ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 5/1 ojú ìwé 4-7
  • Bibeli—Atọ́nà Gbigbeṣẹ kan fun Eniyan Ode-oni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bibeli—Atọ́nà Gbigbeṣẹ kan fun Eniyan Ode-oni
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • To Iṣura Ọgbọ́n Gbigbeṣẹ Jọ
  • Ìwé Kan Tí Ó Wúlò Fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • A Lè Kápá Àìfararọ!
    Jí!—1998
  • Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Àníyàn Ṣíṣe Dá Ọ Lágara
    Jí!—2005
  • Ìdí Tí Bíbélì Fi Wúlò Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 5/1 ojú ìwé 4-7

Bibeli—Atọ́nà Gbigbeṣẹ kan fun Eniyan Ode-oni

“Gbogbo iwe mimọ ni a mísí nipasẹ Ọlọrun a sì lè lò ó lọna ti o ṣanfaani . . . fun ṣiṣamọna igbesi-aye awọn eniyan.”—2 Timoteu 3:16, “The Jerusalem Bible.”

IWE mimọ yii ṣalaye idi rẹ̀ gan-an ti Bibeli fi gbeṣẹ fun ọjọ wa. O ni imisi Ọlọrun. Niwọn bi Ọlọrun ti dá wa, kò si ẹni ti o mọ pupọ sii nipa ara, ọkàn, imọlara, ati aini wa ju bi oun ti ṣe lọ. Ọba Dafidi ti Israeli sọ nigba kan nipa Jehofa Ọlọrun pe: “Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wa laipe: ati ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si.” (Orin Dafidi 139:16) Bi Ẹlẹdaa wa bá mọ pupọ tobẹẹ nipa wa, nigba naa lọna ti o bá ọgbọn-ironu mu itọni ati imọran rẹ̀ nipa bi a ṣe lè jẹ́ alayọ ati alaṣeyọrisirere ninu igbesi-aye gbọdọ yẹ fun ayẹwo dajudaju.

Iriri ti fihàn pe awọn ilana Bibeli jẹ́ eyi ti a gbekari otitọ ti o si gbeṣẹ gidi fun ọjọ wa. Wọn tun ṣe pato bakan naa. Awọn apẹẹrẹ mẹrin ti o tẹlee yii fi ìgbéṣẹ̀ Bibeli lojoojumọ hàn.

Ipo-Ibatan Ẹda ati Ìwà Ẹnikọọkan: Bibeli gbé ofin eto ilana iwa-hihu rere kan eyi ti o lè ṣamọna si ipo-ibatan ọlọyaya, alaṣeyọrisirere pẹlu awọn ẹlomiran larugẹ. Fun apẹẹrẹ, a paṣẹ fun orilẹ-ede Israeli pe: “Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹẹ ni ki o maṣe ṣe ikunsinu . . . ṣugbọn ki iwọ ki ó fẹ́ ẹnikeji rẹ bi araarẹ.” (Lefitiku 19:18) Bi o tilẹ jẹ pe a kò fi wa sabẹ ofin awọn ọmọ Israeli, titẹle awọn ilana rẹ̀ ti o bá Bibeli mu ràn wá lọwọ lati wà ni alaafia pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa. Rò ó wò ná, fun apẹẹrẹ, awọn iṣoro meloo ni a le yanju bi gbogbo eniyan bá gbiyanju lati mú awọn animọ tẹmi ti a ri ninu Galatia 5:22, 23 dagba: “Eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwapẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.”—Fiwe Romu 8:5, 6.

Lọna ti o banininujẹ, nigba ti awọn ikimọlẹ igbesi-aye bá peléke, pákáǹleke ati èdèkòyedè maa ń dide lọpọ ìgbà. Ninu iru ipo bẹẹ, fifi awọn ọ̀rọ̀ oniṣọọra ti a ri ninu Owe 29:11 silo lè gbà wá lọwọ ọpọlọpọ iṣoro. “Aṣiwere a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọn a pa á mọ́ di ìgbà ikẹhin.”—Fiwe Owe 15:1; Matteu 7:12; Kolosse 3:12-14.

Imọran rere—ṣugbọn o ha ń ṣiṣẹ ninu igbesi-aye gidi bi? Wo ọ̀ràn ọkunrin kan ni France ti o ni iṣoro lilekoko kan pẹlu ọkàn ibinu rẹ̀. Laimọye ìgbà oun yoo bá araarẹ ninu iṣoro, àní ninu ọgbà ẹwọn paapaa, nitori lilọwọ ninu ija alariwo. Jíjẹ́ ogbontarigi akànṣẹ́ kan kò yanju iṣoro pẹlu. Ni akoko iṣẹlẹ kan ìjà bẹ́ silẹ laaarin ọkunrin yii ati baba rẹ̀. Kátówí-kátófọ̀, o ti fi ẹ̀ṣẹ́ kan dá baba rẹ̀ lágbàálẹ̀. Iyapa kikoro ninu ibatan wọn bẹsilẹ.

Ni akoko kan-naa, ọkunrin yii bá awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pade ó sì bẹrẹ sii kẹkọọ awọn ilana Bibeli. Eyi sun un lati fi ironujinlẹ wo ọ̀nà ti o ń gba bá awọn ẹlomiran lò. Pẹlu isapa ti o pọ̀ iwa rẹ̀ bẹrẹ sii yipada, ó sì tubọ jẹ́ alalaafia sii. Nigba ti o yá, ni ọjọ kan, ọkunrin naa pada lọ sọdọ baba rẹ̀ lati mú alaafia padabọsipo. Awọn iyipada ti ọmọkunrin rẹ̀ ti ṣe wọ baba rẹ̀ lọkan debi pe ipo-ibatan wọn ni a mu padabọsipo.

Eyi jẹ́ ọ̀kan ninu ọpọlọpọ awọn apẹẹrẹ awọn ti o jẹrii si otitọ ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pe: “Nitori ọ̀rọ̀ Ọlọrun yè, o sì ni agbara, o sì mú ju idakida oloju meji lọ . . . oun sì ni olumọ ero-inu ati ète-ọkan.”—Heberu 4:12.

Igbesi-Aye Idile: Idile rẹ ha jẹ́ alayọ bi? Ọpọlọpọ idile kò ri bẹẹ. “Pé igbesi-aye idile gẹgẹ bi igbekalẹ kan ni a ń halẹ mọ́ daju nisinsinyi,” ni The Natal Witness, iwe-irohin ilẹ South Africa kan sọ, ni fifikun un pe “a ń bi awọn ọmọ ode-oni sinu iyipada ẹgbẹ-oun-ọgba.”

Bi o ti wu ki o ri, Bibeli kun fọ́fọ́ fun imọran ti ó pé ti a ṣeto lati ran awọn idile lọwọ lati kẹsẹjari àní nigba ti awọn iṣoro bá dide paapaa. Niti ila-iṣẹ awọn ọkọ, fun apẹẹrẹ, Bibeli sọ pe: “Bẹẹ ni o tọ́ ki awọn ọkunrin ki ó maa fẹran awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikaraawọn.” Nigba ti ọkọ bá mu ohun ti a beere fun yii ṣẹ, o jẹ́ itẹlọrun fun aya rẹ̀ lati dahunpada nipa níní ‘ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun ọkọ rẹ̀.’ (Efesu 5:25-29, 33) Ipo-ibatan ti o wà laaarin awọn obi ati ọmọ ni a sọrọ lé lori ninu Efesu 6:4 pe: “Ati ẹyin baba, ẹ maṣe mú awọn ọmọ yin binu: ṣugbọn ẹ maa tọ́ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa.” Eyi, ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, ń ṣokunfa ayika idile kan ti ń mu ki o tubọ rọrun sii fun awọn ọmọ lati tẹle aṣẹ Bibeli ki wọn si jẹ́ onigbọran si awọn òbí wọn.—Efesu 6:1.

Ohun ti a sọ ṣaaju yii wulẹ jẹ́ kiki apẹẹrẹ àlàyé ọ̀rọ̀ Bibeli lori igbesi-aye idile ni. Nipa didahunpada si itọsọna Ọlọrun, ọpọ ti ri aṣeyọrisirere wọn sì ti gbadun ayọ ninu ile. Edward, baba awọn ọmọ meji, ṣalaye awọn anfaani ti oun gbadun nipa fifi awọn ilana Bibeli silo. “Igbeyawo mi ń wolulẹ,” ni o ranti. “N kò ni akoko lati ni ipo-ibatan ti o nitumọ pẹlu awọn ọmọ mi. Kiki ohun kanṣoṣo ti o mu ki a wà papọ ni fifi ti a fi ohun ti Bibeli ni lati sọ nipa igbesi-aye idile silo.”—Owe 13:24; 24:3; Kolosse 3:18-21; 1 Peter 3:1-7.

Ilera Nipa ti Ero-Ori, ti Ara, ati ti Ero-Imọlara: Iwadii ti fihàn pe, de iwọn aaye kan, ilera ẹnikan nipa ti ara ni o sopọ mọ́ ipo ilera ti ero-ori ati ero-imọlara rẹ̀. “Awọn ami masunmawo wiwọpọ,” ni The World Book Encyclopedia sọ, “ní ninu ìlùkìkì ọkàn-àyà ti o ga sii, ifunpa giga, igalara iṣu-ẹran, ikimọlẹ ti ọpọlọ, ati ailepọkanpọ.” Bi o ti wu ki o ri, awọn kan gbagbọ pe, fifi awọn igbesẹ oniwa-ipa danrawo jẹ́ ọ̀nà kan lati mu ki masunmawo dẹjú. “Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn lè jẹ adínmásùn-máwo-kù giga kan,” ni iwe-irohin ilẹ South Africa kan, The Star jẹwọ. O fa ọ̀rọ̀ ẹni àfọ̀rànlọ̀ kan lori ìdáṣáṣá ara Jannie Claasens yọ: “Bi obinrin kan bá ti ni oojọ ti ń janikulẹ lọna giga kan, ó lè tú pakanleke rẹ̀ jade nipa dída ẹ̀ṣẹ́ bo àpò kan.”

Bi o ti wu ki o ri, kò ha ni jẹ́ ohun ti o sàn jù fíìfíì lati kẹkọọ lati ṣekawọ gbongbo okunfa ijakulẹ bi? Ninu iwe-agberohinjade naa Stress—The Modern Scourge, Dokita Michael Slutzkin sọ pe “dídá masunmawo mọ̀ . . . ṣe pataki, nitori pe ọpọlọpọ ninu awọn okunfa rẹ̀ jẹ́ eyi ti a lè ṣatunṣe.” O fikun un pe “iṣekawọ masunmawo . . . tilẹ lè mu ki ọ̀nà àtiṣèwòsàn sunwọ̀n sii loniruuru ipo.”

Bibeli ṣalaye ọ̀nà gbigbeṣẹ gidi kan nipasẹ eyi ti a ti lè ṣekawọ masunmawo pe: “Ẹ maṣe aniyan ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo . . . ẹ maa fi ibeere yin hàn fun Ọlọrun. Ati alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ, yoo ṣọ́ ọkàn ati ero yin ninu Kristi Jesu.” (Filippi 4:6, 7) Ṣiṣekawọ masunmawo ni ọ̀nà yii ní ọpọlọpọ anfaani—ani ti nipa ara paapaa. Owe Bibeli kan sọ ọ́ ni ọ̀nà yii pe: “Àyà ti o yè korokoro ni ìyè ara.” (Owe 14:30) Owe miiran sọ pe: “Inu didun mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ.”—Owe 17:22.

Ninu igbidanwo lati jajabọ kuro lọwọ masunmawo ati ikimọlẹ, ọpọ gbarale taba, ọti lile, oogun. Ibajẹ ti iru isọdibaraku bẹẹ ń fà ni a ṣe akọsilẹ rẹ̀ daradara. Sibẹ, Bibeli ti fi ìgbà gbogbo jẹ́ agbẹnusọ fun pipa ara-ẹni mọ́ kuro ninu “gbogbo ẹgbin ti ara.” (2 Korinti 7:1; fiwe Owe 23:29-35.) Dajudaju, yiyẹra fun iru awọn aṣa pipanilara bẹẹ jẹ́ aabo gbigbeṣẹ kan ninu aye ode-oni.

Iṣẹ́, Owó, ati Ailabosi: Iwa ọ̀lẹ kò pé rí. “Ọ̀lẹ kò jẹ́ tú ilẹ̀ nitori òtútù; nitori naa ni yoo fi maa ṣagbe nigba ikore, ki yoo sì ni nǹkan,” ni Owe 20:4 sọ. Iṣẹ aṣekara, ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, lérè. “Ki ẹni ti ń jale maṣe jale mọ,” ni Efesu 4:28 sọ. Iwe mimọ yii fikun un pe o sàn lọpọlọpọ fun ẹnikan lati lọwọ ninu “laalaa, ki o maa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki oun ki o lè ni lati pín fun ẹni ti o ṣe alaini.”—Fiwe Owe 13:4.

Iwọ ha mọ pe awọn ilana Bibeli ni a lè fisilo àní paapaa ninu ipo-ibatan wa ni ibi iṣẹ bi? Awọn oṣiṣẹ, gẹgẹ bi “ọmọ-ọ̀dọ̀” ni akoko ti a kọ Bibeli, ṣe rere lati “gbọ́ ti awọn oluwa [wọn] nipa ti ara ni ohun gbogbo.” Awọn ọ̀gá, tabi “awọn oluwa,” ni ọwọ keji ẹwẹ, gbọdọ “fi eyi ti o tọ́ ti o si dọgba” fun awọn ti wọn gbàsíṣẹ́.—Kolosse 3:22-24; 4:1; fiwe 1 Peteru 2:18-20.

Ohun pupọ ni a sọ ninu Bibeli nipa awọn aṣa iṣowo alailabosi. Bi o tilẹ jẹ pe kò si lonii lọna ti ń banininujẹ, ailaboosi ni a maa ń damọ ti a si ń mọriri lọpọ ìgbà gẹgẹ bi animọ ti a lọkan-ifẹ si. Eyi ni ohun ti Bibeli tẹnumọ. Jesu sọ nigba kan ri pe: “Ẹni ti o bá ṣe oloootọ ni ohun kinnkinni, o ṣe oloootọ ni pupọ pẹlu: ẹni ti o bá sì ṣe alaiṣootọ ni ohun kinnkinni, o ṣe alaiṣootọ ni ohun pupọ pẹlu.”—Luku 16:10; fiwe Owe 20:10; 22:22, 23; Luku 6:31.

Ni orilẹ-ede Africa kan, olè jíjà ati ìwà ibajẹ pọ pupọ ni ile iṣẹ diamondi kan. Wọn pinnu lati fi ẹlomiran kan si abojuto. Awọn minista ijọba ni a sọ fun lati fi orukọ awọn wọnni ti wọn rò pe wọn yoo tọ́ fun ipo naa silẹ. Nigba ti igbimọ ijọba padepọ lati pinnu, orukọ naa ni a yọ kuro lọkọọkan, kiki nititori ìwa ibajẹ. Lẹhin-ọ-rẹhin, wọn dé ibi orukọ ti o gbẹhin lori itolẹsẹẹsẹ naa—ẹni ti ààrẹ funraarẹ yàn.

“Ṣugbọn oun kìí ṣe mẹmba ẹgbẹ oṣelu!” ni minista kan ṣatako.

Ààrẹ naa fesipada pe eyi kìí ṣe ipo oṣelu kan.

“Oun jẹ́ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa,” ni omiran sọ.

“Idi sì niyẹn ti o fi rí iṣẹ naa gbà,” ni ààrẹ sọ. O fikun un nigba naa pe: “A mọ̀ pe wọn jẹ́ alailabosi, eyi sì ni iru eniyan ti a nilo. A mọ̀ pe a lè gbẹkẹle e.”

Bẹẹni, awọn ti wọn fi ilana Bibeli silo lọpọ ìgbà maa ń rii pe eyi jẹ́ fun anfaani wọn àní ninu ayé ode-oni paapaa.

To Iṣura Ọgbọ́n Gbigbeṣẹ Jọ

A ti ṣagbeyẹwo kiki apẹẹrẹ kekere kan nipa ohun ti o tumọsi lati “rí imọ Ọlọrun.” (Owe 2:1-9) Ọpọ jantirẹrẹ imọran gbigbeṣẹ, ti o bá ipo ọ̀ràn mu ni a rí ninu Bibeli. Awọn ilana ti o niiṣe pẹlu imọtoto, jíjẹ́ òṣìṣẹ́kára, ibanisọrọpọ, ibalopọ takọtabo, ikọsilẹ, sísan owo-ori, kikoju awọn aidọgba ninu ọ̀nà igbahuwa, ati kikoju ipo òṣì wulẹ jẹ́ kiki diẹ ninu awọn apa igbesi-aye ti Bibeli gbeyẹwo ni. Araadọta-ọkẹ yoo jẹrii sii pe iyatọ ti o wa laaarin aṣeyọrisirere ati ikuna ninu igbesi-aye wọn ti dalori iwọn ti wọn fi awọn ilana Bibeli silo dé.

Nigba ti a mu igbeṣẹ Bibeli loju ẹsẹ dá wa loju, o tun nawọ ọpọlọpọ anfaani onigba pipẹ jade pẹlu. Fun apẹẹrẹ, Bibeli ṣeleri pe gbòǹgbò okunfa irora ati ijiya ninu ayé ode-oni ni a o tunṣe laipẹ nigba ti a bá dásí i latọrunwa.—Danieli 2:44; 2 Peteru 3:11-13; Ìfihàn 21:1-5.

Nitori naa, a rọ̀ ọ́ lati kẹkọọ bi o bá ti lè ṣe tó nipa Bibeli. Bi iwọ kò bá ni ẹ̀dà kan, rii daju pe o ni ẹyọ kan. Awọn òǹtẹ̀wé iwe-irohin yii yoo fi tidunnu-tidunnu ràn ọ́ lọwọ. Gẹgẹ bi ọpọ awọn ẹlomiran ti janfaani nipa fifi awọn àbá gbigbeṣẹ lati inu Bibeli silo, iwọ pẹlu ni a lè ranlọwọ lati mọriri iniyelori Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, nisinsinyi ati ni ọjọ-ọla.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bibeli jẹ́ amọna kan ti o gbeṣẹ fun mimu ki igbesi-aye idile jẹ́ alayọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́