Ìwé Kan Tí Ó Wúlò Fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
Àwọn ìwé tí ń fúnni ní ìmọ̀ràn wọ́pọ̀ gidigidi láyé òde òní. Ṣùgbọ́n wọ́n sábà máa ń di aláìbágbàmu, kì í sì í pẹ́ tí a fi ń ṣàtúnṣe wọn tàbí kí a fi òmíràn rọ́pò wọn. Bíbélì ńkọ́? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 ọdún sẹ́yìn tí a ti parí rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni a kò tí ì tún ṣe fún ète àtimú un sunwọ̀n sí i tàbí láti mú un bágbà mu. Ó ha ṣeé ṣe kí irú ìwé bẹ́ẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà tí ó wúlò fún ọjọ́ wa bí?
ÀWỌN kan sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́. Dókítà Eli S. Chesen, ní ṣíṣàlàyé ìdí tí òun fi lérò pé Bíbélì kò bágbà mu mọ̀, kọ̀wé pé: “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó máa ṣalágbàwí ti pé kí a máa lo ìwé ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò tí a tẹ̀ ní 1924 nínú kíláàsì ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò lóde òní.”1 Ó jọ bíi pé gbólóhùn yí mọ́gbọ́n dání. Ó ṣe tán, ènìyàn ti kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa ìlera ọpọlọ àti ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn lẹ́yìn tí a ti kọ Bíbélì. Nítorí náà, báwo ní irú ìwé ìgbàanì bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣeé ṣe kí ó ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú ìgbé ayé òde òní?
Àwọn Ìlànà Tí Kò Mọ sí Sáà Kan
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé ìgbà ti yí pa dà, ohun kan náà ṣì ni àwọn àìní ìpìlẹ̀ ènìyàn jẹ́. Jálẹ̀ ìtàn, àwọn ènìyàn máa ń nílò ìfẹ́ àti ìfẹ́ni. Wọ́n ń fẹ́ láti láyọ̀ kí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé tí ó nítumọ̀. Wọ́n ń nílò ìmọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe lè kojú àwọn pákáǹleke ti ọrọ̀ ajé, bí wọ́n ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú ìgbéyàwó, àti bí wọ́n ṣe lè gbin ìlànà ìwà híhù rere àti ti ọmọlúwàbí sínú àwọn ọmọ wọn. Àwọn ìmọ̀ràn tí ó bójú tó àwọn àìní ìpìlẹ̀ wọ̀nyí wà nínú Bíbélì.—Oníwàásù 3:12, 13; Róòmù 12:10; Kólósè 3:18-21; 1 Tímótì 6:6-10.
Àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì ṣàgbéyọ mímọ̀ tí ó mọ àbùdá ènìyàn dunjú. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nínú àwọn ìlànà rẹ̀ tí kò mọ sí sáà kan, tí ó ṣe ṣàkó, tí ó wúlò fún gbígbé ìgbésí ayé lóde òní.
Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Wúlò fún Ìgbéyàwó
Ìwé ìròyìn UN Chronicle sọ pé ìdílé “ni ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ nínú ètò ẹ̀dá ènìyàn; òun ni ìsopọ̀ tí ó ṣe kókó jù lọ láàárín àwọn ìran.” Àmọ́ o, “ìsopọ̀ tí ó ṣe kókó” yìí ń tú ká lọ́nà tí ń kó ìdààmú báni. Ìwé ìròyìn Chronicle náà sọ pé: “Nínú ayé òde òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ní ń dojú kọ àwọn ìpèníjà amunirẹ̀wẹ̀sì tí ń wu agbára wọn láti gbéṣẹ́ ṣe àti, ní ti tòótọ́, láti là á já léwu.”2 Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì pèsè láti lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti là á já?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Bíbélì ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa bí ó ṣe yẹ kí ọkọ àti aya bá ara wọn lò. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ nípa àwọn ọkọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ẹran ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n òun a máa bọ́ ọ a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Éfésù 5:28, 29) Aya ni a fún ní ìmọ̀ràn pé kí ó “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí lílo irú ìmọ̀ràn Bíbélì bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí. Ọkọ kan tí ó nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ ‘gẹ́gẹ́ bí ara òun fúnra rẹ̀’ kò ní kórìíra rẹ̀ tàbí kí ó hùwà òkú òǹrorò sí i. Kò ní lù ú, bẹ́ẹ̀ ni kò ní bú u lọ́rọ̀ ẹnu tàbí kí ó f ìyà jẹ ẹ́ ní ti ìmọ̀lára. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa fi irú ìbuyìkúnni àti ìgbatẹnirò tí ó fi hàn sí ara rẹ̀ hàn sí i. (1 Pétérù 3:7) Aya rẹ̀ a tipa báyìí nímọ̀lára pé òun jẹ́ ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ tí òun sì wà láàbò nínú ìgbéyàwó òun. Ọkọ a sì tipa báyìí pèsè àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ti bí ó ṣe yẹ láti hùwà sí àwọn obìnrin. Ní ọwọ́ kejì, aya kan tí ó ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀ kì í bọ́ iyì ọkọ kúrò lára rẹ̀ nípa ṣíṣòfíntótó tàbí títẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ lemọ́lemọ́. Ní tìtorí pé aya bọ̀wọ̀ fún un, òun a nímọ̀lára pé a gbẹ́kẹ̀ lé òun, a tẹ́wọ́ gba òun, a sì mọrírì òun.
Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ha wúlò nínú ayé òde òní bí? Ó dùn mọ́ni pé àwọn tí wọ́n ń fi ìwádìí nípa àwọn ìdílé ṣiṣẹ́ṣe lónìí ti dé àwọn ìparí èrò tí ó jọ èyí. Olùdarí ètò fífún ìdílé nímọ̀ràn kan sọ pé: “Ìdílé tí ó dúró dáadáa jù lọ tí mo mọ̀ ni àwọn èyí tí ìyá àti bàbá ti ní àjọṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́, tí ó lágbára, láàárín ara wọn. . . . Ó dà bíi pé àjọṣepọ̀ ṣíṣe kókó yìí sábà máa ń fún àwọn ọmọ ní ìmọ̀lára ààbò.”3
Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ìmọ̀ràn Bíbélì nípa ìgbéyàwó hàn pé ó jẹ́ èyí tí ó ṣeé gbára lé gidi gan-an ju ti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn afẹ́nifẹ́re afúnni-nímọ̀ràn nípa ìdílé. Ó ṣe tán, àìpẹ́ yìí ni àwọn ògbógi kan ń ṣalágbàwí ti pé ìkọ̀sílẹ̀ ni ojútùú kíákíá tí ó sì rọrùn sí ìgbéyàwó kan tí kò tuni lára. Lónìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ń rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n mú kí ìgbéyàwó wà pẹ́ bí ó bá ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n ìyípadà yí dé kìkì lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ìpalára tí ó pọ̀ gan-an.
Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó ṣeé gbára lé, tí ó sì wà déédéé lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó. Ó gbà pé àwọn ipò tí ó burú lé kenkà kan lè mú kí a yọ̀ǹda fún ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọ̀sílẹ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ńlẹ̀. (Málákì 2:14-16) Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó pẹ̀lú. (Hébérù 13:4) Ó sọ pé ẹ̀jẹ́ àdéhùn ni ìgbéyàwó jẹ́, pé: “Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”a—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:5, 6.
Ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ìgbéyàwó ṣàǹfààní lónìí gan-an bí ó ṣe jẹ́ ní ìgbà tí a kọ Bíbélì. Nígbà tí ọkọ àti aya bá fi ìfẹ́ àti ìbọ̀wọ̀fúnni bá ara wọn lò tí wọ́n sì wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí àjọṣepọ̀ kan tí ó jẹ́ fún kìkì àwọn nìkan ṣoṣo, ìgbéyàwó ṣeé ṣe kí ó là á já—ìdílé a sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Wúlò fún Àwọn Òbí
Ní ọ̀rúndún mélòó kan sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òbí—bí “àwọn èròǹgbà àdánúṣe” lórí títọ́ ọmọ ti ń tì wọ́n—rò pé “èèwọ̀ ni láti ka nǹkan léèwọ̀.”8 Wọ́n bẹ̀rù pé gbígbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ọmọ yóò fa hílàhílo àti ìjákulẹ̀. Àwọn afẹ́nifẹ́re olùfúnni-nímọ̀ràn nípa títọ́ àwọn ọmọ ń rinkinkin mọ́ ọn pé kí àwọn òbí yẹra fún ohun tí ó bá ju fífún àwọn ọmọ ní ìbáwí tí ó ṣe pẹ̀lẹ́tù jù lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ irú àwọn ògbógi bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ń tún àgbéyẹ̀wò ṣe báyìí lórí ipa tí ìbáwí ń kó, àwọn òbí tí wọ́n ń ṣàníyàn sì ń fẹ́ mọ̀ sí i nípa kókó ẹ̀kọ́ náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìgbà yí wá, Bíbélì ti fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó ṣe kedere, tí ó mọ́gbọ́n dání lórí ọmọ títọ́. Ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, ó sọ pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ọ̀rọ̀ orúkọ ti èdè Gírí ìkì náà tí a túmọ̀ sí “ìbáwí” túmọ̀ sí “ìtọ́dàgbà, ìdálẹ́kọ̀ọ́, ìtọ́ni.”9 Bíbélì sọ pé irú ìbáwí tàbí ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ òbí. (Òwe 13:24) Àwọn ìlànà ìtọ́sọ́nà ṣíṣe kedere lórí ìwà rere máa ń mú kí àwọn ọmọ ní láárí kí wọ́n sì mú òye mímọ ohun tí ó dára àti èyí tí ó burú dàgbà. Ìbáwí ń sọ fún wọn pé àwọn òbí wọn bìkítà nípa wọn àti nípa irú ẹni tí wọ́n ń dà.
Ṣùgbọ́n ọlá àṣẹ òbí—“ọ̀pá ìbáwí”—ni wọn kò gbọ́dọ̀ ṣì ló láé.b (Òwe 22:15; 29:15) Bíbélì fún àwọn òbí ní ìkìlọ̀ pé: “Má ṣe tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà lọ́nà àṣerégèé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ yóò sọ ọkàn wọn domi.” (Kólósè 3:21, Phillips) Ó tún gbà pé ìjẹniníyà ti ara ìyára kì í sábà jẹ́ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ jù lọ láti gbà kọ́ni. Òwe 17:10 sọ pé: “Ìbáwí mímúná ń ṣiṣẹ́ jinlẹ̀ nínú ẹni tí ó ní òye ju lílu arìndìn ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.” Àti pé, ohun tí Bíbélì dámọ̀ràn ni ìbáwí kí wọ́n má baà ṣe àṣìṣe. Nínú Diutarónómì 11:19, a rọ àwọn òbí pé kí wọ́n lo àǹfààní àwọn àyè kéékèèké tí ó bá yọ láti fi gbin ìwà rere sínú àwọn ọmọ wọn.—Tún wo Diutarónómì 6:6, 7.
Ìmọ̀ràn tí kò mọ sí sáà kan, èyí tí Bíbélì fún àwọn òbí yéni yékéyéké. Àwọn ọmọ ń fẹ́ ìbáwí onífẹ̀ẹ́ tí a ń fúnni déédéé. Ìrírí nípa bí ó ṣe ń ṣẹlẹ̀ fi hàn pé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́.c
Bíborí Àwọn Ìdènà Tí Ó Pín Àwọn Ènìyàn Níyà
Ìdènà ti ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, àti ìran ni ó pín àwọn ènìyàn níyà lóde òní. Irú ògiri àtọwọ́dá bẹ́ẹ̀ ni ó dá kún pípa tí a ń pa àwọn ènìyàn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nínú àwọn ogun yí ká ayé. Bí a bá ní kí a wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ìfojúsọ́nà náà pé tọkùnrin tobìnrin láti inú onírúurú ẹ̀yà àti orílẹ̀ èdè yóò ka ara wọn sí ọgbọọgba kí wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ bá ara wọn lò, jẹ́ èyí tí kò dájú. Òṣèlú kan ní ilẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Ọkàn wa ni ojútùú rẹ̀ wà.”11 Ṣùgbọ́n láti yí ọkàn ènìyàn pa dà kò rọrùn. Àmọ́, ṣàgbéyẹ̀wò bí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ṣe darí ọ̀rọ̀ sí ọkàn àyà tí ó sì fún ìwà àparò-kan-ò-ga-jù-kan-lọ níṣìírí.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì náà pé ‘láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn,’ fagi lé èròǹgbà ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá èyíkéyìí. (Ìṣe 17:26) Ó fi hàn pé ìran kan ṣoṣo ni ó wà ní ti gidi—ìran ènìyàn. Bíbélì tún fún wa níṣìírí síwájú sí i pé kí a “di aláfarawé Ọlọ́run,” nípa ẹni tí ó sọ pé: “Kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Éfésù 5:1; Ìṣe 10:34, 35) Ipa asonipọ̀ṣọ̀kan ni ìmọ̀ yí máa ń ní lórí àwọn tí wọ́n fọwọ́ gidi mú Bíbélì tí wọ́n sì ń wọ̀nà láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní tòótọ́. Ó ń ṣiṣẹ́ ní ibi tí ó jinlẹ̀ jù lọ, nínú ọkàn àyà ẹ̀dá ènìyàn, tí ó sì ń tú àwọn ìdènà àtọwọ́dá tí ń pín àwọn ènìyàn níyà. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.
Nígbà tí Hitler jagun jákèjádò Europe, àwùjọ àwọn Kristẹni kan wà—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—tí wọ́n dúró gbọn-ingbọn-in ní kíkọ̀ láti dara pọ̀ nínú pípa àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Wọn “kì yóò gbé idà sókè sí” ẹnì kejì wọn. Wọ́n mú ìdúró yìí nítorí ìfẹ́ ọkàn wọn láti wu Ọlọ́run. (Aísáyà 2:3, 4; Míkà 4:3, 5) Tòótọ́ ni wọ́n gba ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gbọ́—pé kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà kan tí ó dára ju ìkejì lọ. (Gálátíà 3:28) Tìtorí mímú ìdúró wọn fún fífẹ́ àlàáfíà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí ó kọ́kọ́ di èrò àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.—Róòmù 12:18.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé Bíbélì ni wọ́n mú irú ìdúró bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, Martin Niemöller, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kan, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany, kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di ẹ̀bi [àwọn ogun] ru Ọlọ́run kò mọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fẹ́ mọ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. . . . Àtọdúnmọ́dún ni gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ti ń fi ara wọn fún sísúre léraléra fún àwọn ogun, ọmọ ogun, àti àwọn ohun ìjà, wọn a sì . . . gbàdúrà fún ìparun àwọn ọ̀tá wọn nínú ogun lọ́nà tí ó lòdì gbáà sí Kristẹni. Gbogbo èyí jẹ́ ẹ̀bi tiwa àti ẹ̀bi ti àwọn bàbá wa, ṣùgbọ́n a kò lè dá Ọlọ́run lẹ́bi rárá lọ́nàkọnà. Ìtìjú sì bá àwa Kristẹni tòní níwájú àwọn bíi Earnest Bible Students [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà], tí a pè ní ẹ̀ya ìsìn, tí wọ́n wọ àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí wọ́n kú pàápàá nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ogun tí wọ́n sì kọ̀ láti yìnbọn lu ènìyàn.”12
Títí dòní, a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa fún níní ẹ̀mí pé arákùnrin ni gbogbo àwọn, èyí tí ń so àwọn Arébíà àti Júù, àwọn Croat àti Serb, àwọn Hutu àti Tutsi, pọ̀ ṣọ̀kan. Àmọ́ o, Àwọn Ẹlẹ́rìí gbà láìjanpata, pé kì í ṣe tìtorí pé àwọn dára ju àwọn yòó kù lọ ni irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ fi ṣeé ṣe, bí kò ṣe tìtorí pé agbára ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ni ó ń sún wọn ṣiṣẹ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ìtọ́sọ́nà Wíwúlò Tí Ń Ṣokùnfà Ìlera Ọpọlọ Dídára
Ìlera ti ara ìyára ẹnì kan ni ipò tí ìlera ọpọlọ rẹ̀ àti ti èrò ìmọ̀lára rẹ̀ wà sábà máa ń nípa lé lórí. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu f ìdí ipa aṣèpalára tí ìbínú máa ń ní múlẹ̀. Nínú ìwé wọn, Anger Kills, Dókítà Redford Williams, Alábòójútó Ìwádìí Nípa Ìhùwàsí ní Duke University Medical Center, àti aya rẹ̀, Virginia Williams, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fi hàn pé àwọn ènìyàn aláìníwàbí-ọ̀rẹ́ ni wọ́n wà nínú ewu níní àrùn ọkàn (àti àwọn àìsàn míràn) jù nítorí àwọn ìdí púpọ̀, títí kan níní ìwọ̀nba ọ̀rẹ́, àlékún ìrusókè nínú ìṣiṣẹ́ ara nígbà tí a bá mú un bínú àti àlékún nínú sísọ àwọn ìwà tí ó léwu fún ìlera di bárakú.”13
Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí irú ìwádìí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu bẹ́ẹ̀ tó wáyé, Bíbélì ti fi àwọn èdè ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn tí ó sì yéni sọ ìsopọ̀ láàárín ipò èrò ìmọ̀lára àti ti ìlera ara ìyára wa pé: “Ọkàn àyà pípa rọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara, ṣùgbọ́n owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.” (Òwe 14:30; 17:22) Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bíbélì fúnni nímọ̀ràn pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀,” àti “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya [tàbí “bínú,” King James Version].”—Sáàmù 37:8; Oníwàásù 7:9.
Bíbélì tún ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó mọ́gbọ́n dání nínú nípa ṣíṣàkóso ìbínú. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 19:11 sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Ọ̀rọ̀ Hébérù náà fún “ìjìnlẹ̀ òye” ni a mú jáde láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tí ó pe àfiyèsí sí “ìmọ̀ nípa ìdí” tí nǹkan fi ṣẹlẹ̀.14 Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n náà ni: “Rò ó kí o tó ṣe é.” Gbígbìyànjú láti róye ìdí abẹ́nú tí àwọn ẹlòmíràn fi sọ̀rọ̀ tàbí hùwà ní ọ̀nà kan pàtó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ ẹni tí ń rí ara gba nǹkan sí—tí kì í sì í tètè bínú.—Òwe 14:29.
Ìmọ̀ràn wíwúlò míràn ni a rí nínú Kólósè 3:13, tí ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” Àwọn ìdálágara kéékèèké jẹ́ ara ìgbésí ayé. Gbólóhùn náà “máa bá a lọ ní fífaradà á” dámọ̀ràn rírí ara gba àwọn nǹkan tí a kò nífẹ̀ẹ́ sí nínú àwọn ẹlòmíràn. “Dárí jì” túmọ̀ sí jíjọ̀wọ́ ìkórìíra lọ́wọ́. Ní àwọn ìgbà míràn, ó mọ́gbọ́n dání láti jọ̀wọ́ ìmọ̀lára kíkorò lọ́wọ́ kàkà tí a ó fi gbìn wọ́n sínú; gbígbin ìbínú náà sínú yóò wulẹ̀ pa kún ẹrù wa ni.—Wo àpótí “Ìtọ́sọ́nà Wíwúlò fún Àjọṣepọ̀ Ẹ̀dá Ènìyàn.”
Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orísun ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà ni ó wà. Ṣùgbọ́n Bíbélì jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ lóòótọ́. Ìmọ̀ràn rẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe ti àbá èrò orí, bẹ́ẹ̀ sì ni àmọ̀ràn rẹ̀ kì í ṣiṣẹ́ fún ìpalára wa láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ já sí “aṣeégbẹ́kẹ̀lé gan-an.” (Sáàmù 93:5) Síwájú sí i, ìmọ̀ràn Bíbélì kò mọ sí sáà kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a parí rẹ̀ ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì ṣeé mú lò. Ipa kan náà sì ni ó ní lórí ẹni láìka àwọ̀ ara wa tàbí orílẹ̀ èdè tí a ń gbé sí. Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tún ní agbára pẹ̀lú—agbára láti yí àwọn ènìyàn pa dà sí èyí tí ó sunwọ̀n sí i. (Hébérù 4:12) Kíka ìwé yẹn àti fífi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò lè tipa báyìí mú ìjójúlówó ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i.
[Àwọ̀n àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, da·vaqʹ, tí a túmọ̀ sí “fà mọ́” níhìn-ín, “ní òye ti dídìrọ̀mọ́ ẹnì kan láti inú ìfẹ́ni àti ìdúróṣinṣin.”4 Ní èdè Gírí ìkì, ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí “yóò fà mọ́” nínú Mátíù 19:5 ní ìbátan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ó túmọ̀ sí “láti lẹ̀ pọ̀” “láti rẹ́ pọ̀,” “láti so pọ̀ dan-indan-in.”5
b Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọ̀pá” (sheʹvet lédè Hébérù) túmọ̀ sí “igi” tàbí “ọ̀pá gbọọrọ,” irú èyí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń lò.10 Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yí, ọ̀pá àṣẹ dámọ̀ràn ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ìwà òkú òǹrorò.—Fí wé Sáàmù 23:4.
c Wo àwọn orí náà “Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló,” “Ran Ọ̀dọ́langba Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí,” “A Ní Ọlọ̀tẹ̀ Nílé Bí?”, àti “Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun” nínú ìwé náà Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn rírọrùn tí ó sì mọ́gbọ́n dání nípa ìgbésí ayé ìdílé
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn Ànímọ́ Ìdílé tí Kò Níṣòro
Ní àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, olùkọ́ni kan tí ó jẹ́ ògbóǹtagí lórí ọ̀ràn ìdílé ṣe ìwádìí gbígbòòrò kan nínú èyí tí a ti béèrè lọ́wọ́ ohun tí ó ju 500 amọṣẹ́dunjú tí wọ́n ti fún àwọn ìdílé nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣàlàyé lórí àwọn ànímọ́ tí wọ́n ṣàkíyèsí nínú àwọn ìdílé “tí kò níṣòro.” Ó dùn mọ́ni pé àwọn ànímọ́ tí Bíbélì ti dámọ̀ràn tipẹ́tipẹ́ ni èyí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ lára àwọn ànímọ́ tí wọ́n tò sílẹ̀.
Àṣà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó dára ni ó wà lókè pátápátá nínú àkọsílẹ̀ náà, títí kan àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti gbà yanjú àwọn èdèkòyédè. Òǹkọ̀wé ìwádìí náà sọ pé ìlànà ìṣe wíwọ́pọ̀ tí wọ́n rí nínú àwọn ìdílé tí kò níṣòro ni pé “ẹnikẹ́ni kì í lọ sùn tòun tìbínú sí ẹnì kejì.”6 Síbẹ̀, ní ohun tí ó ju 1,900 ọdún sẹ́yìn, Bíbélì fúnni nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìtánnísùúrù.” (Éfésù 4:26) Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, ṣe ni a ń ka ọjọ́ láti ìgbà wíwọ̀ oòrùn dé ìgbà wíwọ̀ oòrùn. Nítorí náà, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí àwọn ògbóǹkangí òde òní tó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn ìdílé, Bíbélì fúnni nímọ̀ràn pé: Yanjú àwọn ọ̀ràn apínniníyà kíákíá—kí ọjọ́ tó kolẹ̀ tí òmíràn yóò sì bẹ̀rẹ̀.
Òǹkọ̀wé náà ṣàwárí pé àwọn ìdílé tí kò níṣòro “kì í dá àwọn kókó ọ̀ràn tí ó lè fa arukutu sílẹ̀ kété ṣáájú kí wọ́n tó jáde tàbí ṣáájú àtisùn. Léraléra ni mo ń gbọ́ gbólóhùn náà, ‘àkókò títọ́.’ ”7 Ṣe ni irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ ń ṣàtúnsọ òwe Bíbélì náà láìmọ̀, èyí tí a ti kọ ní èyí tí ó ju 2,700 ọdún sẹ́yìn pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 15:23; 25:11) Irú àfiwé tààrà yí lè tọ́ka sí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí ó ní ìrísí àwọn ápù tí a kó sínú àwọn àtẹ fàdákà—ohun ìní ẹlẹ́wà tí ó sì ṣeyebíye ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì. Ó gbé àwòrán ẹwà àti ìníyelórí tí àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó ṣe wẹ́kú ní yọ. Ní àwọn àyíká ipò oníhílàhílo, ọ̀rọ̀ títọ́ tí a bá sọ ní àkókò tí ó tọ́ ṣeyebíye gidigidi.—Òwe 10:19.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìtọ́sọ́nà Wíwúlò fún Àjọṣepọ̀ Ẹ̀dá Ènìyàn
“Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n ẹ má ṣẹ̀. Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn-àyà yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Sáàmù 4:4) Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn láìfí kéékèèké, ó lè mọ́gbọ́n dání láti fiyè dénú, kí o sì tipa báyìí yẹra fún ìforígbárí nítorí ìgbónára.
“Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ronú kí o tó sọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ àìnírònú lè ṣèpalára fún àwọn ẹlòmíràn kí ó sì fòpin sí ìbánidọ́rẹ̀ẹ́.
“Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu láti fi ẹ̀mí tútù fèsì, ṣùgbọ́n irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀ sábà máa ń sọ àwọn ìṣòro dẹ̀rọ̀, ó sì máa ń mú kí àjọṣepọ̀ alálàáfíà gbèrú.
“Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 17:14) Ó mọ́gbọ́n dání láti kúrò nínú ipò kan tí gbẹgẹdẹ ti fẹ́ gbiná ṣáájú kí o tó bínú.
“Má ṣe kánjú láti f ìbínú hàn; nítorí àwọn òmùgọ̀ ní ń gbin ìbínú sọ́kàn.” (Oníwàásù 7:9, The New English Bible) Ìmọ̀lára ni ó sábà máa ń ṣáájú àwọn ìgbégbèésẹ̀. Ẹni tí ó bá ń yára bínú jẹ́ òmùgọ̀, nítorí ipa ọ̀nà rẹ̀ lè ṣamọ̀nà sí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe oníwàǹwára.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí ó kọ́kọ́ di èrò àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́