ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 1 ojú ìwé 5-7
  • Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀÌBALẸ̀ ỌKÀN TÓ DÁA ÀTÈYÍ TÍ Ò DÁA
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 1 ojú ìwé 5-7
Oníṣòwò kan ń gòkè lọ sí ilé ìṣòwò kan láàárín ìlú.

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?

Àìbalẹ̀ ọkàn ni ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ara èèyàn bá fẹ́ kojú ewu tàbí ìpèníjà. Ọpọlọ èèyàn á mú kí èròjà kan tú jáde lọ sínú gbogbo ara. Èyí máa ń mú kí ọkàn máa yára lù kìkì, á sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ru sókè ní ìwọ̀n tó yẹ, á mú kí ẹ̀dọ̀fóró tóbi sí i tàbí kó sún kì, gbogbo iṣan ara á wá le. Kéèyàn tó mọ̀, ara ẹ̀ ti ṣe tán láti kojú ewu tàbí ìpèníjà náà. Tí ohun tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn náà bá ti lọ, ara èèyàn á wálẹ̀, á sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.

ÀÌBALẸ̀ ỌKÀN TÓ DÁA ÀTÈYÍ TÍ Ò DÁA

Àìbalẹ̀ ọkàn jẹ́ ọ̀nà tí ara èèyàn máa ń gbà kojú ewu tàbí ìpèníjà. Inú ọpọlọ ni àìbalẹ̀ ọkàn ti ń bẹ̀rẹ̀. Àìbalẹ̀ ọkàn tó mọ níwọ̀n máa ń mú kára èèyàn tètè ṣiṣẹ́. Àìbalẹ̀ ọkàn tó mọ níwọ̀n tún lè jẹ́ kéèyàn lé àfojúsùn rẹ̀ bá tàbí kéèyàn ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ kan. Ó lè jẹ́ nínú ìdánwò ilé ẹ̀kọ́, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò níbi téèyàn ti ń wáṣẹ́ tàbí nínú ìdíje eré ìdárayá.

Àmọ́, tí àìbalẹ̀ ọkàn bá lágbára gan-an, tí kò sì lọ bọ̀rọ̀, ó lè ṣàkóbá fún ẹ. Tí àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara bá ti pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ara rẹ á kọ̀ ọ́, inú lè máa bí ẹ, o ò sì ní lè ronú dáadáa mọ́. Ìwà rẹ lè yí pa dà, o sì lè máa kanra mọ́ àwọn èèyàn. Àìbalẹ̀ ọkàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ tún lè mú kéèyàn máa lo oògùn nílòkulò tàbí kó máa ṣe àwọn nǹkan míì tó lè pa á lára. Ó tiẹ̀ tún lè mú kéèyàn ní ìdààmú ọkàn, kó máa rẹni tẹnutẹnu tàbí kéèyàn máa ronú láti pa ara rẹ̀.

Bí àìbalẹ̀ ọkàn ṣe máa ń rí lára kálukú wa yàtọ̀, síbẹ̀ ó lè yọrí sí oríṣiríṣi àìsàn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀yà ara wa ló lè ṣàkóbá fún.

BÍ ÀÌBALẸ̀ ỌKÀN ṢE LÈ ṢÀKÓBÁ FÚN ARA RẸ

Ọpọlọ.

Ọ̀gbẹ́ni kan gbọwọ́ síwájú orí, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀.

Ọpọlọ rẹ máa ń tú àwọn kẹ́míkà kan sínú ara, irú bí adrenaline àti cortisol. Àwọn kẹ́míkà yìí ló máa ń mú kí ọkàn máa yára lù kìkì, á mú kí ẹ̀jẹ̀ ru sókè ní ìwọ̀n tó yẹ, á sì tún mú kí ṣúgà inú ara lọ sókè, gbogbo nǹkan yìí ló máa ń mú kéèyàn tètè gbé ìgbésẹ̀ téèyàn bá dojú kọ ewu. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • ìkanra, àníyàn, ìdààmú ọkàn, ẹ̀fọ́rí àti àìrí oorun sùn

Iṣan àti egungun inú ara.

Àwọn iṣan ara rẹ máa ń le kó o lè ṣe nǹkan lọ́nà tó ò fi ní ṣèṣe. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • ara ríro, ẹ̀fọ́rí tó lágbára àti iṣan tó ń fani so

Mímí sínú àti síta.

Tó o bá nílò afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó pọ̀, o gbọ́dọ̀ mí léraléra. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • mímí gúlegúle, títí kan kí àyà èèyàn máa já lódìlódì

Ọkàn.

Ọkàn rẹ máa ń yára lù kìkì kó lè pín ẹ̀jẹ̀ káàkiri gbogbo ara rẹ. Àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ máa ń tóbi sí i tàbí kí wọ́n sún kì, kí wọ́n lè darí ẹ̀jẹ̀ síbi tí ara rẹ ti nílò rẹ̀ jù lọ, irú bí iṣan ara. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • ẹ̀jẹ̀ ríru, kí ọkàn daṣẹ́ sílẹ̀ lójijì àti àrùn rọpárọsẹ̀

Àwọn kẹ́míkà inú ara.

Àwọn ohun kan nínú ara máa ń pèsè kẹ́míkà adrenaline àti cortisol tí wọ́n máa ń jẹ́ kí ara rẹ gbéjà ko àìbalẹ̀ ọkàn. Ẹ̀dọ̀ rẹ máa ń mú kí ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ pọ̀ sí i láti fún ẹ lágbára. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • ìtọ̀ ṣúgà, kí ara má lè dènà àrùn dáadáa, àìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀, híhùwà lódìlódì àti kéèyàn máa sanra sí i

Bí oúnjẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ara.

Tí ọkàn rẹ kò bá balẹ̀, ọ̀nà tí oúnjẹ gbà ń ṣiṣẹ́ lára rẹ lè dà rú. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • kí inú èèyàn máa ru, èébì, ìgbẹ́ gbuuru, kí oúnjẹ má dà

Ẹ̀yà ara ìbímọ.

Àìbalẹ̀ ọkàn lè mú kó má ṣe wu èèyàn láti ní ìbálòpọ̀, ó sì lè ṣàkóbá fún ẹ̀yà ìbímọ. Tí àìbalẹ̀ ọkàn bá pọ̀ jù, àwọn ohun tó máa ń fà rèé:

  • ẹ̀yà ìbímọ lè daṣẹ́ sílẹ̀, nǹkan oṣù lè máa ṣe ségesège

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́