ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 1 ojú ìwé 14-15
  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ọkàn Gbogbo Èèyàn Máa Balẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ọkàn Gbogbo Èèyàn Máa Balẹ̀
  • Jí!—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2020
  • Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
    Jí!—2019
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 1 ojú ìwé 14-15
Ọ̀dọ́kùnrin kan àti bàbá rẹ̀ ń ṣeré níbi ìgbì òkun, nígbà tí ìyá àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ń gbádùn bí wọ́n ṣe ń wo òkun.

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ọkàn Gbogbo Èèyàn Máa Balẹ̀

Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ohun tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn. A ò lágbára láti yanjú gbogbo ohun tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn. Àmọ́ Ẹlẹ́dàá wa lè yanjú ẹ̀. Kódà, ó ti yan ẹnì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́. Jésù Kristi ni ẹni náà. Láìpẹ́, ó máa ṣe àwọn ohun ìyanu tó máa ju gbogbo ohun tó ṣe nígbà tó wá sáyé lọ, kárí ayé sì ni. Bí àpẹẹrẹ:

JÉSÙ FI HÀN PÉ ÒUN MÁA MÚ ÀWỌN ALÁÌSÀN LÁRA DÁ.

Wọ́n “gbé gbogbo àwọn tí onírúurú àìsàn ń ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀ . . . , ó sì wò wọ́n sàn.”​—MÁTÍÙ 4:24.

JÉSÙ MÁA PÈSÈ ILÉ ÀTI OÚNJẸ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN.

“Wọ́n [àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba Kristi] á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn. Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé, wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.” ​—ÀÌSÁYÀ 65:21, 22.

ÌJỌBA JÉSÙ MÁA MÚ ÀLÀÁFÍÀ ÀTI ÀÀBÒ WÁ KÁRÍ AYÉ.

“Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́. Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò dé àwọn ìkángun ayé. . . . Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.” ​—SÁÀMÙ 72:7-9.

JÉSÙ MÁA MÚ ÌRẸ́JẸ KÚRÒ.

“Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà, yóò sì gba ẹ̀mí àwọn tálákà là. Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”​—SÁÀMÙ 72:13, 14.

JÉSÙ TÚN MÁA MÚ ÌYÀ ÀTI IKÚ PÀÁPÀÁ KÚRÒ.

“Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—ÌFIHÀN 21:4.

“ÀKÓKÒ TÍ NǸKAN MÁA LE GAN-AN, TÓ SÌ MÁA NIRA”

“Àkókò yìí ni àìbalẹ̀ ọkàn, àníyàn, ìbànújẹ́ àti ìrora pọ̀ jù lọ nínú ìtàn aráyé.”​—Mohamed S. Younis, olórí ilé iṣẹ́ ìwádìí Gallup.

Kí nìdí tí àìbalẹ̀ ọkàn fi pọ̀ gan-an láyé? Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tó bọ́gbọ́n mú jù lọ. Ó sọ ní 2 Tímótì 3:1 pé: “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.” Bíbélì wá ṣàlàyé ìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi rí bẹ́ẹ̀, ó sọ pé ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù ló fà á. Ara àwọn ìwà burúkú náà ni ojúkòkòrò, ìgbéraga, àgàbàgebè nínú ẹ̀sìn, ìwà ipá, àìsí ìfẹ́ nínú ìdílé àti àìsí ìkóra-ẹni-níjàánu. (2 Tímótì 3:​2-5) Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn máa dópin nígbà tí Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso gbogbo ayé láti ọ̀run.​—Dáníẹ́lì 2:44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́