SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone Di Àrímáleèlọ fún Mi
Cindy McIntire
WỌ́N BÍ I NÍ 1960
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1974
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó jẹ́ míṣọ́nnárì láti ọdún 1992. Ó ti sìn ní orílẹ̀-èdè Guinea àti Senegal, ó sì ń sìn ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone báyìí.
KÒ JU ọ̀sẹ̀ méjì péré tí mo dé orílẹ̀-èdè Sierra Leone tó fi di ibi àrímáleèlọ fún mi. Ẹnu yà mí báwọn èèyàn ṣe máa ń pàǹtèté ẹrù tó wúwo sórí. Èrò pọ̀ gan-an láàárín ìgboro. Àwọn ọmọdé ń ṣeré kiri, wọ́n ń jó fàlàlà láàárín ìgboro, wọ́n ń pàtẹ́wọ́, wọ́n sì ń fẹsẹ̀ janlẹ̀ pa pọ̀ lọ́nà tó dùn mọ́ni. Oríṣiríṣi nǹkan ẹlẹ́wà àtàwọn tó ń lọ tó ń bọ̀ ni mò ń rí, mo sì ń gbọ́ àwọn orin aládùn.
Àmọ́ ohun tí mo gbádùn jù níbí ni iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe. Àwọn ará ilẹ̀ Sierra Leone kà á sí ohun iyì láti gba èèyàn lálejò tọwọ́ tẹsẹ̀. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì gan-an, wọ́n sì máa ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n máa ń sọ pé kí n wọlé jókòó. Tí mo bá ń lọ, àwọn míì á tún sìn mí síwájú dáadáa kí wọ́n tó pa dà. Àwọn ìwà tó wuni yìí kò jẹ́ kí ìnira pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bí àìsí omi àti iná mànàmáná tó ń ṣe ségesège ni mí lára púpọ̀ jù.
Torí pé mi ò lọ́kọ, nígbà míì àwọn èèyàn máa ń bi mí bóyá ó tiẹ̀ máa ń ṣe mí bíi pé mo dá nìkan wà. Ká sòótọ́, ọwọ́ mi dí débi pé mi ò tiẹ̀ ráyè láti máa ronú pé mo dá wà àbí mi ò dá wà. Mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan alárinrin tí mo ń fayé mi ṣe.