ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/1 ojú ìwé 30-31
  • Iwọ Ha Mọriri Eto-ajọ Jehofa Ori Ilẹ-aye Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwọ Ha Mọriri Eto-ajọ Jehofa Ori Ilẹ-aye Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yẹra Fun Wiwo Awọn Ẹlomiran Pẹlu Oju Alariiwisi
  • ‘Sopọṣọkan Rẹgirẹgi Ninu Ero-inu Kan Naa’
  • ‘Bii Dáyámọ́ǹdì Kan, Ni Mo Ti Ṣe Iwaju Ori Rẹ’
  • “Awọn Iranṣẹ Temi Yoo Yọ̀”
  • Èé Ṣe Tí Dáyámọ́ńdì Fi Gbówó Lórí Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—1997
  • O Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Bá Ètò Jèhófà Rìn Bó Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/1 ojú ìwé 30-31

Iwọ Ha Mọriri Eto-ajọ Jehofa Ori Ilẹ-aye Bi?

WO OKUTA dáyámọ́ǹdì meremere kan, ti a gé daradara, ki ni iwọ sì rí? Ohun ọṣọ kan ti ó jẹ́ ohun ẹlẹwa kan nitootọ. Nisinsinyi yẹ okuta dáyámọ́ǹdì yẹn wò nipasẹ ẹrọ amú nǹkan tobi, ki ni iwọ sì rí? O ṣeeṣe ki ó ni awọn ìlà tẹẹrẹ, awọn oju sísán, awọn ohun àkìsínú, tabi awọn aleebu miiran.

Iwọ yoo ha fọ́ okuta dáyámọ́ǹdì naa tabi sọ ọ́ nù kiki nitori bi o ṣe rí labẹ ẹrọ amú nǹkan tobi kan? Dajudaju bẹẹkọ! Ani pẹlu igbesẹ kan kuro nidii ẹrọ amú nǹkan tobi naa iwọ ṣì lè mọriri ẹwà ati ìdányanranyanran ara-ọtọ naa ti ó mu ki ó tayọ laaarin awọn okuta iyebiye miiran.

Bi okuta dáyámọ́ǹdì kan, eto-ajọ Jehofa ori ilẹ-aye tayọ ni ọpọlọpọ ọna. Kò sí eto-ajọ miiran ni ori ilẹ-aye ti ó gbadun ipo ibatan timọtimọ pẹlu Ẹlẹdaa. Ninu lẹta kan sí awọn Kristẹni ẹni ami ororo ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ti wọn ṣikẹ ireti ti ọrun, apọsiteli Peteru tọka si ipo ibatan akanṣe yii. O wi pe: “Ẹyin ni iran ti a yàn, olú alufaa, orilẹ-ede mímọ́, eniyan ọtọ.” (1 Peteru 2:9) Lonii ogunlọgọ nla ti “awọn agutan miiran,” ti wọn ni ireti iye ainipẹkun lori ilẹ-aye, ti darapọ mọ awọn aṣẹku “orilẹ-ede mimọ” yẹn ninu jijọsin Ọlọrun. (Johanu 10:16) Awujọ meji wọnyi papọ di eto-ajọ kan ti ó tayọ bi okuta iyebiye meremere ti ó sì ńtàn yanranyanran lọna ara-ọtọ.

Yẹra Fun Wiwo Awọn Ẹlomiran Pẹlu Oju Alariiwisi

Ṣugbọn a gbọdọ mọ pe eto-ajọ yika aye yii ní awọn eniyan alaipe ninu. Nitori naa, ki ni yoo ṣẹlẹ bi a ba wò ó labẹ ohun amú nǹkan tobi iṣapẹẹrẹ kan? Bẹẹni, awa yoo ri awọn itẹsi ti wọn kun fun ẹṣẹ ati awọn àléébù iwa animọ ninu ẹnikọọkan ti ó jẹ́ apakan rẹ̀.—Roomu 3:23.

Apọsiteli Pọọlu gbà pe oun ni iru àléébù bẹẹ. O sọ pe: “Bi emi ti nfẹ lati maa ṣe rere, buburu a maa wà lọdọ mi.” (Roomu 7:21) Olukuluku Kristẹni nniriiri ìwàyá ìjà kan naa. Gbogbo wọn nṣe aṣiṣe. Siwaju sii, laipẹ laijinna ọpọlọpọ njiya nitori aṣiṣe awọn ẹlomiran. O ha yẹ ki a rẹwẹsi tabi sọ igbagbọ nù nigba ti awọn aleebu ati aipe awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ wa ba wá si ojutaye bi? O ha yẹ ki iyẹn din imọriri wa fun eto-ajọ Jehofa kù bi? Dajudaju bẹẹkọ! Kaka bẹẹ, awa gbọdọ wo gbogbo rẹ̀ papọ, gẹgẹ bi ó ti rí, ki a sì dawọ pípa afiyesi pọ̀ sori aipe awọn ẹnikọọkan duro.

Iwe mimọ ṣakọsilẹ lẹsẹẹsẹ awọn animọ ti yoo fi awọn wọnni ti ẹmi mimọ nṣiṣẹ lara wọn han yatọ. Diẹ ninu wọn ni “ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere-iṣeun, igbagbọ, iwapẹlẹ, ikora-ẹni-nijaanu.” (Galatia 5:22, 23, NW) Ni odikeji, awọn eto-ajọ ti isin, ti oṣelu, ati ti iṣowo aye yii maa nfi ohun ti Bibeli tọkasi gẹgẹ bi iṣẹ ti ara hàn: “iṣọta, rogbodiyan, owú, ìbínúfùfù, gbolohun asọ̀, iyapa, awọn ẹya isin, ilara, idije ọti mimu, ariya alariwo, ati awọn nǹkan bi iwọnyi.” (Galatia 5:20, 21, NW) Nipa bayii, bi okuta dáyámọ́ǹdì didan yanranyanran kan laaarin awọn apata lasan, awọn eniyan Jehofa tayọ laaarin aye ti ó dibajẹ nipa tẹmi.—Matiu 5:14-16.

‘Sopọṣọkan Rẹgirẹgi Ninu Ero-inu Kan Naa’

Ìhà titayọ kan ti okuta dáyámọ́ǹdì ni ọna igbekalẹ èérún kínkìnkín ti a hunpọ mọra pẹkipẹki, ti a dèpọ̀ daradara. Lọna ti ó farajọra, eto-ajọ Jehofa ti ori ilẹ-aye fi isopọṣọkan ti kò lẹ́gbẹ́ han ninu ẹkọ igbagbọ ati ẹgbẹ́ ará. Awọn ti wọn jẹ́ apakan eto-ajọ yẹn fi iṣileti ti a rí ninu Bibeli ni 1 Kọrinti 1:10 (NW) silo, eyi ti ó wi pe: “Nisinsinyi mo gbà yin ni iyanju ẹyin ará, nipasẹ orukọ Oluwa wa Jesu Kristi pe gbogbo yin nilati maa sọrọ ni ifohunṣọkan, ati pe iyapa kò nilati sí laaarin yin, ṣugbọn kí á lè so yin pọ ṣọkan rẹgi ninu ero-inu kan naa ati ninu ila ironu kan naa.”

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tun ti tayọ rekọja ẹtanu ẹya-iran ati ẹmi orilẹ-ede temi lọga. Nitori wọn ni “ọgbọn tí ó ti oke wá,” wọn kii ‘ṣe ègbè.’ (Jakobu 3:17) A fi ogo fun Jehofa fun ohun ti ó ti ṣaṣepari ninu ọran yii ninu eto-ajọ kan ti ó ni awọn eniyan alaipe ninu.

Ni ọwọ keji ẹwẹ, iwe irohin naa The Christian Century, ni sisọrọ nipa ọdun 1990, wi pe “aye dabi eyi ti a ti pín yẹlẹyẹlẹ ju ti igbakigba ri lọ nipa awọn awujọ onisin, ati nipa awọn ero iṣẹdalẹ ati ti ifẹ orilẹ-ede ti ó so pọ timọtimọ mọ awọn ero igbagbọ isin. Lati India si Europe ati lati Aarin Ila-oorun si Pacific, isin lúpọ̀ mọ awọn itilẹhin ti iṣẹda ati ti ifẹ orilẹ-ede—niye igba ti ó ni iyọrisi elewu niti oṣelu.” Ni kedere, awọn wọnni ti wọn fẹ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun lè yijusi eto-ajọ kanṣoṣo ti o gbadun ẹmi ati ibukun Jehofa.

‘Bii Dáyámọ́ǹdì Kan, Ni Mo Ti Ṣe Iwaju Ori Rẹ’

Okuta dáyámọ́ǹdì ni ohun ti ó lekoko julọ lọna adanida ti eniyan mọ. Bibeli tọka si ìlò dáyámọ́ǹdì ninu híha tabi gbígbẹ́ ohun èèlò líle. (Jeremaya 17:1) Ṣakiyesi, pẹlu, awọn ọrọ Jehofa si Esikiẹli pe: “Kiyesi i! Mo ti sọ oju rẹ di lile bakan naa gẹgẹ bi oju wọn ati iwaju ori rẹ bakan naa gẹgẹ bi iwaju ori wọn. Bi dáyámọ́ǹdì kan, ti ó le ju okuta líle lọ, ni mo ti ṣe iwaju ori rẹ.” (Esikiẹli 3:8, 9, NW) Jehofa fun Esikiẹli ni ipinnu ti ó le bii dáyámọ́ǹdì ti ó mu ki ó ṣeeṣe fun un lati sasọtẹlẹ fun awọn eniyan alagidi.—Esikiẹli 2:6.

Bakan naa lonii, Jehofa ti fi líle bi dáyámọ́ǹdì fun awọn eniyan rẹ̀ ni oju atako. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti farada ìfòfindè, igbejakoni awujọ eniyankeniyan, pipani laigbẹjọ, lílù, ìfisẹ́wọ̀n ti kò ba idajọ ododo mu, idaloro, ati ifiya iku jẹni paapaa. Sibẹ, wọn ti fi igbagbọ wọn han bi alaile já.

“Awọn Iranṣẹ Temi Yoo Yọ̀”

Bibeli sọ asọtẹlẹ akoko kan nigba ti awọn eniyan yoo ni “afarawe iwa-bi-Ọlọrun” ṣugbọn ti wọn yoo “sẹ́ agbara rẹ̀.” (2 Timoti 3:1, 5) Iwe irohin kan rohin pe “awọn Protẹstanti, Roman Katoliki ati awọn Juu ni ilọsilẹ” ninu ṣọọṣi ati sinagọgu wọn “nkọ lominu.” Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni ọwọ keji ẹwẹ, jẹ́ olufọkansin akẹkọọ Bibeli. Ni iye ti npọ sii, lọmọde ati lagba, ọkunrin ati obinrin, gbogbo wọn nlọ si awọn ipade ọsọọsẹ melookan. Lẹta kan si iwe irohin kan nipa wọn sọ pe “isin wọn ni ohun ti ó ṣeyebiye julọ ti wọn ní, idaniyan wọn kanṣoṣo sì ni lati ṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran.”

Iṣarasihuwa kan bẹẹ mu ki eto-ajọ Jehofa tayọ bi dáyámọ́ǹdì oniyebiye. Ọla sì lọ sí ọdọ Ẹni naa ti nfun awọn eniyan alaipe lokun nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀ ti ó sì ndari wọn.

Wolii Aisaya sọtẹlẹ pe: “Eyi ni ohun ti Oluwa Ọba-alaṣẹ Jehofa ti sọ: ‘Kiyesi i! Awọn iranṣẹ temi yoo jẹun . . . Kiyesi i! Awọn iranṣẹ temi yoo mu . . . Kiyesi i! Awọn iranṣẹ temi yoo yọ̀ . . . Kiyesi i! Awọn iranṣẹ temi yoo ké jade pẹlu ayọ nitori ipo ọkan-aya rere.’”—Aisaya 65:13, 14, NW.

Lonii a rí imuṣẹ asọtẹlẹ yii. Ọlọrun bikita fun awọn eniyan rẹ̀ ni ọna ara-ọtọ kan! Fun idi yii, bi iwọ ba nkẹgbẹpọ pẹlu wọn, maṣe jẹ ki ironu odi kankan jà ọ́ lole ayọ rẹ. Wo aworan naa lodidi kí o sì ranti pe: Kò sí eto-ajọ miiran lori ilẹ-aye ti ngbadun akanṣe itọju ati aabo Ọlọrun. Maṣe dawọ duro lati pa iṣura anfaani rẹ ti jijẹ apakan rẹ̀ mọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́