ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 1 ojú ìwé 12-13
  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọrun?
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 1 ojú ìwé 12-13
Oòrùn tàn sí ayé, bí ayé ṣe máa rí rèé téèyàn bá ń wò ó látinú òfurufú

Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:9, 10) Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Kí ló máa ṣe? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba náà dé?

Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

Lúùkù 1:31-33 sọ pé: “Kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá, wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, Jèhófà Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”

Ìjọba Ọlọ́run ni ìwàásù Jésù dá lé.

Mátíù 9:35 sọ pé: “Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri gbogbo ìlú àti abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.”

Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àmì tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà tí Ìjọba náà máa dé.

Mátíù 24:7 sọ pé: “Torí orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”

Lónìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé.

Mátíù 24:14 sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Ibi tó wà. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀ sí ọ̀run.​—DÁNÍẸ́LÌ 2:44; MÁTÍÙ 4:17.

Ohun tí ìjọba náà máa ṣe. Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè níbi tí gbogbo èèyàn á ti máa gbé ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan, kò sì ní sí àìsàn àti ikú mọ́.​—SÁÀMÙ 37:11, 29.

Àwọn tó máa ṣàkóso. Ọlọ́run yan Jésù láti jẹ́ Ọba lọ́run, ó sì máa ṣàkóso pẹ̀lú àwọn ọ̀ke méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó yàn látinú ayé.​—LÚÙKÙ 1:30-33; 12:32; ÌFIHÀN 14:1, 3.

Àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà. Àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa gbé inú ayé, wọ́n á fi ara wọn sábẹ́ àkóso Jésù, wọ́n á sì máa fi tinútinú ṣègbọràn sí àwọn òfin Ìjọba náà.​—MÁTÍÙ 7:21.

Ìdí Tí Jésù Fi Kúnjú Ìwọ̀n Jù Lọ Láti Ṣàkóso Ayé

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé òun jẹ́ alákòóso tó kúnjú ìwọ̀n tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, torí pé:

  • Ó gba ọ̀rọ̀ àwọn aláìní rò.​—LÚÙKÙ 14:13, 14.

  • Ó kórìíra ìwà ìbàjẹ́ àti ìrẹ́jẹ.​—MÁTÍÙ 21:12, 13.

  • Ó kápá àwọn àjálù bí ìjì líle.​—MÁÀKÙ 4:39.

  • Ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn.​—MÁTÍÙ 14:19-21.

  • Ó káàánú àwọn aláìsàn, ó sì wo gbogbo ẹni tó ń jẹ̀rora sàn.​—MÁTÍÙ 8:16.

  • Ó jí àwọn tó ti kú dìde.​—JÒHÁNÙ 11:43, 44.

Àǹfààní Tí Ìjọba Ọlọ́run Ń Ṣe Fúnni Báyìí

Wàá túbọ̀ gbádùn ayé rẹ ní báyìí tó o bá jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ń:

  • “Lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.”​—HÉBÉRÙ 12:14.

  • Gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú ìdílé, torí pé tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn.​—ÉFÉSÙ 5:22, 23, 33.

  • Láyọ̀ nítorí pé wọ́n ń “wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”​—MÁTÍÙ 5:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́