ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g19 No. 1 ojú ìwé 12-15
  • Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jí!—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌGBÀ WO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO?
  • BÁWO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN ṢE MÁA BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO?
  • BÁWO LO ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌṢÀKÓSO YẸN?
  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
Jí!—2019
g19 No. 1 ojú ìwé 12-15
Àwọn èèyàn ń gbádùn ara wọn nínú Párádísè

BÍ ÌṢÒRO NÁÀ ṢE MÁA YANJÚ PÁTÁPÁTÁ

Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé, ó sì máa mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ kárí ayé. Ọlọ́run ṣèlérí nínú Sáàmù 72:7 pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà” máa wà. Àmọ́ ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé? Báwo ló ṣe máa ṣe é? Báwo sì ni o ṣe lè jàǹfààní nínú ìṣàkóso yẹn?

ÌGBÀ WO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO?

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì máa wáyé tó máa fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó para pọ̀ jẹ́ “àmì” náà ni ogun kárí ayé, ìyàn, àìsàn, ọ̀pọ̀ ìmìtìtì ilẹ̀, àti ìwà àìlófin tó máa gbòde kan.​—Mátíù 24:3, 7, 12; Lúùkù 21:11; Ìṣípaya 6:2-8.

Àsọtẹ́lẹ̀ míì tún sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-4) Lóòótọ́, àwọn ìwà yìí ò ṣàjèjì sí wa, àmọ́ ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń peléke sí i báyìí.

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ṣẹ láti ọdún 1914. Kódà, àwọn òpìtàn, àwọn àgbà òṣèlú, àti àwọn òǹkọ̀wé sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì yẹn ṣe mú kí ayé yí pa dà láti ọdún 1914. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Denmark kan tó ń jẹ́ Peter Munch sọ pé: “Ogun tó wáyé ní ọdún 1914 jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gbòógì kan tó yí ìtàn ìran ẹ̀dá èèyàn pa dà pátápátá. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn èèyàn ń gbé ní ìrọ̀rùn dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa sí i, . . . àmọ́ láti ọdún yẹn ni aráyé ti kàgbákò. Wàhálà, ìkórìíra àti ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú gbòde kan, kò sì sí ààbò mọ́.”

Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ kan ni pé ohun tó le ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀. Ó ṣe tán, adùn ní í gbẹ̀yìn ewúro. Torí pé ńṣe ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ń jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé. Jésù tún wá fi ìṣẹ̀lẹ̀ rere kan kún ara àmì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti dé. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”​—Mátíù 24:14.

Ìhìn rere yẹn ni lájorí ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù fún aráyé. Kódà, orúkọ ìwé ìròyìn wa tí àwọn èèyàn mọ̀ jù ni Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Ìwé yẹn sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé wa yìí.

BÁWO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN ṢE MÁA BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO?

Àwọn kókó pàtàkì mẹ́rin yìí máa ṣàlàyé:

  1. Ìjọba yẹn kò ní yan èyíkéyìí lára àwọn olóṣèlú ayé yìí láti ṣàkóso.

  2. Àwọn olóṣèlú ayé yìí kò ní fẹ́ gbà pé kí Ìjọba Ọlọ́run gba àkóso nítorí pé wọ́n á fẹ́ máa ṣàkóso lọ.​—Sáàmù 2:2-9.

  3. Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run pátápátá, á sì fòpin sí àkóso wọn lórí aráyé. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 19:17-21) Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.​—Ìṣípayá 16:14, 16.

  4. Gbogbo àwọn tó bá fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ló máa la Amágẹ́dọ́nì já, tí wọ́n á sì wọ inú ayé tuntun. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa là á já, àwọn sì ni Bíbélì pè ní “ogunlọ́gọ̀ ńlá.”​—Ìṣípayá 7:9, 10, 13, 14.

    ÀWỌN NǸKAN WO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA ṢE?

    Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa ṣe tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ó mú àwọn aláìsàn àti àwọn arọ lára dá. (Mátíù 4:23) Ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. (Máàkù 6:35-44) Ó tún fi hàn pé òun lágbára lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá bí ìjì.​—Máàkù 4:37-41.

    Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀

    Jésù tún kọ́ àwọn èèyàn bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. Gbogbo àwọn tó bá fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ohun tó sọ tí wọ́n sì fi sílò máa wà láàyè títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí ẹlòmíì láyé yìí tó lè kọ́ àwọn èèyàn ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí ayé. Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ni wà nínú ohun tó sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè, tó wà ní Mátíù orí 5 sí 7. Tó o bá kà á, wàá rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ rọrùn láti lóye, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wọni lọ́kàn sì ni.

BÁWO LO ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌṢÀKÓSO YẸN?

Ohun àkọ́kọ́ tó máa jẹ́ kéèyàn di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni pé kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jésù fi èyí hàn nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”​—Jòhánù 17:3.

Tí àwọn èèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n sì sún mọ́ ọn, wọ́n máa rí àǹfààní tó pọ̀. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì péré lára àwọn àǹfààní náà: Àkọ́kọ́, wọ́n máa ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run. Ìdí sì ni pé wọ́n máa rí àwọn ohun tó máa jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ìjọba Ọlọ́run wà lóòótọ́, kò sì ní pẹ́ dé mọ́. (Hébérù 11:1) Ìkejì ni pé wọ́n á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wọn. Ìfẹ́ tí wọ́n bá ní fún Ọlọ́run á jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣègbọràn sí i látọkàn wá. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún aládùúgbò wọn máa jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe ohun tí Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”​—Lúùkù 6:31.

Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa dà bíi bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ohun tó dáa jù lọ ló ń fẹ́ fún wa. Ó fẹ́ ká ní ohun tí Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́.” (1 Tímótì 6:19) “Ìyè tòótọ́” kọ́ là ń gbádùn láyé tá a wà yìí. Àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn ṣáà ń rọ́jú, wọn ò gbádùn ayé wọn rárá. Tó o bá fẹ́ mọ bí “ìyè tòótọ́” ṣe máa rí, wo díẹ̀ lára àwọn ohun àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà.

ÀWỌN OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ NÍGBÀ TÍ ÌYÈ TÒÓTỌ́ BÁ DÉ

  • “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ [nígbà tí Kristi bá ń ṣàkóso bí Ọba], olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà . . . Òun yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ . . . dé òpin ilẹ̀ ayé.”​—Sáàmù 72:7, 8, 13, 14.

  • “[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”​—Sáàmù 46:9.

  • “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”​—Sáàmù 72:16.

  • “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. . . . Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”​—Aísáyà 65:21, 22.

  • “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ.”​—Ìṣípayá 21:3, 4.

Àwọn èèyàn ń gbádùn ara wọn nínú Párádísè

Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ọkàn àwọn èèyàn á balẹ̀, ààbò Ọlọ́run á wà lórí wọn, oúnjẹ á sì pọ̀ yanturu

KÓKÓ PÀTÀKÌ

ÀWỌN OHUN TÍ JÉSÙ KỌ́ WA MÁA JẸ́ KÁ NÍ ÌWÀ ỌMỌLÚWÀBÍ, KÁ SÌ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN. GBOGBO ÀWỌN TÓ BÁ KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́ LÈ DI ỌMỌ ABẸ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN TÓ MÁA ṢÀKÓSO GBOGBO AYÉ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́