ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/1 ojú ìwé 4-7
  • Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Gan-an!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Gan-an!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Mutí Lámujù
  • Yẹra Fáwọn Ohun Tó Lè Ṣàkóbá fún Ara
  • “Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”
  • Máa Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kẹ́ Ẹ Sún Mọ́ra Nínú Ìdílé Rẹ
  • Òṣìṣẹ́ Tó Mọṣẹ́ Rẹ̀ Níṣẹ́ àti Ọ̀gá Tó Ń Ṣẹ̀tọ́
  • Orísun Ọgbọ́n Tó Ga Jù Lọ
  • Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìwé Kan Tí Ó Wúlò Fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Ọtí Líle
    Jí!—2013
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/1 ojú ìwé 4-7

Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Gan-an!

Ọ̀PỌ̀ ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ìwé afúnni-nímọ̀ràn tó pọ̀ lóde báyìí ló jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ìṣòro ni wọ́n torí wọn ṣe é. Àmọ́ ti Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ràn inú Bíbélì lè ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́, ohun tó ń ṣe jùyẹn lọ. Ìmọ̀ràn inú rẹ̀ ń jẹ́ kéèyàn yẹra fáwọn àṣìṣe tó lè máyé nira fúnni.

Bíbélì lè “fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà,” ó lè “fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.” (Òwe 1:4) Bó o bá fi ìmọ̀ràn inú Bíbélì sílò, “agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú.” (Òwe 2:11, 12) Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ tó fi hàn pé títẹ̀lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì lè jẹ́ kó o ní ìlera tó dára, ó lè jẹ́ kí ìdílé rẹ túbọ̀ láyọ̀, kó o sì túbọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ tàbí ọ̀gá tó dára sí i.

Má Ṣe Mutí Lámujù

Bíbélì kò ní kéèyàn má mutí, ohun tó sọ ni pé àmujù kò dára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ pé wáìnì lè wo àìsàn nígbà tó fún Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé: “Máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí àpòlúkù rẹ àti ọ̀ràn àìsàn rẹ tí ó ṣe lemọ́lemọ́.” (1 Tímótì 5:23) Àmọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn fi hàn pé kì í ṣe ìtọ́jú àìsàn nìkan ni Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo wáìnì fún. Bíbélì sọ pé wáìnì jẹ́ ohun tó “ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀.” (Sáàmù 104:15) Àmọ́ o, Bíbélì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ di “ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.” (Títù 2:3) Ó ní: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì. Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì.” (Òwe 23:20, 21) Kí ló máa ń yọrí sí táwọn èèyàn ò bá tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn yìí? Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan.

Ìwé ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ń tẹ̀ jáde tó ń jẹ́ Global Status Report on Alcohol ti ọdún 2004 gbé ìròyìn kan jáde, ó ní: “Àwọn ìṣòro tí ọtí mímú ń fà ń ná àwọn ará ilẹ̀ Ireland ní nǹkan bíi bílíọ́nù mẹ́tà dọ́là lọ́dún.” Lára àwọn ibi tí owó tàbùàtabua yìí ń wọlẹ̀ sí nìwọ̀nyí: “owó ìtọ́jú àìsàn (àádọ́ta dín nírínwó [350] mílíọ̀nù dọ́là), iye tó ń bá ìjàǹbá ọkọ̀ ojú pópó lọ nítorí ọtí (okòó dín nírínwó [380] mílíọ̀nù dọ́là), iye tó ń bá ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn ń hù nítorí pé wọ́n mutí yó lọ (ẹ̀rìndínláàádóje [126] mílíọ̀nù dọ́là), iye táwọn iléeṣẹ́ ń pàdánù nígbà táwọn èèyàn kò bá wá síbi iṣẹ́ nítorí ọtí (ọgọ́rùn-ún dín légbèje [1,300] mílíọ̀nù dọ́là).”

Èyí tó wá burú ju gbèsè tí ọtí ìmukúmu ń fà ni àkóbá táwọn tó ń mutí ń ṣe fáwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, láàárín ọdún kan péré lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ó ju ìdajì mílíọ̀nù èèyàn táwọn tó mutí ṣe léṣe. Lórílẹ̀-èdè Faransé, wọ́n ní ọtí ìmukúmu ló ń fa mẹ́ta nínú ìwà ipá mẹ́wàá tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé. Tá a bá wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, ǹjẹ́ o ò gbà pé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fúnni lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu bọ́gbọ́n mu?

Yẹra Fáwọn Ohun Tó Lè Ṣàkóbá fún Ara

Láti ọdún 1942, nígbà táwọn èèyàn ṣì ka sìgá mímu sí ayé jíjẹ, ni ìwé ìròyìn yìí, ìyẹn Ilé Ìṣọ́, ti ń ran àwọn tó ń kà á lọ́wọ́ láti rí i pé mímú sìgá tàbí tábà ta ko ìlànà Bíbélì, èèyàn sì gbọ́dọ̀ yẹra fún un. Àpilẹ̀kọ kan tó jáde láàárín ọdún yẹn ṣàlàyé pé àwọn tó bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ tí Bíbélì pa pé kí wọ́n “wẹ ara [wọn] mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ní báyìí, ìyẹn ọdún márùnlélọ́gọ́ta lẹ́yìn ìgbà náà, ǹjẹ́ kò ti hàn kedere pé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí bọ́gbọ́n mu?

Lọ́dún 2006, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé sìgá mímu “ló wà nípò kejì nínú ohun tó ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn jù lọ lágbàáyé.” Lọ́dọọdún, nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-ún èèyàn ni sìgá mímu ń pa. Tá a bá fi iye àwọn tí sìgá ń pa wé iye àwọn tí àrùn éèdì ń pa, ti sìgá ló pọ̀ jù, torí pé mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn ni àrùn éèdì ń pa lọ́dún. Láàárín ọdún 1900 sí 1999, àwọn tí wọ́n fojú bù pé sìgá mímu pa tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù. Iye yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iye gbogbo àwọn tó kú nínú àwọn ogun tó wáyé láwọn ọdún wọ̀nyẹn. Dájúdájú, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ti gbà báyìí pé sìgá mímu kò dára.

“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”

Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Ẹgbàágbèje èèyàn lohun tí wọ́n ń gbọ́ ti mú kí wọ́n gbà pé, tí ọkàn èèyàn bá ṣáà ti fà sí ìbálòpọ̀, ó ti dẹ́ṣẹ̀ nìyẹn, àmọ́ Bíbélì kò sọ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fúnni nímọ̀ràn tó dára gan-an lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Bíbélì kọ́ni pé kìkì ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jọ fẹ́ra wọn nìkan ló lè ní ìbálòpọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:4-6; Hébérù 13:4) Ìbálòpọ̀ ń jẹ́ kí tọkọtaya lè fi ìfẹ́ wọn hàn fún ara wọn kí wọ́n sì ṣìkẹ́ ara wọn. (1 Kọ́ríńtì 7:1-5) Ọmọ èyíkéyìí tí tọkọtaya bá sì bí á lè ní òbí méjì tó bìkítà fún ara wọn.—Kólósè 3:18-21.

Bíbélì sọ pé ìṣekúṣe kò dára, ó pàṣẹ pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Kí ni ọ̀kan lára ìdí tí Bíbélì fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹsẹ Bíbélì yìí ń bá a lọ pé: “Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí ènìyàn lè dá wà lóde ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá kọ̀ láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?

Ìwọ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà láyé, ibẹ̀ làwọn tó ń lóyún láìtíì tó ọmọ ogún ọdún pọ̀ sí jù lọ. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìlélógójì ó lé ẹgbàárùn-ún [850,000] àwọn ọ̀dọ́bìnrin ló ń lóyún níbẹ̀ lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí wọn ò sì ṣẹ́yún wọn dànù ló jẹ́ pé ìyá wọn kò lọ́kọ. Òótọ́ ni pé àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ tó di màmá yìí máa ń sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ àwọn ọmọ wọn tìfẹ́tìfẹ́ wọ́n sì máa ń fún wọn níbàáwí, díẹ̀ lára àwọn ọmọ náà sì máa ń ṣe dáadáa. Àmọ́ kókó kan tó báni nínú jẹ́ ni pé, àwọn ọmọkùnrin tí ìyá wọn jẹ́ ọ̀dọ́ sábà máa ń ṣe nǹkan tó ń sọ wọ́n dèrò ẹ̀wọ̀n nígbà táwọn tó jẹ́ ọmọbìnrin sábà máa ń di ìyá nígbà táwọn náà ṣì jẹ́ ọ̀dọ́. Ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Robert Lerman tó ń ṣèwádìí, gbé àwọn ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn yẹ̀ wò. Ó wá sọ pé: “Ó ní láti jẹ́ pé báwọn ìdílé olóbìí kan ṣe ń pọ̀ sí i ló ń mú káwọn ìṣòro mìíràn túbọ̀ máa pọ̀ sí i láwùjọ. Àwọn ìṣòro bíi: àwọn ọmọ tí kò parí ẹ̀kọ́ wọn, àwọn ọ̀dọ́ tó ń mutí àtàwọn tó ń lo oògùn olóró, àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń lóyún tí wọ́n sì ń bímọ, àtàwọn ọmọ tó ń ya ìpáǹle.”

Àwọn oníṣekúṣe tún wà nínú ewu ńlá tá a bá n sọ nípa ọ̀rọ̀ ìlera, nítorí pé wọ́n lè tètè kó àìsàn, wọ́n sì lè tètè máa ro èròkerò lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àtìgbàdégbà kan tó ń jẹ́ Pediatrics tó dá lórí ìtọ́jú àwọn ọmọdé sọ pé: “Àkọsílẹ̀ fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tó máa ń ní ìbálòpọ̀ gan-an lè tètè ní ìdààmú ọkàn tó lékenkà wọ́n sì lè tètè fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn.” Nígbà tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlera Àwọn Ará Amẹ́ríkà ń sọ nípa àwọn ewu mìíràn, ó ní: “Ohun tó lé ní ìdajì gbogbo èèyàn [ilẹ̀ Amẹ́ríkà] ló máa ní àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ ní àkókò kan nígbèésí ayé wọn.” Ìwọ wo ìbànújẹ́ ọkàn àti ìnira táwọn èèyàn ì bá yẹra fún ká ní wọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀!

Máa Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kẹ́ Ẹ Sún Mọ́ra Nínú Ìdílé Rẹ

Kì í ṣe àwọn ìwàkiwà tó lè bani láyé jẹ́ nìkan ni Bíbélì kìlọ̀ nípa rẹ̀. Wo ìmọ̀ràn tó dára tó fúnni nípa bí ìdílé ẹni ṣe lè láyọ̀.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” (Éfésù 5:28) Dípò káwọn ọkọ máa wo àwọn aya wọn bí ẹni pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan, Bíbélì rọ̀ wọ́n láti máa bá wọn gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí [wọ́n] máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Pétérù 3:7) Tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún àwọn ọkọ ni pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) Ǹjẹ́ o ò gbà pé tí ọkọ kan bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, ìyàwó rẹ̀ á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ á sì máa bọ̀wọ̀ fún un?

Ní ti àwọn aya, ìtọ́sọ́nà tí Bíbélì fún wọn ni pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ . . . Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:22, 23, 33) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ìyàwó tó bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí nígbà tó bá ń bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, tàbí nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọkọ rẹ̀, yóò jẹ́ ẹni tí ọkọ rẹ̀ fẹ́ràn gan-an?

Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ títọ́, ìmọ̀ràn tó fún ẹ̀yin òbí ni pé kẹ́ ẹ máa bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ “nígbà tí [ẹ] bá jókòó nínú ilé [yín] àti nígbà tí [ẹ] bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí [ẹ] bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí [ẹ] bá dìde.” (Diutarónómì 6:7) Ní pàtàkì, Bíbélì fún àwọn bàbá nítọ̀ọ́ni láti máa tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà nípa irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù kí wọ́n sì máa fún wọn níbàáwí tìfẹ́tìfẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Bákan náà ló sọ fáwọn ọmọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín,” ó sì tún sọ pé “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.”a—Éfésù 6:1, 2.

Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ìdílé á jàǹfààní bí wọ́n bá fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò? Ó lè dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Àmọ́, o tún lè sọ pé, ‘ó dùn ún sọ lẹ́nu, ṣùgbọ́n ṣé lóòótọ́ ni ìmọ̀ràn yìí ń ṣiṣẹ́?’ A rọ̀ ọ́ pé kó o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Wàá rí àwọn ìdílé níbẹ̀ tí wọ́n ń sapá láti fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò. Bá wọn sọ̀rọ̀. Kíyè sí bí àwọn tó wà nínú ìdílé ṣe ń ṣe síra wọn. Wàá fojú ara rẹ rí i pé jíjẹ́ káwọn ìlànà inú Bíbélì máa darí ìgbésí ayé ẹni máa ń mú kí ìdílé láyọ̀ gan-an!

Òṣìṣẹ́ Tó Mọṣẹ́ Rẹ̀ Níṣẹ́ àti Ọ̀gá Tó Ń Ṣẹ̀tọ́

Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fúnni nípa ohun téèyàn lè máa ṣe kí iṣẹ́ má bàa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Ó sọ pé kò sí àní-àní pé àwọn èèyàn á mọyì òṣìṣẹ́ tó bá jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, yóò sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Sólómọ́nì tó jẹ́ ọba ọlọ́gbọ́n béèrè pé: “Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí.” (Òwe 22:29) Àmọ́ ni ti “ọ̀lẹ” èèyàn, ó sọ pé, bí “èéfín sí ojú” ló ṣe rí sẹ́ni tó gbà á síṣẹ́. (Òwe 10:26) Bíbélì rọ àwọn òṣìṣẹ́ pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára. Ó ní: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.” (Éfésù 4:28) Ìmọ̀ràn yìí wúlò, kódà nígbà tí ọ̀gá tó gbani sísẹ́ ò bá sí nítòsí pàápàá. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá yín nípa ti ara, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣe àrójúṣe, gẹ́gẹ́ bí olùwu ènìyàn, ṣùgbọ́n pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn-àyà, pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Kólósè 3:22) Bó o bá jẹ́ ọ̀gá, ǹjẹ́ o ò ní mọyì òṣìṣẹ́ tó bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò?

Ní ti àwọn ọ̀gá, Bíbélì rán wọn létí pé: “Aṣiṣẹ́ yẹ fún owó ọ̀yà rẹ̀.” (1 Tímótì 5:18) Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé ẹni tó gba àwọn èèyàn síṣẹ́ kò gbọ́dọ̀ fi owó wọn falẹ̀ ó sì gbọ́dọ̀ san iye tó tọ́ fún wọn. Mósè sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lu ọmọnìkejì rẹ ní jìbìtì, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jalè. Owó ọ̀yà lébìrà tí a háyà kò gbọ́dọ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀.” (Léfítíkù 19:13) Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn bó o bá ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá tó ń fi ìtọ́ni Bíbélì yìí sílò, tó ń sanwó tó tọ́ fún ọ tó sì ń san owó náà lásìkò?

Orísun Ọgbọ́n Tó Ga Jù Lọ

Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu pé inú ìwé tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́, ìyẹn Bíbélì, la ti rí àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò fún wa lóde òní? Ohun tó mú kí Bíbélì ṣì wúlò títí dòní nígbà tọ́pọ̀ àwọn ìwé mìíràn ti di èyí tí kò wúlò mọ́ ni pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ló wà nínú rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ èèyàn.—1 Tẹsalóníkà 2:13.

A rọ̀ ọ́ pé kó o wá àkókò láti túbọ̀ mọ ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé wàá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Ẹni tí Bíbélì ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Fi ìmọ̀ràn rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì sílò, kó o sì rí bí ìmọ̀ràn yìí yóò ṣe máa kó ọ yọ nínú ewu táá sì jẹ́ káyé rẹ túbọ̀ dára sí i. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá “sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ [ọ].” (Jákọ́bù 4:8) Kò sí ìwé mìíràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run bíi Bíbélì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ran ìdílé rẹ lọ́wọ́, wo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ǹjẹ́ o gbà pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọtí mímu bọ́gbọ́n mu?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ǹjẹ́ o fara mọ́ ìmọ̀ràn Bíbélì pé kéèyàn yàgò fún sìgá mímu?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò máa ń jẹ́ kí ìdílé túbọ̀ láyọ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]

Ilẹ̀ ayé: Látinú àwọn fọ́tò NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́