ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/22 ojú ìwé 6-9
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oríṣi Àìfararọ Mẹ́ta
  • Títètèbínú Nípa Àìfararọ
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!
    Jí!—2005
  • Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/22 ojú ìwé 6-9

Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu

“Níwọ̀n bí àìfararọ ti jẹ́ ìhùwàpadà ara sí àìní èyíkéyìí lọ́nà tí kò ṣe pàtó, gbogbo ènìyàn sábà máa ń ní àìfararọ dé ìwọ̀n kan.”—Dókítà Hans Selye.

KÍ ATAGÒJÉ kan tó lè fi ohun èlò náà gbé orin jáde, àwọn okùn rẹ̀ gbọ́dọ̀ le dáradára—ṣùgbọ́n dé ìwọ̀n kan ni. Bí wọ́n ba le jù, wọn óò já. Ṣùgbọ́n bí àwọn okùn náà bá dẹ̀ jù, wọn kò ní gbé ohùn kankan jáde. Ìwọ̀n líle tí ó yẹ wà láàárín ìkángun méjèèjì.

Ó dọ́gba pẹ̀lú àìfararọ. Àpọ̀jù rẹ̀ lè léwu, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i níṣàájú. Ṣùgbọ́n tí kò bá sí àìfararọ rárá ńkọ́? Nígbà tí ìfojúsọ́nà náà lè dà bí ohun tó fani mọ́ra, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé o nílò àìfararọ—ó kéré tán dé ìwọ̀n kan. Fún àpẹẹrẹ, finú wòye pé nígbà tí o ń sọdá òpópónà kan, ó ṣàkíyèsí lójijì pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan dojú kọ ọ́ pẹ̀lú eré burúkú. Kí ó má baà ṣe ọ́ léṣe, àìfararọ ni yóò jẹ́ kí o sá—kíákíá!

Ṣùgbọ́n kì í ṣe ipò pàjáwìrì nìkan ni àìfararọ wúlò fún. O tún nílò àìfararọ láti ṣàṣeparí àwọn iṣẹ́ ojoojúmọ́. Gbogbo ènìyàn ló ń ní ìwọ̀n àìfararọ díẹ̀ nígbà gbogbo. Dókítà Hans Selye sọ pé: ‘Ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè gbà yẹra fún àìfararọ ni kí a kú.’ Ó fi kún un pé, bí ọ̀rọ̀ náà, “ara rẹ̀ ń gbóná,” kò ṣe já mọ́ nǹkan kan ni ọ̀rọ̀ náà, “ó ní àìfararọ,” kò ṣe já mọ́ nǹkan kan. Selye sọ pé: “Ohun tí a ní lọ́kàn ní gidi nínú irú àwọn gbólóhùn báwọ̀nyẹn ni àpọ̀jù àìfararọ tàbí ara gbígbóná.” Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, eré ìtura pẹ̀lú ní àìfararọ nínú, bẹ́ẹ̀ sì ni oorun pẹ̀lú ní, níwọ̀n bí ọkàn-àyà rẹ ti gbọ́dọ̀ máa lù kìkì, kí àwọn ẹ̀dọ̀fóró rẹ sì máa ṣiṣẹ́.

Oríṣi Àìfararọ Mẹ́ta

Bí ó ti jẹ́ pé ìwọ̀n àìfararọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà, bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ pé oríṣi mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà pẹ̀lú.

Pákáǹleke tó wà nínú ìgbòkègbodò ẹ̀dá lójoojúmọ́ ló ń fa akọ àìfararọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń kan àwọn ipò tí kò gbádùn mọ́ni tí a ní láti wá nǹkan ṣe sí. Níwọ̀n bí àwọn wọ̀nyí ti wulẹ̀ máa ń ṣèèṣì ṣẹlẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, àìfararọ náà sábà máa ń ṣeé kápá. Dájúdájú, àwọn kan wà tí wọ́n máa ń ti orí ìṣòro kan bọ́ sí òmíràn—ní gidi, ó jọ pé ìdàrúdàpọ̀ jẹ́ apá kan àkópọ̀ ìwà wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a lè kápá ìpele akọ àìfararọ yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹni tó ń ṣe lè dènà ìyípadà títí yóò fi mọ ipa tí ìgbésí ayé onírúkèrúdò rẹ̀ ń ní lórí òun àti lórí àwọn tí wọ́n yí òun ká.

Nígbà tí akọ àìfararọ ti ń wà fún ìgbà díẹ̀, àìfararọ tí ó ti di bárakú ń wà fún ìgbà gígùn. Ẹni tó ń ṣe kì í rí ọ̀nà kankan tí ó lè gbà yọ nínú ipò àìfararọ, yálà ó jẹ́ ìpọ́njú nítorí ipò òṣì tàbí ìnira nítorí iṣẹ́ tí a fojú tẹ́ńbẹ́lú—tàbí àìríṣẹ́ṣe. Àwọn ìṣòro ìdílé tí kò dáwọ́ dúró tún lè fa àìfararọ tí ó ti di bárakú. Ṣíṣètọ́jú ẹbí kan tí ń ṣàìsàn lè fa àìfararọ pẹ̀lú. Ohun yòówù kí ó fà á, àìfararọ tí ó ti di bárakú máa ń kó àárẹ̀ bá ẹni tó ń ṣe lójoojúmọ́, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lóṣooṣù. Ìwé kan lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí sọ pé: “Apá tó burú jù lọ nínú àìfararọ tí ó ti di bárakú ni pé ó máa ń mọ́ àwọn ènìyàn lára. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ènìyàn ń mọ̀ pé àwọn ní akọ àìfararọ nítorí ó jẹ́ tuntun; wọ́n kì í kọbi ara sí àìfararọ tí ó ti di bárakú nítorí pé ó ti wà pẹ́, kò ṣàjèjì, nígbà mìíràn, ó sì máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ rọni lọ́rùn.”

Àìfararọ adanilórírú jẹ́ ipa tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ bíbonimọ́lẹ̀ pátápátá, bí ìfipábáni-lòpọ̀, ìjàǹbá, tàbí ìjábá àdánidá kan ń ní. Ọ̀pọ̀ àwọn àbọ̀dé ológun àti àwọn tí wọ́n la àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ já ń jìyà irú àìfararọ yìí. Àwọn àmì àìfararọ adanilórírú lè ní nínú, ìrántí àwọn hílàhílo náà gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, kódà lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, papọ̀ pẹ̀lú títètè bínú nítorí àwọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Nígbà mìíràn, a máa ń ṣàwárí pé ẹni tí ó ń ṣe náà ní ìṣòro kan tí a ń pè ní ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ lẹ́yìn àìfararọ mánigbàgbé (PTSD).—Wo àpótí tí ó wà lókè.

Títètèbínú Nípa Àìfararọ

Àwọn kan sọ pé ọ̀nà tí a ń gbà hùwà padà sí àìfararọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ sinmi púpọ̀ lórí bí àìfararọ tí a ti ní tẹ́lẹ̀ ṣe pọ̀ tó àti irú èyí tí ó jẹ́. Wọ́n sọ pé ní gidi, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú lè yí “ìgbésẹ̀ ìsokọ́ra” ìhùwàpadà kẹ́míkà inú ọpọlọ padà, kí ó sì mú kí ẹnì kan wà ní ipò tí yóò fi túbọ̀ máa tètè bínú nípa àìfararọ lọ́jọ́ iwájú. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìwádìí kan tí a fi àwọn àbọ̀dé ológun 556 tí wọ́n jà nínú Ogun Àgbáyé Kejì ṣe, Dókítà Lawrence Brass ṣàwárí pé ewu níní àrùn ẹ̀gbà fi ìlọ́po mẹ́jọ pọ̀ láàárín àwọn tí wọ́n ti ṣẹ̀wọ̀n ní ilẹ̀ ọ̀tá ju láàárín àwọn tí wọn kò tí i ṣẹ̀wọ̀n rí—kódà ní 50 ọdún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ oníhílàhílo náà. “Àìfararọ ti jíjẹ́ POW [ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ ọ̀tá] le gan-an débi tí ó fi yí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ń hùwà nípa àìfararọ padà lọ́jọ́ iwájú—ó mú kí wọ́n tètè máa bínú.”

Àwọn ògbógi sọ pé, a kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ohun tí ń fa àìfararọ tí ó ṣẹlẹ̀ síni nígbà ọmọdé nítorí pé ìwọ̀nyí lè ní ipa púpọ̀ jọjọ. Dókítà Jean King sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n jìyà hílàhílo ni wọn kì í gbé wá sọ́dọ̀ dókítà. Wọ́n máa ń la ìṣòro náà já, wọ́n ń bá ìgbésí ayé wọn lọ, níkẹyìn, wọn óò sì wá sí ọfíìsì wa lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ìsoríkọ́ tàbí àrùn ọkàn-àyà.” Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò hílàhílo ti pípàdánù òbí kan. Dókítà King sọ pé: “Àìfararọ tí ó tóbi tó ìyẹn tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí o wà lọ́mọdé lè fa ìyípadà tí ó wà títí lọ nínú ìṣètò ìṣiṣẹ́ ọpọlọ, kí ó sì fi í sí ipò tí kò ní lè kápá àìfararọ tí ó sábà ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́.”

Dájúdájú, bí ẹnì kan ṣe ń hùwà padà sí àìfararọ lè sinmi lórí àwọn okùnfà bíi mélòó kan pẹ̀lú, títí kan ọ̀nà tí a gbà ṣẹ̀dá rẹ̀ àti àwọn ohun tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀ láti yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́ láti kápá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń fa àìfararọ. Síbẹ̀síbẹ̀, láìka ohun yòówù kí ó máa fà á sí, a lè kápá àìfararọ. Òtítọ́ ni pé èyí kò rọrùn. Dókítà Rachel Yehuda sọ pé: “Sísọ fún ẹnì kan tí ó máa ń bínú nípa àìfararọ láti wulẹ̀ fara balẹ̀ dà bí sísọ fún ẹnì kan tí kì í rí oorun sùn tó pé kí ó wulẹ̀ jẹ́ kí oorun gbé òun lọ.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun púpọ̀ wà tí ẹnì kan lè ṣe láti dín àìfararọ kù, bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí yóò ṣe fi hàn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Àìfararọ Níbi Iṣẹ́—“Ìṣòro Tí Ó Kárí Ayé”

Ìròyìn kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ pé: “Àìfararọ ti di ọ̀kan lára ọ̀ràn àìlera tí ó burú jù lọ ní ọ̀rúndún ogún.” Ó hàn gbàǹgbàgbangba pé ó ti dé ibi iṣẹ́.

• Iye àyè tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní Australia ń gbà nítorí àìfararọ fi ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín ọdún mẹ́ta péré.

• Ìwádìí kan ní ilẹ̀ Faransé fi hàn pé ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn nọ́ọ̀sì àti ìpín 61 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùkọ́ sọ pé àyíká àìfararọ tí àwọn ti ń ṣiṣẹ́ ń ru àwọn nínú.

• Àwọn àìlera tí ó tan mọ́ àìfararọ ń ná United States ní iye tí a fojú díwọ̀n sí 200 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún. A ṣírò pé ìpín 75 sí ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo ìjàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ló tan mọ́ àìfararọ.

• Ní orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, a ṣàwárí pé àwọn obìnrin ń jìyà lọ́wọ́ àìfararọ ju àwọn ọkùnrin lọ, ó lè jẹ́ nítorí pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní ilé àti ibi iṣẹ́ ti pọ̀ jù.

Bí ìròyìn àjọ UN náà ṣe pe àìfararọ níbi iṣẹ́, ó jẹ́ “ìṣòro tí ó kárí ayé.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Àìsàn PTSD—Ìhùwàpadà Tí Ó Yẹ Nípa Ìrírí Búburú Kan

‘Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa forí sọlẹ̀, n kò yé sunkún síbẹ̀, n kì í sì lè sùn mọ́jú. Láti fi ilé sílẹ̀ lásán jẹ́ ohun apániláyà.’—Louise.

ÌṢIṢẸ́GBÒDÌ ọpọlọ lẹ́yìn àìfararọ mánigbàgbé (PTSD), àìsàn kan tí ń sọni di aláìlágbára, tí ń ní ìrántí tàbí àlá nípa ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú tí ń wá lóòrèkóòrè nígbà tí a kò fẹ́ ẹ nínú, ń yọ Louise lẹ́nu. Ẹni tí àìsàn PTSD bá ń yọ lẹ́nu tún lè ní ìṣòro títagìrì ré kọjá ààlà. Fún àpẹẹrẹ, ògbógi nínú ìtọ́jú àrùn ọpọlọ náà, Michael Davis, sọ nípa àbọ̀dé ológun kan tí ó jà nínú ogun Vietnam, tí ó fi pápá bora lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ń ta pàùpàù. Davis sọ pé: “Onírúurú àmì gbọ́dọ̀ ti wà láyìíká náà láti jẹ́ kí ó mọ̀ pé kò séwu. Ó ti lé ní ọdún 25 nígbà náà; United States ni ó sì wà, kì í ṣe Vietnam; . . . kóòtù àwọ̀fiṣafẹ́ funfun ló wà lọ́rùn rẹ̀, kì í ṣe aṣọ tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ń wọ̀ ní pápá ogun. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìmọ̀lára tí ó ti ní tẹ́lẹ̀ rú yọ, ó sá fi pápá bora.”

Ọ̀kan péré ni hílàhílo tí ń báni lójú ogun jẹ́ lára àwọn ohun tí ń fa àìsàn PTSD. Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ìròyìn náà, The Harvard Mental Health Letter, ti sọ, ìṣiṣẹ́gbòdì náà lè jẹ́ àbájáde “ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ọ̀wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó la ikú gidi lọ tàbí sísúnmọ́ bèbè ikú tàbí ìpalára bíburújáì tàbí ọ̀kan tí ó fi ipò ara sábẹ́ ewu. Ó lè jẹ́ ìjábá àdánidá, ìjàǹbá ọkọ̀, tàbí àfọwọ́fà ẹ̀dá: ìkún omi, iná, ìsẹ̀lẹ̀, ìtàkìtì ọkọ̀, ìjubọ́ǹbù, ìyìnbọn, ìdánilóró, ìjínigbé, ìkọluni, ìfipábáni-lòpọ̀, tàbí bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe.” Wíwulẹ̀ ṣẹlẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú kan tàbí gbígbọ́ nípa rẹ̀—bóyá nípasẹ̀ ẹ̀rí yíyanilẹ́nu tàbí fọ́tò—lè súnná sí àwọn àmì àìsàn PTSD, ní pàtàkì, bí àwọn tí nǹkan náà ṣẹlẹ̀ sí bá jẹ́ ara ìdílé ẹni tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

Òtítọ́ ni pé ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà hùwà padà sí hílàhílo yàtọ̀ síra. Lẹ́tà ìròyìn náà, The Harvard Mental Health Letter, ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tí wọ́n ní ìrírí adanilórírú kì í ní àwọn àmì àrùn ọpọlọ tí ó burú, kódà nígbà tí àwọn àmì bá wà, wọ́n kì í wá bí àìsàn PTSD.” Àwọn tí àìfararọ wọn yọrí sí àìsàn PTSD ńkọ́? Bí àkókò ti ń lọ, ó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti kápá ìmọ̀lára tí ń bá hílàhílo náà rìn, kí ó sì rí ìwòsàn. Àwọn mìíràn ṣì ń bá àwọn ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú kan jà lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí ó ti ṣẹlẹ̀.

Èyí tó wù kí ó jẹ́, àwọn tí wọ́n ní àìsàn PTSD—àti àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́—gbọ́dọ̀ rántí pé ìkọ́fẹpadà ń fẹ́ sùúrù. Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” kí wọ́n sì “máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ní ti Louise, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, oṣù márùn-ún kọjá kí ó tó tún lè láyà tó láti wakọ̀. Ó sọ ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tí ìjàǹbá náà ṣẹlẹ̀ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan sunwọ̀n sí i, ọkọ wíwà kò tún lè jẹ́ ìrírí gbígbádùnmọ́ni fún mi bí ó ti rí nígbà kan mọ́. Ó jẹ́ ohun àìgbọdọ̀máṣe fún mi ni mo ṣe ń wà á. Ṣùgbọ́n nǹkan ti túbọ̀ sunwọ̀n sí i fún mi ju ti ìgbà tí ìjàǹbá náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ lọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì ń ní àìfararọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Kì í ṣe gbogbo àìfararọ ló léwu fún ọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́