹ́ òbí. Ní báyìí ná, ìṣípòpadà ọlẹ̀ àti ìmúlóyún lóde ara ń mú kí ìmúrújáde yára kánkán. Ọ̀nà kan ni nípa mímú kí ìpèsè “òbí” tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu gbòòrò sí i. A lè gbé ọlẹ̀ wọn sínú àwọn ẹranko mìíràn tí ó bá wọn tan tímọ́tímọ́—kódà àwọn ẹran ilé pàápàá—tí wọ́n wá di ìyá abánibímọ. Ọ̀nà ìṣe yìí ti mú kí màlúù ńlá ti àríwá Holland bí akọmàlúù ńlá ti Ìlà Oòrùn Íńdíà (akọmàlúù ìgbẹ́), ológbò ilé sì bí ológbò aṣálẹ̀ Íńdíà tí a wu léwu gidigidi. Ó tún ń dín ìnáwónára, ewu, àti hílàhílo tí ó wà nínú kíkó àwọn irú tí a wu léwu tí yóò mú irú ọmọ jáde kiri kù. Gbogbo ohun tí a ní láti máa kó kiri ni ọlẹ̀ tàbí àtọ̀ tí ó ti dì.

Lójú bí ó ti ṣeé ṣe kí àwọn irú ọ̀wọ́ kan pòórá pátápátá, àwọn ọgbà ẹranko mélòó kan ti dáwọ́ lé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ìsọdikékeré ìwọ̀n ooru ara—mímú kí àtọ̀ àti ọlẹ̀ dì fún ìtọ́júpamọ́ onígbà pípẹ́. Ọgbà ẹranko dídì yí pèsè ìfojúsọ́nà fún mímú irú ọmọ jáde ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, bóyá ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún pàápàá lẹ́yìn kíkú àkúrun! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn ipò àìdánilójú, a ti pè é ní “àbọ̀wábá ọ̀nà ìmáàbòdájú ìkẹyìn.”

Ìwádìí Nínú Aginjù Mú Kí Àwọn Ọgbà Ẹranko Lè Mú Ọmọ Púpọ̀ Sí I Jáde

Wíwádìí nípa àwọn ẹranko lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì, títí kan bí wọ́n ṣe ń hùwà ní ibùgbé àdánidá ṣe kókó fún bíbímọ níbi àfidọ́sìn, òun sì ni ìsúnniṣe tí ó wà lẹ́yìn àwọn àfihàn “ìmúbáramu.” Kí àwọn ẹranko lè wà ní àlàáfíà, kí wọ́n sì máa bímọ, àwọn ọgbà ẹranko gbọ́dọ̀ gba ti àwọn ànímọ́ àdánidá wọn rò, kí wọ́n sì mú wọn “láyọ̀.”

Bí àpẹẹrẹ, a máa ń rí akọ àti abo ẹranko cheetah ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìgbẹ́, tí wọ́n sì máa ń ṣàjọpín ìsọfúnni nípasẹ̀ òórùn ìtọ̀ àti ìyàgbẹ́ wọn nìkan. Imú akọ ń sọ ìgbà tí abo bá ṣe tán láti gùn fún un, yóò sì lo ọjọ́ kan tàbí méjì péré lọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọgbà ẹranko mọ̀ nípa ìhùwàsí yìí, wọ́n ṣàtúnṣe àwọn àhámọ́ wọn láti máa ya akọ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ abo ní gbogbo ìgbà, yàtọ̀ sí ìgbà kúkúrú tí wọ́n fi ń gùn, ó sì gbéṣẹ́; àwọn ẹranko náà sì bímọ.

Nígbà tí jíjìnnà síra ẹni ń mú kí àwọn ẹranko cheetah túbọ̀ fẹ́ràn ara wọn sí i, kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti àwọn ẹyẹdò flamingo. Àwọn máa ń gùn kìkì nígbà tí wọ́n bá wà nínú agbo tí ó tóbi ju ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ ọgbà ẹranko lè bójú tó lọ. Nítorí náà, ọgbà ẹranko kan ní ilẹ̀ England ṣàfidánrawò kan—ó “sọ” agbo náà “di ìlọ́po méjì” nípa lílo dígí ńlá kan. Fún ìgbà àkọ́kọ́, àwọn ẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ eré oge wọn gbígbàfiyèsí! Ǹjẹ́ àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fún ọ ní àmì ìsọfúnni nípa bí àwọn ẹran ìgbẹ́ orí ilẹ̀ ayé ṣe ṣòro láti lóye tó? Dájúdájú, àwọn ọgbà ẹranko ní ìpèníjà àrà ọ̀tọ̀ kan.

Báwo Ni Góńgó Ìdáàbòbo Àwọn Ẹranko Ṣe Lè Dòótọ́ Tó?

Ní títọ́ka sí bí agbára ìṣètò tuntun náà ti pọ̀ tó, a ti ń dá àwọn irú ọ̀wọ́ kan tí a bí níbi ìdọ́sìn pa dà sí ibùgbé àdánidá wọn. Lára ìwọ̀nyí ni ẹyẹ igún ilẹ̀ California, ẹranko bison ti ilẹ̀ Europe, ẹranko bison ti ilẹ̀ America, ẹranko oryx ti ilẹ̀ Arébíà, kìnìún tamarin olómi wúrà, àti ẹṣin Przhevalski. Síbẹ̀síbẹ̀, ìfojúsọ́nà wíwàpẹ́ ṣì ṣókùnkùn biribiri.

Ìwé Strategy sọ pé: “Àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ṣòro láti lóye gidigidi, ìṣòro àgbáyé sì pọ̀ rẹpẹtẹ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé láìka ìmọ̀lára àti ìdàníyàn tí ń pọ̀ sí i nípa ẹ̀dá àti àyíká sí, kò tí ì ṣeé ṣe láti dá ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìgbésẹ̀ aṣèparun náà dúró.” Ó fi kún un pé gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀, “àwọn alágbàwí ààbò ẹ̀dá gbọ́dọ̀ múra tán láti wá ọ̀nà lílàájá nínú sáà lílekoko tí a ń wọ̀nà fún náà.” Lọ́nà ti ẹ̀dá, èyí ń béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní gbogbo ìpele ẹgbẹ́ àwùjọ. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé sáyẹ́ǹsì kan ṣe wí, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ “kéré púpọ̀ sí ohun tí a nílò.” Bí ó bá jẹ́ pé ńṣe ni àwọn ohun tí ń fa àkúrun dín kù àmọ́ tí wọn kò pa dà sẹ́yìn, àwọn ìsapá dídára jù lọ pàápàá lè já sí òtúbáńtẹ́. A gbọ́dọ̀ ṣẹ̀dá àwọn ibùgbé àdánidá gbígbòòrò tí ó kún bámúbámú—kì í wulẹ̀ ṣe àwọn àgbègbè kékeré tí ń yọrí sí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ohun alààyè tó bára wọn tan. Nígbà náà nìkan ni àwọn ọgbà ẹranko lè fọkàn balẹ̀ da àwọn ẹranko tí wọ́n mú dàgbà sínú igbó. Àmọ́, irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ha lè dòótọ́ gidi bí, tàbí ó wulẹ̀ jẹ́ ìrònú ohun tí a fẹ́ lásán bí?

Síwájú sí i, ó tún ṣòro láti gbà gbọ́ pé àjọṣepọ̀ ọ̀pọ̀ ọgbà ẹranko lágbàáyé lè jẹ́ ojútùú ìṣòro náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Edward Wilson sọ pé: “Òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro náà ni pé gbogbo ọgbà ẹranko tí ó wà lágbàáyé lónìí kò lè gbà ju kìkì 2,000 irú ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú, ẹyẹ, ẹ̀dá afàyàfà àti jomijòkè lọ”—iye kéréje kan ní ìfiwéra sí iye tí ó wà. Àwọn ọgbà ẹranko ní iṣẹ́ tí kò rọrùn ti pípinnu irú ọ̀wọ́ wo la óò yàn láti dáàbò bò nígbà tí a óò fi àwọn yòó kù sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń forí lé kíkú àkúrun.

Ní ti àwọn ògbóǹkangí ní ẹ̀ka iṣẹ́ yìí, èyí ṣokùnfà ìbéèrè atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi kan. Lójú pé gbogbo ohun alààyè gbára lé ara wọn, ìgbà wo ni ìjónírúurú ohun alààyè yóò kéré dé ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ lílekoko tí yóò tanná ran ìdàgẹ̀ẹ̀rẹ̀ òjijì ti àkúrun tí ó lè mú ìparun bá ọ̀pọ̀ lára ohun alààyè tó bá ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé, títí kan ìran aráyé? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wulẹ̀ lè méfò ni. Linda Koebner sọ nínú ìwé Zoo Book pé: “Irú ọ̀wọ́ kan tàbí méjì tàbí àádọ́ta tí ó kú àkúrun yóò ní ipa tí a kò lè sọ tẹ́lẹ̀. Kíkú àkúrun ń mú ìyípadà wá kí a tó lóye àbájáde rẹ̀ pàápàá.” Ìwé náà, Zoo—The Modern Ark, sọ pé, ní báyìí ná, “àwọn ọgbà ẹranko wà láàárín àwọn ibi ààbò ṣíṣe kókó jù lọ fún ìwàláàyè nínú ogun ìṣekúpa àwọn ẹranko kárí ayé, ogun kan tí a kò lè sàsọtẹ́lẹ̀ bí yóò ti gbòòrò tó ṣùgbọ́n tí àwọn ìran ọjọ́ iwájú yóò dá wa lẹ́bi rẹ̀ pátápátá.”

Nítorí náà, ìpìlẹ̀ kankan ha wà fún ìrètí bí? Tàbí àwọn ìran ọjọ́ iwájú ha wà fún jíjẹ́ ohun alààyè tí ó dá wà lágbàáyé, nígbà tí àwọn fúnra wọn forí lé kíkú àkúrun bí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ènìyàn ni ọ̀tá wọn tó burú jù lọ

[Credit Line]

Ẹkùn àti Àwọn Erin: Zoological Parks Board of NSW

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn ẹranko mélòó kan tí a wu léwu—“bison,” “cheetah,” àti “rhinoceros” dúdú

[Àwọn Credit Line]

Bison àti Cheetah: Zoological Parks Board of NSW

Rhinoceros: National Parks Board of South Africa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́