ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 1 ojú ìwé 14-15
  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọjọ́ Iwájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọjọ́ Iwájú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌJỌBA RERE
  • ÌLERA TÓ DÁA
  • ÀLÀÁFÍÀ KÁRÍ AYÉ
  • ÈÈYÀN RERE NÌKAN LÓ MÁA WÀ LÁYÉ
  • GBOGBO AYÉ MÁA DI PÁRÁDÍSÈ
  • Ìrètí
    Jí!—2018
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àyè Tí Ọlọ́run Fi Gba Ìjìyà Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ ní Gbogbo Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 1 ojú ìwé 14-15
Àwọn èèyàn ń gbádùn ara wọn ní Párádísè

Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọjọ́ Iwájú

Ṣé o máa ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, tó sì máa kan gbogbo èèyàn.

Jésù sọ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká “mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Lára àwọn nǹkan tó sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni, àwọn ogun ńlá, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn. Àwọn nǹkan yìí sì ń ṣẹlẹ̀ lónìí lóòótọ́.​—Lúùkù 21:10-17.

Bíbélì tún sọ ìwà táwọn èèyàn á máa hù nígbà tí ìṣàkóso èèyàn bá ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó ní àwọn èèyàn á máa hùwàkíwà. O lè ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní 2 Tímótì 3:1-5. Tó o bá kíyè sí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn lónìí, ó dájú pé wàá gbà pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn mu.

Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe àwọn àyípadà ńlá tó máa tún ayé yìí ṣe lọ́nà tó dára gan-an. (Lúùkù 21:36) Ọlọ́run ṣèlérí àwọn ohun rere fún aráyé nínú Bíbélì. Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára wọn nìyí.

ÌJỌBA RERE

“A sì fún [Jésù] ní àkóso, ọlá àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín. Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.”​—DÁNÍẸ́LÌ 7:14.

Ohun tó túmọ̀ sí: O lè gbádun ayé rẹ lábẹ́ ìjọba gidi tó máa kárí ayé, èyí tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tó sì fi Ọmọ rẹ̀ ṣe Ọba.

ÌLERA TÓ DÁA

Ọmọbìnrin kan ń dìde lórí kẹ̀kẹ́ arọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn

“Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’”​—ÀÌSÁYÀ 33:24.

Ohun tó túmọ̀ sí: Àìsàn ò ní ṣe ẹ́ mọ́ láé, o ò sì ní di aláàbọ̀ ara; wàá tún ní àǹfààní láti wà láàyè láìní kú.

ÀLÀÁFÍÀ KÁRÍ AYÉ

Ìbọn tó fọ́ sí wẹ́wẹ́

Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”​—SÁÀMÙ 46:9.

Ohun tó túmọ̀ sí: A ò ní gbúròó ogun mọ́ àtàwọn nǹkan burúkú tó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ogun.

ÈÈYÀN RERE NÌKAN LÓ MÁA WÀ LÁYÉ

“Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́ . . . Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé.”​—SÁÀMÙ 37:10, 11.

Ohun tó túmọ̀ sí: Kò ní sí àwọn ẹni burúkú mọ́, àwọn tó ń gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu nìkan ló máa ṣẹ́ kù.

GBOGBO AYÉ MÁA DI PÁRÁDÍSÈ

“Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn.”​—ÀÌSÁYÀ 65:21, 22.

Ohun tó túmọ̀ sí: Gbogbo ayé máa lẹ́wà gan-an. Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà tá a máa ń gbà pé kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ “ní ayé.”​—Mátíù 6:10.

Àwọn èèyàn ń gbádùn ara wọn ní Párádísè
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́