ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 1 ojú ìwé 4
  • Kí Ló Ń Fa Àìbalẹ̀ Ọkàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Fa Àìbalẹ̀ Ọkàn?
  • Jí!—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àníyàn Ṣíṣe Ń Da Aráyé Ríborìbo!
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 1 ojú ìwé 4

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Kí Ló Ń Fa Àìbalẹ̀ Ọkàn?

Ilé ìwòsàn tó ń jẹ́ Mayo Clinic sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn àgbàlagbà ni ọkàn wọn kì í balẹ̀. Láyé tá a wà yìí, oríṣiríṣi àyípadà ló lè dé bá ẹnikẹ́ni.” Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àyípadà tó ń fa àìbalẹ̀ ọkàn:

  • ìkọ̀sílẹ̀

  • ikú èèyàn ẹni

  • àìsàn tó le

  • jàǹbá burúkú

  • ìwà ọ̀daràn

  • wàhálà ìgbésí ayé

  • àwọn àjálù tó dédé wáyé àti èyí táwọn èèyàn ń fà

  • ìdààmú nílé ẹ̀kọ́ àti níbi iṣẹ́

  • àníyàn nípa iṣẹ́ àti owó

TÍ IṢẸ́ BÁ BỌ́ LỌ́WỌ́ ẸNI

Ẹgbẹ́ Afìṣemọ̀rònú Nílẹ̀ Amẹ́ríkà (American Psychological Association) sọ pé: “Tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni, ó lè ba nǹkan jẹ́. Ó lè mú kí èèyàn máa ṣàìsàn, ó lè mú kí tọkọtaya má gbọ́ ara wọn yé, ó lè fa àníyàn àti ìdààmú ọkàn, ó sì lè mú kéèyàn fẹ́ pa ara ẹ̀. Bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹni, ó máa ń ṣàkóbá fún gbogbo ìgbésí ayé ẹni.”

ỌKÀN ÀWỌN ỌMỌDÉ KÌ Í BALẸ̀

Ọkàn àwọn ọmọdé pàápàá kì í balẹ̀. Wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ kan nílé ẹ̀kọ́, àwọn míì kò sì rí àbójútó nílé wọn. Wọ́n máa ń lu àwọn ọmọ míì, wọ́n ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn, wọ́n sì máa ń bá àwọn míì ṣèṣekúṣe. Ọ̀pọ̀ ọmọ máa ń ṣàníyàn nípa ìdánwò nílé ẹ̀kọ́ àti máàkì tí wọ́n gbà. Àwọn ọmọ kan tún máa ń ṣàníyàn torí pé àwọn òbí wọn kọ ara wọn sílẹ̀. Àwọn ọmọ tí ọkàn wọn ò balẹ̀ lè máa lá àlá burúkú tàbí kí wọ́n máa ṣèrànrán, wọ́n lè má pọkàn pọ̀ tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́, ìdààmú ọkàn lè bá wọn tàbí kí wọ́n má fẹ́ bá àwọn ẹgbẹ́ wọn da nǹkan pọ̀. Àwọn ọmọ kan ò tiẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè ní àmúmọ́ra. Ó gba pé ká tètè ṣèrànwọ́ fún ọmọ tó ní àìbalẹ̀ ọkàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́