O Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
ÓLÈ ṣòro láti mọ bí ohun kan ti níye lórí tó. Bí ọ̀ràn dáyámọ́ńdì ti rí gan-an nìyẹn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dáyámọ́ńdì tí a ti dán máa ń tàn yinrin, ìtànyinrin dáyámọ́ńdì tí a kò tí ì dán kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun ẹlẹ́wà kan tí ó ṣeyebíye wà nínú dáyámọ́ńdì tí a kò tí ì dán náà.
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni àwọn Kristẹni fi jọ dáyámọ́ńdì tí a kò tí ì dán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tí ì sún mọ́ ìjẹ́pípé rárá, ohun ìníyelórí kan wà nínú wa tí ó ṣeyebíye fún Jèhófà. Bí dáyámọ́ńdì, gbogbo wa pátá ní àwọn ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí bí ó bá jẹ́ ìyẹn ni ìfẹ́-ọkàn wa. A lè dán àwọn àkópọ̀ ìwà wa, kí wọ́n bàa lè túbọ̀ máa tàn yinrin láti fi ògo fún Jèhófà.—1 Kọ́ríńtì 10:31.
Lẹ́yìn tí a bá ti gé e, tí a sì dán an, a óò fi dáyámọ́ńdì sí ibi tí a ó lẹ̀ ẹ́ mọ́ tí ìtànyinrin rẹ̀ yóò ti lè mọ́lẹ̀ dáradára. Lọ́nà jíjọra, Jèhófà lè lò wá ní àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tàbí lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí a bá “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:20-24.
Irú ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lè máà rọrùn, gan-an gẹ́gẹ́ bí dáyámọ́ńdì kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ wà jáde kì í ti í fi bẹ́ẹ̀ tàn yinrin gẹ́gẹ́ bí òkúta iyebíye. Ó lè pọndandan fún wa láti wá nǹkan ṣe sí àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó tí ó ṣì wà lára wa, kí a tún ìrònú wa ṣe nípa títẹ́wọ́gba ẹrù iṣẹ́, tàbí kí a tilẹ̀ tiraka láti bọ́ nínú ipò wíwà bí adágún odò nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n bí a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, ó ṣeé ṣe, níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13.
Jèhófà Ń fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Lókun
Gígé dáyámọ́ńdì ń béèrè ìdánilójú tí ó ń wá láti inú ìmọ̀ pípéye, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé, bí a bá ti gé apá dáyámọ́ńdì kan tí a kò tí ì dán sọnù, kò ṣeé lò mọ́ nìyẹn. Nígbà mìíràn a ní láti gé ohun tí ó lówó lórí—nǹkan bí ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún òkúta tí a kò tí ì gé náà—sọnù láti mú irú ìrísí tí a ń fẹ́ jáde. Àwa pẹ̀lú nílò ìdánilójú tí ó ń wá láti inú ìmọ̀ pípéye kí a bàa lè fún àkópọ̀ ìwà wa ní ìrísí tí ó wuni, kí a sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ní pàtàkì, a gbọ́dọ̀ ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò gbé agbára wọ̀ wá.
Ṣùgbọ́n, a lè nímọ̀lára pé a kò kún ojú òṣùwọ̀n, tàbí kí a nímọ̀lára pé a kò lè ṣe púpọ̀ sí i. Nígbà àtijọ́, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń nímọ̀lára lọ́nà bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn. (Ẹ́kísódù 3:11, 12; 1 Àwọn Ọba 19:1-4) Nígbà tí Ọlọ́run yan Jeremáyà láti jẹ́ “wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ó wí pé: “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” (Jeremáyà 1:5, 6) Ṣùgbọ́n, láìfi ìlọ́tìkọ̀ rẹ̀ pè, Jeremáyà di wòlíì onígboyà tí ó jíṣẹ́ tí ó ṣe tààràtà fún àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ oníkanra. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe? Ó kọ́ láti gbára lé Jèhófà. Jeremáyà kọ̀wé lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí Jèhófà di ìgbọ́kànlé rẹ̀.”—Jeremáyà 17:7; 20:11.
Bákan náà lónìí Jèhófà ń fún àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ lókun. Edward,a tí ó jẹ́ bàbá ọmọ mẹ́rin, tí kò sì tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Mo ti jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọdún mẹ́sàn-án, ṣùgbọ́n ó dà bí pé ń kò kúrò lójú kan nípa tẹ̀mí. Ìṣòro náà ni pé kò sí ohun tí ń fún mi níṣìírí, n kò sì dá ara mi lójú. Lẹ́yìn tí mo ṣí lọ sí Sípéènì, mo wà nínú ìjọ kékeré kan tí ó ní alàgbà kan àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan. Nítorí àìní yìí, alàgbà náà ní kí ń máa bójútó ọ̀pọ̀ iṣẹ́. Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ sọ àsọyé, tí mo sì kọ́kọ́ kópa nínú ìpàdé ojora mú mi. Síbẹ̀, mo kọ́ láti gbára lé Jèhófà. Ìgbà gbogbo ni alàgbà náà máa ń gbóríyìn fún mi, ó sì ń fún mi ní ìmọ̀ràn yíyẹ láti lè tẹ̀ síwájú.
“Ní àkókò kan náà, mo fi kún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá mi, mo sì túbọ̀ mú ipò iwájú nípa tẹ̀mí nínú ìdílé mi. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, òtítọ́ túbọ̀ di ohun pàtàkì fún ìdílé mi, mo sì túbọ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni mí nísinsìnyí, mo sì ń ṣiṣẹ́ kára láti mú àwọn ànímọ́ Kristẹni alábòójútó dàgbà.”
“Ẹ Bọ Ògbólógbòó Àkópọ̀ Ìwà Sílẹ̀”
Gẹ́gẹ́ bí Edward ti rí i, ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí ń béèrè fún ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Mímú “àkópọ̀ ìwà tuntun” bí ti Kristi dàgbà tún ṣe kókó. Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni láti “bọ́” àwọn ànímọ́ tí ó jẹ́ apá kan ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà “sílẹ̀.” (Kólósè 3:9, 10) Gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ kí a mú àbààwọ́n, àwọn èròjà mineral tí ó ṣàjèjì, kúrò lára dáyámọ́ńdì kí ó bàa lè dán yinrin, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe yẹ kí a mú àwọn ìṣarasíhùwà “tí ó jẹ́ ti ayé” kúrò pátápátá kí àkópọ̀ ìwà wa tuntun bàa lè mọ́lẹ̀ yòò.—Gálátíà 4:3.
Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ ni lílọ́tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ẹrú iṣẹ́ nítorí ìbẹ̀rù pé a óò béèrè ohun púpọ̀ lọ́wọ́ wa. Lóòótọ́, ẹrù iṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta, ṣùgbọ́n iṣẹ́ kan tí ó ń tuni lára ni. (Fi wé Ìṣe 20:35.) Pọ́ọ̀lù gbà pé ìfọkànsin Ọlọ́run ń béèrè pé kí a ‘ṣiṣẹ́ kára, kí a sì tiraka.’ Ó wí pé, a ń fi ayọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, “nítorí tí a ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè,” ẹni tí kì í gbàgbé iṣẹ́ tí a ń ṣe nítorí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa àti àwọn mìíràn.—1 Tímótì 4:9, 10; Hébérù 6:10.
Àwọn dáyámọ́ńdì kan ti lè “sán” nígbà tí a ń wà wọ́n, ó ń béèrè pé kí a fìṣọ́ra dì wọ́n mú. Ṣùgbọ́n, olùdán-dáyámọ́ńdì lè lo irinṣẹ́ kan tí a ń pè ní polariscope láti mọ ibi tí ó sán náà, kí ó sì ṣàṣeyọrí nínú dídán òkúta náà. Ó ṣeé ṣe kí àwa pẹ̀lú ti sán nínú, tàbí kí àkópọ̀ ìwà wa ní àléébù, nítorí ipò àtilẹ̀wá wa tàbí ìrírí adanilórírú kan tí a ti ní. Kí ni a lè ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ gbà pé a ní ìṣòro náà, kí a sì pinnu láti borí rẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Dájúdájú, ó yẹ kí a kó àníyàn kúrò lọ́kàn ara wa nípa títọ Jèhófà lọ nínú àdúrà, a tún lè wá ìrànwọ́ tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ alàgbà Kristẹni kan.—Sáàmù 55:22; Jákọ́bù 5:14, 15.
Irú sísán nínú lọ́hùn-ún bẹ́ẹ̀ nípa lórí Nicholas. Ó ṣàlàyé pé: “Onímukúmu ni bàbá mi, ó sì kó ìyà púpọ̀ jẹ èmi àti arábìnrin mi. Nígbà tí mo jáde ilé ìwé, mo wọṣẹ́ ológun, ṣùgbọ́n ìwà ọ̀tẹ̀ mi mú kí n tètè kó wọ wàhálà. Àwọn aláṣẹ ológun jù mí sẹ́wọ̀n nítorí tí mo ń gbé oògùn olóró, ní àkókò kan mo sá lọ. Níkẹyìn, mo fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, ṣùgbọ́n wàhálà mi ṣì wà níbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé mi kò nítumọ̀ nítorí ìjoògùnyó àti ọtí àmuyíràá, mo nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, mo sì fẹ́ láti ní ète kan nínú ìgbésí ayé. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, mo yí ìgbésí ayé mi padà, mo sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́.
“Ṣùgbọ́n, ó gba ọ̀pọ̀ ọdún kí n tó borí àléébù kan tí ó wà nínú àkópọ̀ ìwà mi. Mo kórìíra ọlá àṣẹ gidigidi, mo sì máa ń bínú nígbà tí a bá fún mi nímọ̀ràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ kí Jèhófà lò mí ní kíkún, àìlera yìí ti jẹ́ ìfàsẹ́yìn fún mi. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn alàgbà méjì tí wọ́n jẹ́ afòyebánilò, mo tẹ́wọ́ gba ìṣòro mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ wọn tí ó wá láti inú Ìwé Mímọ́ sílò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń bínú díẹ̀díẹ̀ nígbà mìíràn, mo ti ṣàkóso ìwà ọ̀tẹ̀ mi nísinsìnyí. Mo dúpẹ́ púpọ̀ fún ọ̀nà sùúrù tí Jèhófà gbà bá mi lò àti fún ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ ti àwọn alàgbà. Nítorí ìtẹ̀síwájú mi nípa tẹ̀mí, láìpẹ́ yìí a yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.”
Gẹ́gẹ́ bí Nicholas ti rí i, yíyí ìwà tí ó ti di mọ́líkì padà kò rọrùn. A lè dojú kọ irú ìpèníjà kan náà. Bóyá ara wa tètè máa ń gbóná. A lè máa di kùnrùngbùn, tàbí kí a máa tẹnu mọ́ wíwà lómìnira jù. Nípa báyìí, ìtẹ̀síwájú Kristẹni wa lè ní ààlà. Àwọn olùdán-dáyámọ́ńdì ń ní ìrírí tí ó jọra pẹ̀lú òkúta kan tí wọ́n ń pè ní naats. Ìwọ̀nyí jẹ́ òkúta méjì tí ó yọ́ pọ̀ di ọ̀kan ṣoṣo nígbà tí òkúta ń di dáyámọ́ńdì. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, òkúta naats ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó gbà ń dàgbà, èyí sì mú kí ó ṣòro láti gé nítorí bí ohun apilẹ̀ wọ́n ṣe rí. Nínú ọ̀ràn tiwa, “ohun apilẹ̀” ti ẹ̀mí tí ń fẹ́ ṣe rere ń bá “ohun apilẹ̀” ti ẹran ara àìpé jà. (Mátíù 26:41; Gálátíà 5:17) Nígbà mìíràn, a lè fẹ́ láti juwọ́ sílẹ̀ pátápátá nínú ìjàkadì náà, ní wíwí àwíjàre pé àìpé inú àkópọ̀ ìwà wa kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. A lè sọ pé, ‘ó ṣe tán, ìdílé mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣì nífẹ̀ẹ́ mi.’
Ṣùgbọ́n, bí a óò bá sin àwọn ará wa, kí a sì yin Baba wa ọ̀run lógo, a ní láti ‘di tuntun nínú ipá ti ń mú èrò inú wa ṣiṣẹ́’ nípa gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Nicholas àti àìníye àwọn mìíràn ti lè jẹ́rìí sí i, ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀. Olùdán-dáyámọ́ńdì kan mọ̀ pé àbààwọ́n kan ṣoṣo lè ba odindi dáyámọ́ńdì jẹ́. Bákan náà, bí a kò bá ka apá tí ó kù-díẹ̀-káàtó nínú àkópọ̀ ìwà wa sí, a lè ba ìrísí wa nípa tẹ̀mí jẹ́. Èyí tí ó tún burú jù lọ ni pé, àìlera lílékenkà lè yọrí sí ìṣubú wa nípa tẹ̀mí.—Òwe 8:33.
Bí “Iná” Nínú Wa
Olùdán-dáyámọ́ńdì ń fẹ́ láti rí iná tí ó wà nínú dáyámọ́ńdì. Ó ń ṣe èyí nípa ṣíṣètò àwọn igun rẹ̀ lọ́nà tí yóò fi mú onírúurú àwọ̀ mèremère jáde. Nínú dáyámọ́ńdì náà lọ́hùn-ún ìmọ́lẹ̀ onírúurú àwọ̀ yóò máa kọ mànàmànà, yóò sì pèsè iná tí ń mú kí dáyámọ́ńdì máa tàn yinrinyinrin. Lọ́nà tí ó jọra, ẹ̀mí Ọlọ́run lè dà bí “iná” nínú wa.—1 Tẹsalóníkà 5:19; Ìṣe 18:25; Róòmù 12:11.
Ṣùgbọ́n bí a bá mọ ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ ẹni tí a ń sún ṣiṣẹ́ nípa tẹ̀mí ńkọ́? Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? A ní láti ‘gbé àwọn ọ̀nà wa yẹ̀ wò.’ (Sáàmù 119:59, 60) Èyí yóò kan mímọ àwọn ohun tí ń fà wá sẹ́yìn nípa tẹ̀mí, a óò sì wá pinnu àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run tí a ní láti túbọ̀ lépa tokuntokun. A lè mú kí ìmọrírì wa fún ohun tẹ̀mí jinlẹ̀ sí nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àdúrà onítara-ọkàn. (Sáàmù 119:18, 32; 143:1, 5, 8, 10) Ní àfikún sí i, nípa kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìgbàgbọ́, a óò fún ìpinnu wa láti fi ìtara sin Jèhófà lókun.—Títù 2:14.
Louise, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin Kristẹni kan, sọ pé: “Ọdún méjì ni mo fi ronú lórí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé kí n tó forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, tàbí olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún. Kò sí ohunkóhun tí ó dí mi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n mo kàn ń gbé ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́ ni, n kò sì fẹ́ wá nǹkan ṣe sí i. Lójijì, baba mi kú. Ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé ìwàláàyè gbẹgẹ́ àti pé n kò tí ì lo tèmi lọ́nà dídára jù lọ. Nítorí náà, mo yí ojú ìwòye mi nípa ohun tẹ̀mí padà, mo fi kún iṣẹ́ ìsìn mi, mo sì di aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ní pàtàkì, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí tí wọ́n ń fìgbà gbogbo tì mí lẹ́yìn nínú ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá, tí wọ́n sì máa ń bá mi jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ràn mí lọ́wọ́ gidigidi nípa rẹ̀. Mo ti kọ́ pé yálà lọ́nà tí ó bára dé tàbí èyí tí kò bára dé, a ń ṣàjọpín ọ̀pá ìdiwọ̀n àti góńgó àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa.”
Fífi Ohun Tí Ó Jọ Irin Pọ́n Ọn
Dáyámọ́ńdì ni ohun ìṣẹ̀dá tí ó le koránkorán jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, dáyámọ́ńdì ni ó lè gé dáyámọ́ńdì. Èyí lè rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì létí òwe náà tí ó sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17) Báwo ni a ṣe ń “pọ́n” ojú ẹnì kan? Ẹnì kan lè ṣàṣeyọrí nínú pípọ́n ipò òye àti ipò tẹ̀mí ti ẹnì kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè lo irin láti pọ́n ojú idà tí a fi irú irin kan náà ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ká ní àwọn ìjákulẹ̀ kan mú wa sorí kọ́, ìṣírí láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lè gbé wa ró gidigidi. Ojú wa tí ó kọ́rẹ́ lọ́wọ́ lè yí padà, a sì lè mú kí ó jí pépé fún ìgbòkègbodò onítara tí a mú sọjí. (Òwe 13:12) Ní pàtàkì, àwọn alàgbà ìjọ lè ràn wá lọ́wọ́ láti pọ́n ara wa lẹ́nì kíní kejì nípa pípèsè ìṣírí inú Ìwé Mímọ́ àti ìmọ̀ràn kí a bàa lè sunwọ̀n sí i. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà tí Sólómọ́nì sọ pé: “Fi fún ọlọ́gbọ́n, òun yóò sì túbọ̀ gbọ́n sí i. Fi ìmọ̀ fún olódodo, òun yóò sì pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́.”—Òwe 9:9.
Àmọ́ ṣáá o, ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí ń béèrè àkókò. Ó lé ní ọdún mẹ́wàá tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ṣàjọpín ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú Tímótì, tí ó sì kọ́ ọ ní ọ̀nà ìkọ́ni. (1 Kọ́ríńtì 4:17; 1 Tímótì 4:6, 16) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ gígùn tí Mósè fún Jóṣúà fún ohun tí ó lé ní 40 ọdún ṣàǹfààní fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fún ìgbà pípẹ́. (Jóṣúà 1:1, 2; 24:29, 31) Ọdún 6 ni Èlíṣà fi bá wòlíì Èlíjà rìn, tí ó sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ó gbámúṣé fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tí yóò gbà tó nǹkan bí 60 ọdún. (1 Àwọn Ọba 19:21; 2 Àwọn Ọba 3:11) Nípa fífi sùúrù pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ń lọ lọ́wọ́, àwọn alàgbà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, Mósè, àti Èlíjà.
Gbígbóríyìn fúnni jẹ́ apá pàtàkì ìdálẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá tí ń fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ àyànfúnni tí a ṣe dáradára tàbí fún ìwà tí ó yẹ kí a gbóṣùbà fúnni fún lè sún àwọn ẹlòmíràn láti fẹ́ láti sin Ọlọ́run ní kíkún sí i. Oríyìn ń gbé ìdánilójú ró, ẹ̀wẹ̀, ìdánilójú ń pèsè àwọn àrànṣe tí ó lè múni borí àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 11:2.) Ìṣírí láti tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́ tún ń wá láti inú jíjẹ́ ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí fọ́fọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba àti àwọn ìgbòkègbodò ìjọ mìíràn. (Ìṣe 18:5) Nígbà tí àwọn alàgbà bá fún àwọn arákùnrin ní ẹrù iṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí, èyí ń mú kí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ìrírí tí ó ṣeyebíye, ó sì lè mú kí ó fún ìfẹ́-ọkàn wọn láti máa tẹ̀ síwájú sí i nípa tẹ̀mí lókun.—Fílípì 1:8, 9.
Ìdí Rere fún Títẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí
A ka dáyámọ́ńdì sí ohun iyebíye. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà káàkiri ayé nísinsìnyí rí. Ní tòótọ́, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ pè wọ́n ní àwọn ohun “fífani-lọ́kàn-mọ́ra,” tàbí ohun “iyebíye,” ti gbogbo orílẹ̀-èdè. (Hágáì 2:7, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Ní ọdún tí ó kọjá, 375,923 ni ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a batisí. Láti rí ibi gba ìbísí yìí sí, ó pọndandan láti ‘mú ibi àgọ́ náà ní àyè gbígbòòrò.’ Nípa títẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí—àti nípa nínàgà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Kristẹni—ó ṣeé ṣe láti nípìn-ín nínú bíbójútó ìmúgbòòrò yìí.—Aísáyà 54:2; 60:22.
Láìdàbí ọ̀pọ̀ dáyámọ́ńdì ṣíṣeyebíye tí a tọ́jú sí akóló báǹkì tí a kì í sì í sábà rí, ìníyelórí wa nípa tẹ̀mí lè mọ́lẹ̀ yòò. Bí a sì ṣe ń dán àwọn ànímọ́ Kristẹni wa déédéé, tí a sì ń fi hàn, a ń fògo fún Jèhófà Ọlọ́run. Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Dájúdájú, ìyẹn ń fún wa ní ìdí yíyèkooro láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn orúkọ àfidípò ni a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.