Ìwé Kan Tí Ó Wá Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
“A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 PÉTÉRÙ 1:21.
1, 2. (a) Èé ṣe tí àwọn kan fi ń béèrè bóyá Bíbélì wúlò fún gbígbé ìgbésí ayé òde òní? (b) Àwọn ẹ̀rí mẹ́ta pàtàkì wo ni a lè lò láti fi hàn pé Bíbélì wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
BÍBÉLÌ ha wúlò fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ọ̀rúndún kọkànlélógún bí? Àwọn kan rò pé kò wúlò fún wọn. Dókítà Eli S. Chesen, nígbà tí ó ń ṣàlàyé ìdí tí òun fi lérò pé Bíbélì kò bágbà mu mọ́, kọ̀wé pé: “Kò sí ẹni tí ó máa ṣalágbàwí lílo ìwé ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò tí a tẹ̀ ní 1924 nínú kíláàsì ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò lóde òní—a ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa ẹ̀kọ́ oògùn pípò láti ìgbà yẹn wá.” Lóréfèé, ó jọ pé ìjiyàn yìí mọ́gbọ́n dání. Ó ṣe tán, ènìyàn ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì, ìlera ọpọlọ, àti ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn lẹ́yìn tí a ti kọ Bíbélì. Nítorí náà, àwọn kan ń ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo ni irú ìwé ìgbàanì bẹ́ẹ̀ ṣe lè wá jẹ́ èyí tí kò ní àṣìṣe kankan lọ́nà tí ọ̀ràn sáyẹ́ǹsì? Báwo ni ó ṣe lè wá ní ìmọ̀ràn tí ó gbéṣẹ́ fún ìgbésí ayé òde òní?’
2 Bíbélì fúnra rẹ̀ pèsè ìdáhùn. Nínú 2 Pétérù 1:21, a sọ fún wa pé àwọn wòlíì inú Bíbélì “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” Nípa báyìí, Bíbélì fi hàn pé òun jẹ́ ìwé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè mú kí àwọn ẹlòmíràn gbà gbọ́ pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí? Ẹ jẹ́ kí a gbé ẹ̀rí mẹ́ta tí ó fi hàn pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ̀ wò: (1) Ó péye ní ti sáyẹ́ǹsì, (2) ó kún fún àwọn ìlànà tí kò mọ sí sáà kan, tí ó wúlò fún ìgbésí ayé òde òní, (3) ó sì kún fún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtó tí ó ti nímùúṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn òtítọ́ ìtàn ti fi hàn.
Ìwé Tí Ó Fohùn Ṣọ̀kan Pẹ̀lú Sáyẹ́ǹsì
3. Èé ṣe tí àwọn àwárí sáyẹ́ǹsì kò fi dẹ́rù ba Bíbélì?
3 Bíbélì kì í ṣe ìwé àkànlò lórí sáyẹ́ǹsì. Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ìwé òtítọ́, òtítọ́ kì í sì í kùtà. (Jòhánù 17:17) Àwọn àwárí sáyẹ́ǹsì kò dẹ́rù ba Bíbélì. Nígbà tí ó bá mẹ́nu kan ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, ó máa ń bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àwọn àbá èrò orí “tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu” nígbàanì tí ó wá jẹ́ àwọn ìtàn àròsọ lásán. Ní tòótọ́, àwọn gbólóhùn tí kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ òtítọ́ ní ti ìlànà sáyẹ́ǹsì nìkan ṣùgbọ́n tí wọ́n tún ta ko àwọn èròǹgbà tí ó bóde mu ní àkókò náà pátápátá wà nínú rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, gbé ìṣọ̀kan tí ó wà láàárín Bíbélì àti ìmọ̀ ìṣègùn sáyẹ́ǹsì yẹ̀ wò.
4, 5. (a) Kí ni àwọn oníṣègùn ìgbàanì kò mọ̀ nípa àrùn? (b) Èé ṣe tí kò fi sí iyè méjì pé Mósè mọ ìlànà ìmọ̀ ìṣègùn àwọn oníṣègùn Íjíbítì dunjú?
4 Àwọn oníṣègùn ìgbàanì kò lóye lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa bí àrùn ṣe ń gbèèràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ìjẹ́pàtàkì tí ìmọ́tótó ní lórí dídènà àìsàn. Ọ̀pọ̀ nínú ìlànà ìṣègùn ìgbàanì ni yóò dà bí ìwà àìlajú bí a bá fi ti òde òní díwọ̀n rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìṣègùn tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni ti Ebers Papyrus, àkójọ ìmọ̀ ìṣègùn àwọn ará Íjíbítì, tí ó ti wà láti nǹkan bí ọdún 1550 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó ní 700 ìtọ́jú nínú fún onírúurú àmódi “bẹ̀rẹ̀ láti orí ìbunijẹ ọ̀nì dórí kí orí èékánná máa dunni.” Èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú oògùn wọn kò gbéṣẹ́, ṣùgbọ́n mélòó kan nínú wọn léwu ré kọjá ààlà. Láti tọ́jú ọgbẹ́, ọ̀kan lára oògùn tí wọ́n dábàá ni pé kí a fi àpòpọ̀ kan tí a fi ìgbọ̀nsẹ̀ ènìyàn àti àwọn ohun mìíràn ṣe pa á lójú.
5 A kọ ìwé àkọsílẹ̀ nípa oògùn àwọn ará Íjíbítì yìí ní nǹkan bí àkókò kan náà tí a kọ àwọn ìwé àkọ́kọ́ Bíbélì, lára èyí tí Òfin Mósè wà. Íjíbítì ni Mósè, ẹni tí a bí ní ọdún 1593 ṣááju Sànmánì Tiwa, dàgbà sí. (Ẹ́kísódù 2:1-10) A tọ́ Mósè dàgbà nínú agboolé Fáráò, a sì fún un ní “ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22) Ó mọ “àwọn oníṣègùn” Íjíbítì dáadáa. (Jẹ́nẹ́sísì 50:1-3) Ìlànà ìṣègùn wọn tí kò gbéṣẹ́ tàbí tí ó léwu ha nípa lórí àwọn ìwé tí ó kọ bí?
6. Ìlànà ìmọ́tótó wo nínú Òfin Mósè ni ìmọ̀ ìṣègùn sáyẹ́ǹsì òde òní yóò kà sí èyí tí ó bọ́gbọ́n mu?
6 Ní òdì kejì pátápátá, Òfin Mósè ní ìlànà ìmọ́tótó tí ìmọ̀ ìṣègùn sáyẹ́ǹsì òde òní yóò kà sí èyí tí ó bọ́gbọ́n mu nínú. Fún àpẹẹrẹ, òfin kan nípa ìpabùdó fún ìtẹ́gun sọ pé kí wọ́n bo ìgbọ̀nsẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀yìn òde ibùdó. (Diutarónómì 23:13) Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ adáàbòboni tí ó lọ jìnnà ré kọjá ìgbà tiwọn ní ti ìjìnlẹ̀ òye. Ó ṣèrànwọ́ láti mú kí orísun omi máà ní ẹ̀gbin nínú, ó sì pèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ àrùn ìgbẹ́ gbuuru shigellosis tí a ń kó láti ara eṣinṣin àti àwọn àìsàn mìíràn tí ó jẹ mọ́ àrunṣu, tí ó ṣì ń ṣekú pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́dọọdún, pàápàá jù lọ ní àwọn ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.
7. Ìlànà ìmọ́tótó wo nínú Òfin Mósè ni ó ṣèrànwọ́ láti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn tí ń ranni?
7 Òfin Mósè ní àwọn ìlànà ìmọ́tótó mìíràn nínú, tí ó ṣèrànwọ́ láti dènà ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn tí ń ranni. A máa ń sé ẹni tí ó bá ní àìsàn tí ó lè gbèèràn tàbí tí a fura sí pé ó ní i mọ́. (Léfítíkù 13:1-5) Àwọn ẹ̀wù tàbí ohun èlò tí ó bá kan ẹranko kan tí ó fúnra rẹ̀ kú (bóyá tí àìsàn pa) ni a ó fọ̀ kí a tó tún wọn lò tàbí kí a run wọ́n. (Léfítíkù 11:27, 28, 32, 33) Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú ni a máa ń kà sí aláìmọ́, tí ó sì ní láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwẹ̀nùmọ́ tí ó ní fífọ àwọn ẹ̀wù rẹ̀ àti wíwẹ̀ nínú. Nínú ọjọ́ méje tí ó fi jẹ́ aláìmọ́ náà, ó ní láti yẹra fún níní ìfarakanra pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Númérì 19:1-13.
8, 9. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àkójọ òfin lórí ìmọ́tótó nínú Òfin Mósè fi ọgbọ́n tí ó ré kọjá àkókò tirẹ̀ hàn?
8 Àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ lórí ìmọ́tótó yìí ṣàfihàn ọgbọ́n tí ó ré kọjá àkókó tiwọn. Ìmọ̀ ìṣègùn sáyẹ́ǹsì òde òní ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa ìtànkálẹ̀ àti ìdènà àrùn. Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún yọrí sí lílo ohun agbógunti kòkòrò àrùn—wíwà ní mímọ́ tónítóní láti dín àkóràn àrùn kù. Ó yọrí sí àkóràn àrùn àti ikú ní rèwerèwe tí ó dín kù lọ́nà tí ó kàmàmà. Ní ọdún 1900, ìfojúdíwọ̀n iye ọdún tí a retí pé kí ẹnì kan gbé láyé ní ilẹ̀ Yúróòpù àti ní United States kò tó 50. Láti ìgbà náà wá, ó ti lọ sókè gidigidi, kì í ṣe kìkì nítorí ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìṣègùn nínú kíkápá àrùn ṣùgbọ́n, tìtorí ìmúsunwọ̀n sí i nínú ipò ìmọ́tótó àti àwọn ọ̀nà ìgbégbèésí ayé pẹ̀lú.
9 Síbẹ̀, ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí ìmọ̀ ìṣègùn sáyẹ́ǹsì tó mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí àìsàn ń gbà tàn kálẹ̀, Bíbélì ti tọ́ka àwọn ìgbésẹ̀ adáàbòboni tí ó bọ́gbọ́n mu láti dáàbò boni lọ́wọ́ àìsàn. Abájọ tí Mósè fi lè sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbogbòò ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ ń gbé tó 70 tàbí 80 ọdún láyé. (Sáàmù 90:10) Báwo ni Mósè ṣe mọ̀ nípa àwọn ìlànà ìmọ́tótó wọ̀nyẹn? Bíbélì fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé: “A ta” àkójọ Òfin náà “látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì.” (Gálátíà 3:19) Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì kì í ṣe ìwé tí ó kún fún ọgbọ́n ènìyàn; ó jẹ́ ìwé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ìwé Kan Tí Ó Wúlò fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
10. Bí a tilẹ̀ ti parí Bíbélì ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, kí ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa ìmọ̀ràn rẹ̀?
10 Àwọn ìwé tí ń fúnni nímọ̀ràn sábà máa ń di aláìbágbàmu, kì í sì í pẹ́ tí a fi ń ṣàtúnṣe wọn tàbí kí a fi òmíràn rọ́pò wọn. Ṣùgbọ́n Bíbélì kò láfiwé ní tòótọ́. Sáàmù 93:5 sọ pé: “Àwọn ìránnilétí rẹ ti já sí aṣeégbẹ́kẹ̀lé gan-an.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti parí kíkọ Bíbélì ní nǹkan bí 2,000 ọdún sẹ́yìn, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣeé fi sílò. Wọ́n sì kan gbogbo wa lọ́nà kan náà láìka irú àwọ̀ ara wa tàbí orílẹ̀-èdè tí a ń gbé sí. Gbé díẹ̀ nínú àwọn àpẹẹrẹ ìmọ̀ràn Bíbélì tí kò mọ sí sáà kan, tí ó sì jẹ́ “aṣeégbẹ́kẹ̀lé gan-an” yẹ̀ wò.
11. Ní ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn, kí ni a mú kí ọ̀pọ̀ òbí gbà gbọ́ nípa bíbá àwọn ọmọ wí?
11 Ní àwọn ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí—bí “àwọn èròǹgbà àdánúṣe” lórí títọ́ ọmọ ti ń tì wọ́n—rò pé “èèwọ̀ ni láti ka nǹkan léèwọ̀.” Wọ́n bẹ̀rù pé gbígbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ọmọ yóò fa hílàhílo àti ìjákulẹ̀. Àwọn afẹ́nifẹ́re olùfúnni-nímọ̀ràn ń rin kinkin mọ́ ọn pé kí àwọn òbí yẹra fún ohun tí ó bá ju fífún àwọn ọmọ ní ìbáwí onípẹ̀lẹ́tù. Ìwé ìròyìn The New York Times, sọ pé, nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ irú àwọn ògbógi bẹ́ẹ̀ ni wọ́n “ń rọ àwọn òbí láti túbọ̀ jẹ́ aláìgbagbẹ̀rẹ́, láti kápá àwọn ọmọ wọn.”
12. Kí ni ọ̀rọ̀ orúkọ ti èdè Gíríìkì náà tí a tú sí “ìbáwí” túmọ̀ sí, èé sì ti ṣe tí àwọn ọmọ fi nílò irú ìbáwí bẹ́ẹ̀?
12 Ṣùgbọ́n, láti ìgbà yìí wa, Bíbélì ti fúnni ní ìmọ̀ràn pàtó, tí ó wà déédéé lórí ọ̀ràn ọmọ títọ́. Ó gbani níyànjú pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ọ̀rọ̀ orúkọ ti èdè Gíríìkì náà tí a tú sí “ìbáwí” túmọ̀ sí “ìtọ́dàgbà, ìdálẹ́kọ̀ọ́, ìtọ́ni.” Bíbélì sọ pé ìbáwí, tàbí ìtọ́ni, jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ òbí. (Òwe 13:24) Àwọn ìlànà ìtọ́sọ́nà ṣíṣe kedere lórí ìwà rere máa ń mú kí àwọn ọmọ ní láárí, kí wọ́n sì mú òye wọn nípa mímọ ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú dàgbà. Ìbáwí tí a fún wọn lọ́nà tí ó tọ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nífọkànbalẹ̀; ó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí wọn bìkítà nípa wọn àti nípa irú ẹni tí wọ́n ń dà.—Fi wé Òwe 4:10-13.
13. (a) Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìbáwí, ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì fún àwọn òbí? (b) Irú ìbáwí wo ni Bíbélì dámọ̀ràn?
13 Ṣùgbọ́n Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn òbí lórí ọ̀ràn ìbáwí yìí. Àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ ṣi ọlá àṣẹ wọn lò. (Òwe 22:15) Kò yẹ kí a fi ìyà tí ó fi ìwà òǹrorò hàn jẹ ọmọ. Kò gbọ́dọ̀ sí ìwà ipá nínú ìdílé tí ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì. (Sáàmù 11:5) Bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọ́dọ̀ sí gbígbẹ́mìí ẹni gbóná—ọ̀rọ̀ gbàkanṣubú, ṣíṣe lámèyítọ́ nígbà gbogbo, òdì ọ̀rọ̀ tí ń dunni wọra, gbogbo èyí ni ó lè ba ọmọ lọ́kàn jẹ́. (Fi wé Òwe 12:18.) Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn òbí pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò [tàbí, “ìwọ yóò sọ ọkàn wọn domi,” Phillips].” (Kólósè 3:21) Bíbélì dámọ̀ràn ìbáwí tí yóò mú kí wọ́n yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe. Nínú Diutarónómì 11:19, a rọ àwọn òbí pé kí wọ́n lo àǹfààní àwọn àkókò gbẹ̀fẹ́ tí ó bá yọ láti fi gbin ìlànà ìwà rere àti tẹ̀mí sínú àwọn ọmọ wọn. Irú ìmọ̀ràn ṣíṣe kedere, tí ó sì lọ́gbọ́n nínú bẹ́ẹ̀ lórí títọ́ ọmọ wúlò lónìí gẹ́gẹ́ bí ó ti wúlò ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì.
14, 15. (a) Ní ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà pèsè ju ìmọ̀ràn tí ó bọ́gbọ́n mu lọ? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wo ni ó lè ran tọkùnrin tobìnrin láti inú ìran àti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ láti ka ara wọn sí ọgbọọgba?
14 Ìmọ̀ràn tí Bíbélì pèsè ré kọjá ìmọ̀ràn tí ó bọ́gbọ́n mu. Àwọn ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ ń wọni lọ́kàn ṣinṣin. Hébérù 4:12 sọ pé: “Nítorí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” Gbé àpẹẹrẹ agbára ìsúnniṣe tí Bíbélì ní yẹ̀ wò.
15 Ìdènà ti ìran, orílẹ̀-èdè, àti ẹ̀yà ti pín àwọn ènìyàn níyà lóde òní. Irú ìdènà àtọwọ́dá bẹ́ẹ̀ ti dá kún pípa tí a ń pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ènìyàn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nínú àwọn ogun yí ká ayé. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Bíbélì ní àwọn ẹ̀kọ́ tí ń ran tọkùnrin tobìnrin tí ó ti inú ìran àti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá lọ́wọ́ láti ka ara wọn sí ọgbọọgba. Fún àpẹẹrẹ, Ìṣe 17:26 sọ pé “láti ara ọkùnrin kan ni” Ọlọ́run “ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” Èyí fi hàn pé ìran kan ṣoṣo ni ó wà ní ti gidi—ìran ẹ̀dá ènìyàn! Bíbélì tún fún wa níṣìírí síwájú sí i pé kí a “di aláfarawé Ọlọ́run,” ẹni tí ó sọ nípa rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Éfésù 5:1; Ìṣe 10:34, 35) Ipa asonipọ̀ṣọ̀kan ni ìmọ̀ yìí máa ń ní lórí àwọn tí wọ́n ń wá ọ̀nà ní tòótọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó ń ṣiṣẹ́ ní ibi tí ó jinlẹ̀ jù lọ—nínú ọkàn-àyà—ó sì ń tú àwọn ìdènà àtọwọ́dá tí ń pín àwọn ènìyàn níyà ká. Ó ha gbéṣẹ́ ní tòótọ́ nínú ayé òde òní bí?
16. Sọ ìrírí kan tí ó fi hàn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ́ ará tòótọ́ kárí ayé.
16 Dájúdájú, ó gbéṣẹ́! A mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ẹní mowó fún ẹgbẹ́ ara wọn kárí ayé, tí ń so àwọn ènìyàn tí ó ní ipò àtilẹ̀wá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọn kì bá tí gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà, pọ̀ ṣọ̀kan. Fún àpẹẹrẹ, nígbà ìjà ẹ̀yà tí ó wáyé ní Rwanda, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan dáàbò bo àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wọn tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà kejì, ní ṣíṣe èyí, wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wewu. Nígbà kan, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ Hutu fi ìdílé Tutsi ẹlẹ́ni mẹ́fà tí ó wà ní ìjọ rẹ̀ pa mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó ṣeni láàánú pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín àwọn panipani rí àwọn ìdílé Tutsi náà, wọ́n sì pa wọ́n. Arákùnrin Hutu náà àti ìdílé rẹ̀ nísinsìnyí rí ìrunú àwọn panipani náà, wọ́n sì ní láti sá lọ sí Tanzania. A ròyìn ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ irú ìrírí bẹ́ẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbangba pé irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe nítorí pé agbára ìsúnniṣe tí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ní, ti gbún ọkàn-àyà wọn ní kẹ́ṣẹ́. Pé Bíbélì lè so àwọn ènìyàn pọ̀ ṣọ̀kan nínú ayé tí ó kún fún ìkórìíra yìí jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Tòótọ́
17. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kò ṣe dà bí àsọtẹ́lẹ̀ ènìyàn?
17 Pétérù Kejì 1:20 sọ pé: “Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí.” Àwọn wòlíì inú Bíbélì kò ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àlámọ̀rí ayé ìgbà náà, lẹ́yìn náà, kí wọ́n wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n gbé karí ìtumọ̀ ti ara wọn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ òfegè tí a lè mú kí ó bá ohunkóhun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la mu. Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ó ṣe pàtó lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdì kejì ohun tí àwọn ènìyàn tí ń gbé nígbà náà lè máa retí.
18. Èé ṣe tí ó fi dáni lójú pé àwọn olùgbé Bábílónì ìgbàanì nímọ̀lára pé kò séwu, síbẹ̀, kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Bábílónì?
18 Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Tiwa, Bábílónì ti di olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Bábílónì tí ó dà bí èyí tí a kò lè ṣẹ́gun. Odò Yúfírétì yí ìlú ńlá náà ká, a sì fi omi rẹ̀ ṣe yàrà fífẹ̀, tí ó jìn àti àwọn ipa odò tí a là já ara wọn. A fi àwọn odi fẹ̀ǹfẹ̀ méjì tí a mọ pọ̀, tí ó tún ní àwọn ilé gogoro tí ó wà fún ìgbèjà, dáàbò bò ó. Abájọ tí àwọn olùgbé Bábílónì fi nímọ̀lára pé kò séwu. Síbẹ̀síbẹ̀, ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, àní kí Bábílónì tó dé téńté ògo rẹ̀, wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Bábílónì . . . yóò sì dà bí ìgbà tí Ọlọ́run bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú. A kì yóò gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran. Àwọn ará Arébíà kì yóò sì pàgọ́ sí ibẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì yóò sì jẹ́ kí agbo ẹran wọn dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀.” (Aísáyà 13:19, 20) Ṣàkíyèsí pé kì í ṣe nípa pípa Bábílónì run nìkan ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ ṣùgbọ́n ó tún sọ pé yóò di ahoro títí láé. Àsọtẹ́lẹ̀ tí a fi ìgboyà sọ ní èyí mà jẹ́ o! Ó ha lè jẹ́ pé lẹ́yìn ìgbà tí Aísáyà ti rí ìsọdahoro Bábílónì ni ó tó kọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí? Ìtàn dáhùn pé rárá o!
19. Èé ṣe tí a kò fi mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ ní kíkún ní October 5, ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa?
19 Ní òru October 5, 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Bábílónì ṣubú sọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà lábẹ́ Kírúsì Ńlá. Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà kò tí ì ní ìmúṣẹ ní kíkún nígbà náà. Lẹ́yìn tí Kírúsì gba àkóso ibẹ̀, Bábílónì tí a ń gbé inú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lágbára tó bẹ́ẹ̀ mọ́—ṣì ń bẹ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, ní sáà ìgbà tí a da Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Aísáyà kọ, àwọn ará Pátíà gba àkóso Bábílónì, tí a kà sí ohun ìṣúra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká ń jà lé lórí nígbà náà. Júù òpìtàn náà, Josephus, ròyìn pé, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ” àwọn Júù ń gbé níbẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Cambridge Ancient History, ti sọ, àwọn oníṣòwò ará Pálímírà dá ibùdó òwò ńlá kan sílẹ̀ ní Bábílónì ní ọdún 24 Sànmánì Tiwa. Nítorí náà, títí fi di nǹkan bí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, a kò tí ì pa Bábílónì run pátápátá; síbẹ̀, a ti parí ìwé Aísáyà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà náà.—1 Pétérù 5:13.
20. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé Bábílónì di “ìtòjọpelemọ òkúta” nígbẹ̀yìngbẹ́yín?
20 Aísáyà ti kú kí Bábílónì tó di ahoro. Ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Bábílónì di kìkì “ìtòjọpelemọ òkúta” nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Jeremáyà 51:37) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Jerome, tí ó jẹ́ Hébérù (tí a bí ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa), sọ, nígbà tí ó fi máa di ọjọ́ rẹ̀, Bábílónì ti di ibi ìṣọdẹ nínú èyí tí “àwọn ẹranko onírúurú” ti ń jẹ̀, ó sì wà ní ahoro títí di òní olónìí. Ìmúbọ̀sípò yòó wù tí a bá ṣe sí Bábílónì láti sọ ọ́ di ibi àṣèbẹ̀wòsí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ lè sún àwọn ènìyàn láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, “àtọmọdọ́mọ àti ìran àtẹ̀lé” Bábílónì ti pòórá títí láé.—Aísáyà 14:22.
21. Èé ṣe tí àwọn wòlíì olùṣòtítọ́ fi lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la láìtàsé?
21 Wòlíì Aísàyà kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó gbé karí ìmọ̀ ti ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò tún ìtàn kọ láti mú kí ó dà bí àsọtẹ́lẹ̀. Aísáyà jẹ́ wòlíì tòótọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo àwọn wòlíì inú Bíbélì yòó kù tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́. Èé ṣe tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí fi lè ṣe ohun tí ẹ̀dá ènìyàn mìíràn kò lè ṣe—sísọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la láìtàsé? Ìdáhùn náà ṣe kedere. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀, Jèhófà, “ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin.”—Aísáyà 46:10.
22. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a sa gbogbo ipá wa láti rọ àwọn aláìlábòsí ọkàn láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì fúnra wọn?
22 Nítorí náà, ó ha yẹ kí a ṣàyẹ̀wò Bíbélì bí? A mọ̀ pé ó yẹ bẹ́ẹ̀! Ṣùgbọ́n kò dá ọ̀pọ̀ ènìyàn lójú. Wọ́n ti gbin àwọn èrò kan sọ́kàn nípa Bíbélì àní bí wọn kò tilẹ̀ kà á rí. Rántí ọ̀jọ̀gbọ́n tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú. Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lẹ́yìn tí ó sì ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì, ó dé ìparí èrò náà pé ó jẹ́ ìwé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lónìí, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà! Ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti rọ àwọn aláìlábòsí ọkàn láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì fúnra wọn, kí wọ́n sì wá ní èrò kan nípa rẹ̀. A ní ìgbọ́kànlé pé bí wọ́n bá ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ fúnra wọn láìṣàbòsí, wọn yóò mọ̀ pé ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ yìí, Bíbélì, ní tòótọ́ jẹ́ ìwé kan tí ó wà fún gbogbo ènìyàn!
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni o ṣe lè lo Òfin Mósè láti fi hàn pé Bíbélì kò ti ọwọ́ ènìyàn wá?
◻ Àwọn ìlànà tí kò mọ sí sáà kan wo nínú Bíbélì ni ó wúlò fún ìgbésí ayé òde òní?
◻ Èé ṣe tí kò fi lè jẹ́ pé a kọ Aísáyà 13:19, 20 lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
◻ Kí ni ó yẹ kí a rọ àwọn aláìlábòsí ọkàn láti ṣe, èé sì ti ṣe?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn Ohun tí A Kò Lè Fẹ̀rí Rẹ̀ Hàn Ńkọ́?
Bíbélì kún fún onírúurú gbólóhùn tí kò ní ẹ̀rí tí a lè fojú rí. Fún àpẹẹrẹ, a kò lè fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fi ẹ̀rí ohun tí ó sọ nípa ilẹ̀ àkóso tí a kò lè fojú rí tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé hàn—bẹ́ẹ̀ sì ni a kò lè lò ó láti fi sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀. Irú àwọn ìtọ́kasí tí a kò lè fẹ̀rí rẹ̀ hàn bẹ́ẹ̀ ha fi hàn pé Bíbélì ta ko sáyẹ́ǹsì bí?
Èyí ni ìbéèrè tí ó dojú kọ onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti àwọn ohun alààyè inú rẹ̀, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Ó rántí pé: “Mo gbà pé ó ṣòro fún mi láti tẹ́wọ́ gba Bíbélì lákọ̀ọ́kọ́ nítorí pé n kò lè fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹ̀rí àwọn gbólóhùn kan nínú Bíbélì hàn.” Ọkùnrin olóòótọ́ ọkàn yìí ń bá kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó gbà gbọ́ dájú pé ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Ó ṣàlàyé pé: “Èyí dín ìyánhànhàn tí mo ní fún wíwá ẹ̀rí sí gbogbo kókó inú Bíbélì lọ́kọ̀ọ̀kan kù. Ẹnì kan tí ó bá ní ẹ̀mí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì láti ojú ìwòye tẹ̀mí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kì yóò tẹ́wọ́ gba òtítọ́ láé. A kò lè retí pé kí sáyẹ́ǹsì fẹ̀rí hàn sí gbogbo gbólóhùn inú Bíbélì. Ṣùgbọ́n, tìtorí pé a kò lè fẹ̀rí àwọn gbólóhùn kan hàn, kò túmọ̀ sí pé wọn kì í ṣe òtítọ́. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe láti fẹ̀rí hàn, a máa ń fìdí ìpéye Bíbélì múlẹ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Mósè ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìlànà ìmọ́tótó tí ọgbọ́n wọn ré kọjá àkókò tiwọn