ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 1 ojú ìwé 3
  • Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?
  • Jí!—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́”
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 1 ojú ìwé 3
Obìnrin kan tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ wà níbiiṣẹ́, inú rẹ̀ kò sì dùn rárá.

BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?

“Kò sẹ́ni tí ọkàn ẹ̀ balẹ̀ tán, àmọ́ ọkàn tèmi ò tiẹ̀ balẹ̀ rárá. Ìṣòro ńlá kan ṣoṣo kọ́ ló fà á, ọ̀pọ̀ nǹkan ni, lára ẹ̀ ni wàhálà ojoojúmọ́ àti bí mo ṣe ń fi ọ̀pọ̀ ọdún tọ́jú ọkọ mi tí ara rẹ̀ kò yá, tó sì tún ní àìsàn ọpọlọ.”​—Jill.a

“Ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ lọ, mo wá ń dá tọ́ àwọn ọmọ wa méjèèjì. Kò rọrùn rárá láti jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ. Iṣẹ́ tún bọ́ lọ́wọ́ mi, mi ò rówó gba àwọn ìwé ọkọ̀ mi, mi ò sì mọ ohun tí mo lè ṣe. Ìdààmú tó bá mi pọ̀ jù, mo mọ̀ pé kò dáa kí n pa ara mi, ni mo bá bẹ Ọlọ́run pé kó kúkú gbẹ̀mí mi.”​—Barry.

Bíi ti Jill àti Barry, ṣé nǹkan máa ń tojú sú ẹ, tí ọkàn ẹ kì í sì í balẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yìí máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, wọ́n á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wọ́n á tún sọ àwọn ohun tó sábà máa ń fa àìbalẹ̀ ọkàn àti àkóbá tó ń ṣe fúnni, wọ́n á sì tún sọ béèyàn ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà ìdààmú.

a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́