Ìgbàgbọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Gbani Là
BÍ JÉSÙ ti ń jáde nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù nígbà tó wá síbẹ̀ kẹ́yìn, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé wọ̀nyí mà kàmàmà o!” Àwọn Júù máa ń fi tẹ́ńpìlì yìí yangàn wọ́n sì kà á sóhun tó ṣeyebíye sí wọn jù lọ. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ṣé ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Lọ́nàkọnà, a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yóò wó palẹ̀.”—Máàkù 13:1, 2.
Ọ̀rọ̀ yìí ṣòroó gbà gbọ́! Àwọn kan lára àwọn òkúta tí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà tóbi gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí Jésù sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ńpìlì náà túmọ̀ sí pé ìlú Jerúsálẹ́mù fúnra rẹ̀ yóò pa run, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó má sóhun tó ń jẹ́ orílẹ̀-èdè àwọn Júù mọ́, tẹ́ńpìlì yẹn sì ni ojúkò gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn. Èyí ló mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún béèrè pé: “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá sí ìparí?”—Máàkù 13:3, 4.
Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé “òpin kì í ṣe ìsinsìnyí.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyí á kọ́kọ́ gbọ́ nípa ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri. Lẹ́yìn èyí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanilẹ́rù yóò wá fa ìparun yán-ányán-án bá orílẹ̀-èdè àwọn Júù. Ká sòótọ́, “ìpọ́njú ńlá” ni yóò jẹ́. Àmọ́ Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn náà, kó lè gba “àwọn àyànfẹ́” là, ìyẹn àwọn Kristẹni tòótọ́. Lọ́nà wo?—Máàkù 13:7; Mátíù 24:7, 21, 22; Lúùkù 21:10, 11.
Àwọn Júù Ṣọ̀tẹ̀ sí Ìjọba Róòmù
Ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n kọjá, síbẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣì ń dúró de ìgbà tí òpin máa dé. Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn kò jẹ́ kí àlàáfíà wà láwọn àgbègbè tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso lé lórí. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 9.) Ogun abẹ́lé àti ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ń lọ nílẹ̀ Jùdíà. Síbẹ̀, àlááfíà díẹ̀ ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ ìlú olódi. Àwọn èèyàn ń jẹun, wọ́n ń ṣiṣẹ́, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń bímọ, bí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ tẹ́lẹ̀. Tẹ́ńpìlì gìrìwò tó wà níbẹ̀ sì ń fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀ pé mìmì kan ò lè mi ìlú náà.
Ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni, àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó yìn wọ́n fún ìfaradà wọn, àmọ́ inú rẹ̀ kò dùn bó ṣe dà bíi pé àwọn kan nínú ìjọ kò gbé ìgbésí ayé bíi pé ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé. Àwọn kan ti ń sú lọ kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́, àwọn kan ò sì jẹ́ Kristẹni tó lóye. (Hébérù 2:1; 5:11, 12) Pọ́ọ̀lù wá rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ má ṣe gbé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yín sọnù . . . Nítorí ní ‘ìgbà díẹ̀ kíún’ sí i, àti pé ‘ẹni tí ń bọ̀ yóò dé, kì yóò sì pẹ́.’ ‘Ṣùgbọ́n olódodo mi yóò yè nítorí ìgbàgbọ́,’ àti pé, ‘bí ó bá fà sẹ́yìn, ọkàn mi kò ní ìdùnnú nínú rẹ̀.’” (Hébérù 10:35-38) Ìmọ̀ràn yìí bọ́ sákòókò gan-an! Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn Kristẹni yóò ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́, pé wọ́n sì wà lójúfò tí wọ́n bá rí i tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ń nímùúṣẹ? Ṣé òótọ́ ni ìparun Jerúsálẹ́mù sún mọ́lé?
Láàárín ọdún márùn-ún tó tẹ̀ lé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí, ipò nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í burú ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó di ọdún 66 Sànmánì Kristẹni, Gómìnà ọmọ ilẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Florus tó jẹ́ oníjẹkújẹ fipá gba tálẹ́ńtì mẹ́tàdínlógún nínú àpótí ọrẹ mímọ́ tó wà ní tẹ́ńpìlì. Owó yìí jẹ́ gbèsè “owó orí” táwọn Júù jẹ ìjọba Róòmù. Èyí bí àwọn Júù nínú gan-an, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ nìyẹn. Àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ rọ́ wá sí Jerúsálẹ́mù wọ́n sì pa àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wà níbẹ̀ nípakúpa. Wọ́n wá kéde láìbẹ̀rù pé ilẹ̀ Jùdíà kò sí lábẹ́ ìjọba Róòmù mọ́. Bí ogún ṣe bẹ̀rẹ̀ láàárín ilẹ̀ Jùdíà àti Róòmù nìyẹn!
Láàárín oṣù mẹ́ta péré, Cestius Gallus, Gómìnà ilẹ̀ Róòmù tó ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ Síríà, kó àwọn ọmọ ogun tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] gba ọ̀nà gúúsù láti lọ paná ọ̀tẹ̀ àwọn Júù. Àkókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà làwọn ọmọ ogun rẹ̀ dé àgbègbè Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ya wọ àwọn ìgbèríko rẹ̀ kíákíá. Àwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀, tí wọn ò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ogun náà, sá lọ sínú tẹ́ńpìlì tí odi yí ká. Kò pẹ́ táwọn ọmọ ogun Róòmù fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ ògiri tẹ́ńpìlì náà nídìí. Ẹ̀rù ba àwọn Júù. Èèmọ̀, àwọn sójà tó jẹ́ abọ̀rìṣà ń sọ ibi táwọn ẹlẹ́sìn Júù kà sí ibi mímọ́ jù lọ di aláìmọ́! Àmọ́ o, àwọn Kristẹni tó wà nílùú yẹn rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: ‘Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.’ (Mátíù 24:15, 16) Ǹjẹ́ wọ́n á gba àsọtẹ́lẹ̀ Jésù gbọ́ kí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́? Bí nǹkan ṣe wá yọrí sí, èyí gba ẹ̀mí wọn là. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe rọ́nà sá lọ?
Lójijì, láìsí ìdí kan gúnmọ́, gómìnà Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò wọ́n sì forí lé ọ̀nà etíkun. Báwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀ ṣe gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn nìyẹn. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ìpọ́njú tó bá ìlú yẹn wá sópin lọ́gán báyẹn! Àwọn Kristẹni náà fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, wọ́n sá jáde ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sílùú Pẹ́là tó wà lórí àwọn òkè lódìkejì Odò Jọ́dánì, níbi tí kò sí wàhálà kankan. Àkókò tó dára jù ni wọ́n sá lọ yẹn. Kò pẹ́ táwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀ yẹn fi padà sí Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì ń fipá mú àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà láti dara pọ̀ mọ́ wọn.a Àmọ́ àwọn Kristẹni ti wà ní Pẹ́là ní tiwọn, wọ́n sì ti bọ́ lọ́wọ́ ewu, wọ́n wá ń retí àwọn nǹkan tó máa tún ṣẹlẹ̀.
Gbogbo Nǹkan Dojú Rú
Láàárín oṣù díẹ̀, àwọn ọmọ ogun Róòmù mìíràn ti ń múra láti gbógun lọ sí Jerúsálẹ́mù. Lọ́dún 67 Sànmánì Kristẹni, Ọ̀gágun Fẹsipásíà àtọmọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Títù kó ọ̀pọ̀ ọmọ ogun jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] làwọn ọmọ ogun náà. Odindi ọdún méjì làwọn ológun tó jẹ́ àkòtagìrì yìí fi wà lọ́nà Jerúsálẹ́mù, gbogbo ohun tó sì lè dí wọn lọ́wọ́ ni wọ́n ń mú kúrò. Nínú Jerúsálẹ́mù lọ́hùn-un, àwọn ólóṣèlù tó yapa síra wọn ń bára wọn jà gan-an. Wọ́n ba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n kó pa mọ́ nítorí ebi jẹ́, wọ́n sì wó gbogbo ilé tó wà láyìíká tẹ́ńpìlì náà lulẹ̀, ó sì lé ní ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn Júù tó kú. Fẹsipásíà kò tètè gbógun wọ Jerúsálẹ́mù. Ó sọ pé: ‘Ọlọ́run mi ń ṣe ọ̀gágun fún ilẹ̀ Róòmù lọ́nà témi alára ò lè gbà ṣe é; àwọn ọ̀tá wa ń fọwọ́ ara wọn para wọn.’
Nígbà tí Nérò, Olú Ọba Róòmù, kú, Fẹsipásíà lọ sí Róòmù láti lọ gbapò rẹ̀, ó sì fi Títù sílẹ̀ láti parí ogun náà. Àkókò àjọ̀dún Ìrékọjá ọdún 70 Sànmánì Kristẹni ti sún mọ́lé nígbà tí Títù dé sí Jerúsálẹ́mù, bó ṣe sé gbogbo àwọn tó ń gbébẹ̀ mọ́ nìyẹn àtàwọn tó rìnrìn àjò wá síbẹ̀ nítorí àjọ̀dún náà. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gé àwọn igi tó wà láwọn ìgbèríko Jùdíà, wọ́n gbẹ́ ẹnu wọn ṣóńṣó, wọ́n sì fi wọ́n ṣe odi tó tó kìlómítà méje yí olú ìlú náà ká. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́ẹ́ ló rí, ó ní: “Àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo.”—Lúùkù 19:43.
Kò pẹ́ tí ìyàn fi gba ìlú náà kan. Àwọn èèyànkéèyàn tó kó ohun ìjà dání bẹ̀rẹ̀ sí í já wọlé àwọn tó ti kú àtàwọn tó ń kú lọ, wọ́n sì ń kó ohunkóhun tí wọ́n bá rí. Ó kéré tán, obìnrin kan tí kò mọ ohun tó lè ṣe mọ́ pa ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ìkókó, ó sì jẹ̀ ẹ́. Ó tipa báyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ìwọ yóò ní láti jẹ àwọn èso ikùn rẹ, ẹran ara àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ . . . nítorí ìlepinpin àti másùnmáwo tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi há ọ mọ́.”—Diutarónómì 28:53-57.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti há Jerúsálẹ́mù mọ́ fún oṣù márùn-ún, wọ́n ṣẹ́gun ìlú náà. Gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ àti nínú tẹ́ńpìlì tó jẹ́ àrímáleèlọ yẹn ni wọ́n kó lọ, wọ́n dáná sun ún, wọ́n sì yọ gbogbo òkúta tí wọ́n fi ṣe odi rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. (Dáníẹ́lì 9:26) Àwọn tó kú tó mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ márùn-ún [1,100,000], àwọn tí wọ́n sì tà lẹ́rú jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97,000].b (Diutarónómì 28:68) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣẹ́ ku Júù kankan ní gbogbo Jùdíà. Ká sòótọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè náà ni àjálù náà bá, irú rẹ̀ ò sì ṣẹlẹ̀ rí. Ó yí ètò ìṣèlú, ìsìn, àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Júù padà pátápátá.c
Àmọ́ ńṣe làwọn Kristẹni tó wà nílùú Pẹ́là ń fi gbogbo ọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó gba àwọn là. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló gbà wọ́n là!
Ó yẹ ká ronú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo ní ìgbàgbọ́ tó máa gbà mí là lákòókò ìpọ́njú ńlá tó sún mọ́lé? Ǹjẹ́ mo ní ìgbàgbọ́ tó lè pa ọkàn mi mọ́ láàyè?’—Hébérù 10:39; Ìṣípayá 7:14.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Òpìtàn tó jẹ́ Júù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus sọ pé ọjọ́ méje làwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀ náà fi lépa àwọn ará Róòmù yẹn kí wọ́n tó padà sí Jerúsálẹ́mù.
b Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn kan fojú bù, ó lé ní ìdá méje àwọn Júù tó kú láwọn àgbègbè tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso rẹ̀.
c Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì, Alfred Edersheim, tó jẹ́ Júù, sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó ti ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kò tíì sí ìpọ́njú tó tó [èyí] rí, kò sì sí àjálù burúkú mìíràn tó tún lè dà bí èyí mọ́ lọ́jọ́ iwájú.”
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Tó Nímùúṣẹ Lára Àmì Náà ní Ọ̀rúndún Kìíní
OGUN:
Gọ́ọ̀lù (ọdún 39 sí ọdún 40 Sànmánì Kristẹni)
Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà (ọdún 41 Sànmánì Kristẹni)
Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (ọdún 43 àti ọdún 60 Sànmánì Kristẹni)
Àméníà (ọdún 58 sí 62 Sànmánì Kristẹni)
Ogun abẹ́lé àti ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà nílẹ̀ Jùdíà (ọdún 50 sí ọdún 66 Sànmánì Kristẹni)
ÀWỌN ÌSẸ̀LẸ̀:
Róòmù (ọdún 54 Sànmánì Kristẹni)
Pompeii (ọdún 62 Sànmánì Kristẹni)
Éṣíà Kékeré (ọdún 53 àti ọdún 62 Sànmánì Kristẹni)
Kírétè (ọdún 62 Sànmánì Kristẹni)
ÌYÀN:
Róòmù, Gíríìsì, Íjíbítì (nǹkan bí ọdún 42 Sànmánì Kristẹni)
Jùdíà (nǹkan bí ọdún 46 Sànmánì Kristẹni)
ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN:
Bábílónì (ọdún 40 Sànmánì Kristẹni)
Róòmù (ọdún 60 àti 65 Sànmánì Kristẹni)
ÀWỌN WÒLÍÌ ÈKÉ:
Jùdíà (nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni)
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ogun Tí Róòmù Bá Palẹ́sìnì Jà, ọdún 67 sí ọdún 70 Sànmánì Kristẹni
Tólẹ́máísì
Òkun Gálílì
Pẹ́là
PÈRÍÀ
SAMÁRÍÀ
Jerúsálẹ́mù
Òkun Iyọ̀
JÙDÍÀ
Kesaréà
[Credit Line]
Map only: Based on maps copyrighted by Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
‘Àwọn ọ̀tá wa ń fọwọ́ ara wọn pa ara wọn.’—Fẹsipásíà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù pa ìlú Jerúsálẹ́mù run
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]
Relief: Soprintendenza Archeologica di Roma; Vespasian: Bildarchiv Preussischer Kulturbesitz/Art Resource, NY