ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 1 ojú ìwé 8-13
  • Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Da Àníyàn Tọ̀la Pọ̀ Mọ́ Tòní
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Àfojúsùn Rẹ Ga Jù
  • Mọ Ohun Tó Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè
  • Máa Ṣe Nǹkan Létòlétò
  • Má Ṣe Ju Ara Ẹ Lọ
  • Máa Tọ́jú Ara Rẹ
  • Mọ Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù
  • Wá Ìrànwọ́
  • Wá Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 1 ojú ìwé 8-13
Obìnrin kan tí inú ẹ̀ ń dùn tí ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀ ń lọ láàárín ìlú ńlá.

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn

Tó o bá fẹ́ kojú àìbalẹ̀ ọkàn, máa ronú nípa ìlera rẹ, bó o ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn, àwọn àfojúsùn rẹ àtàwọn ohun tó o kà sí pàtàkì jù. Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé àwọn ìlànà mélòó kan tó máa jẹ́ kó o lè kojú àìbalẹ̀ ọkàn tàbí kó o dín in kù.

Má Ṣe Da Àníyàn Tọ̀la Pọ̀ Mọ́ Tòní

Obìnrin kan tí inú ẹ̀ ń dùn tí ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀ ń lọ láàárín ìlú ńlá.

“Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀.”​—MÁTÍÙ 6:34.

Ohun tó túmọ̀ sí: Kò sí báwa èèyàn ò ṣe ní máa ṣàníyàn. Àmọ́, tó o bá kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn, ńṣe lò ń dá kún àníyàn rẹ. Torí náà, má ṣe da àníyàn tọ̀la pọ̀ mọ́ tòní.

  • Àníyàn máa ń fa àìbalẹ̀ ọkàn. Torí náà, máa fi ohun méjì yìí sọ́kàn: Àkọ́kọ́, gbà pé kì í ṣe gbogbo ohun tó ń kóni lọ́kàn sókè lo lè yẹra fún pátápátá. Tó o bá ń dààmú lórí àwọn nǹkan tó kọjá agbára rẹ, ọkàn ẹ ò ní balẹ̀. Ohun kejì tó yẹ kó o fi sọ́kàn ni pé ohun téèyàn ń bẹ̀rù pé ó máa ṣẹlẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àfojúsùn Rẹ Ga Jù

“Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.”​—JÉMÍÌSÌ 3:17.

Ohun tó túmọ̀ sí: Má ṣe jẹ́ adára-mákù-síbì-kan. Má ṣe jẹ́ kí àfojúsùn rẹ ga jù, má sì retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì.

  • Mọ̀wọ̀n ara rẹ, kí àfojúsùn rẹ má ga jù, kó o má sì retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara rẹ àti lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dín wàhálà rẹ kù, wàá sì ṣe ara rẹ àtàwọn ẹlòmíì láǹfààní. Ohun míì tí wàá ṣe ni pé, kó o máa pa ara rẹ lẹ́rìn-ín. Tí nǹkan ò bá tiẹ̀ lọ bó o ṣe fẹ́, tó o bá rẹ́rìn-ín, ọkàn rẹ á fúyẹ́, ìyẹn á sì jẹ́ kí ara rẹ yá gágá.

Mọ Ohun Tó Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè

‘Ẹni tó ní òye kì í gbaná jẹ.’​—ÒWE 17:27.

Ohun tó túmọ̀ sí: Téèyàn bá gbaná jẹ, ìyẹn kéèyàn bínú sódì, kò ní jẹ́ kéèyàn ronú lọ́nà tó tọ́. Torí náà, sapá kó o máa ṣe sùúrù.

  • Mọ ohun tó máa ń kó ẹ lọ́kàn sókè àti bó o ṣe máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tí ohun kan bá kó ẹ lọ́kàn sókè, fiyè sí èrò tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn, bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ àti ìwà rẹ, o tiẹ̀ lè kọ wọ́n sílẹ̀. Tó o bá túbọ̀ mọ bó o ṣe máa ń ṣe nígbà tí nǹkan bá kó ẹ lọ́kàn sókè, wàá lè mọ bó o ṣe máa kojú àìbalẹ̀ ọkàn. Bákan náà, ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o lè gbà yẹra fún àwọn ohun tó ń kóni lọ́kàn sókè. Tí ìyẹn ò bá ṣeé ṣe, wá àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà dín ìdààmú tí wọ́n ń fà kù, bóyá kó o máa bójú tó iṣẹ́ rẹ lọ́nà tó já fáfá tàbí kó o máa lo àkókò rẹ lọ́nà tó túbọ̀ ṣàǹfààní.

  • Gbìyànjú láti fi ojú míì wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè lè má kó ẹlòmíì lọ́kàn sókè. Ohun tó fà á ni pé ojú tẹ́ ẹ fi ń wo nǹkan yàtọ̀ síra. Jẹ́ ká wo ohun mẹ́ta tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:

    1. Má ṣe rò pé ohun tó burú ló wà lọ́kàn ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè sáré bọ́ síwájú rẹ nígbà tó o wà lórí ìlà. Tó o bá rò pé ìwà ògbójú ló hù yẹn, ó lè mú kínú bí ẹ. Dípò kó o rò bẹ́ẹ̀, gbà pé kì í ṣe èèyàn burúkú. Ó sì lè má jẹ́ èèyàn burúkú lóòótọ́!

    2. Máa wo àǹfààní tó wà nínú ipò tó o wà. Tó o bá ń dúró de ìgbà tí dókítà màá pè ẹ́ wọlé fún ìtọ́jú tàbí ò ń dúró níbi tó o ti fẹ́ wọkọ̀ òfúrufú, o ò ṣe máa ka ìwé kan tàbí kó o wo díẹ̀ lára ohun tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ yẹn, o sì lè máa wo lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà rẹ, ìyẹn ò ní jẹ́ kó sú ẹ tàbí kó dà bíi pé ò ń fi àkókò rẹ ṣòfò.

    3. Máa ronú jinlẹ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ìṣòro yìí ṣì lè jẹ́ nǹkan bàbàrà lọ́la tàbí lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀?’ Fìyàtọ̀ sáàárín ìṣòro tó le àtèyí tí kò le tàbí èyí tó máa ń wà fún ìgbà díẹ̀.

Máa Ṣe Nǹkan Létòlétò

Obìnrin kan ń fi fóònù wo ètò tó ṣe fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

“Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.”​—1 KỌ́RÍŃTÌ 14:40.

Ohun tó túmọ̀ sí: Máa wà létòlétò nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe.

  • Gbogbo wa la mọyì kí nǹkan wà létòlétò. Àmọ́, ohun tí kì í jẹ́ kí nǹkan wà létòlétò, tó sì máa ń fa àìbalẹ̀ ọkàn ni téèyàn bá ń fi nǹkan falẹ̀, èyí sì máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ pọ̀ nílẹ̀ láìparí wọn. Ohun méjì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ rèé:

    1. Ṣètò ohun tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o sì rí i dájú pé o ṣe wọ́n.

    2. Mọ ohun tó máa ń jẹ́ kó o fi nǹkan falẹ̀, kó o sì ṣàtúnṣe.

Má Ṣe Ju Ara Ẹ Lọ

“Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”​—ONÍWÀÁSÙ 4:6.

Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn tó máa ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kì í jèrè “ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára” tí wọ́n ṣe, torí pé á ti rẹ̀ wọ́n débi pé wọn ò ní lágbára tàbí àkókò láti gbádùn èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

  • Má ṣiṣẹ́ àṣejù nítorí owó. Kéèyàn lówó rẹpẹtẹ kò ní kéèyàn láyọ̀, kò sì ní kéèyàn ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Òótọ́ pọ́ńbélé nìyẹn. Oníwàásù 5:12 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ọlọ́rọ̀ ní kì í jẹ́ kó rí oorun sùn.” Torí náà, ṣe bí o ti mọ, má sì ná ju iye tó ń wọlé fún ẹ.

  • Máa sinmi dáadáa. Tó o bá ń ṣe eré ìnàjú tó o gbádùn, ara máa tù ẹ́. Àmọ́, tó o bá ń wo eré ìnàjú tí ìwọ fúnra rẹ ò kópa níbẹ̀, irú bíi wíwo tẹlifíṣọ̀n, kò ní mára tù ẹ́.

  • Lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ́nà tó tọ́. Má ṣe máa yẹ àwọn lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà wò lemọ́lemọ́, títí kan àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí kó o máa lọ sórí ìkànnì àjọlò léraléra. Tó o bá ti délé lẹ́yìn iṣẹ́, má ṣe yẹ ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ wò lórí kọ̀ǹpútà rẹ àyàfi tó bá pọn dandan.

Máa Tọ́jú Ara Rẹ

Ọ̀dọ́kùnrin kan ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe ń sáré níta.

‘Àǹfààní wà nínú eré ìmárale.’ ​—1 TÍMÓTÌ 4:8.

Ohun tó túmọ̀ sí: Tó o bá ń ṣeré ìmárale déédéé, á mú kí ìlera rẹ dára sí i.

  • Máa ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ara rẹ le. Tó o bá ń ṣe eré ìmárale, ara ẹ á jí pépé, èyí á sì mú kí ara rẹ balẹ̀. Máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó o sì máa jẹun lásìkò tó yẹ kó o jẹ ẹ́. Rí i dájú pé ò ń sinmi dáadáa.

  • Máa yẹra fún àwọn nǹkan tó lè dá kún àìbalẹ̀ ọkàn rẹ, irú bíi sìgá mímu, ìlòkulò oògùn àti ọtí àmujù, torí pé níkẹyìn, ńṣe làwọn nǹkan yìí máa dá kún ìṣòro rẹ. Wọ́n lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ tàbí kí wọ́n kó ẹ sí gbèsè.

  • Tí ìdààmú ọkàn rẹ bá fẹ́ pọ̀ jù, lọ rí dókítà rẹ. Fi sọ́kàn pé kì í ṣe nǹkan ìtìjú láti ṣe bẹ́ẹ̀.

    FI INÚURE ṢẸ́GUN ÀÌBALẸ̀ ỌKÀN

    “Ẹni tó ń ṣoore ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní, àmọ́ ìkà èèyàn ń fa wàhálà bá ara rẹ̀.” ​—ÒWE 11:17.

    Ìwé kan tó ń jẹ́ Overcoming Stress ní àkòrí kan tó ní kéèyàn fi inúure ṣẹ́gun àìbalẹ̀ ọkàn. Dókítà Tim Cantopher tó ṣe ìwé náà sọ pé tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, ìlera rẹ á máa dára sí i, wàá sì máa láyọ̀. Àmọ́, ẹni tí kò láàánú tàbí ẹni tó burú kì í láyọ̀ torí ńṣe làwọn èèyàn á máa sá fún un.

    Tá ò bá lo ara wa nílòkulò, ara máa tù wá. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa ṣe ohun tí agbára wa ò gbé tàbí ká ní àfojúsùn tí ọwọ́ wa kò lè tẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni a ò ní máa rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Jésù Kristi sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”​—Máàkù 12:31.

Mọ Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

“Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—FÍLÍPÌ 1:10.

Ohun tó túmọ̀ sí: Fara balẹ̀ ronú nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.

  • Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe, kó o wá tò wọ́n bí wọ́n ṣe ṣe pàtàkì tó. Èyí á jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ṣe pàtàkì jù, á sì jẹ́ kó o mọ èyí tó yẹ kó o ṣe nígbà míì, èyí tó yẹ kó o gbé fún ẹlòmíì àtèyí tí kò yẹ kó o ṣe rárá.

  • Ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o lo àkókò rẹ fún ní ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, wo bó o ṣe lè túbọ̀ máa lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára. Tó o bá ń fiyè sí ọ̀nà tó ò ń gbà lo àkókò rẹ, wàhálà rẹ á dín kù.

  • Wá àkókò tí wàá máa fi sinmi. Kódà tó o bá sinmi díẹ̀, á mú kí ara ẹ jí pépé, á sì mú kí ara ẹ balẹ̀.

Tọkọtaya kan ń gbádùn àkókò alárinrin pẹ̀lú ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

Wá Ìrànwọ́

“Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.”​—ÒWE 12:25.

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọ̀rọ̀ rere tó ń mára tuni táwọn èèyàn bá sọ fún ẹ lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀.

  • Bá ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ rẹ yé sọ̀rọ̀. Ẹnì kan tó o fọkàn tán lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fojú míì wo ọ̀rọ̀ náà tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ kó o rí ojútùú kan tó ò kà sí tẹ́lẹ̀. Tó o bá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ jáde, ara máa tù ẹ́.

  • Jẹ́ káwọn èèyàn ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ṣó o lè gbé iṣẹ́ náà fún ẹnì kan tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣe é?

  • Bí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá ń ni ẹ́ lára, wá àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti mú kí àárín yín gún régé sí i. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè rọra fọgbọ́n sọ fún un pé àwọn nǹkan kan wà tó máa ń ṣe tí kò bá ẹ lára mu? (Òwe 17:27) Bí nǹkan ò bá yàtọ̀ lẹ́yìn tó o ṣe bẹ́ẹ̀, ṣó o lè dín àkókò tó ò ń lò pẹ̀lú ẹni náà kù?

Wá Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run

Ọkùnrin oníṣòwò kan ń gbàdúrà níbi iṣẹ́.

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”​—MÁTÍÙ 5:3.

Ohun tó túmọ̀ sí: Torí pé èèyàn ni wá, kì í ṣe oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé nìkan la nílò. A nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Tá a bá fẹ́ láyọ̀, a gbọ́dọ̀ máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ká sì máa tẹ̀ lé e.

  • Àdúrà máa ń ranni lọ́wọ́ gan-an. Ọlọ́run rọ̀ ẹ́ pé kó o ‘kó gbogbo àníyàn rẹ wá sọ́dọ̀ òun, torí òun ń bójú tó ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Tó o bá ń gbàdúrà tó o sì ń ṣàṣàrò, wàá ní àlàáfíà ọkàn.​—Fílípì 4:6, 7.

  • Máa ka àwọn ohun tó lè mú kó o sún mọ́ Ọlọ́run. lnú Bíbélì làwọn ìlànà tá a sọ nínú ìwé yìí ti wá, wọ́n kọ Bíbélì kó lè mú wá sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn ìlànà náà tún lè mú kéèyàn ní “ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè.” (Òwe 3:21) Ṣó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ láti máa ka Bíbélì? O lè bẹ̀rẹ̀ látinú ìwé Òwe.

AGBÁRA TÍ ÌDÁRÍJÌ NÍ

“Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀, ẹwà ló sì jẹ́ fún un pé kó gbójú fo àṣìṣe.”​—ÒWE 19:11.

Dókítà Loren Toussaint sọ nínú ìwé náà Journal of Health Psychology pé: “Àìbalẹ̀ ọkàn máa ń ṣàkóbá [fún ìlera ẹni], àmọ́ téèyàn bá lẹ́mìí ìdáríjì ìlera rẹ̀ á máa dáa sí i.” Ó tún sọ pé: “Ìdáríjì ni pé kéèyàn má ṣe bínú sẹ́ni tó ṣẹ̀ ẹ́ mọ́, kó sì máa ṣe dáadáa sí onítọ̀hún.” Torí náà, kókó ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé téèyàn bá lẹ́mìí ìdáríjì, “ó máa ń dín àìbalẹ̀ ọkàn kù.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́