Wa Si Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùfẹ́ Ominira”!
ỌJỌ mẹta ti ńmú ere wà ti itọni Bibeli nduro dè ọ. Wà nibẹ ni 9:20 owurọ Friday nigba ti Apejọpọ naa yoo bẹrẹ pẹlu igbejade ohùn orin. Gbadun ọrọ asọye ibẹrẹ naa, “Eeṣe Ti A Fi Nilati Bojuwo Ofin Pipe ti Ominira?,” ati apa ipari itolẹsẹẹsẹ owurọ, ọrọ asọye pataki naa: “Ète ati Ilo Ominira tí Ọlọrun Fifun Wa.”
Ni ọsan ọjọ Friday, iṣileti ni a o pese fun awọn Kristẹni lati mu iṣẹ ti a yàn fun wọn ṣẹ gẹgẹ bi awọn ojiṣẹ Ọlọrun. “Ọwọ Rẹ Dí—Ninu Awọn Òkú Iṣẹ́ tabi Ninu Iṣẹ isin Jehofa?” ati “Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn Ti Wọn Yoo Jíhìn” jẹ ẹṣin ọrọ meji ti a o sọrọ le lori. Ìṣírí lati lo ominira ẹni lati ṣiṣẹsin Jehofa ni a o pese ninu awokẹkọọ lọna aṣa iwọṣọ igbaani. Yoo fa awọn iriri Ẹsira jade ati awọn alabaakẹgbẹ rẹ ti wọn pada lati Babiloni si Jerusalẹmu ni 468 B.C.E. lati ṣe tẹmpili Ọlọrun lọṣọọ.
Itolẹsẹẹsẹ owurọ ọjọ Saturday yoo gbe apinsọ ọrọ asọye alapa mẹta jade, “Ominira Pẹlu Ẹru iṣẹ Ninu Agbo Idile.” Tẹle awiye ti nwadii ọkan naa “Mú Ara Rẹ Wà Lominira Lati Ṣiṣẹsin Jehofa” ni ọrọ asọye kan yoo wà lori iyasimimọ ati iribọmi Kristẹni. Ni ọsan ọpọlọpọ yoo fi ìháragàgà duro de apa naa “Igbeyawo Ha Ni Kọkọrọ Naa Si Ayọ Bi?” Itolẹsẹẹsẹ naa yoo pari pẹlu koko itẹnumọ kan eyi ti laisi iyemeji yoo mu idunnu nlanla wa fun gbogbo awọn olufẹ ominira.
Iwọ yoo fẹ lati wà nibẹ ni owurọ ọjọ Sunday lati gbọ apinsọ ọrọ asọye alapa mẹta naa “Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Apẹja Eniyan.” Eyi yoo jiroro apejuwe Jesu nipa àwọ̀n ati ẹja ti yoo si ṣagbeyẹwo ipa ti awa le ni ninu imuṣẹ rẹ̀. Itolẹsẹẹsẹ owurọ yoo pari pẹlu awọn ijiroro pataki naa “Wíwà Lójúfò Ni ‘Akoko Opin’” ati “Ta ni Yoo Yèbọ́ Ni ‘Akoko Idaamu?’” Lẹhin naa ní ọsan, iwọ ki yoo fẹ lati padanu ọrọ asọye fun gbogbo eniyan, “Kíkókìkí Aye Titun Olominira Ti Ọlọrun.” Ṣaaju ọrọ asọye ipari arumọlara soke kan, ni ijiroro ọrọ-ẹkọ ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́nà ti ọsẹ naa yoo wà. Mu ẹda iwe irohin tirẹ ti a o kẹkọọ ni ọsẹ yẹn wá.
Laaarin oṣu November, December, ati January, eyi ti ó tó 67 awọn apejọpọ ni a wewee yika gbogbo Nigeria nikan. Nitori naa ọkan yoo wa ti ki yoo jinna si ile rẹ. Wadii wo lọdọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni adugbo fun akoko ati ibi ti o sunmọ ọ julọ.