ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/22 ojú ìwé 10-13
  • A Lè Kápá Àìfararọ!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Lè Kápá Àìfararọ!
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Tọ́jú Ara Rẹ
  • Di Àjọṣepọ̀ Gbígbámúṣé Mú
  • Máa Wá Àyè fún Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ
  • Fi Ojú Tí Ó Yẹ Wo Àìfararọ
  • Mú Ipò Tẹ̀mí Dàgbà
  • Ìrètí Tí Ó Dájú
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/22 ojú ìwé 10-13

A Lè Kápá Àìfararọ!

“Kò sí ìgbà tí a kò ní máa ní àìfararọ nínú ìgbésí ayé, ohun tí a sì ní láti máa yẹ̀ wò ní gidi ni ọ̀nà tí a ń gbà hùwà padà nípa rẹ̀ dípò gbígbìyànjú láti lé àìfararọ náà lọ.”—Leon Chaitow, olókìkí òǹkọ̀wé nípa ìlera.

BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yóò wà. Ẹ̀rí fi hàn kedere pé àkókò yẹn ni a ń gbé, nítorí pé—ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn—àwọn ènìyàn jẹ́ “ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.”—2 Tímótì 3:1-5.

Kò yani lẹ́nu pé níní ìwọ̀n ìparọ́rọ́ ọkàn-àyà ṣòro gan-an! Kódà, ó lè kan àwọn tí wọ́n gbìyànjú láti máa gbé ìgbésí ayé alálàáfíà pàápàá. Onísáàmù náà, Dáfídì, kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo.” (Sáàmù 34:19; fi wé 2 Tímótì 3:12.) Síbẹ̀, ohun púpọ̀ wà tí o lè ṣe láti dín àìfararọ kù kí ó má baà bò ọ́ mọ́lẹ̀ pátápátá. Gbé àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

Máa Tọ́jú Ara Rẹ

Máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ. Oúnjẹ tí ń ṣara lóore ń ní èròjà protein, èso, ewébẹ̀, yangan àti àwọn oríṣi ọkà mìíràn, àti oúnjẹ tí ń ti ara ẹran jáde nínú. Ṣọ́ra fún jíjẹ àwọn ìyẹ̀fun funfun tí a ti tún ṣe àti ògidì ọ̀rá. Ṣọ́ bí o ṣe ń jẹ iyọ̀, ṣúgà tí a ti tún ṣe, ọtí líle, àti kaféènì tó. Máa jẹ oúnjẹ tí ó sunwọ̀n, ó sì lè ṣeé ṣe kí àìfararọ má lè rí ọ gbé ṣe.

Máa ṣe eré ìmárale. Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “ara títọ́ ṣàǹfààní.” (1 Tímótì 4:8) Ní tòótọ́, eré ìmárale tí ó mọ níwọ̀n àmọ́ tí a ń ṣe déédéé—àwọn kan dámọ̀ràn ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀—ń mú ọkàn-àyà lágbára, ó ń mú ìgbékiri ẹ̀jẹ̀ sunwọ̀n sí i, ó ń dín ìpele èròjà cholesterol kù, ó sì ń dín ṣíṣeéṣe pé kí o ní àrùn ọkàn-àyà kù. Lékè gbogbo rẹ̀, eré ìmárale ń fi kún ipò ara líle, bóyá nítorí èròjà endorphin tí ń tú jáde nígbà tí a bá ń ṣe eré tí ó gba agbára.

Máa sùn tó. Àìróorunsùn ń fa àárẹ̀, ó sì ń dín agbára rẹ láti kápá àìfararọ kù. Bí o bá ní ìṣòro oorun sísùn, gbìyànjú láti máa sùn ní àkókò pàtó, kí o sì máa jí ní àkókò pàtó déédéé. Àwọn kan dámọ̀ràn pé kí a fi rírẹjú mọ sí 30 ìṣẹ́jú, kí ó má baà ṣèdíwọ́ fún oorun àsùndọ́kàn lálẹ́.

Máa ṣètò ara rẹ. Àwọn tí wọ́n ń ṣètò àkókò wọn ń lè kápá àìfararọ dáadáa. Láti ṣètò ara rẹ, kọ́kọ́ pinnu àwọn ojúṣe wo ló yẹ láti fi sí ipò kìíní. Lẹ́yìn náà, ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan kí o má baà pa ìwọ̀nyí tì.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 14:33, 40 àti Fílípì 1:10.

Di Àjọṣepọ̀ Gbígbámúṣé Mú

Máa gba ìtìlẹ́yìn. Ní àwọn àkókò tí ó kún fún àìfararọ, àwọn tí wọ́n ní ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ púpọ̀ ń jèrè ìwọ̀n ààbò díẹ̀ lòdì sí dídi ẹni tí ìṣòro bò mọ́lẹ̀. Wíwá ọ̀rẹ́ kan ṣoṣo tí a gbọ́kàn lé, tí a lè finú hàn lè ṣèrànwọ́ gan-an. Òwé Bíbélì kan sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Máa yanjú èdèkòyédè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) A fi ọgbọ́n tí ó wà nínú títètè yanjú aáwọ̀ dípò gbígbin ìbínú sínú hàn nínú ìwádìí kan tí a fi àwọn 929 ènìyàn tí wọ́n la ìkọlù àrùn ọkàn-àyà já ṣe. Àwọn tí ìwà jàgídíjàgan pọ̀ nínú ọ̀ràn wọn ni ó ṣeé ṣe ní ìlọ́po mẹ́ta pé kí ọkàn-àyà wọn dáwọ́ dúró láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó kọ́kọ́ ṣe wọ́n ju àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ onínú tútù lọ. Àwọn olùdásílẹ̀ ìwádìí náà sọ pé bí ó tilẹ̀ jọ pé ìbínú ni okùnfà tí ó lágbára jù lọ, èrò ìmọ̀lára òdì èyíkéyìí tí ó ré kọjá àlà, tí ń gbé ìlọsókè omi ìsúnniṣe àìfararọ lílágbára kiri nínú ara lè ní ìyọrísí kan náà. Òwe 14:30 sọ pé: “Owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.”—Òwe 14:30.

Máa wá àkókò fún ìdílé. A fún àwọn òbí ní Ísírẹ́lì láṣẹ láti lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n máa gbin àwọn ìlànà títọ́ sọ́kàn wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Ìdè tí ó jẹ́ ìyọrísí èyí fi kún ìṣọ̀kan ìdílé—ohun kan tí ó ṣeni láàánú pé kò sí lóde òní. Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn tọkọtaya kan tí àwọn méjèèjì ń ṣiṣẹ́ ń fi ìpíndọ́gba ìṣẹ́jú 3.5 péré bá àwọn ọmọ wọn ṣeré lójoojúmọ́. Síbẹ̀, ìdílé rẹ lè jẹ́ orísun ìrànwọ́ àti okun ńlá tí o bá ní àìfararọ. Ìwé kan lórí àìfararọ sọ pé: “Ìdílé ń fún ọ ní àǹfààní jíjẹ́ apá kan àwùjọ, tí ó mọ irú ẹni tí o jẹ́ ní gidi, tí ó sì fẹ́ràn rẹ lọ́nàkọnà, tí ń ṣètìlẹ́yìn ní ti èrò ìmọ̀lára fàlàlà. Àjọṣepọ̀ ìdílé jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà dídára jù lọ láti dín àìfararọ kù.”

Máa Wá Àyè fún Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ

Máa lo ìfòyebánilò. Ó ṣeé ṣe jù lọ fún ẹni tí ó máa ń fìgbà gbogbo lo ara rẹ̀ àti èrò ìmọ̀lára rẹ̀ jù láti ṣàárẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí ìsoríkọ́ má jìnnà sí i. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ni kókó pàtàkì ibẹ̀. Ọmọlẹ́yìn náà, Jákọ́bù, kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.” (Jákọ́bù 3:17; fi wé Oníwàásù 7:16, 17 àti Fílípì 4:5.) Kọ́ láti kọ àwọn ohun tí ó ju agbára rẹ lọ sílẹ̀.

Má máa fi ara rẹ wé ẹlòmíràn. Gálátíà 6:4 sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.” Bẹ́ẹ̀ ni, kódà nínú àwọn ọ̀ràn ìjọsìn pàápàá, Ọlọ́run kì í ṣe àwọn ìfiwéra tí kò bára dé, kí ó máa béèrè ju ohun tí ipò wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan fàyè gbà lọ. Ó ń tẹ́wọ́ gba àwọn ọrẹ àti ìrúbọ wa ‘ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kò ní.’—2 Kọ́ríńtì 8:12.

Máa wá àyè fún ìsinmi. Jésù pàápàá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣìṣẹ́kára ni òun jẹ́, ó wá àyè láti fún ara rẹ̀ àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nísinmi. (Máàkù 6:30-32) Òǹkọ̀wé tí a mí sí, tí ó kọ ìwé Oníwàásù lérò pé ìsinmi ń ṣàǹfààní. Ó ṣàkọsílẹ̀ pé: “Èmi alára sì gbóríyìn fún ayọ̀ yíyọ̀, nítorí pé aráyé kò ní nǹkan kan tí ó sàn lábẹ́ oòrùn ju pé kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n sì máa mu, kí wọ́n sì máa yọ̀, kí ó sì máa bá wọn rìn nínú iṣẹ́ àṣekára wọn ní àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé wọn, èyí tí Ọlọ́run tòótọ́ ti fi fún wọn lábẹ́ oòrùn.” (Oníwàásù 8:15) Ìtẹ́lọ́rùn tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè mú àjíǹde ara wá, kí ó sì ṣèrànwọ́ láti mú àìfararọ kúrò.

Fi Ojú Tí Ó Yẹ Wo Àìfararọ

Bí o bá wà nínú àwọn ipò àìfararọ:

Má máa sáré parí èrò sí pé Ọlọ́run kò fi ojú rere wò ọ́. Bíbélì wí fún wa pé Hánà, obìnrin olùṣòtítọ́ kan, “ní ìkorò ọkàn” (“ìbànújẹ́ ọkàn,” Revised Standard Version) fún ọ̀pọ̀ ọdún. (1 Sámúẹ́lì 1:4-11) Ní Makedóníà, Pọ́ọ̀lù “ń ní ìbànújẹ́ níhà gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 7:5, Byington) Kí Jésù tó kú, ó “wà nínú ìroragógó,” àìfararọ tí ó ní sì pọ̀ gan-an débi pé “òógùn rẹ̀ . . . wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń já bọ́ sí ilẹ̀.”a (Lúùkù 22:44) Àwọn wọ̀nyí jẹ́ olùṣòtítọ́ ìrànṣẹ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, bí o bá ní àìfararọ, kò sí ìdí kankan tí o fi ní láti parí èrò sí pé Ọlọ́run ti pa ọ́ tì.

Máa kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ipò tí ń mú ọ ní àìfararọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, òun ní láti fara da ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara,’ láìṣe àní-àní, ìṣòro àìlera kan tí ó fa àìfararọ púpọ̀ fún un. (2 Kọ́ríńtì 12:7) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ó lè wí pé: “Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní. Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:12, 13) Pọ́ọ̀lù kò gbádùn ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’ rẹ̀, àmọ́ nípa fífaradà á, ó kọ́ bí ó ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run fún okun.—Sáàmù 55:22.

Mú Ipò Tẹ̀mí Dàgbà

Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí o sì máa ṣàṣàrò nínú rẹ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣàṣàrò nínú rẹ̀ ṣe pàtàkì. Lọ́pọ̀ ìgbà, nípa fífi aápọn wá inú Ìwé Mímọ́, a ń rí ọ̀rọ̀ ìṣírí tí ó bá a mu gẹ́lẹ́ tí a nílò láti lo ọjọ́ náà. (Òwe 2:1-6) Onísáàmù náà ṣàkọsílẹ̀ pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ [ti Ọlọ́run] ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”—Sáàmù 94:19.

Máa gbàdúrà déédéé. Pọ́ọ̀lù ṣàkọsílẹ̀ pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni, “àlàáfíà Ọlọ́run” lè borí ìmọ̀lára wa tí ó ní ìdààmú kí ó sì mú un dúró déédéé, kódà nígbà tí a bá nílò “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” pàápàá.—2 Kọ́ríńtì 4:7.

Máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Ìjọ Kristẹni ń ṣe ètò ìtìlẹ́yìn tí ó níye lórí, nítorí pé a gba àwọn tí wọ́n wà nínú rẹ̀ níyànjú láti ‘máa gba ti ara wọn rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí wọ́n máa fún ara wọn ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.” Pẹ̀lú ìdí rere, Pọ́ọ̀lù wí fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n jẹ́ Hébérù láti má ‘máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀.’—Hébérù 10:24, 25.

Ìrètí Tí Ó Dájú

Òtítọ́ ni pé dídín àìfararọ kù sábà máa ń ju ọ̀ràn títẹ̀lé ìlànà rírọrùn kan lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ń béèrè ìyípadà pàtàkì nínú ìrònú. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè ní láti kọ́ àwọn ọ̀nà tuntun tí ó ní láti máa gbà hùwà padà sí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí i kí wọ́n má baà bò ó mọ́lẹ̀ pátápátá. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìwọ̀n ìṣelemọ́lemọ́ tàbí bí àìfararọ náà ṣe le tó lè mú kí ó di ọ̀ranyàn láti gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ oníṣègùn tí ó dáńgájíá.

Dájúdájú, kò sí ẹnì kankan lónìí tí ó ní ìgbésí ayé tí ó bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àìfararọ tí ń pani lára. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò darí àfiyèsí rẹ̀ síhà àwọn ẹ̀dá ènìyàn láìpẹ́, yóò sì mú àwọn ipò tí ń mú àìfararọ tí ń pa wọ́n lára púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ kúrò. Nínú Ìṣípayá 21:4, a kà pé, Ọlọ́run yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Lẹ́yìn náà, ìràn ènìyàn olódodo yóò máa gbé ní àìséwu. Wòlíì Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wá rìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”—Míkà 4:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìròyìn ti sọ pé, àwọn ènìyàn làágùn ẹlẹ́jẹ̀, nínú àwọn ọ̀ràn àìfararọ ti èrò orí tí ó légbá kan. Fún àpẹẹrẹ, nínú hematidrosis, ènìyàn máa ń la òógùn ẹlẹ́jẹ̀ tàbí ohun aláwọ̀ ẹ̀jẹ̀ tàbí òógùn ara tí ẹ̀jẹ̀ pa pọ̀ mọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò lè fọwọ́ sọ̀yà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Jésù.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

Àìfararọ àti Iṣẹ́ Abẹ

Àwọn oníṣègùn kan máa ń ronú nípa ìwọ̀n àìfararọ tí àwọn tí wọ́n ń tọ́jú ní kí wọ́n tó lọ ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn. Fún àpẹẹrẹ, Dókítà Camran Nezhat, oníṣẹ́ abẹ kan, sọ pé:

“Bí ẹnì kan tí a ti ṣètò láti ṣiṣẹ́ abẹ fún bá sọ fún mi pé jìnnìjìnnì mú òun lọ́jọ́ náà, tí kò sì fẹ́ kí a ṣe iṣẹ́ abẹ fún òun nínú ipò yẹn, n óò fagi lé iṣẹ́ abẹ náà.” Èé ṣe? Nezhat ṣàlàyé pé: “Gbogbo oníṣẹ́ abẹ ló mọ̀ pé àwọn ènìyàn tí ìbẹ̀rùbojo máa ń ṣe gan-an máa ń ní ìṣòro tí a bá ṣe iṣẹ́ abẹ fún wọn. Ẹ̀jẹ̀ máa ń dà jù lára wọn, wọ́n máa ń ní àkóràn àti ìṣòro púpọ̀. Ó máa ń ṣòro gan-an fún wọn láti kọ́fẹ padà. Ó sàn jù nígbà tí ara wọn bá balẹ̀.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Mímú ipò tẹ̀mí dàgbà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sinmẹ̀dọ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Bíbójútó ìlera rẹ ń dín àìfararọ kù

Ìsinmi

Oúnjẹ tí ń ṣara lóore

Eré ìmárale

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́