ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/22 ojú ìwé 4-6
  • Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́”
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìfararọ àti Ìgbékalẹ̀ Adènà Àrùn Rẹ
  • Kì Í Ṣe Okùnfà Àrùn, Kò Sì Yọni Nínú Àìsàn
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?
    Jí!—2020
  • Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?
    Jí!—2020
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/22 ojú ìwé 4-6

Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́”

“A ń gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ ní gbogbo ìgbà pé, ‘Má fi ìdààmú ṣe ara rẹ léṣe.’ Bóyá wọn kò mọ̀ pé ohun pàtàkì kan tí ó kan ìlànà àdánidá ló ń fà á.”—Dókítà David Felten.

JILL, ìyá kan tí ó jẹ́ anìkàntọ́mọ tí ó ní ọmọkùnrin ọ̀dọ́langba kan, tí owó rẹ̀ ní báńkì ń tán lọ, tí ipò ìbátan àárín òun àti àwọn òbí rẹ̀ kò sì dára, ní ìdí púpọ̀ láti ní àìfararọ. Lẹ́yìn náà, láìròtẹ́lẹ̀, apá rẹ̀ sú, ó sì ń yún un. Ó gbìyànjú oògùn agbógunti kòkòrò àrùn, àwọn ìpara olóògùn oríkèé ríroni, àti àwọn oògùn agbógunti èèwọ̀ ara, àmọ́ kò sí èyí tí ó ṣèrànwọ́ lára wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ara Jill ló sú, títí kan ojú rẹ̀. Àìfararọ ń kan án lára lójú méjèèjì.

Wọ́n gbé Jill lọ sí ilé ìwòsàn àrùn awọ ara kan tí ó máa ń ṣàyẹ̀wò ipò ìmọ̀lára ẹni tí ó ń tọ́jú. Dókítà Thomas Gragg, ọ̀kan lára àwọn tó dá ilé ìwòsàn náà sílẹ̀, sọ pé: “A máa ń gbìyànjú láti wádìí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn nínú ìgbésí ayé wọn.” Ó sábà máa ń rí i pé yàtọ̀ sí pé àwọn tí wọ́n ní ìṣòro awọ ara yíyi ní láti lo oògùn, wọ́n tún nílò ìrànlọ́wọ́ láti kápá àìfararọ. Dókítà Gragg gbà pé: “Ìtànjẹ ni yóò jẹ́ bí a bá wí pé, bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí tàbí bí o ṣe ń ṣe ló ń fa àrùn awọ ara. Ṣùgbọ́n a lè sọ pé ipò ìmọ̀lára ẹni lè kó ipa títóbi nínú àrùn awọ ara, a kò sì gbọ́dọ̀ máa kọ oògùn ìpara aleṣan fún ẹnì kan láìjẹ́ pé a tún ràn án lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ lórí àìfararọ tó wà nínú ìgbésí ayé rẹ̀.”

Jill lérò pé kíkọ́ láti kápá àìfararọ lójú méjèèjì ló dáàbò bo awọ ara òun. Ó sọ pé: “Mo ṣì ń nímọ̀lára àìbalẹ̀ ara, ṣùgbọ́n awọ ara mi kò burú tó bó ṣe rí tẹ́lẹ̀.” Ọ̀ràn tí kò wọ́pọ̀ ha lèyí bí? Ó tì o. Ọ̀pọ̀ dókítà gbà gbọ́ pé àìfararọ sábà máa ń jẹ́ okùnfà kan nínú oríṣiríṣi ìṣòro àrùn àwọ ara, títí kan ìléròrò, èépá, rorẹ́, àti ifo. Ṣùgbọ́n awọ ara rẹ nìkan kọ́ ni àìfararọ lè ṣe nǹkan fún.

Àìfararọ àti Ìgbékalẹ̀ Adènà Àrùn Rẹ

Ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé àìfararọ lè tẹ ìgbékalẹ̀ adènà àrùn rẹ rì, tí ó sì lè mú kí o ní àwọn àrùn àkóràn bíi mélòó kan. Onímọ̀ nípa fáírọ́ọ̀sì náà, Ronald Glaser, sọ pé: “Àìfararọ kì í jẹ́ kí o ṣàìsàn. Ṣùgbọ́n ó ń mú kí ewu àtiṣàìsàn rẹ pọ̀ sí i nítorí ohun tí ó ń ṣe fún ìgbékalẹ̀ adènà àrùn rẹ.” Ní pàtàkì, ẹ̀rí tí ó dáni lójú wà tí ń so àìfararọ pọ̀ mọ́ ọ̀fìnkìn, àrùn gágá, àti àrùn herpes. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni a máa ń ṣíra pa yá sí irú àwọn fáírọ́ọ̀sì bẹ́ẹ̀, ìgbékalẹ̀ adènà àrùn wa sábà máa ń bá wọn jà. Ṣùgbọ́n àwọn ògbógi kan sọ pé, bí ẹnì kan bá wà nínú wàhálà ìmọ̀lára, àwọn odi ìgbèjà wọ̀nyí lè ṣàìgbéṣẹ́.

A kò tí ì lóye kíkún nípa ìlànà àdánidá tí ó rọ̀ mọ́ ọn, ṣùgbọ́n àwọn kan sọ àbá èrò orí pé àwọn omi ìsúnniṣe tí ń múra rẹ sílẹ̀ láti hùwà padà tí àìfararọ bá kì ọ́ mọ́lẹ̀ lè ṣèdíwọ́ fún ìṣiṣẹ́ ìgbékalẹ̀ adènà àrùn rẹ bí wọ́n ṣe ń lọ sókè sódò nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Bí ó ti sábà máa ń rí, èyí kì í ṣe okùnfà àníyàn, níwọ̀n bí iṣẹ́ àwọn omi ìsúnniṣe wọ̀nyí ti jẹ́ fún ìgbà kúkúrú. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan sọ pé bí ẹnì kan bá ní àìfararọ tí kò dáwọ́ dúró, tí ó sì le, ó lè sọ ìgbékalẹ̀ adènà àrùn rẹ̀ di aláìgbéṣẹ́mọ́ débi pé àìsàn lè tètè ṣe é.

Èyí lè ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé ìdí tí àwọn dókítà ilẹ̀ Kánádà fi fojú díwọ̀n pé nǹkan bí ìpín 50 sí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn aláìsàn tí wọ́n ń wá rí àwọn ni àrùn wọn tan mọ́ àìfararọ, tí ó jẹ́ irú èyí tó kan ẹ̀fọ́rí, àìróorunsùn-tó, àárẹ̀, àti inú rírun. Ní United States, a fojú díwọ̀n iye náà sí àárín ìpín 75 sí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún. Dókítà Jean King lérò pé òun kò sàsọdùn nígbà tí òun sọ pé: “Àìfararọ tí ó ti di bárakú dà bí ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́.”

Kì Í Ṣe Okùnfà Àrùn, Kò Sì Yọni Nínú Àìsàn

Bí ohun tí a ń sọ bọ̀ bá tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò dá àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lójú bóyá àìfararọ nìkan lè nípa lórí ìgbékalẹ̀ adènà àrùn tó láti mú ìyípadà pàtàkì kan wá nínú ipò àìlera ẹnì kan. Nípa bẹ́ẹ̀, a kò lè sọ láìsí ẹ̀rí tí ó dájú pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ìṣòro àìfararọ, kódà tí ó bá ti di bárakú pàápàá, yóò ní àrùn kan. Lọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání, a kò lè sọ pé bí ẹnì kan kò bá ní ìṣòro àìfararọ, ìdánilójú wà pé ara rẹ̀ yóò yá gágá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì bọ́gbọ́n mu láti kọ ìtọ́jú ìṣègùn látàrí èrò àṣìlóye pé àìsàn yóò lọ tí a bá ní ẹ̀mí pé nǹkan-yóò-dára àti ìrònú títọ̀nà. Dókítà Daniel Goleman kìlọ̀ pé: “Àbáyọrí èrò pé ìṣarasíhùwà ẹni yóò woni sàn yìí ti yọrí sí dídá ìdàrúdàpọ̀ àti àṣìlóye tí ó tàn kálẹ̀ sílẹ̀ nípa àyè tí èrò inú lè nípa lórí àìsàn dé, àti, bóyá èyí tí ó burú jù lọ, nígbà mìíràn láti mú kí àwọn ènìyàn nímọ̀lára ẹ̀bi fún níní àrùn kan, bíi pé ó jẹ́ àmì ìrélànà ìwà rere kọjá lọ́nà kan tàbí àìjámọ́ǹkan nípa tẹ̀mí.”

Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a kò lè fìgbà gbogbo sọ pé ohun kan ṣoṣo ló ń fa àìsàn kan. Síbẹ̀, ìsopọ̀ tó wà láàárín àìfararọ àti àìsàn ṣàlàyé ọgbọ́n tí ó wà nínú kíkọ́ bí a ṣe lè dín agbára “ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́” yìí kù nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe.

Kí a tó ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè ṣe èyí, jẹ́ kí a wo bí àìfararọ ṣe rí kínníkínní àti bí ó tilẹ̀ ṣe lè ṣàǹfààní fún ọ nínú àwọn ọ̀ràn kan.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Àìlera Díẹ̀ Tí A Ti So Pọ̀ Mọ́ Àìfararọ

• àwọn èèwọ̀ ara

• oríkèé ríro

• ikọ́ fée

• ẹ̀yìn, ọrùn, àti èjìká ríro

• ọ̀fìnkìn

• ìsoríkọ́

• ìgbẹ́ gbuuru

• àrùn gágá

• inú rírun

• ẹ̀fọ́rí

• àrùn ọkàn-àyà

• àìróorunsùn-tó

• túúlu

• ọgbẹ́ inú

• àbùkù agbára ìbálòpọ̀

• àrùn awọ ara

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Púpọ̀ àwọn tí wọ́n ń wá rí dókítà ló jẹ́ nítorí àìfararọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́