ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 31
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ìṣubú Íjíbítì, igi kédárì tó ga fíofío (1-18)

Ìsíkíẹ́lì 31:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:2; Isk 29:2

Ìsíkíẹ́lì 31:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkùukùu.”

Ìsíkíẹ́lì 31:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Igi tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ fẹ̀, tó sì máa ń bó èèpo rẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:8; Isk 28:12, 13

Ìsíkíẹ́lì 31:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìwọ.”

  • *

    Tàbí “ìkùukùu.”

Ìsíkíẹ́lì 31:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:10, 11; Hab 1:6

Ìsíkíẹ́lì 31:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 32:5, 6

Ìsíkíẹ́lì 31:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:5; 32:4

Ìsíkíẹ́lì 31:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkùukùu.”

  • *

    Tàbí “sàréè.”

Ìsíkíẹ́lì 31:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìsíkíẹ́lì 31:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “sàréè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 31:9

Ìsíkíẹ́lì 31:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Ní Héb., “pẹ̀lú apá rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 32:18, 20
  • +Isk 30:6; 32:31

Ìsíkíẹ́lì 31:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìkọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 31:9; 32:19

Àwọn míì

Ìsík. 31:2Jer 46:2; Isk 29:2
Ìsík. 31:8Jẹ 2:8; Isk 28:12, 13
Ìsík. 31:11Isk 30:10, 11; Hab 1:6
Ìsík. 31:12Isk 32:5, 6
Ìsík. 31:13Isk 29:5; 32:4
Ìsík. 31:16Isk 31:9
Ìsík. 31:17Isk 32:18, 20
Ìsík. 31:17Isk 30:6; 32:31
Ìsík. 31:18Isk 31:9; 32:19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 31:1-18

Ìsíkíẹ́lì

31 Ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kẹta, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ fún Fáráò ọba Íjíbítì àti ọ̀pọ̀ èèyàn rẹ̀ pé,+

‘Ta ló lágbára bíi tìrẹ?

 3 Ará Ásíríà kan wà, igi kédárì ní Lẹ́bánónì,

Tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ rẹwà, tó ṣíji bolẹ̀, tó sì ga fíofío;

Orí rẹ̀ kan àwọsánmà.*

 4 Omi mú kó di ńlá, àwọn ìsun omi sì mú kó ga.

Omi tó ń ṣàn wà yí ká ibi tí wọ́n gbìn ín sí;

Àwọn ipadò rẹ̀ bomi rin gbogbo igi inú oko.

 5 Ìdí nìyẹn tó fi ga ju gbogbo igi yòókù lọ nínú oko.

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i, ọwọ́ rẹ̀ sì ń gùn

Torí omi pọ̀ nínú àwọn odò rẹ̀.

 6 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run kọ́ ìtẹ́ wọn sí ara àwọn ẹ̀ka rẹ̀,

Gbogbo ẹranko bímọ sí abẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀,

Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá sì ń gbé abẹ́ ibòji rẹ̀.

 7 Ẹwà rẹ̀ ga lọ́lá, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn dáadáa,

Torí pé àwọn gbòǹgbò rẹ̀ wọnú omi tó pọ̀.

 8 Kò sí igi kédárì kankan nínú ọgbà Ọlọ́run+ tó ṣeé fi wé e.

Kò sí igi júnípà kankan tí ẹ̀ka rẹ̀ dà bíi tirẹ̀,

Kò sì sí àwọn igi alára dídán* tí ẹ̀ka wọn dà bíi tirẹ̀.

Kò sí igi míì nínú ọgbà Ọlọ́run tó lẹ́wà bíi tirẹ̀.

 9 Mo mú kó rẹwà, kí ewé rẹ̀ sì pọ̀ rẹpẹtẹ,

Gbogbo igi yòókù tó wà ní Édẹ́nì, nínú ọgbà Ọlọ́run tòótọ́ sì ń jowú rẹ̀.’

10 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé ó* ga gan-an, tí orí rẹ̀ kan àwọsánmà,* tó sì ń gbéra ga nínú ọkàn rẹ̀ torí pé ó ga, 11 èmi yóò fi í lé alágbára tó ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́.+ Ó dájú pé ó máa bá a jà, èmi yóò sì kọ̀ ọ́ torí ìwà ìkà rẹ̀. 12 Àwọn àjèjì, àwọn tó burú jù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò gé e lulẹ̀, wọ́n á sì pa á tì sórí àwọn òkè, àwọn ewé rẹ̀ á já bọ́ sí gbogbo àfonífojì, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ á sì ṣẹ́ sínú gbogbo odò ilẹ̀ náà.+ Gbogbo èèyàn ayé yóò kúrò lábẹ́ ibòji rẹ̀, wọ́n á sì pa á tì. 13 Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run á máa gbé lórí ìtì rẹ̀ tó wó lulẹ̀, gbogbo ẹran inú igbó á sì máa gbé lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+ 14 Èyí máa rí bẹ́ẹ̀, kó má bàa sí igi kankan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó máa ga tó bẹ́ẹ̀, tí orí rẹ̀ á kan àwọsánmà,* kí igi kankan tó ń rí omi mu dáadáa má sì ga tó wọn. Torí gbogbo wọn ló máa kú, wọ́n á lọ sí ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọmọ aráyé tí wọ́n ń lọ sínú kòtò.’*

15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ tó bá lọ sínú Isà Òkú,* màá mú kí wọ́n ṣọ̀fọ̀. Torí náà, èmi yóò bo ibú omi, màá sì sé àwọn odò rẹ̀ kí omi tó pọ̀ náà má bàa ṣàn. Màá mú kí Lẹ́bánónì ṣókùnkùn torí rẹ̀, gbogbo igi oko yóò sì gbẹ dà nù. 16 Tí ìró ìṣubú rẹ̀ bá dún, màá mú kí àwọn orílẹ̀-èdè gbọ̀n rìrì nígbà tí mo bá mú un lọ sí Isà Òkú* pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ń lọ sínú kòtò* àti gbogbo igi Édẹ́nì,+ èyí tó dáa jù tó sì jẹ́ ààyò ti Lẹ́bánónì, gbogbo àwọn tó ń rí omi mu dáadáa, yóò rí ìtùnú ní ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀. 17 Wọ́n ti bá a lọ sínú Isà Òkú,* sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa,+ pẹ̀lú àwọn tó ń tì í lẹ́yìn,* tí wọ́n ń gbé lábẹ́ òjìji rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’+

18 “‘Igi wo ní Édẹ́nì ló ní ògo tó sì lágbára bíi tìrẹ?+ Àmọ́, ó dájú pé ìwọ àti àwọn igi Édẹ́nì yóò lọ sínú ilẹ̀ tó wà nísàlẹ̀. Àárín àwọn aláìdádọ̀dọ́* ni wàá dùbúlẹ̀ sí, pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi idà pa. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Fáráò àti gbogbo èèyàn rẹ̀ nìyí,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́