Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀
Àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ nínú ọjọ́ ọ̀la. Wọn a máa wá àwọn àwítẹ́lẹ̀ nípa onírúurú àwọn kókó ẹ̀kọ́, látorí àsọbádé nípa ojú ọjọ́ dórí ohun tí ń sọ nípa ipò ọrọ̀ ajé. Àmọ́, nígbà tí wọ́n bá fi irú àwítẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ gbégbèésẹ̀, ìjákulẹ̀ sábà máa ń bá wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwítẹ́lẹ̀, tàbí àsọtẹ́lẹ̀ ni ó wà nínú Bíbélì. Báwo ni irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe péye tó? Ṣé ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ti kọ kí ó tó ṣẹlẹ̀ ni? Àbí ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wulẹ̀ gbé àwọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀ ni?
CATO (234 sí 149 ṣáájú Sànmánì Tiwa), òṣèlú ará Róòmù kan, ni a sọ pé ó wí pé: “Ó yà mí lẹ́nu pé aláfọ̀ṣẹ kì í rẹ́rìn ín nígbàkígbà tí ó bá rí aláfọ̀ṣẹ mìíràn.”1 Lóòótọ́, títí di òní yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń kọminú nípa àwọn alákìíyèsí-ìgbà, awòràwọ̀, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ yòó kù. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó ni wọ́n fi ń gbé àwítẹ́lẹ̀ wọn kalẹ̀, àwọn tí ó jẹ́ pé a lè fún ní onírúurú ìtumọ̀.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wá ńkọ́? Ṣé ìdí wà láti kọminú nípa wọn? Àbí ìdí ha wà láti gbọ́kàn lé wọn bí?
Kì Í Kàn Í Ṣe Àsọbádé Tí A Gbé Karí Ìsọfúnni Bíi Mélòó Kan
Àwọn olóye ènìyàn lè gbìyànjú láti lo bí ipò àwọn nǹkan ṣe ń lọ sí láti sọ àròbájọ tí ó lè ṣẹlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, ṣùgbọ́n wọn kì í f ìgbà gbogbo tọ̀nà. Ìwé náà, Future Shock, sọ pé: “Ohun tí olúkúlùkù àwùjọ ń dojú kọ kì í wulẹ̀ í ṣe ti ìtòtẹ̀léra àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó ṣẹlẹ̀, bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀, àti ìforígbárí tí ó ní pẹ̀lú àwọn ohun tí a ń fẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Lóòótọ́, kò sí ẹni tí ó lè ‘mọ’ ọjọ́ iwájú fínnífínní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ṣe ni a kàn lè fètò gbé àwọn àròbájọ wa nípa ọjọ́ ọ̀la kalẹ̀ kí a sì mú wọn kún rẹ́rẹ́ sí i kí a sì gbìyànjú láti lẹ ohun tí a rò pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣẹlẹ̀ jù lọ lọ́jọ́ iwájú mọ́ wọn lára.”2
Ṣùgbọ́n àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì kò wulẹ̀ “lẹ àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó ṣẹlẹ̀ jù lọ” mọ́ “àwọn àròbájọ” nípa ọjọ́ iwájú lára. Bẹ́ẹ̀ sì ni a ò kàn lè fọwọ́ rọ́ àwọn àwítẹ́lẹ̀ wọn tì ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ kan pé ó jẹ́ àwọn gbólóhùn tí ó lọ́jú, èyí tí a lè fún ní onírúurú ìtumọ̀ púpọ̀. Ní òdì kejì èyí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọn ni a sọ lọ́nà tí ó yéni yékéyéké lárà ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì sábà máa ń ṣe ṣàkó, àti lọ́pọ̀ ìgbà, wọn a wí àwítẹ́lẹ̀ tí ó jẹ́ òdì kejì sí ohun tí a lè retí. Mú ohun tí Bíbélì sọ ṣáájú nípa ìlú ìgbàanì náà, Bábílónì, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan.
A Ó “Fi Ìgbálẹ̀ Ìparẹ́ráúráú Gbá A”
Bábílónì ìgbàanì di “ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba.” (Aísáyà 13:19, The New American Bible) ìlú tí ń yára gbèrú yìí ni a fi ìwéwèé tẹ̀ dó sí ojú ọ̀nà ìṣòwò láti Persian Gulf sí Òkun Mẹditaréníà, tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ibi ìkẹ́rùsí fún àwọn olówò orí ilẹ̀ àti ojú òkun láàárín Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn.
Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Tiwa, Bábílónì ti di olú ìlú tí ó dà bí èyí tí a kò lè ṣẹ́gun fún Ilẹ̀-Ọba Bábílónì. Ìlú náà ni a kọ́ ré kọjá láti ìhà kan Odò Yúfírétì sí ìkejì, tí a sì fi omi rẹ̀ ṣe yàrà fífẹ̀, tí ó jìn àti àwọn odò lílà tí a là já ara wọn. Ní àfikún, a fi àwọn odi fẹ̀ǹfẹ̀ méjì tí a mọ pọ̀, tí ó tún ní àwọn ilé gogoro ìgbèjà tí ó pọ̀ gan-an, dáàbò bò ó. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé àwọn olùgbé rẹ̀ nímọ̀lára pé àwọn wà láàbò.
Síbẹ̀síbẹ̀, ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Tiwa, kí Bábílónì tó dé téńté ògo rẹ̀, wòlí ì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Bábílónì ni a ó “fi ìgbálẹ̀ ìparẹ́ráúráú gbá.” (Aísáyà 13:19; 14:22, 23) Aísáyà tún ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Bábílónì yóò gbà ṣubú gan-an. Àwọn agbóguntini yóò mú kí àwọn odò rẹ̀—orísun ohun tí ó dà bíi yàrà àfigbèjà rẹ̀—‘gbẹ táútáú’ ní sísọ ìlú náà di èyí tí a lè tètè gbà. Aísáyà tilẹ̀ tún sọ orúkọ aṣẹ́gun náà—“Kírúsì,” ọba ńlá kan láti Páṣíà, “iwájú ẹni tí a ó ti ṣí àwọn ẹnubodè sílẹ̀ tí kò sì ní sí ilẹ̀kùn kankan ti a ó tì.”—Aísáyà 44:27–45:2, The New English Bible.
Àsọtẹ́lẹ̀ tí a f ìgboyà sọ ni ìwọ̀nyí jẹ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ha ṣẹ bí? Ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ pèsè ìdáhùn.
“Láìsí Ìjà Ogun”
Ní ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn tí Aísáyà ti kọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ní òru October 5, 539 ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà lábẹ́ ìdarí Kírúsì Ńlá pabùdó sí itòsí Bábílónì. Ṣùgbọ́n àwọn ará Bábílónì kò mikàn. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gírí ìkì náà, Herodotus (ti ọ̀rúndún karùn ún ṣáájú Sànmánì Tiwa) ṣe sọ, àwọn ìpèsè tí wọ́n ti tò jọ pa mọ́ tó fún ìlò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.3 Odò Yúfírétì àti àwọn odi alágbára ńlá ti Bábílónì tún wà níbẹ̀ láti dáàbò bò wọ́n. Láìka èyí sí, ní òru yẹn gan-an, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Ìtàn Nabonidus ṣe sọ, “àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kírúsì wọnú Bábílónì láìsí ìjà ogun.”4 Báwo ni ìyẹn ṣe ṣeé ṣe?
Herodotus ṣàlàyé pé nínú ìlú yẹn, àwọn ènìyàn “ń jó wọ́n sì ń jẹ fàájì níbi àjọyọ̀ kan.”5 Àmọ́ lóde, Kírúsì ti darí àwọn omi Yúfírétì síbòmíràn. Bí kíkún omi náà ṣe lọọlẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ wọ́dò la ìsàlẹ̀ odò náà kọjá, omi náà sì dé itan wọn. Wọ́n yan kọjá àwọn odi gíga fíofío wọ́n sì gba àwọn ohun tí Herodotus pè ní “àwọn ẹnubodè tí ó ṣí sí ojú omi,” àwọn ẹnubodè tí a ṣí sílẹ̀ láìbìkítà.6 (Fi wé Dáníẹ́lì 5:1-4; Jeremáyà 50:24; 51:31, 32.) Àwọn òpìtàn míràn, títí kan Xenophon (nǹkan bí 431 sí nǹkan bí 352 ṣáájú Sànmánì Tiwa), àti àwọn wàláà amọ̀ tí a fín ọ̀rọ̀ sí, tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí, jẹ́rìí sí i pé ìṣubú òjijì Bábílónì jẹ́ láti ọwọ́ Kírúsì.7
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa ìṣubú Bábílónì ni a tipa báyìí mú ṣẹ. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó ha lè jẹ́ pé èyí kì í ṣe àwítẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n pé ṣe ni a kọ ọ́ ní ti gidi lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọn bí? Lóòótọ́, ohun kan náà ni a lè béèrè nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòó kù nínú Bíbélì.
Ṣé Ìtàn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí Ó Gbé Àwọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Wọ̀ Ni?
Bí ó bá ṣe pé ṣe ni àwọn wòlí ì inú Bíbélì—títí kan Aísáyà—wulẹ̀ kọ ìtàn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì mú kí ó dà bí àsọtẹ́lẹ̀, a jẹ́ pé ògbówọ́ aṣèrú gbáà ni àwọn ọkùnrin náà jẹ́. Ṣùgbọ́n kí ni ì bá jẹ́ ète wọn fún irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀? Àwọn wòlí ì tòótọ́ kò jáfara láti fi hàn pé a kò lè fún wọn ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 12:3; Dáníẹ́lì 5:17) A sì ti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí alágbára nípa pé àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì (tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ wòlí ì) jẹ́ àwọn ènìyàn tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tí ó ṣe tán àní láti fi àwọn àṣìṣe atinilójú tiwọn fúnra wọn hàn. Kò dà bíi pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ní ìtẹ̀sí àtiṣe irú èrú tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, ní gbígbé àwọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀.
Ohun mìíràn tún wà láti gbé yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ní nínú, àwọn ìbáwí ìkannú kíkorò lórí àwọn ènìyàn ti àwọn wòlí ì náà fúnra wọn, tí ó ní àwọn àlùfáà àti àwọn alákòóso nínú. Fún àpẹẹrẹ, Aísáyà sọ̀rọ̀ líle lòdì sí ipò amúnibanújẹ́ tí ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì—àwọn aṣáájú àti àwọn ènìyàn lápapọ̀—wà ní ọjọ́ rẹ̀. (Aísáyà 1:2-10) Àwọn wòlí ì míràn tú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà fó lọ́nà mímúná. (Sefanáyà 3:4; Málákì 2:1-9) Ó ṣòro láti lóye ìdí tí wọn yóò fi hùmọ̀ irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní irú ìbáwí mímúná jù lọ tí a lè ronú kàn bẹ́ẹ̀ lòdì sí àwọn ènìyàn tiwọn àti ìdí tí àwọn àlùfáà yóò fi fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú irú mọ̀kàrúrù bẹ́ẹ̀.
Ní àfikún sí i, báwo ni àwọn wòlí ì—bí wọ́n bá jẹ́ èkìdá afàwọ̀rajà—ṣe lè mú irú èrú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ? A fún ìmọ̀wéékà níṣìírí ní Ísírẹ́lì. Láti ìgbà ọmọdé ni a ti ń kọ́ àwọn ọmọ láti mọ̀wéékà kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kọ. (Diutarónómì 6:6-9) A rọni láti máa dá ka Ìwé Mímọ́. (Sáàmù 1:2) Ìwé Mímọ́ ni a máa ń kà ní gbangba nínú àwọn sínágọ́gù lọ́jọ́ Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Ìṣe 15:21) Ó dà bíi pé kò ṣeé ṣe pé kí irú ìtànjẹ bẹ́ẹ̀ mú odindi orílẹ̀-èdè kan tí ó mọ̀ ọ́n kọ, tí ó mọ̀ ọ́n kà, tí ó sì mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa.
Yàtọ̀ sí ìyẹn, ohun púpọ̀ sí i tún wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa ìṣubú Bábílónì. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan wà nínú rẹ̀ tí kò wulẹ̀ lè jẹ́ èyí tí a kọ lẹ́yìn tí ó ti ní ìmúṣẹ.
“A Kì Yóò Gbé Inú Rẹ̀ Mọ́ Láé”
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì lẹ́yìn ìṣubú rẹ̀? Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A kì yóò gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran. Àwọn ará Arébíà kì yóò sì pàgọ́ sí ibẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì yóò sì jẹ́ kí agbo ẹran wọn dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀.” (Aísáyà 13:20) Ó ti lè dà bí ohun tí ó ṣàjèjì, ó kéré tán, láti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú ìlú kan, tí a tẹ̀ dó sí ibi tí ó dára bẹ́ẹ̀, yóò di aláìlólùgbé títí ayé. Ó ha lè jẹ́ pé ṣe ni Aísáyà kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kíyè sí Bábílónì tí ó ti dahoro bí?
Lẹ́yìn tí Kírúsì gba àkóso ibẹ̀, Bábílónì tí a ń gbé inú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lágbára tó bẹ́ẹ̀ mọ́—ń bá a lọ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Rántí pé ìwé Aísáyà lódindi, tí a ṣírò ọjọ́ orí rẹ̀ lọ sẹ́yìn sí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa, wà nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Ní sáà ìgbà tí a ń da ìwé yẹn kọ lọ́wọ́ ni àwọn ará Pátíà gba àkóso Bábílónì. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn Júù wà tí wọ́n tẹ̀ dó sí Bábílónì, Pétérù tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì sì ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. (1 Pétérù 5:13) Ní nǹkan bí àkókò yẹn, Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Aísáyà ti wà fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀rúndún méjì. Nítorí náà, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Bábílónì kò tí ì di ahoro pátápátá síbẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ kẹ̀, a ti parí ìwé Aísáyà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn.a
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Bábílónì di kìkì “ìtòjọpelemọ òkúta” ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Jeremáyà 51:37) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Hébérù náà, Jerome (ti ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa) ṣe sọ, nígbà tí ó fi máa di ọjọ́ tirẹ̀, Bábílónì ti di ibi ìṣọdẹ nínú èyí tí “àwọn ẹranko onírúurú” ti ń jẹ̀.9 Ahoro ni Bábílónì wà títí di òní yìí.
Aísáyà kò pẹ́ láyé tó àtirí kí Bábílónì di aláìlólùgbé. Ṣùgbọ́n àlàpà ohun tí ó ti f ìgbà kan jẹ́ ìlù ńlá alágbára, ní nǹkan bí 80 kìlómítà níhà gúúsù ìlú Baghdad, ní Iraq òde òní, ń jẹ́rìí láìsọ̀rọ̀ sí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “A kì yóò gbé inú rẹ̀ mọ́ láé.” Ìmúbọ̀sípò yòó wù tí a bá ṣe sí Bábílónì láti sọ ọ́ di ibi àṣèbẹ̀wòsí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ lè sún àwọn ènìyàn láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, ṣùgbọ́n “àtọmọdọ́mọ àti ìran àtẹ̀lé” Bábílónì ti pòórá títí láé.—Aísáyà 13:20; 14:22, 23.
Nípa báyìí, Aísáyà kò sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí kò ṣe kedere tí a lè mú kí ó bá ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí ṣáá mu lọ́jọ́ iwájú. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ tán ni ó kọ sílẹ̀ láti mú kí ó dà bí àsọtẹ́lẹ̀. Rò ó wò ná: Báwo ni afàwọ̀rajà kan yóò ṣe dáwọ́ lé “sísọ àsọtẹ́lẹ̀” ohun kan tí òun kò ní ní agbára ìdarí lé lórí rárá—pé Bábílónì alágbára ńlá yóò di ibi tí a kò ní gbé mọ́ láé?
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Bábílónì yí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan ṣoṣo láti inú Bíbélì ni.b Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n rí i pé ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé Bíbélì ní láti wá láti orísun kan tí ó ga ju ènìyàn lọ. Bóyá ìwọ yóò gbà pé, ó kéré pin, ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yí tó gbé yẹ̀ wò. Ohun kan dájú: Gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn àwítẹ́lẹ̀ tí ó rújú tàbí tí ó jẹ́ àf ìwàǹwárasọ ti àwọn aláfọ̀ṣẹ òde òní àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ó yéni yékéyéké, tí ó múni ronú jinlẹ̀, tí ó sì ṣe ṣàkó.
[Àwọ̀n àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gbankọgbì ẹ̀rí wà pé àwọn ìwé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù—títí kan Aísáyà—ni a ti kọ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Òpìtàn náà, Josephus (ti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa), fi hàn pé a ti parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọjọ́ tirẹ̀.8 Ní àfikún sí i, Septuagint ti Gírí ìkì, ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a túmọ̀ sí èdè Gírí ìkì, ni a bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹta ṣáájú Sànmánì Tiwa tí a sì parí rẹ̀ nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa.
b Fún àfikún ìjíròrò lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àwọn kókó inú ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń fìdí ẹ̀rí ìmúṣẹ wọn múlẹ̀, jọ̀wọ́ wo ojú iwé 117 sí 133 nínú ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
Ṣé wòlíì tí ó péye ni àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì jẹ́ tàbí ògbówọ́ aṣèrú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àlàpà Bábílónì ìgbàanì