Ìtàn Ìgbésí Ayé
Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Mi
Gẹ́gẹ́ bí Lynette Peters ṣe sọ ọ́
Àwọn ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà wá kó wa kúrò nibi tá à ń gbé. Ọmọ ogun kan tí ìbọn rẹ̀ kì í tàsé dúró sẹpẹ́ lórí ilé tá à ń gbé. Àwọn ọmọ ogun ojú omi yòókù sì dọ̀bálẹ̀ sórí koríko pẹ̀lú ìbọn wọn lọ́wọ́. Bí èmi àtàwọn míṣọ́nnárì yòókù ti ń sáré lọ sídìí hẹlikọ́pítà, ìyẹn ọkọ̀ òfuurufú tó ń dúró dè wá láàárọ̀ ọjọ́ Sunday yẹn, a ṣọkàn gírí, a ò gbọ̀n jìnnìjìnnì. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, a ti wà lójú òfuurufú. Nígbà tó sì fi máa tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá lẹ́yìn náà, a ti wà nínú ọkọ̀ ojú omi àwọn ológun tó wà létíkun, ọkàn wa sì balẹ̀.
LÁÀÁRỌ̀ ọjọ́ kejì, a gbọ́ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti lọ ju bọ́ǹbù sí hòtẹ́ẹ̀lì tá a sá sí lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí wọ́n wá kó wa yẹn. Wàhálà tó ti ń ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Sierra Leone fún ọ̀pọ̀ ọdún ti wá di ogun ńlá. Gbogbo àwa àjèjì, títí kan àwa míṣọ́nnárì, ló di dandan ká sá kúrò lórílẹ̀-èdè náà láìròtẹ́lẹ̀. Kí n lè ṣàlàyé ohun tó fà á tí mo fi bá ara mi nírú ipò yìí, ẹ jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀.
Orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pè ní British Guiana, tó wá di Guyana láti ọdún 1966 ni mo dàgbà sí. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé ní àwọn ọdún 1950, mi ò níṣòro kankan, mo sì láyọ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òbí ló ka ẹ̀kọ́ ìwé sóhun tó ṣeyebíye, wọ́n sì retí pé káwọn ọ̀dọ́ máa ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ wọn. Mo rántí pé nígbà kan, akọ̀wé báńkì kan béèrè lọ́wọ́ bàbá mi pé, “Kí ló dé tó o fi ń san owó tó pọ̀ tó báyìí lórí ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ?” Èsì tí Bàbá mi fún un ni pé, “Ẹ̀kọ́ tó péye nìkan ló lè jẹ́ káyé wọn dára.” Lákòókò yẹn, ó rò pé àwọn iléèwé tó gbayì lèèyàn ti lè rí ẹ̀kọ́ tó dára gan-an gbà. Àmọ́ kò pẹ́ tó fi rí i pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òun àti aládùúgbò wa kan ti jọ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ohun tí wọ́n sì gbọ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn mú un dá àwọn méjèèjì lójú pé wọ́n ti rí òtítọ́. Lẹ́yìn ìgbà náà, màmá mi sọ ohun tí wọ́n jíròrò nípàdé yẹn fún aládùúgbò wa mìíràn. Kò pẹ́ táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Daphne Harry (tó wá di Baird nígbà tó yá) àti Rose Cuffie. Kó tó pé ọdún kan, màmá mi àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjèèjì ṣèrìbọmi. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, bàbá mi fi Ṣọ́ọ̀ṣì Seventh-Day Adventist sílẹ̀, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ṣèrìbọmi.
Nígbà témi àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjì tá a dàgbà jù nínú àwa ọmọ mẹ́wàá wà ní kékeré, a máa ń pẹ́ nílé àwọn míṣọ́nnárì níbi tí Daphne àti Rose ń gbé, inú wa sì máa ń dùn gan-an. Láwọn àkókò yẹn, wọ́n máa ń sọ àwọn ohun tí wọ́n gbádùn lóde ẹ̀rí fún wa. Àwọn míṣọ́nnárì yìí máa ń láyọ̀ nítorí pé ìgbà gbogbo ni wọ́n ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ wọn ló jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti di míṣọ́nnárì.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wà láàárín àwọn ẹbí àtàwọn ojúgbà nílé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ka ìwé rẹpẹtẹ àti kéèyàn ríṣẹ́ àtàtà ṣe sóhun pàtàkì, síbẹ̀ kí ló ràn mí lọ́wọ́ tí mi ò fi mọ́kàn kúrò lórí iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún? Ọ̀pọ̀ àǹfààní tó fani mọ́ra gan-an ló ṣí sílẹ̀. Mo lè lọ kọ́ nípa iṣẹ́ amòfin, orin kíkọ, ìmọ̀ ìṣègùn tàbí ohunkóhun tó bá wù mí. Àmọ́ àpẹẹrẹ rere táwọn òbí mi fi lélẹ̀ ló fún mi ní ìtọ́sọ́nà tí mo nílò. Wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì sílò, wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà.a Ìyẹn nìkan kọ́, gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún wá sílé wa. Ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọ̀nyí ní jẹ́ kó túbọ̀ wù mí gan-an láti fi ìgbésí ayé mi ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi. Bí mo sì ti ń ṣe tán nílé ẹ̀kọ́ gíga ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Philomena tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn lẹni àkọ́kọ́ tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó sì ṣèyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Ayọ̀ tí mo ní bí mo ti ń rí i tó dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jẹ́ kó túbọ̀ wù mí gan-an láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún lọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n sọ pé wọ́n fẹ́ gbé mi sípò gíga níbi iṣẹ́ ìjọba tí mo ti ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé. Mo sọ pé mi ò fẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ mo yàn láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ.
Mo ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí mi lákòókò yẹn, àwọn míṣọ́nnárì ò sì yéé wá sílé wa. Mo máa ń gbádùn àwọn ìrírí tí wọ́n máa ń sọ gan-an! Gbogbo èyí sì jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mí gan-an láti di míṣọ́nnárì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní yẹn dà bí èyí tí ọwọ́ mi kò lè tẹ̀. Àwọn míṣọ́nnárì máa ń wá sìn lórílẹ̀-èdè Guyana nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣì ń wá títí dòní. Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1969, ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo gba lẹ́tà pé kí n wá sílé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead nílùú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York.
Iṣẹ́ Ìsìn Tí Mi Ò Retí
Àwa akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] la wà ní kíláàsì kejìdínláàádọ́ta [48] ti ilé-ẹ̀kọ́ Gílíádì, a sì wá láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlélógún. Àwa mẹ́tàdínlógún la jẹ́ arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ti lé lọ́dún mẹ́tàdínlógójì báyìí, gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín oṣù márùn-ún yẹn ni mo ṣì rántí dáadáa. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ní láti kọ́, kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nìkan, àmọ́ títí kan àwọn àbá àti ìmọ̀ràn tó lè ran àwa tá a fẹ́ lọ di míṣọ́nnárì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ó dára láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà, pé kò dára láti máa bẹ́ mọ́ àwọn àṣà aṣọ tó lòde, mo sì tún kẹ́kọ̀ọ́ pé kí n má ṣe juwọ́ sílẹ̀ bí ipò nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn.
Àwọn òbí mi ti jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa lọ sípàdé déédéé. Ẹnikẹ́ni nínú wa tó bá díbọ́n pé ara òun ò yá débi tí kò fi lè lọ sípàdé lọ́jọ́ Sunday kò lè ṣàdédé sọ pé ara òun ti yá pé òun fẹ́ lọ síbi tí wọ́n ti ń tẹ dùrù tàbí agbo eré mìíràn, lálẹ́ ọjọ́ kejì. Àmọ́ láàárín àkókò kan nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, mi ò lọ sáwọn ìpàdé kan. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday kan, mo gbìyànjú láti wí àwíjàre nípa ìdí tí mi ò fi lọ sípàdé fún arákùnrin àti arábìnrin Don àti Dolores Adams, ìyẹn tọkọtaya tí wọ́n ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n sì máa ń gbé mi lọ sípàdé. Mo sọ pé iṣẹ́ àṣetiléwá àtàwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tí mo ní láti kọ ti pọ̀ jù! Báwo ni mo ṣe fẹ ráyè lọ sí Ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn? Lẹ́yìn tí Arákùnrin Adams ti bá mi sọ̀rọ̀ fúngbà díẹ̀, ó wá sọ pé: “Nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn rẹ bá sọ fún ẹ ni kó o ṣe.” Mo ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn rẹ̀, mi ò sì pa ìpàdé jẹ lọ́jọ́ yẹn àtàwọn ọjọ́ mìíràn lẹ́yìn ìgbà yẹn. Látìgbà náà títí di ìsinsìnyí, mi ò jẹ́ kí ohunkóhun dí mi lọ́wọ́ àtilọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, àyàfi àwọn ohun tí mi ò bá lè ṣe nǹkan kan sí.
Nígbà tá a ti lo nǹkan bí ìdajì nínú àkókò ilé ẹ̀kọ́ wa, àwa akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bára wa sọ̀rọ̀ nípa ibi tó ṣeé ṣe kí wọ́n yàn wá sí. Mo ti ń rò ó lọ́kàn pé orílẹ̀-èdè Guyana ni wọ́n máa dá mi padà sí, nítorí pé a nílò ìrànwọ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo gbọ́ pé mi ò ní padà síbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orílẹ̀-èdè Sierra Leone, tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, ni wọ́n yàn mí sí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ ohun tó wù mí, ìyẹn ni láti lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ́nà jíjìn!
Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Mo Ní Láti Kọ́
“Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́wà” ni gbólóhùn tí mo lè lò láti ṣàpèjúwe bí ilẹ̀ Sierra Leone ṣe rí lójú mi nígbà tí mo kọ́kọ́ débẹ̀. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òkè kéékèèké àtàwọn òkè ńlá, àwọn omi tó ya wá sórí ilẹ̀ látinú òkun, àtàwọn etíkun. Síbẹ̀ ohun tó jẹ́ ojúlówó ẹwà orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà yìí ni àwọn èèyàn ibẹ̀, tí ìfẹ́ wọn àti inú rere wọn máa ń mú kára tuni, kódà ó ń mú kára tu àjèjì pàápàá. Ìwà rere wọn yìí máa ń ran àwọn míṣọ́nnárì lọ́wọ́ gan-an, kì í jẹ́ kí wọ́n ṣàárò ilé. Àwọn ará Sierra Leone máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn, pàápàá jù lọ, wọ́n máa ń fẹ́ láti ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síbẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ èdè Krio sọ, ìyẹn èdè tí gbogbo wọ́n máa ń sọ lórílẹ̀-èdè náà.
Àwọn tó ń sọ èdè Krio ní ọ̀pọ̀ òwe tó ń jẹ́ kí nǹkan tètè yéni. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀bọ ń ṣiṣẹ́, ìnàkí ń jẹ ẹ́, èyí tó túmọ̀ sí pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló jẹ́ pé ẹni tó gbin nǹkan ló máa ń kórè rẹ̀. Ẹ ò rí i pé òwe yìí bá ìwà ìrẹ́jẹ tó gbáyé kan lónìí mu gan-an!—Aísáyà 65:22.
Iṣẹ́ wíwàásù àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ń fún mi láyọ̀ gan-an. Ó ṣọ̀wọ́n kéèyàn tó rí ẹnì kan tí kò ní fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn míṣọ́nnárì àtàwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ọmọdé wà lára àwọn èèyàn náà àgbà sì wà lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni ipò wọn nígbèésí ayé yàtọ̀ síra, wọ́n sì wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Arábìnrin Erla St. Hill jẹ́ akíkanjú èèyàn, míṣọ́nnárì ni, èmi pẹ̀lú rẹ̀ la sì kọ́kọ́ jọ ṣiṣẹ́ pọ̀. Bó ṣe mú iṣẹ́ ìwàásù lọ́kùnkúndùn náà nì kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ ilé táwa míṣọ́nnárì máa ń ṣe. Ó jẹ́ kí n mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì. Àwọn bíi dídi ojúlùmọ̀ àwọn tó ń gbé ládùúgbò wa, lílọ kí àwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn olùfìfẹ́hàn tára wọn kò yá, àti lílọ síbi ìsìnkú tó bá ṣeé ṣe. Ó tún jẹ́ kí n mọ̀ pé ká tó kúrò ní ìpínlẹ̀ tá a bá ti wàásù, ó ṣe pàtàkì ká máa yà kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ń gbé ládùúgbò náà, bí kò tiẹ̀ ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ. Ṣíṣe àwọn ohun tó sọ yìí jẹ́ kí n yára ní ọ̀pọ̀ màmá, arákùnrin, arábìnrin, àti ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́, orílẹ̀-èdè tí mo ti ń sìn yìí sì wá di ilé mi.—Máàkù 10:29, 30.
Èmi àtàwọn míṣọ́nnárì àtàtà tá a jọ sìn pa pọ̀ tún di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Àwọn bí arábìnrin Adna Byrd tó sìn nílẹ̀ Sierra Leone láàárín ọdún 1978 sí 1981 tá a sì jọ gbé yàrá, àti Cheryl Ferguson, tá a ti jọ ń gbé yàrá láti ọdún mẹ́rìnlélógún sẹ́yìn.
Ogun Abẹ́lé Fa Àdánwò
Lọ́dún 1997, ní nǹkan bí oṣù kan péré lẹ́yìn ìyàsímímọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tuntun nílẹ̀ Sierra Leone, a ní láti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ tipátipá nítorí ogun, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀. Lọ́dún mẹ́fà ṣáájú ìgbà yẹn, ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó sá wá sórílẹ̀-èdè Sierra Leone láti ilẹ̀ Làìbéríà nítorí ogun tó ń jà níbẹ̀ wú wa lórí gan-an. Àwọn kan ò ní gá, wọn ò ní go, nígbà tí wọ́n dé. Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe wà nínú ìṣòrò ńlá yẹn, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń lọ sóde ìwàásù. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn máa ń wú wa lórí gan-an.
Ní báyìí táwa náà wá dẹni tógun lé wá sórílẹ̀-èdè Guinea, a tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin wa láti ilẹ̀ Làìbéríà, a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bẹ́ẹ̀ la sì ń fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Ọdún kan lẹ́yìn ìgbà náà, a padà sórílẹ̀-èdè Sierra Leone, àmọ́ láàárín oṣù méje tá a padà débẹ̀, ìjà tún bẹ̀rẹ̀, a sì tún ní láti padà sórílẹ̀-èdè Guinea.
Kò pẹ́ la gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń bá ẹgbẹ́ mìíràn jà ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nílé àwa míṣọ́nnárì tó wà lágbègbè Kissy, àti pé gbogbo ẹrù wa ni wọ́n ti jí kó tí wọ́n sì ba àwọn mìíràn jẹ́. A ò jẹ́ kí èyí kó ìbànújẹ́ bá wa rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe là ń dúpẹ́ pé ẹ̀mí wa ṣì wà. Ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ la ní, àmọ́ à ń fara da ipò náà.
Lẹ́yìn tí wọ́n kó wa kúrò lẹ́ẹ̀kejì, èmi àti Cheryl tá a jọ ń gbé kúkú fìdí kalẹ̀ sórílẹ̀-èdè Guinea. Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti kọ́ èdè Faransé. Àwọn kan lára àwọn tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì ń yára fi ìwọ̀nba tí wọ́n gbọ́ nínú èdè náà wàásù, wọn ò si jẹ́ káwọn àṣìṣe wọn kó ìdààmú bá wọn. Àmọ́ èmi kórìíra kí n máa sọ̀rọ̀ kí n sì máa ṣàṣìṣe, nípa bẹ́ẹ̀, tó bá di dandan nìkan ni mo máa ń sọ èdè Faransé. Èyí máa ń dùn mí gan-an. Mo ní láti máa rán ara mi létí lójoojúmọ́ pé kí n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà ni mo ṣe wá sórílẹ̀-èdè Guinea.
Díẹ̀díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọ èdè náà sọ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti nípa títẹ́tí sáwọn tó ń sọ èdè náà dáadáa. Mo tún bẹ àwọn ọmọdé nínú ìjọ láti máa kọ́ mi, nítorí pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn ni wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́. Nígbà tó wá yá, láìròtẹ́lẹ̀, ètò Jèhófà pèsè àwọn ohun tó lè ràn mí lọ́wọ́. Láti oṣù September ọdún 2001 ni Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti ń ní àwọn àbá tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn lọni láfikún sáwọn ohun tá a lè sọ nígbà tá a bá ń fi àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ lọ àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹ̀rù kì í fi bẹ́ẹ̀ bà mí mọ́ báyìí tí mo bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè náà kò yọ̀ mọ́ mi lẹ́nu bí ìgbà tí mo bá ń sọ èdè ìlú mi.
Nítorí pé inú ìdílé tó tóbi ni mo ti wá, èyí ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti lè bá ọ̀pọ̀ èèyàn gbé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé àwa mẹ́tàdínlógún la jọ ń gbé. Láti ọdún mẹ́tàdínlógójì tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì bọ̀, àwọn míṣọ́nnárì tí mo ti bá gbé ti lé lọ́gọ́rùn-ún. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi láti mọ àwọn èèyàn tó pọ̀ tó báyìí, tí ìwà gbogbo wọn yàtọ̀ síra àmọ́ tó jẹ́ pé iṣẹ́ Ọlọ́run ni gbogbo wọn ń ṣe! Mò ń láyọ̀ gan-an pé mò ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ mo sì ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì!—1 Kọ́ríńtì 3:9.
Látìgbà tí mo ti di míṣọ́nnárì, ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì táwọn ìdílé mi ń ṣe ni kò ṣeé ṣe fún mi láti wà níbẹ̀, irú bí ìgbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn àbúrò mi ń ṣègbéyàwó. Mi ò sì lè rí àwọn ọmọ àwọn àbúrò mi tó bí mo ṣe fẹ́. Àǹfààní ńlá tí èmi àti ìdílé mi yááfì lèyí jẹ́, àwọ́n èèyàn mi sì máa ń fún mi níṣìírí pé kí n máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì nìṣó.
Síbẹ̀, ibi tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nárì ni mo ti wá ń gbádùn àwọn ohun tí mi ò ráyè gbádùn lórílẹ̀-èdè mi yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pinnu pé mi ò ní lọ́kọ, síbẹ̀ mo ní ọ̀pọ̀ ọmọ nípa tẹ̀mí. Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan, àwọn tá a ti jọ dọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tún wà lára wọn. Ìyẹn nìkan kọ́, mo ti rí i táwọn ọmọ wọn dàgbà, tí wọ́n ṣègbéyàwó, táwọn náà sì ń tọ́ àwọn ọmọ tiwọn náà ní ọ̀nà òtítọ́. Bíi tèmi, iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn làwọn kan lára wọn yàn láti fi ìgbésí ayé tiwọn náà ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí màmá mi fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, nígbà tí bàbá mi sì fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ó di aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Orílẹ̀-èdè Sierra Leone tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, ni wọ́n yàn mí sí
GUINEA
SIERRA LEONE
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn àbúrò mi obìnrin méjì témi pẹ̀lú wọn jọ máa ń pẹ́ nílé àwọn míṣọ́nnárì láwọn ọdún 1950 tínú wa sì máa ń dùn gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Èmi àtàwọn tá a jọ wà ní kíláàsì Kejìdínláàádọ́ta ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìgbà tá a ṣe ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Sierra Leone