Ìgbà Tí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Yóò Jẹ́ Ibi Ààbò
ṢÉ O fẹ́ láti rí ẹ̀dá eléwu jù lọ lágbàáyé? Ṣáà wo dígí! Bẹ́ẹ̀ ni, àwa, ìran ènìyàn, ni aṣèparun búburú jù lọ lórí ilẹ̀ ayé! Kódà, a ń pa ara wa lọ́nà gbígbòòrò gan-an.
Kí ilẹ̀ ayé lè di ibi ààbò fún àwọn ẹran ìgbẹ́, kódà nínú àwọn ọgbà ẹranko—bí wọn bá wá di ibi ààbò ìkẹyìn—a gbọ́dọ̀ fòpin sí ogun, ìgbóguntì láti ọ̀dọ̀ ìran ènìyàn. Kìkì 91 péré ló la Ogun Àgbáyé Kejì já lára 12,000 ẹranko tí ó wà ní Ọgbà Ẹranko ti Berlin. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgbà ẹranko mìíràn. Nínú ogun àìpẹ́ yìí ní àgbègbè Balkan, àwọn onígboyà òṣìṣẹ́ ọgbà ẹranko dáàbò bo ọ̀pọ̀ ẹranko; àmọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹranko mìíràn, títí kan ìgalà, àwọn ẹran ìjà ńláńlá, àwọn béárì, àti ìkookò, ni a pa. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Australian ṣe wí, ẹgbẹ́ Khmer Rouge ti mọ̀ọ́mọ̀ pa ọ̀pọ̀ ẹranko ṣíṣọ̀wọ́n nínú igbó kìjikìji Cambodia. Èé ṣe? Kí wọ́n lè fi awọ wọn àti àwọn ohun àmújáde mìíràn láti ara wọn gba ìpààrọ̀ ohun ìjà ogun!
Mímọ̀ọ́mọ̀ ba ìbátan àárín àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn jẹ́, irú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn Erékùṣù Peron tí ó wà ní àdádó, ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Darwin, Australia, tún jẹ́ ìwà ibi mìíràn tí a ní láti ṣẹ́gun bí àwọn ẹranko yóò bá láàbò—nínú àwọn ọgbà ẹranko tàbí lóde wọn. Wọ́n ti dáná sun ibi tí àwọn ẹyẹ pelican ti n pamọ ní àwọn erékùṣù wọ̀nyí lẹ́ẹ̀mejì láàárín ọdún mẹ́ta, láìsídìí gúnmọ́ kan ju pípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ẹyẹ tí kò tí ì lè fò, lọ́nà oníkà jù lọ.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́, ìpàdánù àwọn irú ọ̀wọ́ lọ́nà gíga jù lọ kì í ṣe nítorí ìfẹ́ ọkàn láti ṣèjàǹbá láìbófinmu; ó jẹ́ àbájáde búburú iye ènìyàn tí ń yára pọ̀ sí i tó sì ń fi ìgbékútà wá àyè ibùgbé àti ilẹ̀ tí yóò máa ro. Nítorí yíya wọ ibùgbé àwọn ẹranko láìdáwọ́dúró yìí àti ìbàyíkájẹ́ tí ń bá a rìn, ìwé The World Zoo Conservation Strategy kìlọ̀ pé: “Àkíyèsí nípa ọ̀rúndún kọkànlélógún fún gbogbo ìgbékalẹ̀ àdánidá orí ilẹ̀ ayé pòkúdu. Kò sí ohunkóhun tí ó tọ́ka sí i pé ìparun tí ń ṣẹlẹ̀ níbi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo apá àgbáyé yóò ṣíwọ́ láìpẹ́.”
Lójú ìdàníyàn tí ń pọ̀ sí i nípa ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ ayé, ìgbà kan tí gbogbo pílánẹ́ẹ̀tì náà yóò di ibi ààbò lè dà bí àròsọ lásán. Síbẹ̀, ìrètí yẹn fìdí múlẹ̀, kì í ṣe lọ́dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn olójú-ìwòye-kúkúrú—tí kò ní èrò kankan nípa ìsọdahoro ìbátan tí ó wà láàárín àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìwọ̀nba nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé sáyẹ́ǹsì kan ṣe sọ ọ́—ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ ẹni náà tí ó rí i ṣáájú, Jèhófà Ọlọ́run. Ní èyí tí ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún sẹ́yìn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò rí ẹ̀dá ènìyàn tí ń “run ayé bà jẹ́” ní àkókò wa. (Ìṣípayá 11:18) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti lè dà bí àròsọ tí kò lè ṣẹ lójú ọ̀pọ̀ àwọn alààyè nígbà tí a sọ ọ́, nítorí iye ẹ̀dá ènìyàn kéréje kan ló wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà náà, ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ti ṣe gẹ́lẹ́ tó!
Lọ́nà ẹ̀dà ọ̀rọ̀, ìrunbàjẹ́ yìí ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí ó jọ pé díẹ̀ ló kù kí sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ máa ṣe iṣẹ́ ìyanu: àtagbà rédíò kéékèèké àti àwọn sátẹ́láìtì ń ṣèṣirò àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu, a ń díwọ̀n ìparun àwọn igbó kìjikìji ní ìwọ̀n mítà kọ̀ọ̀kan níbùú lóròó láti ojúde òfuurufú, a sì ń díwọ̀n ìbafẹ́fẹ́jẹ́ ní ìwọ̀n kíkéré níye gan-an. Síbẹ̀, yàtọ̀ sí nínú àwọn àyàfi ṣíṣọ̀wọ́n kan, kò jọ pé ènìyàn lè ṣe ohunkóhun nípa ìsọfúnni oníṣirò tí a tò jọ pelemọ wọ̀nyí. Bóyá ńṣe ni ènìyàn dà bí awakọ̀ ọkọ̀ ojú irin kan tó yawọ́. Ó ní àtẹ tí a to àwọn ohun èlò ìdarí oníná mànàmáná àti àwọn tí ń ṣàkíyèsí bí nǹkan ṣe ń lọ, tí wọ́n ń sọ gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ fún un sí, ṣùgbọ́n kò lè dá ọkọ̀ ojú irin náà dúró!
Èé Ṣe Tí Àwọn Ìsapá Fi Ń Kùnà?
Finú wòye olùdarí ilé iṣẹ́ ńlá kan, tí ó jẹ́ onígbèéraga, tí kò sì ní ìlànà ìwà híhù, tí ó wá yọ́ kẹ́lẹ́ gbọ́ nígbà tí onílé iṣẹ́ náà sọ pé a kò ní gbé òun ga, kàkà bẹ́ẹ̀, a óò lé òun kúrò nílé iṣẹ́ náà lóṣù mélòó kan sí i. Bí a ṣe mú inú bí i, tí a sì pẹ̀gàn rẹ̀, ó ń lo irọ́, àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àti onírúurú àrékérekè abẹ́lẹ̀ láti kó àwọn òṣìṣẹ́ mélòó kan, kí wọ́n sì dá yánpọnyánrin sílẹ̀. Wọn kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ lè ṣiṣẹ́, wọ́n fawọ́ ìṣeǹkanjáde sẹ́yìn, wọ́n mú kí àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe jáde lábùkù—síbẹ̀ lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí a kò fi lè dá wọn lẹ́bi. Lásìkò kan náà, àwọn òṣìṣẹ́ olóòótọ́ inú, tí kò mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an, ń gbìyànjú láti ṣe àtúnṣe; ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ń tiraka tó, ni nǹkan ń burú sí i.
Lọ́nà kan náà ni onímàgòmágó “olùdarí” àgbáyé yìí ti ṣe àrékérekè lòdì sí aráyé àti ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn yí, a kò ní láti ṣe “aláìmọ àwọn ète ọkàn rẹ̀,” nítorí pé Bíbélì ń fa aṣọ ìbòjú rẹ̀ ya, ó sì ń fi ẹ̀dá ẹ̀mí kan tí inú ń bí hàn—Sátánì Èṣù—áńgẹ́lì kan tí ó di elérò ìjọra-ẹni-lójú bí ọmọdé, tí ó sì fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun. (Kọ́ríńtì Kejì 2:11; 4:4) Ọlọ́run ta á nù kúrò nínú ìdílé Rẹ̀ ti ọ̀run, ó sì dájọ́ ìparun fún un.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Róòmù 16:20.
Bíi ti onímàgòmágó olùdarí ilé iṣẹ́ náà, “baba irọ́” yìí ń lo ìtòpelemọ ọgbọ́n abẹ́lẹ̀ láti fi tagbáratagbára ṣàgbéyọ ìbínú rẹ̀. Ó kórìíra Jèhófà Ọlọ́run, ó sì ń fẹ́ láti fipá fọ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀ yángá. (Jòhánù 8:44) Àwọn irinṣẹ́ lílágbára jù lọ tí Sátánì ń lò ni ìtànkálẹ̀ èrò irọ́, ìwọra, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, àti àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí ń pani lára. Nípasẹ̀ ìwọ̀nyí, ó ti “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” ó sì yí àwọn ẹ̀dá ènìyàn—tí a pète láti máa ṣàbójútó ilẹ̀ ayé—pa dà di àwọn aṣèparun aláìláàánú jù lọ, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n di ọmọlẹ́yìn Nímírọ́dù ìgbàanì, “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.”—Ìṣípayá 12:9, 12; Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 10:9.
Ìrètí Dídájú Kan Ṣoṣo fún Ibi Ààbò Lórí Ilẹ̀ Ayé
Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣẹ́gun lórí àwọn ipá ẹ̀dá ènìyàn àti èyí tí ó ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ, tí ń fa àkúrun, kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe. Ẹlẹ́dàá alágbára ńlá gbogbo tí ó dá ohun gbogbo lè gbé wa dìde kúrò nínú ọ̀fìn burúkú yìí, ó sì ti ṣèlérí láti ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àkóso rẹ̀ àtọ̀runwá. Ó ṣèlérí láti mú àwọn aṣèparun tí ń run ilẹ̀ ayé bà jẹ́ wọ̀nyẹn wá sí ìrunbàjẹ́. A ń gbàdúrà fún èyí nígbà tí a ń wí pé: “Kí ìjọba rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe, bíi ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.”—Mátíù 6:9, 10, King James Version; Ìṣípayá 11:18.
Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé a so dídé Ìjọba náà pọ̀ mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé bí? Èyí jẹ́ nítorí pé Ìjọba Ọlọ́run ni àkóso Ọlọ́run tí yóò ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí. Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ ìjọba kan, ó ní ọba kan—Jésù Kristi, “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.” (Ìṣípayá 19:16) Ó tún ní àwọn ọmọ abẹ́. Ní tòótọ́, Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn onínú tútù wọ̀nyí ni àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọn yóò sì fìfẹ́ ṣàbójútó ogún wọn, ní yíyí i pa dà di párádísè gbígbèrú kan tí àwọn ohun alààyè ń gbá yìn-ìn nínú rẹ̀. Ó dùn mọ́ni pé ìwé Strategy sọ pé: “Kìkì bí àpapọ̀ ẹ̀dá ènìyàn bá lè gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun tí a ṣẹ̀dá nínú ọ̀tun ìṣọ̀kan ni a lè mú ọjọ́ ọ̀la ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ohun tí a ṣẹ̀dá dájú.”
Ìtàn àti ìṣesí ìran aráyé aláìpé ń tọ́ka sí àìlèṣeéṣe àjọgbépọ̀ “àpapọ̀ ẹ̀dá ènìyàn” òde òní àti àwọn ohun tí a ṣẹ̀dá nínú irú “ọ̀tun ìṣọ̀kan” bẹ́ẹ̀ láéláé, nítorí pé wọ́n ti pa Jèhófà tì sápá kan. Ní tòótọ́, ìdí kan tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí ayé yìí wà pẹ́ tó báyìí ti jẹ́ kí a lè fẹ̀rí àìwúlò ìdáṣàkóso-ara-ẹni ti ẹ̀dá ènìyàn múlẹ̀. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, àwọn tí ń yán hànhàn fún ìṣàkóso Kristi yóò gbádùn àlàáfíà kíkọyọyọ. Aísáyà 11:9 (NW) fìdí èyí múlẹ̀, ó sì tún tọ́ka sí ìdí tí ó fi jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí nìkan ni yóò lè bá àwọn ohun tí a ṣẹ̀dá gbé nínú “ọ̀tun ìṣọ̀kan” pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ni kókó pàtàkì náà. Ìyẹn kò ha bọ́gbọ́n mu bí, àbí ta ló tún lè ní irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí Orísun àwọn ohun tí a ṣẹ̀dá?
Àwọn tí ń tẹra mọ́ pípa Jèhófà tì sápá kan ńkọ́? Òwe 2:22 sọ pé: “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìwà ìbaǹkanjẹ́ tàbí ẹ̀mí ìdágunlá wọn yóò ná wọn ní ìwàláàyè wọn nínú “ìpọ́njú ńlá” tí ń yára bọ̀ kánkán náà—ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò gbà mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ lára gbogbo àwọn tí ń tẹra mọ́ fífi ìmọtara-ẹni-nìkan lo ìṣẹ̀dá rẹ̀ nílòkulò, tí wọ́n sì ń bà á jẹ́.—Ìṣípayá 7:14; 11:18.
O ha fẹ́ láti nípìn-ín nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìmúbọ̀sípò ilẹ̀ ayé bí? Nígbà náà, jọ̀wọ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí o ṣe nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun nìkan ló lágbára láti mú kí ìrònú rẹ bá ti Ẹlẹ́dàá mu. (Tímótì Kejì 3:16; Hébérù 4:12) Ní àfikún sí i, nípa fífi ohun tí o bá kọ́ sílò, kì í ṣe kìkì pé ìwọ yóò di olùgbé tí ó túbọ̀ dára sí i nísinsìnyí nìkan ni, ṣùgbọ́n yóò tún jẹ́rìí pé ní gidi ni o jẹ́ irú ènìyàn tí Jèhófà yóò gbé àbójútó “ilẹ̀ ayé tuntun” tí ń yára bọ̀ kánkán lé lọ́wọ́.—Pétérù Kejì 3:13.
Àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yí jáde, tàbí ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó sún mọ́ ọ jù lọ yóò láyọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí láti gba àfikún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣàlàyé àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.