Bawo Ni Awọn Isọtẹlẹ Bibeli Ti Ṣeegbarale Tó?
AWỌN iwe ìtàn pọ̀ rẹpẹtẹ lonii. Awọn irohin iṣẹlẹ nipa awọn ohun ti o ti ṣẹlẹ kọja wọnyi maa ń sábà jasi ọ̀kan ti o fanimọra niti gidi. Bi a ti ń kà wọn, awa lè woye pe a wà ninu ayika iṣẹ ìgbà atijọ. Iwoye wa lè ga soke fiofio bí awọn eniyan, agbegbe, ati iṣẹlẹ ti dabi eyi ti ń rúyọ lati inu awọn oju-iwe dídákẹ́rọ́rọ́ naa.
Bibeli jẹ iru iwe kan bẹẹ—ọkan ti ó kún fun awọn irohin iṣẹlẹ inú ìtàn ti ń runisoke. Nipasẹ awọn oju-iwe rẹ̀, awa lè di ojulumọ iru awọn ọkunrin ati obinrin bi Abrahamu, aya rẹ̀ Sara, Ọba Dafidi, Ayaba Esteri, ati Olukọ Nla naa, Jesu Kristi. Ní ọ̀nà kan-naa, awa lè rin pẹlu wọn, gbọ ohun ti wọn sọ, ki a sì rí ohun ti wọn rí. Ṣugbọn ọpọlọpọ ka Bibeli si ohun ti o fi pupọpupọ ju iwe ìtàn kan lọ. Wọn gbagbọ pe o ni ohun ti a ti pe ni ìtàn ti a ti kọ ṣaaju ninu. Eeṣe ti o fi ri bẹẹ? Nitori pe Bibeli kun fun awọn isọtẹlẹ, tabi asọtẹlẹ.
Sibẹ, bawo ni awọn isọtẹlẹ Bibeli ti ṣeegbarale to? Bi awọn asọtẹlẹ Bibeli bá ni imuṣẹ ninu awọn iṣẹlẹ ìgbà ti o ti kọja, kò ha yẹ ki awa reti pe ki iru awọn isọtẹlẹ bẹẹ nipa awọn iṣẹlẹ ọjọ iwaju ni imuṣẹ bi? Ẹ jẹ ki a wá ṣayẹwo awọn apẹẹrẹ diẹ nisinsinyi lati rí i bi awọn isọtẹlẹ Bibeli bá ṣeegbarale.
Israeli ati Assiria Lori Ìtàgé Ayé
Wolii Ọlọrun Isaiah, ẹni ti o bẹrẹ sii sọtẹlẹ ni nǹkan bii 778 B.C.E., sọtẹlẹ pe: “Ade igberaga, awọn ọmuti Efraimu [Israeli], ni a o fi ẹsẹ tẹ̀ mọlẹ: ati ògo ẹwà, ti o wà lori afonifoji ọlọ́ràá, yoo jẹ itanna rírọ, gẹgẹ bi eso ti o yara ṣaaju ìgbà ikore; eyi ti nigba ti ẹni ti o bá ń wò ó bá ri i, nigba ti o wà ni ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbé e mì.” (Isaiah 28:3, 4) Gẹgẹ bi a ti sasọtẹlẹ rẹ̀ yii, ni agbedemeji ọrundun kẹjọ B.C.E., olu-ilu Israeli, Samaria, ti dabi eso ọpọtọ pípọ́n ti a o ká ti a o sì gbémì nipasẹ awọn agbo ọmọ-ogun Assiria. Iyẹn gan-an ni ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti Assiria bori Samaria ni 740 B.C.E.—2 Ọba 17:6, 13, 18.
Bi akoko ti ń lọ, Assiria ni ọpọ́n sún kan lati di ilẹ-ọba ti o ti kọjalọ ninu ìtàn. Olu-ilu rẹ̀ jẹ́ Ninefe, ti o lokiki buruku tobẹẹ fun ṣíṣe awọn ti a kolẹru bí ọṣẹ́ ti ń ṣe ojú debi ti a fi pe e ni “ìlú ẹ̀jẹ̀ nì.” (Nahumu 3:1) Jehofa Ọlọrun funraarẹ ti paṣẹ iparun Ninefe. Fun apẹẹrẹ, nipasẹ wolii Nahumu, Ọlọrun wi pe: “Kiyesi i, emi dojukọ ọ . . . emi o sì sọ ọ di aláìmọ́, emi o sì gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹya. Yoo sì ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ́ yoo sá fun ọ, wọn ó sì wi pe, a ti fi Ninefe ṣòfò.” (Nahumu 3:5-7) Sefaniah pẹlu sasọtẹlẹ iparun Assiria ati isọdahoro Ninefe. (Sefaniah 2:13-15) Awọn asọtẹlẹ wọnyi ni imuṣẹ ni 632 B.C.E. nigba ti lairotẹlẹ, apapọ agbo ọmọ ogun ọba Babiloni Nabopolasar ati Cyaxares ara Media kó Ninefe ti o si pa á run wómúwómú—debi ti a kò fi mọ ọgangan ilu-nla naa mọ́ fun eyi ti o ju 2,000 ọdun lọ. Ijọba Babiloni ni o tẹle e lori ìtàgé ilẹ̀-ayé.
Iparun Babiloni Ni A Sọtẹlẹ
Bibeli sọ asọtẹlẹ pe Ilẹ-ọba Babiloni ni a o bìṣubú o sì sọ asọtẹlẹ bi ilu-nla olu-ilu rẹ̀, Babiloni, yoo ṣe ṣubu. Ní eyi ti o fẹrẹẹ tó ọrundun meji ṣaaju, wolii Isaiah kilọ pe Odò Euferate ni a o mú kí ó gbẹ. Ó ń ṣàn sọda Babiloni, ti awọn ẹnu ibode lẹba odò naa sì jẹ apa pataki aabo ilu naa. Asọtẹlẹ naa darukọ Kirusi gẹgẹ bi ajagunṣẹgun rẹ̀ ó sì ṣakọsilẹ pe “ilẹkun mejeeji” Babiloni kì yoo sí ní títì mọ́ awọn agboguntini naa. (Isaiah 44:27–45:7) Bẹẹ gẹgẹ, Ọlọrun ri sii pe awọn ilẹkun mejeeji Babiloni ti o wa lẹba Euferate ni a fi silẹ ni ṣíṣí lakooko àjọ̀dún kan ni alẹ́ ti awọn agbo ọmọ-ogun Kirusi Nla ṣe ikọlu naa. Nitori naa, laisi iṣoro, wọn gba aarin odò naa wọnu ilu-nla naa wọn sì kó Babiloni lẹ́rú.
Opitan naa Herodotus kọwe pe: “Kirusi . . . fi diẹ ninu awọn agbo ọmọ-ogun rẹ̀ si ibi ti Euferate ṣàn gbà wọ [Babiloni] ati awọn ọmọ-ogun miiran ni apa odikeji nibi ti o ti ṣàn jade, pẹlu àṣẹ fun awọn mejeeji lati fi ipa wọle si aarin odò naa gbara ti wọn bá ti rii pe omi naa ti lọsilẹ tó. . . . Nipasẹ ọ̀nà kan ti a là o dari odò naa lọ sinu adagun (eyi ti o jẹ́ àbàtà nigba naa) ati ni ọ̀nà yii o dín jíjìn omi ti o wà ni inu odò naa niti gidi kù lọpọlọpọ ti o fi jẹ pe o di eyi ti a lè wọ̀, ti awọn ọmọ ogun Persia, ti a ti fi silẹ ni Babiloni fun ète naa, sì wọnú odo naa, eyi ti jíjìn rẹ̀ nisinsinyi kò kọja agbedemeji itan, bi wọn si ti gba inu rẹ̀ kọja, wọn wọle sinu ilu naa. . . . Ajọdun kan ń lọ lọwọ, àní nigba ti ilu-nla naa ń wolulẹ wọn ń ba ijo lọ ti wọn si ń gbadun araawọn, titi fi di ìgbà ti wọn mọ ohun ti ń ṣẹlẹ niti gidi.”—Herodotus—The Histories, ti a ṣetumọ lati ọwọ́ Aubrey de Selincourt.
Ní alẹ́ ọjọ yẹn gan an, Danieli wolii Ọlọrun kilọ fun oluṣakoso Babiloni nipa ajalu ti o rọdẹdẹ. (Danieli, ori 5) Babiloni kan ti o rẹlẹ lagbara wà fun ọpọ ọrundun lẹhin naa. Lati ibẹ, fun apẹẹrẹ, aposteli Peteru kọ lẹta rẹ̀ akọkọ ti a misi ni ọrundun kin-in-ni C.E. (1 Peteru 5:13) Ṣugbọn asọtẹlẹ Isaiah ti sọ pe: “Babiloni . . . yoo dabi ìgbà ti Ọlọrun bi Sodomu oun Gomorra ṣubu. A kì yoo tẹ̀ ẹ́ dó mọ́.” Ọlọrun tun ti wi pe: “Emi o sì ké orukọ ati iyoku kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ ni Oluwa wi.” (Isaiah 13:19-22; 14:22) Gẹgẹ bi a ti sọtẹlẹ, ni ikẹhin Babiloni di òkìtì àlàpà. Imupadabọsipo eyikeyii ti ilu-nla atijọ yẹn lè gba afiyesi awọn arinrin-ajo ṣugbọn yoo ṣi fi i silẹ ninu ọ̀fọ̀ awọn “ọmọ, ati ọmọ de ọmọ” rẹ̀.
Danieli—wolii Jehofa tí ó wà ni Babiloni nigba ti o ṣubu—ri iran kan ti o ni awọn ará Media ati Persia oluṣẹgun ninu. Ó rí àgbò oniwo meji ati akọ ewurẹ kan ti o ni ìwo nla kan ni aarin oju rẹ̀. Ewurẹ naa kọlu àgbò naa o sì gbá a lulẹ, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ mejeeji. Lẹhin naa awọn ìwo nla ewurẹ naa ni a ṣẹ́, ti awọn ìwo mẹrin sì hù jade ni ipo rẹ̀. (Danieli 8:1-8) Gẹgẹ bi Bibeli ti sọtẹlẹ tí ìtàn sì jẹrii sí i, àgbò oniwo meji naa duro fun Media-oun-Persia. Akọ ewurẹ naa duro fun Greece. Ki sì ni nipa ti “ìwo nla” rẹ̀? Eyi jasi Aleksanda Nla. Nigba ti a ṣẹ́ ìwo nla iṣapẹẹrẹ naa, awọn ìwo iṣapẹẹrẹ (tabi, awọn ijọba) mẹrin rọpo rẹ̀. Gẹgẹ bi asọtẹlẹ naa ti fihan, lẹhin ti Aleksanda kú, mẹrin ninu awọn olori ogun rẹ̀ gbé araawọn sori aleefa—Ptolemy Lagus ni Egypt ati Palestine; Seleucus Nicator ni Mesopotamia ati Syria; Cassander ni Macedonia ati Greece; ati Lysimachus ni Thrace ati Asia Kekere.—Danieli 8:20-22.
Awọn Asọtẹlẹ Nipa Ọjọ Iwaju Dídányanran Kan
Awọn isọtẹlẹ Bibeli nipa iru awọn iṣẹlẹ bii ti isọdahoro Babiloni ati ibiṣubu Media-oun-Persia wulẹ jẹ́ awọn apẹẹrẹ ọpọ awọn asọtẹlẹ Iwe Mimọ ti o ti ní imuṣẹ ni awọn ìgbà ti o ti kọja ni. Bibeli tun ni awọn isọtẹlẹ nipa ọjọ iwaju dídányanran kan ninu, eyi ti yoo ní imuṣẹ nitori ti Messia naa, Ẹni Àmì-Òróró Ọlọrun.
Awọn isọtẹlẹ diẹ nipa Messia ninu awọn Iwe Mimọ Lede Heberu ni awọn onkọwe Iwe Mimọ Lede Griki mú bá Jesu Kristi mu. Fun apẹẹrẹ, awọn onkọwe Ihinrere ṣalaye pe Jesu ni a bí ni Betlehemu, gẹgẹ bi a ti sọtẹlẹ lati ẹnu wolii Mika. (Mika 5:2; Luku 2:4-11; Johannu 7:42) Ní imuṣẹ asọtẹlẹ Jeremiah, awọn ọmọ-ọwọ ni a pa lẹhin ìbí Jesu. (Jeremiah 31:15; Matteu 2:16-18) Awọn ọ̀rọ̀ Sekariah (9:9) ní imuṣẹ nigba ti Kristi wọ Jerusalemu lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan. (Johannu 12:12-15) Nigba ti awọn jagunjagun si pín asọ Jesu lẹhin ti a kàn án mọgi, eyi mú awọn ọ̀rọ̀ olorin naa ṣẹ pe: “Wọn pín aṣọ mi fun ara wọn, wọn si ṣẹ́ kèké lé aṣọ-ileke mi.”—Orin Dafidi 22:18.
Awọn isọtẹlẹ miiran nipa Messia naa tọka si akoko alayọ kan fun iran eniyan. Ninu iran, Danieli ri “ẹnikan bi ọmọ eniyan” ń gba ‘agbara ijọba, ati ògo, ati ijọba’ lati ọwọ́ Jehofa, “Ẹni-àgbà ọjọ naa.” (Danieli 7:13, 14) Nipa ti iṣakoso Messia Ọba ti ọrun yẹn, Jesu Kristi, Isaiah polongo pe: “A o sì maa pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Ayeraye, Ọmọ-Alade Alaafia. Ijọba yoo bi sii, alaafia kì yoo ni ipẹkun: lori ìtẹ́ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati maa tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati òdodo lati isinsinyi lọ, àní titi lae. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yoo ṣe eyi.”—Isaiah 9:6, 7.
Ṣaaju ki ijọba òdodo Messia tó bẹrẹ akoso lẹkun-unrẹrẹ, ohun kan ti o ṣe pataki gan-an gbọdọ ṣẹlẹ. Eyi pẹlu ni a sọtẹlẹ ninu Bibeli. Nipa ti Ọba Messia naa, olorin naa kọrin pe: “Sán idà rẹ mọ́ idi rẹ, Alagbara julọ, . . . ninu ọla-nla rẹ maa gẹṣin lọ ni alaafia, nitori otitọ ati iwatutu ati òdodo.” (Orin Dafidi 45:3, 4) Ní titọka si ọjọ wa, Iwe Mimọ tun sọtẹlẹ pe: “Ní ọjọ awọn ọba wọnyi ni Ọlọrun ọrun yoo gbé ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yoo lè parun titi lae: a kì yoo sì fi ijọba naa lé orilẹ-ede miiran lọwọ, yoo sì fọ́ tuutuu, yoo sì pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn oun ó duro titi laelae.”—Danieli 2:44.
Orin Dafidi 72 pese ìrítẹ́lẹ̀ṣaájú nipa awọn ipo ọjọ-iwaju labẹ iṣakoso Messia. Fun apẹẹrẹ, “ni ọjọ rẹ̀ ni awọn olódodo yoo gbilẹ: ati ọpọlọpọ alaafia niwọn bi oṣupa yoo ti pẹ́ tó.” (Ẹsẹ 7) Kì yoo si inilara tabi iwa-ipa. (Ẹsẹ 14) Ebi ki yoo pa ẹnikẹni, nitori pe “ìkúnwọ́ ọkà ni yoo maa wà lori ilẹ; lori awọn oke nla ni eso rẹ̀ yoo maa mì.” (Ẹsẹ 16) Sì wulẹ rò ó wò ná! Iwọ lè gbadun iwọnyi ati awọn ibukun miiran ninu paradise ilẹ̀-ayé kan nigba ti a bá ti fi ayé titun tí Ọlọrun ṣeleri rọ́pò eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi.—Luku 23:43; 2 Peteru 3:11-13; Ìfihàn 21:1-5.
Dajudaju, nigba naa, awọn isọtẹlẹ Bibeli yẹ fun ayẹwo rẹ. Nitori naa, eeṣe ti o kò beere lọwọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun isọfunni pupọ sii? Ayẹwo awọn asọtẹlẹ Bibeli lè ràn ọ́ lọwọ lati ri ibi ti a wà ninu ìṣàn àkókò. Ó tún lè gbe imọriri jijinlẹ ró ninu ọkan-aya rẹ fun Jehofa Ọlọrun ati iṣeto agbayanu rẹ̀ fun ibukun ayeraye ti gbogbo awọn ti wọn nifẹẹ ti wọn sì ṣe igbọran si i.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Iwọ ha mọ itumọ iran Danieli ti o ni akọ ewurẹ ati àgbò ninu bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Iwọ yoo ha wà nibẹ lati gbadun imuṣẹ awọn isọtẹlẹ Bibeli nipa igbesi-aye alayọ ninu paradise ilẹ̀-ayé kan bi?