ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/8 ojú ìwé 12-15
  • Èé Ṣe Tí Dáyámọ́ńdì Fi Gbówó Lórí Tó Bẹ́ẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Dáyámọ́ńdì Fi Gbówó Lórí Tó Bẹ́ẹ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀wò sí Antwerp
  • Dídán Dáyámọ́ńdì Tí A Kò Tí Ì Dà
  • Ìníyelórí Dáyámọ́ńdì
  • O Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Iwọ Ha Mọriri Eto-ajọ Jehofa Ori Ilẹ-aye Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Tó Dára Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìgbọ́kànlé Tí Mo Ní Nínú Ọlọ́run Ló Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró
    Jí!—2002
Jí!—1997
g97 7/8 ojú ìwé 12-15

Èé Ṣe Tí Dáyámọ́ńdì Fi Gbówó Lórí Tó Bẹ́ẹ̀?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ

NÍGBÀ míràn a lè ṣàwárí ẹwà. Nígbà míràn a gbọ́dọ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni. Bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ ṣàwárí dáyámọ́ńdì, kí a sì ṣẹ̀dá rẹ̀ lápapọ̀ ni.

Láìsíyèméjì, dáyámọ́ńdì tí a kò tí ì dà jẹ́ ẹ̀dá rírẹwà nínú ìṣẹ̀dá. Ìkìmọ́ra lílekoko àti ìwọ̀n ìgbóná gíga lábẹ́ erukuru ojú ilẹ̀ rọra ń sọ èédú lásán di ohun dídì gbagidi, mímọ́ kedere. Ṣùgbọ́n àwọn òkúta iyebíye wọ̀nyí kì í sábà ṣeé wá rí. A ti gbẹ́ àwọn kan lára àwọn ihò títóbi jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn gbẹ́ lórí ilẹ̀ ayé—tí ó wà káàkiri ojú ilẹ̀ ní Australia, Siberia, àti Gúúsù Áfíríkà—nítorí tí a ń wá àwọn òkúta iyebíye wọ̀nyí. Láti wa ìwọ̀n dáyámọ́ńdì mélòó kan tí ó wọn nǹkan bíi gíráàmù mẹ́fà péré, a lè ní láti wa ọgọ́rọ̀ọ̀rún tọ́ọ̀nù ilẹ̀ jáde kí a sì sẹ́ ẹ!

Nígbà tí a bá ṣàwárí dáyámọ́ńdì, àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ gbẹ́ ẹ sí ẹwà tí ó ṣeé ṣe kí ó ní kí ó tó ṣeé fi dá òrùka tàbí gbẹ̀dẹ̀ kan lọ́lá.

Bí ó ṣe sábà máa ń rí, gbogbo ìsapá àti òye iṣẹ́ yìí kò lè jẹ́ olówó pọ́ọ́kú. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ obìnrin—àti ọkùnrin—gbà pé ìnáwó náà tóótun, ní pàtàkì, bí dáyámọ́ńdì náà bá jẹ́ ẹ̀bùn tí a fún alábàá-ṣègbéyàwó tàbí àfẹ́sọ́nà ẹni gẹ́gẹ́ bí ìnawọ́sí ìfẹ́ni pípẹ́títí. Ẹwà àti ọ̀ràn ìfẹ́ ti sọ dáyámọ́ńdì di ohun ọ̀ṣọ́ mímọ́ kedere tí a mọyì rẹ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.a

Ìbẹ̀wò sí Antwerp

Nígbà ìbẹ̀wò kan sí Antwerp, Belgium, ìlú ńlá kan tí ọrọ̀ rẹ̀ gbára lé dáyámọ́ńdì ní pàtàkì, ọkàn ìfẹ́ tí mo ní sí àwọn òkúta iyebíye aláìlẹ́gbẹ́ wọ̀nyí ru sókè. Mo ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló mú kí dáyámọ́ńdì máa fani mọ́ra tó bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe ń ṣe dáyámọ́ńdì?’

Kí n lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyẹn, mo bá Dirk Loots, tí ìdílé rẹ̀ ti ṣòwò dáyámọ́ńdì jálẹ̀ ìran mẹ́ta, sọ̀rọ̀. Ó ṣàlàyé pé: “A ń pe Antwerp ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn dáyámọ́ńdì nítorí pé ìlú ńlá yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tí a ti ń rí dáyámọ́ńdì gan-an lágbàáyé. Nítorí náà, ibi tí ó yẹ jù lọ gan-an láti wádìí bí a ṣe ń ṣe dáyámọ́ńdì ni o wá yìí.”

Lákọ̀ọ́kọ́, ó fi dáyámọ́ńdì díẹ̀ tí a kò tí ì dà, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rà, hàn mí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, 350,000 dọ́là ni a ṣírò wọn sí, wọn kò jọ ohun tí ó fani mọ́ra tó bẹ́ẹ̀ bí a bá kọ́kọ́ rí wọn—kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dà bí ègé pẹlẹbẹ dígí mélòó kan. Ṣùgbọ́n, wíwò ó láwòfín mú kí a rí ìdányanran tí ń ṣàfihàn ẹwà tí oníṣọ̀nà dáyámọ́ńdì lè gbé jáde. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìdí tí wọ́n fi ń fani mọ́ra.

Dirk jẹ́wọ́ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí mo bá rí ọ̀pọ̀ dáyámọ́ńdì tí a kò tí ì dà, mo máa ń nímọ̀lára pé nǹkan kan ń dì mí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ rí bí ìsomọ́ra ìmọ̀lára. Láìtún rò ó wò, mo máa ń fẹ́ láti ra òkúta iyebíye yẹn. Ó mú mi rántí àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin kan tí ó rí péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ pọ̀, péálì kan tí ó péye tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi múra tán láti ta gbogbo ohun tí ó ní, kí ó lè rà á. N kò tí ì ṣe ohun tí ó tó bẹ́ẹ̀,” ó rẹ́rìn-ín músẹ́, “àmọ́ mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé àwọn òkúta iyebíye kan ń fani mọ́ra lákànṣe, pàápàá, fún àwa tí a ń lo ìgbésí ayé wa ní rírà wọ́n àti títà wọ́n. Dájúdájú, sísọ òkúta iyebíye tí a kò tí ì dà kan di ojúlówó òkúta iyebíye, bí ó ti wù kí ó wuni tó, kò ṣàìní àwọn ìkùkáàtó tirẹ̀.”

Dídán Dáyámọ́ńdì Tí A Kò Tí Ì Dà

Mo ti gbọ́ pé oníṣọ̀nà dáyámọ́ńdì tí kò ní ìṣọ́ra lè fọ́ òkúta ṣíṣeyebíye kan yángá. Mo ṣe kàyéfì bóyá ìyẹn máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Dirk jẹ́wọ́ pé: “Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Kì í ṣe nígbà tí wọ́n bá ń fọ́ òkúta náà sí wẹ́wẹ́ nìkan ni irú rẹ̀ sì lè ṣẹlẹ̀. Kódà, ẹni tí ń dán dáyámọ́ńdì lè gbá gletz kan, tàbí ibi tí òkúta náà ti sán sára tẹ́lẹ̀, kí ó sì run òkúta náà. A sábà máa ń fara balẹ̀ fi iná tí ó ní ìgbì ìmọ́lẹ̀ gbígbọ̀nrìrì ṣàyẹ̀wò òkúta tí a kò tí ì dà náà, kí a lè mọ ibi tí ìṣòro bá wà; àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé, kò sí ọgbọ́n kan tí a lè dá, tí kò ní ní àbùkù tirẹ̀.

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ohun tí a bẹ̀rù jù lọ ni kí òkúta kan fọ́ yángá, ìyẹn nìkan kọ́ ni ìṣòro ibẹ̀. Nígbà míràn, àwọ̀ òkúta náà máa ń dúdú sí i lẹ́yìn tí a bá ti gé e, tí a sì ti dán an, ìníyelórí rẹ̀ sì ń dín kù. O sì tún gbọ́dọ̀ rántí pé, a sábà máa ń ní láti gé ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ dà nù kí a tó lè sọ ọ́ di òkúta ṣíṣeyebíye jù lọ kan.”

Lójú mi, ìyẹn jọ bí ọ̀pọ̀ owó tí ń ṣègbé, títi mo fi lóye gbogbo ohun tí ó rọ̀ mọ́ ṣíṣe dáyámọ́ńdì. Dirk fi dáyámọ́ńdì ràgàjì kan tí ó ní ìrísí ọkàn àyà, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́, tí wọ́n sì dán hàn mí. Ó bi mí pé: “Ṣé o rí bí ó ti ń kọ mànà? ‘Iná’ tí ó wà nínú òkúta yẹn kì í ṣe ohun kan ní gidi ju ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn pa dà lọ.

“Gbogbo ohun tí oníṣẹ́ ọnà náà ní láti ṣe ni kí ó gé gbogbo ìhà tí a ti lè wò ó lọ́nà tí ìmọ́lẹ̀ yóò fi wọnú òkúta náà, tí yóò sì tún tàn pa dà sọ́dọ̀ ẹni tí ń wò ó. Àwọn ìrísí wíwọ́pọ̀ kan, bí ègé roboto, máa ń ṣe èyí lọ́nà gbígbéṣẹ́ jù lọ. Àmọ́ àwọn oríṣi ọnà àfiṣọ̀ṣọ́ mìíràn bí irú èyí, tí ó ní ìrísí ọkàn àyà yí, lè tan ìmọ́lẹ̀ púpọ̀ jù lọ tí ó ṣeé ṣe pa dà. Iṣẹ́ ọnà ṣíṣe pàtàkì jù lọ lọ́wọ́ ẹni tí ń ṣe dáyámọ́ńdì nìyẹn. Ní gidi, gbajúmọ̀ olùṣe-dáyámọ́ńdì kan ti yan ‘Ẹwà náà wà nínú ìrísí ọnà’ gẹ́gẹ́ bí àkọmọ̀nà tirẹ̀.”

Mo bi Dirk pé: “Báwo ni o ṣe ń pinnu irú ìrísí tí o máa gé dáyámọ́ńdì sí?” Ó wí pé: “A máa ń bẹ̀rẹ̀ nípa fífarabalẹ̀ wo òkúta tí a rà níbẹ̀rẹ̀ náà dáradára. Mo sì ń tẹnu mọ́ fífarabalẹ̀ dáradára! Mo rántí òkúta ńlá kan tí a fi odindi oṣù kan ṣàyẹ̀wò kí a tó pinnu bí a óò ṣe gé e níkẹyìn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń rọrùn díẹ̀ nítorí pé òkúta tí a kò tí ì dà náà ń fara hàn lọ́nà tí a fi lè gé e sí ìrísí kan pàtó. Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ète náà ni láti pinnu ìrísí tí ó dára jù lọ fún òkúta yẹn gan-an kí èyí tí a óò gé dà nù lè mọ níwọ̀n bí ó bá ti ṣeé ṣe tó. Àmọ́ ojú kọ̀ọ̀kan tí a ń gé—àfiṣàpẹẹrẹ dáyámọ́ńdì kan sì máa ń ní ju 50 ojú lọ—jẹ́ ìpàdánù ìwọ̀n ìwúwo kan.”

Dirk wá sọ pé kí n fara balẹ̀ wo òkúta kan dáradára. Ó mú loupe kan, awò kékeré tí ń sọ nǹkan di ńlá tí àwọn aṣehun-ọ̀ṣọ́ ń lò fún mi, ó sì béèrè pé: “Ǹjẹ́ o rí ìdọ̀tí tí ó wà lókè ní apá ọ̀tún òkúta yẹn?” Mo rí àwọn ìlà tí kò dọ́gba mélòó kan, irú èyí tí ó máa ń wà lára dígí kan tí ó sán, ní igun kan lára òkúta ṣíṣeyebíye náà. “Irú àìpéye bẹ́ẹ̀ máa ń dín ìníyelórí dáyámọ́ńdì kù gan-an ni. Ó dájú pé a lè gé e sọ nù, àmọ́ ìyẹn lè túmọ̀ sí gígé púpọ̀ gan-an dà nù lára òkúta iyebíye náà. Bí àbùkù náà kò bá ṣeé fojú lásán rí, a ṣì lè ta òkúta iyebíye náà lówó pọ́ọ́kú.”

Mo fẹ́ mọ ìdí tí irú òkúta tíntínní bẹ́ẹ̀ fi níye lórí tó bẹ́ẹ̀. Ní kedere, àwọn kókó abájọ náà tó mélòó kan.

Dirk wí pé: “Ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ látìgbàdégbà náà, ‘dáyámọ́ńdì wà títí láé’—bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ amóríwú ìpolówó ọjà—jẹ́ òtítọ́ ní ti gbogbogbòò. Dáyámọ́ńdì kì í ṣá, ìtànyanran rẹ̀ kì í sì í pajú rẹ́. Wọn kò wọ́pọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ń rí wọn ju ti àtijọ́ lọ, wọ́n sì lẹ́wà—ìyẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ iyàn jíjà! Ṣùgbọ́n, bóyá kókó tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń pinnu ìníyelórí wọn ni bí a ṣe ń béèrè fún dáyámọ́ńdì kárí ayé. Lọ́nà púpọ̀, èyí sinmi lórí ìpolówó ọjà.

Dirk fìrònú sọ pé: “Èé ṣe tí obìnrin kan fi máa ń fẹ́ òrùka dáyámọ́ńdì? Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, ó ń so dáyámọ́ńdì pọ̀ mọ́ ìfẹ́ àti òòfà ìfẹ́. Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ni dáyámọ́ńdì, ohun kan tí a ní láti tọ́jú títí ayérayé, láti máa rán an létí ìfẹ́ tí a retí pé kí ó wà pẹ́ bíi dáyámọ́ńdì náà. A ti fòye mú èrò yí, tàbí èrò ọlọ́wọ̀ yí, bí àwọn kan yóò ti pè é, dàgbà. Nǹkan bí 180,000,000 dọ́là ni a ná ní 1995 láti fi polówó èròǹgbà abẹ́nú yìí, èròǹgbà kan tí ń mú kí àwọn ènìyàn kárí ayé máa ra dáyámọ́ńdì.”

Ìníyelórí Dáyámọ́ńdì

Mo sọ pé: “Mo rò pé ìníyelórí òkúta ṣíṣeyebíye tí a ti ṣe parí náà sinmi lórí bí ó ṣe tóbi tó ni.” Dirk dáhùn pé: “Kò wulẹ̀ rọrùn bẹ́ẹ̀. Ó ti mọ́ àwọn oníṣòwò dáyámọ́ńdì lára láti sọ pé kókó mẹ́rin: gígé, ìwọ̀n, àwọ̀, àti bí ó ṣe mọ́ kedere sí, ní ń pinnu ìníyelórí dáyámọ́ńdì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nípa lórí ẹwà—àti nípa bẹ́ẹ̀, lórí ìníyelórí—òkúta náà.

“Jẹ́ kí a kọ́kọ́ jíròrò gígé e. Iṣẹ́ ọnà ni gígé dáradára jẹ́, o lè pè é ní iṣẹ́ gbígbẹ́ ère kan lọ́nà kékeré. Fara balẹ̀ wo dáyámọ́ńdì onírìísí ọkàn àyà tí o ń wò lẹ́ẹ̀kan yẹn dáradára. Ìrísí rẹ̀ kò rọrùn láti gé, ó sì jẹ́ ọ̀kan tí ó gba fífi apá púpọ̀ lára ojúlówó òkúta iyebíye náà ṣòfò ju bí àwọn ìrísí mìíràn ti ṣe lọ. Ṣàkíyèsí bí a ṣe to gbogbo ojú rẹ̀ bára dọ́gba láti ṣàlékún ẹwà òkúta ṣíṣeyebíye náà. A lè sọ pé dáyámọ́ńdì yí ní pàtàkì ní gígé jíjojúnígbèsè kan.

“Ìtóbi rẹ̀ ló kọ́kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, a sì lóye ìdí rẹ̀, nítorí pé ó tóbi gan-an, òkúta iyebíye oníwọ̀n mẹ́jọ. Ó ṣe kòńgẹ́ pé ìwọ̀n kan jẹ́ ìdámárùn-ún gíráàmù kan, nítorí náà, a ń pinnu iye ìwọ̀n nípa wíwulẹ̀ wọn òkúta iyebíye náà. Ká sọ̀rọ̀ ní ti gbogbogbòò, àfikún ìwọ̀n túmọ̀ sí dáyámọ́ńdì tí ó túbọ̀ níye lórí, àmọ́ àwọ̀ àti ìmọ́kedere yóò tún nípa lórí ìníyelórí rẹ̀.

“A máa ń rí dáyámọ́ńdì ní onírúurú ìrísí àti àwọ̀, bí o ṣe ti lè kíyè sí i nínú ìdì òkúta iyebíye tí a kò tí ì dà. Ohun tí a kọ́kọ́ ń ṣe ni kí a ṣà wọ́n bí àwọ̀ wọn ti rí, àwọn tí ó funfun jù ni ó níye lórí jù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òkúta iyebíye mélòó kan wà tí ó ní ohun tí a ń pè ní àwọ̀ ọ̀ṣọ́, bí àwọ̀ osùn, búlúù, tàbí pupa; àwọn wọ̀nyí sì lówó lórí ju àwọn aláwọ̀ funfun lọ, nítorí pé wọ́n ṣọ̀wọ́n púpọ̀ jù.

“Paríparí gbogbo rẹ̀, a ń díwọ̀n òkúta iyebíye kan nípa bí ó ṣe mọ́ kedere tó. Bí a bá pín òkúta iyebíye kan sí ìsọ̀rí kòlábùkù, ó túmọ̀ sí pé, bí o bá wo inú rẹ̀—kódà bí o bá fi loupe wò ó—o kò ní rí àbùkù kankan. Nípa báyìí, ìrísí dáyámọ́ńdì kan, ìmọ́kedere rẹ̀, àti àwọ̀ rẹ̀ lè ṣe pàtàkì bí ìwúwo rẹ̀ ní ti ìwọ̀n tí ó tẹ̀ ti ṣe pàtàkì. Kí a fún ọ ní àpẹẹrẹ kan, ní 1995, a gbé dáyámọ́ńdì tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ èyí tí o tóbi jù tí a tí ì dán lára rí (ìwọ̀n 546.67) jáde fún àfihàn. Ṣùgbọ́n láìka ìtóbi rẹ̀—ti ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti bọ́ọ̀lù golf sí—èyí kọ́ ni dáyámọ́ńdì tí ó níye lórí jù lọ lágbàáyé, nítorí ìmọ́kedere rẹ̀ tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ àti àwọ̀ ìyeyè-òun-ilẹ̀ tí ó ní.”

Kí a tó kúrò ní Antwerp, mo bá Hans Wins, tí ó ti lo 50 ọdún nídìí iṣẹ́ dáyámọ́ńdì sọ̀rọ̀. Mo fẹ́ láti béèrè ìbéèrè kan tí ó kẹ́yìn, Kí ló mú kí dáyámọ́ńdì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

Ó dáhùn pé: “Àwọn òkúta kéékèèké wọ̀nyẹn kò jọ mí lójú tó bẹ́ẹ̀—a tilẹ̀ lè fi ẹ̀rọ gé wọn kí a sì fi dán wọn. Ṣùgbọ́n àwọn dáyámọ́ńdì ńláńlá ló wọ̀ mí lọ́kàn. Òkúta kọ̀ọ̀kan yàtọ̀—ìṣẹ̀dá aláìlẹ́gbẹ́ kan tí a mú jáde láti inú èédú gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún tí a fi ki òkúta abúgbàù mọ́lẹ̀. Nígbà tí o bá ṣàyẹ̀wò òkúta náà, o lè rí ìlà ìdàgbà rẹ̀ ní ti gidi, tí ó rí bíi ti ìtì igi bákan ṣáá. Olùrajà kan tí ó nírìírí dáradára tilẹ̀ lè sọ ibi ìwakùsà tí a ti wà á jáde.

“Olùṣèmújáde dáyámọ́ńdì kan máa ń wo irú òkúta iyebíye bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí oníṣọ̀nà mábìlì kan ń gbà wo odindi mábìlì kan. Ó ti fojú inú rẹ̀ wo ohun tí ó lè fi ṣe. Nínú ìfinúwòye rẹ̀, ó ti ń gé e, ó ń dán an, àgbàyanu òkúta ṣíṣeyebíye kan sì ti ń yọjú bọ̀. Mo máa ń fẹ́ láti ronú pé, nígbà tí a bá gbé dáyámọ́ńdì náà sórí òrùka tàbí gbẹ̀dẹ̀ kan níkẹyìn, yóò fún ẹni tí ó ni ín ní irú ìtẹ́lọ́rùn kan náà.”

Lẹ́yìn tí a ti ṣàyẹ̀wò ohun gbogbo, ìyẹn ni ìdí tí ó fi tóyeyẹ láti ṣe dáyámọ́ńdì kan.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìdí pàtàkì kan tí dáyámọ́ńdì fi gbówó lórí ni agbára ìnìkandarí ilé iṣẹ́ kan ṣoṣo, Àjọ Ìdarí Ìtajà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Dáyámọ́ńdì onírìísí ọkàn àyà tí ó tẹ ìwọ̀n 8 (òkúta náà kò sí ní ìwọ̀n ìrísí)

Onírìísí èso píà

Onírìísí “fìlà kádínà”

Pípinnu ìwọ̀n òkúta tí kò tí ì ní ìrísí

Ṣíṣa dáyámọ́ńdì tí a kò tí ì dà sọ́tọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọ̀

Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ojú láti mọ̀ bóyá a nílò dídán wọn sí i

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́