ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/15 ojú ìwé 4-7
  • Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ ní Gbogbo Ọ̀nà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ ní Gbogbo Ọ̀nà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Mú Kí Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ?
  • Ìjọba Náà Bẹ̀rẹ̀
  • “Kí Ìjọba Rẹ Dé”
  • Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/15 ojú ìwé 4-7

Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ ní Gbogbo Ọ̀nà

JÉSÙ KRISTI fi ohun kan kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’” (Mátíù 6:9, 10) Àdúrà yìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa jẹ́ ká mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣètò Ìjọba Ọlọ́run.

Ìjọba yìí ni Ọlọ́run yóò lò láti fi sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Gbogbo ẹ̀gàn tí Sátánì àtàwọn èdá èèyàn ti kó bá orúkọ Ọlọ́run nítorí ìṣọ̀tẹ̀ wọn ni Ìjọba yìí yóò mú kúrò. Èyí ṣe pàtàkì gidigidi torí pé kí gbogbo àwọn ẹ̀dá láyé àti lọ́run tó lè láyọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé orúkọ Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, kí wọ́n sì fi tinútinú gbà pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso.—Ìṣípayá 4:11.

Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run gbé Ìjọba yìí kalẹ̀ láti mú “kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí? Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí àjọṣe tó dán mọ́rán tún padà wà láàárín òun àtọmọ aráyé, torí pé Ádámù ti ba àjọṣe ọ̀hún jẹ́. Ìjọba náà yóò tún rí sí i pé ohun kan tí Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, ní lọ́kàn láti ṣe di ṣíṣe, ìyẹn ni sísọ ayé di Párádísè níbi táwọn èèyàn rere yóò máa gbé títí ayé. Dájúdájú, Ìjọba Ọlọ́run yóò yanjú gbogbo ìṣòro tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti dá sílẹ̀, yóò sì mú kí àwọn ohun rere tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ní lọ́kàn láti ṣe sórí ilẹ̀ ayé di ṣíṣe. (1 Jòhánù 3:8) Ìjọba yìí àtàwọn ohun tó máa gbé ṣe ni ọ̀rọ̀ Bíbélì dá lé lórí.

Kí Ló Mú Kí Ìjọba Ọlọ́run Ta Yọ?

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan tó lágbára gan-an. Wòlíì Dáníẹ́lì jẹ́ ká róye bí ìjọba yìí ṣe lágbára tó. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí yóò fọ́ gbogbo ìjọba èèyàn túútúú, tí yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.’ Ìyẹn nìkan kọ́ o, Ìjọba Ọlọ́run tún ju ìjọba àwọn èèyàn lọ ní ti pé bí ìjọba àwọn èèyàn ṣe ń wá ni wọ́n ń lọ látọjọ́ pípẹ́, àmọ́ ní ti Ìjọba Ọlọ́run, ‘a kì yóò run ún láé.’ (Dáníẹ́lì 2:44) Àwọn nǹkan míì tún wà tó mú kí Ìjọba Ọlọ́run ju tèèyàn lọ ni gbogbo ọ̀nà.

Ọba tó ju ọba lọ ni Ìjọba Ọlọ́run ní. Wo ẹni tí Ọba náà jẹ́. Nínú ‘àlá àti ìran’ tí Ọlọ́run fi han Dáníẹ́lì, ó rí Alákòóso Ìjọba náà, ìyẹn “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn” tí wọ́n mú wá síwájú Ọlọ́run Olódùmarè, tí wọ́n sì fún ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba.” (Dáníẹ́lì 7:1, 13, 14) Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà ni Ọmọ ènìyàn náà. (Mátíù 16:13-17) Jèhófà Ọlọ́run fi Jésù, Ọmọ rẹ̀ yìí jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fáwọn Farisí tí wọ́n jẹ́ ẹni ibi pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín,” tó túmọ̀ sí pé òun tí òun máa jẹ́ Ọba Ìjọba náà wà lọ́dọ̀ wọn.—Lúùkù 17:21.

Ǹjẹ́ èèyàn kankan tún wà tó kúnjú òṣùwọ̀n bíi Jésù táá lè jẹ́ Alákòóso? Kò sí o. Jésù ti fi hàn gbangba pé Aṣáájú gidi tó jẹ́ olódodo, aláàánú àtẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé lòun. Àwọn ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù jẹ́ akíkanjú ọkùnrin, síbẹ̀ ó tún jẹ́ olójú àánú. (Mátíù 4:23; Máàkù 1:40, 41; 6:31-34; Lúùkù 7:11-17) Síwájú sí i, ní báyìí tí Jésù ti jíǹde sí ọ̀run kò lè kú mọ́, kò sì dà bí àwa èèyàn tó jẹ́ pé ó níbi tágbára wa mọ.—Aísáyà 9:6, 7.

Ibi tó ga lọ́lá ni Jésù àtàwọn tí yóò bá a ṣèjọba yóò wà nígbà tí wọ́n bá ń ṣàkóso. Nínú ìran àti àlá tí Ọlọ́run fi hàn Dáníẹ́lì, ó tún rí i pé “ìjọba àti agbára ìṣàkóso [ni a] fi fún àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́.” (Dáníẹ́lì 7:27) Èyí túmọ̀ sí pé Jésù nìkan kọ́ ló máa ṣàkóso. Àwọn míì yóò tún wà pẹ̀lú rẹ̀ tí yóò jẹ́ ọba àti àlùfáà. (Ìṣípayá 5:9, 10; 20:6) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa wọn pé: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì . . . tí a ti rà láti ilẹ̀ ayé wá.”—Ìṣípayá 14:1-3.

Jésù Kristi ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí Jòhánù rí yìí, àmọ́ èyí jẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi í jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Jòhánù 1:29; Ìṣípayá 22:3) Ọ̀run ni Òkè Ńlá Síónì yìí.a (Hébérù 12:22) Ibẹ̀ sì ni Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn tí yóò bá a ṣèjọba yóò ti máa ṣàkóso. Ẹ ò rí i pé ipò tó ga gan-an ni wọ́n máa wà! Wíwà tí wọ́n sì máa wà lọ́run á jẹ́ kí wọ́n lè rí ilẹ̀ ayé mójú tó dáadáa. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé láti ọ̀run ni “ìjọba Ọlọ́run” yóò ti máa ṣàkóso, Bíbélì tún pè é ní “ìjọba ọ̀run.” (Lúùkù 8:10; Mátíù 13:11) Kò sóhun ìjà èyíkéyìí, àní títí kan ohun ìjà arunlé-rùnnà pàápàá, tó lè dé ibi tí ìjọba ọ̀run náà wà láti bì í ṣubú. Kò sí mìmì kan tó lè mì í rárá. Ìjọba náà yóò ṣe ohun tí Jèhófà tìtorí rẹ̀ gbé e kalẹ̀ láṣeyọrí.—Hébérù 12:28.

Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn aṣojú tó ṣeé fọkàn tán lórí ilẹ̀ ayé. Báwo la ṣe mọ̀? Sáàmù 45:16 sọ pé: “Ìwọ yóò [yan] olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ọmọ Ọlọ́run lẹni tí ọ̀rọ̀ náà “ìwọ” tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń tọ́ka sí. (Sáàmù 45:6, 7; Hébérù 1:7, 8) Nítorí náà, Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ni yóò yan àwọn aṣojú tí yóò jẹ́ olórí. Kí ó dá wa lójú pé tọkàntọkàn ni wọn á fi máa tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀. Àní lóde òní náà pàápàá, ètò Ọlọ́run ti kọ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n kúnjú òṣùwọ̀n tí wọ́n jẹ́ alàgbà nínú ìjọ Ọlọ́run pé ńṣe ni kí wọ́n máa dáàbò bo àwọn ará wọn, kí wọ́n máa fún wọn níṣìírí, kí wọ́n sì máa tù wọ́n nínú, kì í ṣe pé kí wọ́n máa “jẹ olúwa lé wọn lórí.”—Mátíù 20:25-28; Aísáyà 32:2.

Àwọn olódodo èèyàn ni ọmọ abẹ́ Ìjọba náà. Aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán ni wọ́n lójú Ọlọ́run. (Òwe 2:21, 22) Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Ọlọ́kàntútù, ìyẹn ẹni pẹ̀lẹ́ àti onírẹ̀lẹ̀ tó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ làwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Nǹkan tẹ̀mí lohun tó gbawájú lọ́kàn wọn. (Mátíù 5:3) Ohun tó tọ́ ni wọ́n máa ń fẹ́ láti ṣe wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run.

Àwọn òfin tí Ìjọba Ọlọ́run ń tẹ̀ lé ga ju òfin ìjọba èyíkéyìí lọ. Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣe àwọn òfin àti ìlànà tí Ìjọba náà ń lò. Òfin tó ń ṣeni láǹfààní ni wọ́n, kì í ṣe èyí tó kàn ń káni lọ́wọ́ kò ṣáá. (Sáàmù 19:7-11) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń jàǹfààní báyìí látinú pípa àwọn òfin òdodo tí Jèhófà ṣe mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìdílé wa ń láyọ̀ bí ọkọ, aya àtàwọn ọmọ ṣe ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́. (Éfésù 5:33-6:3) Tá a bá pa àṣẹ Bíbélì tó ní ká ‘fi ìfẹ́ wọ ara wa láṣọ’ mọ́, àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì á túbọ̀ dán mọ́rán. (Kólósè 3:13, 14) Bí a bá sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́, a óò tún mọ bá a ṣe lè fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́, a ó sì ní èrò tó tọ́ nípa owó. (Òwe 13:4; 1 Tímótì 6:9, 10) Tí a kì í bá ṣèṣekúṣe, tí a kì í lo tábà àtàwọn oògùn olóró tó ń di bárakú, tí a kì í sì í mu ọtí lámujù, a ò ní fa àìsàn bá ara wa.—Òwe 7:21-23; 23:29, 30; 2 Kọ́ríńtì 7:1.

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan tí Ọlọ́run gbé kálẹ̀. Jésù Kristi tí í ṣe Mèsáyà, tó jẹ́ ọba Ìjọba yìí àti gbogbo àwọn tí yóò bá a ṣèjọba gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà òdodo Ọlọ́run torí pé wọ́n máa jíhìn fún un. Gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà, títí kan àwọn aṣojú Kristi lórí ilẹ̀ ayé, ló sì nífẹ̀ẹ́ sí pípa òfin Ọlọ́run mọ́. Èyí fi hàn pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló jẹ àwọn alákòóso àtàwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà lógún. Gbogbo èyí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ló ń darí Ìjọba yìí. Dájúdájú, ìjọba náà yóò ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ gbé e kalẹ̀ láṣeyọrí. Àmọ́, ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run tá a tún mọ̀ sí Ìjọba Mèsáyà bẹ̀rẹ̀?

Ìjọba Náà Bẹ̀rẹ̀

Ọ̀rọ̀ kan tí Jésù sọ yóò jẹ́ ká lóye ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. Ó ní: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé.” (Lúùkù 21:24) Jerúsálẹ́mù nìkan ni ìlú tí Ọlọ́run fi orúkọ rẹ̀ sí ní gbogbo àgbáyé. (1 Àwọn Ọba 11:36; Mátíù 5:35) Òun ni olú ìlú ìjọba kan lórí ilẹ̀ ayé, tí Ọlọ́run fọwọ́ sí tó sì ń ṣe àtìlẹ́yìn fún. Bí àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ṣe tẹ ìlú náà mọ́lẹ̀ ni pé àwọn ìjọba ayé yóò dáwọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run lórí àwọn èèyàn rẹ̀ dúró fúngbà díẹ̀. Ìgbà wo lèyí ṣẹlẹ̀?

Jèhófà sọ fún ọba tó jẹ kẹ́yìn lórí ìtẹ́ Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé: “Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé kúrò. . . . Dájúdájú, kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.” (Ìsíkíẹ́lì 21:25-27) Àwọn kan yóò ṣí adé orí ọba náà kúrò, tó túmọ̀ sí pé ìṣàkóso Ọlọ́run lórí àwọn èèyàn rẹ̀ yóò dáwọ́ dúró fúngbà díẹ̀. Èyí ṣẹlẹ̀ lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run. Láàárín “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀” tó máa tẹ̀ lé e, Ọlọ́run kò ní ní ìjọba kankan lórí ilẹ̀ ayé tí yóò máa ṣojú fún ìṣàkóso rẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Jèhófà máa fún Jésù Kristi tó jẹ́ “ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” lágbára láti ṣàkóso. Báwo ni àkókò yẹn ṣe máa gùn tó?

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Dáníẹ́lì sọ pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì run ún. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀, ṣùgbọ́n tòun ti ọ̀já irin àti ti bàbà . . . títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 4:23) Àlàyé tí a ó ṣe yóò jẹ́ ká rí i pé “ìgbà méje” tí ibí yìí sọ jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.”

Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo igi láti fi ṣàpẹẹrẹ ẹnì kan tàbí alákòóso kan tàbí ìjọba kan. (Sáàmù 1:3; Jeremáyà 17:7, 8; Ìsíkíẹ́lì, orí 31) Dáníẹ́lì sọ pé ‘a lè rí igi ìṣàpẹẹrẹ náà ní ìkángun gbogbo ilẹ̀ ayé.’ (Dáníẹ́lì 4:11) Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣàkóso tí igi tí a ó gé lulẹ̀ tí a ó sì fi ọ̀já irin dè yìí dúró fún yóò “dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,” èyí tó túmọ̀ sí pé kò síbi tí ìṣàkóso yìí ò ní dé láyé. (Dáníẹ́lì 4:17, 20, 22) Nítorí náà, ohun tí igi náà ń ṣàpẹẹrẹ ni ìṣàkóso Ọlọ́run tó ga jù lọ láyé àti lọ́run, pàápàá tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ìṣàkóso náà ṣe kan ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run lo ìjọba tó gbé kalẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti fi ṣàkóso ayé fúngbà díẹ̀. Àmọ́, wọ́n gé igi tó dúró fún ìṣàkóso Ọlọ́run náà lulẹ̀, wọ́n sì fi ọ̀já irin àti ti bàbà de kùkùté rẹ̀ kó má bàa hù. Èyí fi hàn pé ìjọba tó ń ṣojú fún Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé dáwọ́ dúró, ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìyẹn sì ṣẹlẹ̀. Àmọ́ kò ní wà bẹ́ẹ̀ títí lọ. Wọ́n yóò fi ọ̀já wé igi náà títí tí “ìgbà méje” yóò fi kọjá lórí rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà méje yìí, Jèhófà yóò gbé ìṣàkóso náà fún ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i gan-an, ìyẹn Jésù Kristi. Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé àkókò kan náà ni “ìgbà méje” àti “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” ń tọ́ka sí.

Bíbélì jẹ́ ká mọ bí “ìgbà méje” náà ṣe gùn tó. Ó fi hàn pé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́ jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú “àkókò kan [ìyẹn àkókò kan ṣoṣo] àti àwọn àkókò [ìyẹn ìlọ́po méjì àkókò kan ṣoṣo] àti ààbọ̀ àkókò,” èyí tí àròpọ̀ gbogbo rẹ̀ jẹ́ “àkókò” mẹ́ta àti ààbọ̀. (Ìṣípayá 12:6, 14) Èyí túmọ̀ sí pé àkókò mẹ́ta àtààbọ̀ lọ́nà méjì tí í ṣe ìgbà méje yìí jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún [2,520] ọjọ́.

Tá a bá kàn ka ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọjọ́ láti ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọdún 600 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìṣirò wa yóò dé dúró. Àmọ́, ìgbà méje náà gùn gan-an jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àní, ìgbà méje náà ṣì ń bá a nìṣó nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbà méje yìí kì í ṣe ìgbà méje lásán. Nítorí náà, ìlànà kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ la máa lò láti ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ìyẹn ìlànà “ọjọ́ kan fún ọdún kan.” (Númérì 14:34; Ìsíkíẹ́lì 4:6) Èyí wá fi hàn pé ìgbà méje táwọn ìjọba ayé fi ṣàkóso ayé láìsí pé Ọlọ́run dá wọn dúró jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọdún. Tá a bá wá ka ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọdún láti ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọdún 1914 Sànmánì Kristẹni ni ìṣirò wa yóò dé dúró. Ọdún yẹn ni ìgbà tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” tàbí ìgbà méje dópin. Èyí túmọ̀ sí pé ọdún 1914 ni Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Níwọ̀n bí Ìjọba Mèsáyà ti bẹ̀rẹ̀ lókè ọ̀run, ṣé ó yẹ ká ṣì máa gbàdúrà pé kí ìjọba náà dé gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ nínú Àdúrà Olúwa. (Mátíù 6:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni o. Ohun tó tọ́ tó sì yẹ ni láti máa gbàdúrà pé kó dé. Ó ṣì dọjọ́ iwájú kí Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣàkóso gbogbo ayé pátá.

Àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run yóò rọ̀jò rẹ̀ sórí aráyé olóòótọ́ yóò pọ̀ gan-an ni! Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Lákòókò náà, “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò wà láàyè títí láé. (Jòhánù 17:3) Bí a ṣe ń fojú sọ́nà láti rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀ tó gọntíọ, ẹ jẹ́ ká “máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.”—Mátíù 6:33.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Dáfídì Ọba gba ìlú olódi tó wà lórí Òkè Ńlá Síónì ti orí ilẹ̀ ayé mọ́ àwọn ará Jébúsì lọ́wọ́, ó sì sọ ọ́ di olú ìlú ìjọba rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 5:6, 7, 9) Ó tún gbé Àpótí mímọ́ náà wá síbẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 6:17) Níwọ̀n bí Àpótí náà ti jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà níbẹ̀, Bíbélì pe Síónì ní ibi tí Ọlọ́run ń gbé, èyí sì mú kí Síónì jẹ́ ohun tó dára láti fi ṣàpẹẹrẹ ọ̀run.—Ẹ́kísódù 25:22; Léfítíkù 16:2; Sáàmù 9:11; Ìṣípayá 11:19.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Jèhófà ti fi Jésù Kristi jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

2,520 ọdún

October 607 ◀ṣáájú Sànmánì Kristẹni Sànmánì Kristẹni▸ October 1914

606 ọdún àti oṣù mẹ́ta 1,913 ọdún àti oṣù mẹ́sàn-án

Ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” bẹ̀rẹ̀, ó sì parí lọ́dún 1914 Sànmánì Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀pọ̀ ìbùkún laráyé yóò rí gbà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́