ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 152-153
  • Ohun Tó Dára Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Dára Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone Di Àrímáleèlọ fún Mi
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • O Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Èé Ṣe Tí Dáyámọ́ńdì Fi Gbówó Lórí Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 152-153

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

Ohun Tó Dára Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ

Tamba Josiah

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1948

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1972

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa òkúta dáyámọ́ǹdì kó tó wá sínú òtítọ́. Ní báyìí, ó ti di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Orílẹ̀-èdè Sierra Leone.

LỌ́DÚN 1970, mo ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìwakùsà kan tó jẹ́ ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní àgbègbè Tongo Fields níbi tí òkúta dáyámọ́ǹdì pọ̀ sí gan-an ní àríwá ìlú Kenema. Mo sì máa ń fúnra mi wá òkúta dáyámọ́ǹdì nígbà tí mo bá ráyè. Tí mo bá ti ṣa àwọn òkúta tèmi jọ, màá múra dáadáa, màá gba ìlú Kenema lọ láti lọ tà á, màá sì gbádùn ara mi.

Ní ọdún 1972, mo bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, mo kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi. Torí pé mo ti lo ìgbà ìsinmi tí wọ́n yọ̀ǹda fún mi níbi iṣẹ́ tán, mo bẹ ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ pé kó bá mi ṣiṣẹ́ mi nígbà àpéjọ àgbègbè wa, kí n lè ráyè lọ sí àpéjọ náà, kí n sì ṣèrìbọmi. Ó gbà láti bá mi ṣe é, àmọ́ ó ní màá yọ owó ọ̀sẹ̀ kan fún òun nínú owó oṣù mi. Ìrìbọmi tí mo fẹ́ ṣe jẹ mí lógún ju owó lọ, torí náà kíá ni mo fara mọ́ ohun tó sọ. Nígbà tí mo pa dà dé láti àpéjọ náà, ó ní kí n fọwọ́ mú owó mi, pé ohun tó tọ́ ni mo ṣe bí mo ṣe lọ sin Ọlọ́run. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, mo fi iṣẹ́ olówó ńlá tí mò ń ṣe sílẹ̀, mo sì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kí n lè máa to ìṣúra jọ pa mọ́ sí ọ̀run.—Mát. 6:19, 20.

Ọdún méjìdínlógún [18] ni mo fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti alábòójútó àyíká káàkiri orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Àkókò náà ni mo fẹ́ Christiana. Olóòótọ́ àti alátìlẹyìn gidi ni. Jèhófà fi ọmọbìnrin kan jíǹkí wa. Lynette ni orúkọ rẹ̀.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, bí màá ṣe rí òkúta dáyámọ́ǹdì ni mo máa ń rò ṣáá. Àmọ́ mo ti wá rí ohun tó dára ju dáyámọ́ǹdì lọ, ìyẹn àwọn ìṣúra tẹ̀mí

Nígbà ogun abẹ́lé ní Sierra Leone, èmi àti Christiana ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Bo tó wà ní ọ̀kan lára àgbègbè pàtàkì tí wọ́n ti ń wa dáyámọ́ǹdì. A sì rí ọ̀pọ̀ àwọn tá a lè pè ní dáyámọ́ǹdì tẹ̀mí níbẹ̀, ìyẹn àwọn tó di ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Láàárín ọdún mẹ́rin, akéde ìjọ wa fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po méjì. Ìjọ mẹ́ta tó ń gbèrú dáadáa ló sì ti wà ní ìlú Bo báyìí.

Lọ́dún 2002, ètò Ọlọ́run fi mí ṣe ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Bẹ́tẹ́lì Sierra Leone. Ìtòsí Bẹ́tẹ́lì ni èmi àti Christiana ń gbé. Ńṣe ni mo ń ti ilé lọ sí Bẹ́tẹ́lì lọ ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́, Christiana sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Lynette ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń túmọ̀ èdè Krio ní Bẹ́tẹ́lì.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, bí màá ṣe rí òkúta dáyámọ́ǹdì ni mo máa ń rò ṣáá. Àmọ́ mo ti wá rí ohun tó dára ju dáyámọ́ǹdì lọ, ìyẹn àwọn ìṣúra tẹ̀mí. Mo tún rí àwọn dáyámọ́ǹdì tẹ̀mí méjìdínlógún [18] wà jáde, ìyẹn àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ní tòótọ́, Jèhófà ti bù kún mi lọ́pọ̀lọpọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́